Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?

 Apá 11

Àwọn Orin Onímìísí, Tó Ń Tuni Nínú, Tó sì Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́

Àwọn Orin Onímìísí, Tó Ń Tuni Nínú, Tó sì Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́

Dáfídì àtàwọn míì kó orin jọ fún lílò nínú ìjọsìn. A lè rí àádọ́jọ [150] lára àwọn ọ̀rọ̀ orin náà nínú ìwé Sáàmù

ÌWÉ tó pọ̀ jù lọ nínú Bíbélì lèyí tó ní àkójọ àwọn orin mímọ́ nínú. Ó tó ẹgbẹ̀rún [1,000] ọdún tí wọ́n fi ṣàkọsílẹ̀ gbogbo orin náà. Inú àwọn ìwé Sáàmù la ti rí àwọn ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀, tó sì tani jí jù lọ tó tíì wà lákọsílẹ̀ rí. Onírúurú ìmọ̀lára téèyàn lè ní ló fara hàn níbẹ̀, látorí ayọ̀, ìyìn, ìdúpẹ́ títí lọ dórí ẹ̀dùn ọkàn àti ìrònúpìwàdà. Ó ṣe kedere pé àwọn tó kọ ìwé sáàmù ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, wọ́n sì fọkàn tán an. Jẹ́ ká yẹ díẹ̀ wò lára àwọn gbólóhùn tí wọ́n fàwọn ọ̀rọ̀ orin yìí gbé lárugẹ.

Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run, òun ló yẹ ká máa jọ́sìn ká sì máa fìyìn fún. A rí i kà nínú Sáàmù 83:18 pé: “Ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” Ọ̀pọ̀ sáàmù ló fi hàn pé Jèhófà lẹni tí ìyìn yẹ nítorí àwọn ohun tó dá, bí ojú ọ̀run tó kún fáwọn ìràwọ̀, báwọn ohun tó dá sórí ilẹ̀ ayé ṣe jẹ́ àgbàyanu tó àti ọ̀nà àrà tó gbà ṣẹ̀dá àwa èèyàn. (Sáàmù 8, 19, 139, 148) Àwọn míì fi hàn pé Jèhófà ló yẹ ká máa fògo fún gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tó ń gba àwọn tó ń fòótọ́ sìn ín tó sì ń dáàbò bò wọ́n. (Sáàmù 18, 97, 138) Àwọn míì sì gbé Ọlọ́run ga lọ́lá gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́ òdodo, tó máa ń mú ìtura bá àwọn tá a ni lára, tó sì máa ń fìyà jẹ àwọn ẹni búburú.—Sáàmù 11, 68, 146.

Jèhófà máa ń ran àwọn tó fẹ́ràn rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì máa ń tù wọ́n nínú. Àfàìmọ̀ ni kì í ṣe pé Sáàmù kẹtàlélógún ló gbajúmọ̀ jù lọ; níbẹ̀, Dáfídì ṣàpèjúwe Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Olùṣọ́ Àgùntàn onífẹ̀ẹ́, tó máa ń ṣamọ̀nà àwọn àgùntàn rẹ̀, tó ń dáàbò bò wọ́n, tó sì ń bójú tó wọn. Sáàmù 65:2 rán àwọn olùjọsìn Ọlọ́run létí pé Jèhófà ni “Olùgbọ́ àdúrà.” Ọ̀pọ̀ àwọn tó ti dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì ti rí i pé Sáàmù 39 àti 51 tu àwọn nínú gidigidi. Nínú àwọn sáàmù yìí ni Dáfídì ti fi ọ̀rọ̀ tó wọni lọ́kàn ṣinṣin ṣàlàyé bó ṣe ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ bíburú jáì tó dá àti bó ṣe fi hàn pé òun ní ìdánilójú pé Jèhófà máa dárí ji òun. Ìwé Sáàmù 55:22 gbà wá níyànjú pé ká ní ìgbọ́kànlé nínú Jèhófà ká sì kó gbogbo ẹrù ìnira wa lé E.

Jèhófà máa lo Ìjọba Mèsáyà láti yí ayé pa dà. Ọ̀pọ̀ ẹsẹ inú ìwé Sáàmù sọ̀rọ̀ nípa Mèsáyà, Ọba tí Ọlọ́run ṣèlérí. Sáàmù Kejì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Olùṣàkóso yìí máa mú ìparun wá sórí àwọn orílẹ̀-èdè búburú, tó ń ta ko àkóso rẹ̀. Sáàmù 72 fi hàn pé Ọba yìí máa fòpin sí ebi, ìṣègbè àti ìnilára. Gẹ́gẹ́ bí Sáàmù 46:9 ṣe sọ, Ọlọ́run máa lo Ìjọba Mèsáyà láti fòpin sí ogun, àti láti fi gbogbo ohun èlò ogun jóná. A kà nínú Sáàmù 37 pé àwọn èèyàn burúkú ò ní sí mọ́, ṣùgbọ́n àwọn olódodo yóò máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n á sì máa gbádùn àlàáfíà àti ìṣọ̀kan tó máa wà kárí ayé.

—A gbé e ka ìwé Sáàmù.

Mọ Púpọ̀ Sí I

ILÉ ÌṢỌ́

Ọlọ́run Ń Tù Ẹ́ Nínú

Tí ìṣòro rẹ bá rí bíńtín lẹ́gbẹ̀ẹ́ ti ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn tí ìṣòro wọn gadabú ńkọ́?

ÌRÒYÌN AYỌ̀ LÁTỌ̀DỌ̀ ỌLỌ́RUN!

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

Ta ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, kí ni ìjọba náà sì máa ṣe?