Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì

Ìwé yìí máa ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ látìgbà ìṣẹ̀dá tí Bíbélì sọ títí dé ìgbà tí wọ́n bí Jésù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, wàá sì tún kọ́ nípa àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ títí dìgbà tí Ìjọba náà máa dé.

Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Báwo la ṣe lè lo ìwé yìí?

Ọlọ́run Dá Ọ̀run àti Ayé

Bíbélì sọ pé Ọlọ́run dá ọ̀run àti ayé. Àmọ́ ṣe o mọ áńgẹ́lì tí Jèhófà kọ́kọ́ dá kó tó dá gbogbo nǹkan mí ì?

Ọlọ́run Dá Ọkùnrin àti Obìnrin Àkọ́kọ́

Ọlọ́run dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, ó sì fi wọ́n sínú ọgbà Édẹ́nì. Ó fẹ́ kí wọ́n bímọ, kí wọ́n sì sọ gbogbo ilẹ̀ ayé di Párádísè.

Ádámù àti Éfà Ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run

Kí ló mú kí igi kan dá yàtọ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì? Kí nìdí tí Éfà fi jẹ́ èso igi náà?

Kéènì Bínú Pa Àbúrò Rẹ̀

Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ẹ̀bọ́ Ébẹ́lì àmọ́ kò gba ti Kéènì. Nígbà tí Kéènì rí ohun tó ṣẹlẹ̀, inú bí i, ó sì hùwà búburú kan.

Nóà Kan Áàkì

Nígbà táwọn áńgẹ́lì burúkú kan fẹ́ àwọn obìnrin tó wà láyé, wọ́n bí àwọn ọmọ tó lágbára, tó sì máa ń fìyà jẹ àwọn èèyàn. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń hùwà burúkú. Àmọ́ Nóà yátọ̀ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ó sì máa ń ṣègbọràn sí i.

Èèyàn Mẹ́jọ La Ìparun Já

Òjò rọ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru. Ó ju ọdún kan lọ ti Nóà àti ìdílé rẹ̀ fi wà nínú áákì náà. Nígbà tó yá, wọ́n jáde kúrò nínú rẹ̀.

Ilé Gogoro Bábélì

Àwọn èèyàn fẹ́ kọ́ ilé gogoro kan tí ó máa ga dé ọ̀run. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi da èdè wọn rú?

Ábúráhámù àti Sárà Ṣègbọràn sí Ọlọ́run

Kí ló mú kí Ábúráhámù àti Sárà fi ìlú wọn sílẹ̀ láti lọ máa gbé nínú àgọ́ nílẹ̀ Kénáánì?

Sárá Bímọ Nígbà Tó Di Arúgbó!

Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa mú ìlérí tó ṣe fún Ábúráhámù ṣẹ? Ṣé ìpasẹ̀ Ísákì ni tàbí Íṣímáẹ́lì?

Rántí Ìyàwó Lọ́ọ̀tì

Ọlọ́run mú kí iná àti imí ọjọ́ rọ̀ sórí ìlú Sódómù àti Gòmórà. Kí ló dé tí Ọlọ́run fi pa àwọn ìlú yẹn run? Kí nìdí tó fi yẹ ká rántí ìyàwó Lọ́ọ̀tì?

Ọlọ́run Dán Ìgbàgbọ́ Ábúráhámù Wò

Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù pé: ‘Jọ̀ọ́, mú ọmọ kan ṣoṣo tí o ní, ẹ jọ lọ sí orí òkè kan ní Móráyà kí o sì fi ọmọ náà rúbọ.’ Báwo ni Ábúráhámù ṣe máa kojú ìdánwò ìgbàgbọ́ yìí?

Jékọ́bù Rí Ogún Gbà

Ísákì àti Rèbékà bí ìbejì, wọ́n sì sọ wọ́n ní Ísọ̀ àti Jékọ́bù. Torí pé Ísọ̀ ní àkọ́bí, òun ló yẹ kó gba ogún ìdílé wọn. Kí nìdí tó fi sọ ogún yẹn nù torí oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan péré?

