Jèhófà ni Ọba tó ju ọba lọ. Láti ìbẹ̀rẹ̀ títí di òní, òun ló ń darí ohun gbogbo, òun lá sì máa darí ohun gbogbo títí láé. Bí àpẹẹrẹ, ó dáàbò bo Jeremáyà kó má bàa kú. Ó tún gba Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò nínú iná tó ń jó lala, òun náà ló sì gba Dáníẹ́lì lọ́wọ́ àwọn kìnnìún. Jèhófà tún dáàbò bo Ẹ́sítérì kó lè gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀. Èyí jẹ́ ká rí i pé Jèhófà kò ní jẹ́ kí àwọn èèyàn máa hùwà ìkà títí lọ. Jèhófà fi ìran nípa ère ńlá kan àti igi ńlá kan sọ àsọtẹ́lẹ̀. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà sì jẹ́ ká mọ̀ pé Ìjọba Jèhófà máa tó pa àwọn èèyàn búburú, ó sì máa jọba lórí ayé.