Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì

 Ẹ̀KỌ́ 65

Ẹ́sítérì Gba Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Nínú Ewu

Ẹ́sítérì Gba Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Nínú Ewu

Júù ni Ẹ́sítérì, ìlú Ṣúṣánì tó wà ní ilẹ̀ ọba Páṣíà ló sì ń gbé. Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, Nebukadinésárì kó ìdílé Ẹ́sítérì kúrò ní Jerúsálẹ́mù. Ìbátan Ẹ́sítérì kan tó ń jẹ́ Módékáì ló sì tọ́ ọ dàgbà. Módékáì jẹ́ ìránṣẹ́ Ọba Ahasuwérúsì ti ilẹ̀ Páṣíà.

Ọba Ahasuwérúsì fẹ́ ní ayaba tuntun. Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ mú àwọn arẹwà obìnrin tó wà ní ìlú náà wá fún ọba, Ẹ́sítérì náà sì wà lára wọn. Nínú gbogbo wọn, Ẹ́sítérì ni ọba yan láti jẹ́ ayaba. Àmọ́, Módékáì sọ fún Ẹ́sítérì pé kó má sọ fún ẹnikẹ́ni pé Júù ni òun.

Ọkùnrin agbéraga kan tó ń jẹ́ Hámánì ni olórí àwọn ọmọ aládé. Ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn máa tẹrí ba fún òun. Ṣùgbọ́n Módékáì kò ṣe bẹ́ẹ̀, torí náà, inú bí Hámánì débi pé ó fẹ́ láti pa á. Nígbà tí Hámánì gbọ́ pé Júù ni Módékáì, ó wá ọ̀nà láti pa gbogbo àwọn Júù tó wà ní ilẹ̀ náà. Hámánì sọ fún ọba pé: ‘Èèyàn burúkú ni àwọn Júù, àfi kí o pa wọ́n danù.’ Ahasuwérúsì wá sọ pé: ‘Ohun tó bá wù ẹ́ ni kó o ṣe fún wọn,’ ó sì fún Hámánì lágbára láti ṣe òfin. Hámánì wá ṣe òfin pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn Júù ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù Ádárì. Àmọ́ Jèhófà ń rí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí.

Ẹ́sítérì kò gbọ́ nípa òfin yìí. Módékáì wá fi ẹ̀dà ìwé òfin náà ránṣẹ́ sí i, ó sì sọ pé: ‘Lọ bá ọba sọ̀rọ̀.’ Ẹ́sítérì ní: ‘Wọ́n máa pa ẹnikẹ́ni tó bá lọ bá ọba láìjẹ́ pé ọba pè é. Ó ti tó ọgbọ̀n [30] ọjọ́ báyìí tí ọba ti pè mí kẹ́yìn! Àmọ́ mo máa lọ. Tí ọba bá na ọ̀pá àṣẹ sí mi, wọ́n kò ní pa mí. Ṣùgbọ́n tí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n máa pa mí.’

Ẹ́sítérì lọ sí ààfin ọba. Nígbà tí ọba rí i, ó na ọ̀pá aládé wúrà rẹ̀ sí i. Ẹ́sítérì sì wọlé lọ bá a, ọba wá béèrè pé: ‘Kí lo fẹ́  kí n ṣe fún ẹ, Ẹ́sítérì?’ Ó dáhùn pé: ‘Mo fẹ́ kí ẹ̀yin àti Hámánì wá síbi àsè kan.’ Níbi àsè náà, Ẹ́sítérì tún pè wọ́n síbi àsè míì. Ibi àsè kejì yìí ni ọba tún ti béèrè pé: ‘Kí lo fẹ́ kí n ṣe fún ẹ?’ Ẹ́sítérì sọ pé: ‘Ẹnì kan fẹ́ pa èmi àti àwọn èèyàn mi. Jọ̀wọ́ gbà wá.’ Ọba béèrè pé: ‘Ta ló fẹ́ pa yín?’ Ó ní: ‘Hámánì ọkùnrin burúkú yìí ni.’ Ahasuwérúsì bínú gan-an débi pé ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló ní kí wọ́n lọ pa Hámánì.

Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tó lè yí òfin tí Hámánì ṣe pa dà, kódà ọba pàápàá kò lè yí i pa dà. Torí náà, ọba fi Módékáì jẹ olórí àwọn ọmọ aládé, ó sì fún un lágbára láti ṣe òfin tuntun míì. Ó ṣòfin pé kí àwọn Júù gbèjà ara wọn tí wọ́n bá gbéjà kò wọ́n. Ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù Ádárì, àwọn Júù ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn. Láti ìgbà yẹn lọ, ọdọọdún ni wọ́n máa ń ṣe àjọyọ̀ ìṣẹ́gun náà.

“Wọn yóò fà yín lọ síwájú àwọn gómìnà àti àwọn ọba nítorí mi, láti ṣe ẹ̀rí fún wọn àti fún àwọn orílẹ̀-èdè.”​—Mátíù 10:18