Jékọ́bù àti Ísọ̀ Parí Ìjà Wọn

Kí ni Jékọ́bù ṣe tó fi rí ìbùkún gbà lọ́dọ̀ áńgẹ́lì kan? Báwo ni òun àti Ísọ̀ ṣe parí ìjà wọn?

Ẹrú Tó Ṣègbọràn sí Ọlọ́run

Jósẹ́fù ṣe ohun tó tọ́ ṣùgbọ́n ó jìyà gan an. Kí ló dé?

Jèhófà Kò Gbàgbé Jósẹ́fù

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jósẹ́fù jìnnà sáwọn ẹbí rẹ̀, Jèhófà dúró tì í.

Ta Ni Jóòbù?

Ó ṣègbọràn sí Jèhófà kódà nígbà tó ní ìṣòro.

Mósè Pinnu Láti Jọ́sìn Jèhófà

Ohun tí màmá Mósè ṣe ló gba ẹ̀mí Mósè là ní kékeré.

Iná Ń Jó Lára Igi Kékeré Kan

Kí ló dé tí iná yẹn kò fi jó igi náà run?

Ìyọnu Mẹ́ta Àkọ́kọ́

Fáráò fa àjálù bá àwọn èèyàn rẹ̀ torí pé ó jẹ́ agbéraga.

Àwọn Ìyọnu Mẹ́fà Tí Ó Tẹ̀ Lé E

Báwo ni àwọn ìyọnu mẹ́fà yìí ṣe yàtọ̀ sí mẹ́ta àkọ́kọ́?

Ìyọnu Kẹwàá

Ìyonu yìí burú débi pé ara Fáráò kò lè gbà á, ó sì dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀.

Iṣẹ́ Ìyanu ní Òkun Pupa

Fáráò la àwọn ìyọnu mẹ́wàá já, àmọ́ ṣé ó ye iṣẹ́ ìyanu tí Ọlọ́run ṣe yìí?

Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 5

Ní Òkè Sínáì, Ọlọ́run bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú pé wọ́n máa jẹ́ èèyàn òun, ó sì bójú tó wọn kódà nígbà tí wọ́n ṣàṣìṣe.

Wọ́n Ṣèlérí fún Jèhófà

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣèlérí kan fún Ọlọ́run nígbà tí wọ́n wà ní Òkè Sínáì.

Wọn Kò Mú Ìlérí Wọn Ṣẹ

Nígbà tí Mósè lọ gba òfin mẹ́wàá náà lórí òkè, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì hùwà burúkú.

Wọ́n Kọ́ Àgọ́ Ìjọsìn

Inú àgọ́ pàtàkì yìí ni apótí májẹ̀mú wà.

Àwọn Amí Méjìlá

Jóṣúà àti Kálébù yàtọ̀ sáwọn ọkùnrin mẹ́wàá tó kù tí wọ́n rán lọ ṣe amí ilẹ̀ Kénáánì.

Wọ́n Tako Jèhófà

Kórà, Dátánì, Ábírámù àti àwọn 250 mí ì kò mọ òtítọ́ pàtàkì kan nípa Jèhófà.

Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Báláámù Sọ̀rọ̀

Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà rí ẹnì kan tí Báláámù kò lè rí.

Jèhófà Yan Jóṣúà

Ọlọ́run fún Jóṣúà ní àwọn ìtọ́ni tó ṣàǹfààní fáwa náà lónìí.

Ráhábù Fi Àwọn Amí Pa Mọ́

Ògiri Jẹ́ríkò wó lulẹ̀. Àmọ́ ilé Ráhábù dúró bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara ògiri yẹn ni wọ́n kọ́ ọ mọ́.

Joshua and the Gibeonites

Jóṣúà gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Oòrùn, dúró sójú kan!” Ǹjẹ́ Ọlọ́run gbọ́ àdúrà rẹ̀?

