Ṣé o rò pé . . .

  • Ọlọ́run ni?

  • àbí àwọn èèyàn?

  • àbí ẹlòmíì kan?

 OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Gbogbo ayé patapata wà lábẹ́ Èṣù.”—1 Jòhánù 5:19.

“Ọmọ Ọlọ́run . . . wá, kí ó lè pa àwọn iṣẹ́ Èṣù run.”—1 Jòhánù 3:8, Ìròyìn Ayọ̀.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ BÍBÉLÌ YẸN LÈ ṢE FÚN Ẹ

Á jẹ́ kó o mọ àlàyé tó bọ́gbọ́n mu nípa ohun tó fa ìṣòro tó kún inú ayé yìí.—Ìṣípayá 12:12.

Wàá mọ ìdí tó fi yẹ kó o gbà gbọ́ pé ayé yìí ṣì ń bọ̀ wá dára.—1 Jòhánù 2:17.

 ǸJẸ́ A LÈ GBA OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ GBỌ́?

Bẹ́ẹ̀ ni. Mẹ́ta lára ìdí tó fi yẹ ká gba ọ̀rọ̀ Bíbélì gbọ́ rèé:

  • Ọlọ́run máa fòpin sí ìṣàkóso Èṣù. Jèhófà ti pinnu pé òun kò ní jẹ́ kí Sátánì darí àwọn èèyàn mọ́. Ó ṣèlérí pé òun máa “sọ agbára Satani . . . di asán,” òun sì máa ṣàtúnṣe gbogbo ohun tí Sátánì ti bà jẹ́.—Hébérù 2:14, Ìròyìn Ayọ̀.

  • Ọlọ́run ti yan Jésù láti ṣàkóso ayé. Jésù yàtọ̀ pátápátá sí alákoso ayé yìí tó jẹ́ ìkà tí kò mọ̀ ju tara rẹ̀ lọ. Ọlọ́run ṣèlérí nípa àkóso Jésù pé: “Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì . . . Yóò tún ọkàn wọn rà padà lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá.”—Sáàmù 72:13, 14.

  • Ọlọ́run kò lè purọ́. Bíbélì sọ ní kedere pé: “Kò ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti purọ́.” (Hébérù 6:18) Bí Jèhófà bá ṣèlérí láti ṣe nǹkan kan, bí ìgbà tó ti ṣe é tán ló máa ń rí! (Aísáyà 55:10, 11) “Olùṣàkóso ayé yìí ni a óò lé jáde.”—Jòhánù 12:31.

 RÒ Ó WÒ NÁ

Tí ẹni tó ń ṣàkóso ayé yìí bá kúrò, báwo ni nǹkan ṣe máa rí?

Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí nínú ìwé SÁÀMÙ 37:10, 11 àti ÌṢÍPAYÁ 21:3, 4.