Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 1

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 1

Ohun tó bẹ̀rẹ̀ Bíbélì ni ìtàn bí Jèhófà ṣe dá gbogbo nǹkan, ó jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tó rẹwà tí Jèhófà dá ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé. Tí o bá jẹ́ òbí, jẹ́ kí ọmọ rẹ rí oríṣiríṣi nǹkan tí Ọlọ́run dá. Jẹ́ kó rí i pé Ọlọ́run fún wa ní ọgbọ́n tó ju ti àwọn ẹranko lọ. Bí àpẹẹrẹ, àwa lè sọ̀rọ̀, a lè ronú, a lè ṣe nǹkan, a lè kọrin, a tún lè gbàdúrà. Bákan náà, jẹ́ kó mọrírì agbára àti ọgbọ́n tí Jèhófà ní, kí o sì jẹ́ kó rí i pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ gbogbo nǹkan tó dá títí kan gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.

NÍ APÁ YÌÍ

Ọlọ́run Dá Ọ̀run àti Ayé

Bíbélì sọ pé Ọlọ́run dá ọ̀run àti ayé. Àmọ́ ṣe o mọ áńgẹ́lì tí Jèhófà kọ́kọ́ dá kó tó dá gbogbo nǹkan mí ì?

Ọlọ́run Dá Ọkùnrin àti Obìnrin Àkọ́kọ́

Ọlọ́run dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, ó sì fi wọ́n sínú ọgbà Édẹ́nì. Ó fẹ́ kí wọ́n bímọ, kí wọ́n sì sọ gbogbo ilẹ̀ ayé di Párádísè.