Aṣáájú Tuntun àti Obìnrin Onígboyà Méjì

Lẹ́yìn tí Jóṣúà kú, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn àwọn òrìṣà. Àwọn ọ̀tá wá ni wọ́n lára, àmọ́ Ọlọ́run ràn wọ́n lọ́wọ́ nípasẹ̀ Bárákì, Dèbórà tó jẹ́ wòlí ì àti Jáẹ́lì.

Rúùtù àti Náómì

Àwọn obìnrin méjì tí ọkọ wọn ti kú pa dà sí Ísírélì. Ọ̀kan tó ń jẹ́ Rúùtù lọ ṣiṣẹ́ ní oko, Bóásì sì ṣàkíyèsí rẹ̀.

Gídíónì Ṣẹ́gun Àwọn Ará Mídíánì

Nígbà táwọn ará Mídíánì fayé ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lára, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́. Báwo làwọn ọmọ ogun Gídíónì ṣe ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá 135,000?

Hánà Gbàdúrà Pé Kí Ọlọ́run Fún Òun ní Ọmọkùnrin

Ẹlikénà mú Hánà, Pẹ̀nínà àtàwọn ọmọ rẹ̀ lọ jọ́sìn ní àgọ́ ìjọsìn ní Ṣílò. Níbẹ̀, Hánà gbàdúrà fún ọmọkùnrin. Lẹ́yìn ọdún kan, ó bí Sámúẹ́lì.

Ìlérí Tí Jẹ́fútà Ṣe

Ìlérí wo ni Jẹ́fútà ṣe, kí sì nìdí? Kí ni ọmọbìnrin Jẹ́fútà ṣe nígbà tó gbọ́ nípa ìlérí bàbá rẹ̀?

Jèhófà Bá Sámúẹ́lì Sọ̀rọ̀

Élì Àlùfáà Àgbà ní ọmọkùnrin méjì tó ń sìn ní àgọ́ ìjọsìn, àmọ́ wọn kò pa òfin Ọlọ́run mọ́. Sámúẹ́lì yàtọ̀ ní tirẹ̀. Lálẹ́ ọjọ́ kan, Jèhófà bá Sámúẹ́lì sọ̀rọ̀.

Jèhófà Sọ Sámúsìnì Di Alágbára

Ọlọ́run mú kí Sámúsìnì lágbára láti bá àwọn Filísínì jà. Sámúsìnì wá ṣèpinnu tí kò dára, àwọn Filísínì sì mú un.

Ọba Àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì

Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní àwọn onídàájọ́, àmọ́ wọ́n béèrè fún ọba. Sámúẹ́lì yan Sọ́ọ̀lù gẹ́gẹ́ bí ọba àkọ́kọ́, àmọ́ nígbà tó yá, Jèhófà kọ̀ ọ́ lọ́ba. Kí nìdí?

Dafidi ati Golayati

Jèhófà yan Dáfídì láti jẹ oba tó kàn ní Ísírẹ́lì, ìwà Dáfídì fi hàn pé ọba tọ́ sí i.

Dáfídì àti Sọ́ọ̀lù

Kí nìdí tí ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin yìí fi kórìíra ìkejì, báwo ni ìkejì yìí ṣe hùwà sí èyí tó kórìíra rẹ̀?

Jónátánì Láyà, Ó sì Jẹ́ Adúrótini

Jónátánì tó jẹ́ ọmọ ọba di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ Dáfídì.

Ọba Dáfídì Dá Ẹ̀ṣẹ̀

Àṣìṣe kan tó fa ọ̀pọ̀ wàhálà.

Wọ́n Kọ́ Tẹ́ńpìlì fún Jèhófà

Ọlọ́run gbọ́ àdúrà Sólómọ́nì, ó sì fún un ní àwọn nǹkan dáradára.

Ìjọba Ísírẹ́lì Pín sí Méjì

Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò sin Jèhófà mọ́.

Ìṣẹ̀lẹ̀ kan Lórí Òkè Ńlá Kámẹ́lì

Ta ni Ọlọ́run tòótọ́? Jèhófà ni àbí Báàlì?

Jèhófà Fún Èlíjà Lókun

Ǹjẹ́ o rò pé ó lè fún ìwọ náà lókun?

Ọmọkùnrin Opó kan Jíǹde

Iṣẹ́ ìyanu méjì ṣẹlẹ̀ nínú ilé kan!

Ọlọ́run Fìyà Jẹ Ayaba Búburú Kan

Jésíbẹ́lì gbìmọ̀ láti pa ọmọ Ísírẹ́lì kan tó ń jẹ́ Nábọ́tì kó lè gba ọgbà àjàrà rẹ̀! Jèhófà Ọlọ́run rí ìwà ìkà àti ìwà ìrẹ́jẹ yẹn.

Jèhófà Gbèjà Jèhóṣáfátì

Ọba Jèhóṣáfátì gbàdúrà sí Ọlọ́run nígbà táwọn ọ̀tá gbógun ti ilẹ̀ Júdà.

Jagunjagun àti Ọmọbìnrin Kékeré Kan

Ọmọbìnrin Ísírẹ́lì kan sọ fún ìyàwó ọ̀gá rẹ̀ nípa agbára Jèhófà, wọ́n sì rí agbára Jèhófà lóòótọ́.

Àwọn Ọmọ Ogun Jèhófà

Bí ìránṣẹ́ Èlíṣà ṣe wá mọ̀ pé ‘àwọn tó wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tó wà pẹ̀lú wọn.’

Jèhóádà Kò Bẹ̀rù

Àlùfáà olóòótọ́ kan ko ayaba búburú lójú.

Jèhófà Ní Sùúrù fún Jónà

Báwo lo ṣe di pé ẹja ńla gbé ìránṣẹ́ Ọlọ́run mì? Báwo lo ṣe jáde? Ẹ̀kó wo ni Jèhófà kọ́ ọ?

Áńgẹ́lì Jèhófà Dáàbò Bo Hesekáyà

Àwọn ọ̀tá Júdà sọ pé Jèhófà kò ní dáàbò bo àwon èèyàn rẹ̀, àmọ́ irọ́ ni wọ́n pa!

Jòsáyà Fẹ́ràn Òfin Ọlọ́run

Jòsáyà di ọba nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mẹ́jọ, ó sì ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa jọ́sìn Jèhófà.

Jèhófà Rán Jeremáyà Pé Kó Lọ Wàásù

Ohun tí wòlí ì ọ̀dọ́ yìí sọ múnú bí àwọn àgbààgbà ìlú.

Wọ́n Pa Jerúsálẹ́mù Run

Àwọn èèyàn Júdà ò jáwọ́ nínú ìsìn èké, torí náà Jèhófà pa wọ́n tì.

Ọ̀dọ́kùnrin Mẹ́rin Ṣègbọràn sí Jèhófà

Àwọn ọ̀dọ́ kan láti Júdà pinnu láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, kódà nígbà tí wọ́n wà ní ààfin ọba Bábílónì.

Ìjọba kan Tó Máa Wà Títí Láé

Dáníẹ́lì ṣàlàyé ohun tí àlá Nebukádinésárì túmọ̀ sí.

Wọn Kò Tẹrí Ba

Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbédínígò kò tẹrí ba fún ère wúrà tí ọba Bábílónì gbé kalẹ̀

Ìjọba kan Tó Dà Bí Igi Ńlá

Àlá Nebukadinésárì sọ nipa ọjọ́ iwájú òun fúnra rẹ̀

Ọ̀rọ̀ Tó Hàn Lára Ògiri

Ìgbà wo ni ọ̀rọ̀ àjèjì bẹ̀rẹ̀ sí í fara hàn, kí ló sì túmọ̀ sí?

Wọ́n Ju Dáníẹ́lì Sínú Ihò Kìnnìún

Gbàdúrà sí Jèhófà lójoojúmọ́, gẹ́gẹ́ bí Dáníẹ́lì ti ṣe.

Ẹ̀KỌ́ 65

Ẹ́sítérì Gba Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Nínú Ewu

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àjèjì ni, ó sì jẹ́ ọmọ òrukàn, ó di ayaba.

Ẹ̀KỌ́ 66

Ẹ́sírà Kọ́ Àwọn Èèyàn ní Òfin Ọlọ́run

Lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fetí sí Ẹ́sírà, wọ́n ṣe ìlérí pàtàkì kan fún Ọlọ́run.

Ẹ̀KỌ́ 67

Ògiri Jerúsálẹ́mù

Nehemáyà gbọ́ pé àwọn ọ̀tá fẹ́ gbéjà kò wọ́n. Kí nìdí tí kò fi bẹ̀rù?

Ẹ̀KỌ́ 68

Èlísábẹ́tì Bí Ọmọ Kan

Kí nìdí tí áńgẹ́lì náà fi sọ fún ọkọ Èlísábẹ́tì pé kò ní lè sọ̀rọ̀ títí wọ́n á fi bí ọmọ náà?

Ẹ̀KỌ́ 69

Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì Lọ Sọ́dọ̀ Màríà

Ó fún un ní ìròyìn tó yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà.

Ẹ̀KỌ́ 70

Àwọn Áńgẹ́lì Kéde Pé Wọ́n Bí Jésù

Àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó gbọ́ ìkéde náà gbéra lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Ẹ̀KỌ́ 71

Jèhófà Dáàbò Bo Jésù

Ọba búburú kan fẹ́ pa Jésù.

Ẹ̀KỌ́ 72

Nígbà Tí Jésù Wà ní Ọmọdé

Kí ló ṣe tó ya àwọn olùkọ́ inú tẹ́ńpìlì lẹ́nu?

Jòhánù Múra Àwọn Èèyàn Sílẹ̀

Jòhánù sì dàgbà di wòlí ì. Ó kọ́ àwọn èèyàn pé Mèsáyà ń bọ̀. Kí làwọn èèyàn ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀?

Jésù Di Mèsáyà

Kí ni Jòhánù ní lọ́kàn nígbà tó pe Jésù ní Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run?

Èṣù Dán Jésù Wò

Ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Èṣù dán Jésù wò. Kí làwọn ìdẹwò mẹ́ta náà? Báwo ni Jésù ṣe dáhùn pa dà?

Jésù Lé Àwọn Tó Ń Tajà Nínú Tẹ́ńpìlì

Kí nìdí tí Jésù fi lé àwọn ẹran tó wà nínú tẹ́ńpìlì tó sì da tábìlì àwọn tó ń ṣẹ́ owó nù?

Obìnrin kan Wá Pọn Omi Nínú Kànga

Ẹnu ya obìnrin ará Samáríà kan pé Jésù bá òun sọ̀rọ̀. Kí nìdí? Kí ni Jésù sọ fún un tó jẹ́ pé kò sọ fún ẹlòmí ì rí?

Jésù Wàásù Nípa Ìjọba Ọlọ́run

Jésù sọ pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun wá di “apẹja ènìyàn.” Nígbà tó yá, ó kọ́ àádọ́rin lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bí wọ́n á ṣe máa wàásù ìhìn rere náà.

Jésù Ṣe Ọ̀pọ̀ Iṣẹ́ Ìyanu

Gbogbo ibi tó bá lọ làwọn aláìsàn máa ń wá bá a kó lè wò wọ́n sàn. Ó tiẹ̀ jí ọmọbìnrin kan tó ti kú dìde.

Jésù Yan Àwọn Àpọ́sítélì Méjìlá

Kí ló dé tó fi yàn wọ́n? Ǹjẹ́ o rántí orúkọ wọn?

TÌwàásù Lórí Òkè

Jésù kọ́ àwọn èèyàn tó péjọ ní àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì kan.

Jésù Kọ́ Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Rẹ̀ Bí Wọ́n Á Ṣe Máa Gbàdúrà

Àwọn nǹkan wo ni Jésù ní kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa béèrè?

Jésù Fún Àwọn Èèyàn Púpọ̀ ní Oúnjẹ

Kí ni iṣẹ́ ìyanu yìí jẹ́ ká mọ̀ nípa Jésù àti Jèhófà?

Jésù Rìn Lórí Omi

Ǹjẹ́ o lè fọkàn yàwòrán bó ṣe máa rí lára àwọn àpọ́sítélì lẹ́yìn tí wọ́n rí iṣẹ́ ìyanu yìí?

Jésù Wo Ẹnì Kan Sàn Lọ́jọ́ Sábáàtì

Kí nìdí tí inú gbogbo èèyàn ò ṣe dùn sí ohun tí Jésù ṣe?

Jésù Jí Lásárù Dìde

Nígbà tí Jésù rí i tí Màríà ń sunkún, òun náà bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. Àmọ́ ẹkún wọn dayọ̀ lẹ́yìn-ò-rẹyìn.

Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa

Jésù fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ní àwọn ìtọ́ni pàtàkì kan nígbà tí wọ́n ń jẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa.

Wọ́n Mú Jésù

Júdásì Ísíkáríótùṣáájú àwọn èrò rẹpẹtẹ tó mú idà àti igi dání láti wá mú Jésù.

Pétérù Sọ Pé Òun Ò Mọ Jésù Rí

Kí ló ṣẹlẹ̀ nínú ọgbà ilé Káyáfà? Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Jésù nínú ilé yẹn?

Wọ́n Pa Jésù ní Gọ́gọ́tà

Kí nìdí tí Pílátù fi pàṣẹ pé kí wọ́n pa Jésù?

Jésù Jíǹde

Nǹkan ìyanu wo ló ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn tí wọ́n pa Jésù?

Jésù Fara Han Àwọn Apẹja

Nǹkan ìyanu wo ni Jésù ṣe tó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun ni?

Jésù Pa Dà sí Ọ̀run

Kó tó ṣe bẹ́ẹ̀, ó fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láwọn ìtọ́ni pàtàkì kan.

Àwọn Ọmọlẹ́yìn Jésù Gba Ẹ̀mí Mímọ́

Nǹkan ìyanu wo ni ẹ̀mí mímọ́ mú kí wọ́n ṣe?

Kò Sí Ohun Tó Lè Dá Wọn Dúró

Àwọn aṣáájú ìsìn tó pa Jésù ń wá bí wọ́n á ṣe dá iṣẹ́ ìwàásù àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù dúró. Àmọ́ wọn ò rí i ṣe.

Jésù Yan Sọ́ọ̀lù

Ọ̀tá àwọn Kristẹni ni Sọ́ọ̀lù, àmọ́ nǹkan máa tó yí pa dà.

Kọ̀nílíù Gba Ẹ̀mí Mímọ́

Kí nìdí tí Ọlọ́run fi rán Pétérù lọ sílé ọkùnrin tí kì í ṣe Júù?

Ẹ̀sìn Kristẹni Dé Ọ̀pọ̀ Orílẹ̀-Èdè

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò mú ìhìn rere lọ sáwọn ìlú tó jìnnà.

Ẹ̀ṣọ́ Ọgbà Ẹ̀wọ̀n kan Gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Ẹ máa kà nípa ẹ̀mí èṣù kan, ìmìtìtì ilẹ̀ àti idà kan nínú ìtàn yìí?

Pọ́ọ̀lù àti Tímótì

Àwọn méjèèjì jọ ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ àti arákùnrin fún ọ̀pọ̀ ọdún.

Wọ́n Gbé Pọ́ọ̀lù Lọ sí Róòmù

Ewu pọ̀ lójú ọ̀nà, ṣùgbọ́n kò sóhun tó lè dá àpọ́sítélì yìí dúró.

Ìran Tí Jòhánù Rí

Jésù fi àwọn ìran nípa ọjọ́ iwájú hàn án.

“Kí Ìjọba Rẹ Dé”

Jòhánù rí ìran nípa bí Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa tún ayé yìí ṣe.