Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?

 Apá 7

Ọlọ́run Dá Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Nídè

Ọlọ́run Dá Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Nídè

Jèhófà mú ìyọnu wá sórí Íjíbítì, Mósè sì kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ náà. Ọlọ́run tipasẹ̀ Mósè fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òfin

Ọ̀PỌ̀ ọdún làwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi gbé ní ilẹ̀ Íjíbítì, wọ́n ń láásìkí, wọ́n sì ń pọ̀ sí i. Nígbà tó ṣe Fáráò tuntun gorí oyè. Olùṣàkóso yìí ò mọ Jósẹ́fù. Òṣìkà tó rorò gan-an ni, ẹ̀rù sì ń bà á pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń pọ̀ sí i, torí náà ó sọ wọ́n di ẹrú ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n máa ju gbogbo ọmọkùnrin tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sínú Odò Náílì. Àmọ́, ìyá kan tó jẹ́ onígboyà dáàbò bo ọmọkùnrin rẹ̀ jòjòló, ó gbé e sínú apẹ̀rẹ̀ ó sì tọ́jú ẹ̀ pa mọ́ sáàárín esùsú lẹ́bàá odò. Ọmọbìnrin Fáráò rí ọmọ kékeré náà, ó sọ ọ́ ní Mósè, ó sì tọ́ ọ dàgbà láàfin ọba ilẹ̀ Íjíbítì.

Nígbà tí Mósè pé ọmọ ogójì [40] ọdún, ó wọ wàhálà níbi tó ti fẹ́ gba ọmọ Ísírẹ́lì kan tó jẹ́ ẹrú sílẹ̀ lọ́wọ́ ará Íjíbítì tó jẹ́ akóniṣiṣẹ́. Mósè sá lọ sí ilẹ̀ kan tó jìnnà réré, ó sì wà ní ìgbèkùn níbẹ̀. Nígbà tí Mósè pé ọmọ ọgọ́rin [80] ọdún, Jèhófà rán an pa dà sí Íjíbítì pé kó lọ fara hàn níwájú Fáráò kó sì sọ fún un pé kó dá àwọn èèyàn Ọlọ́run sílẹ̀.

Fáráò kọ̀ jálẹ̀. Torí náà, Ọlọ́run mú ìyọnu mẹ́wàá wá sórí Íjíbítì. Gbogbo ìgbà tí Mósè bá fara hàn níwájú Fáráò pé bóyá ó lè yí ọkàn rẹ̀ pa dà kí ìyọnu náà lè dúró, ńṣe ni Fáráò ń ta kú, tó sì ń fi Mósè àti Ọlọ́run rẹ̀, Jèhófà ṣẹlẹ́yà. Níkẹyìn, ìyọnu kẹwàá pa gbogbo àkọ́bí tó wà nílẹ̀ Íjíbítì, àwọn ìdílé tó ṣègbọràn sí Jèhófà nípa fífi ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ àgùntàn tí wọ́n fi rúbọ sára àwọn òpó ilẹ̀kùn ilé wọn nìkan ni àkọ́bí wọn yè. Áńgẹ́lì tí Ọlọ́run rán wá láti pa gbogbo àkọ́bí run ré ilé àwọn tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ kọjá. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣèrántí ìgbàlà àgbàyanu yìí, nípa ṣíṣe ayẹyẹ ọdọọdún tí wọ́n ń pè ní Ìrékọjá.

Lẹ́yìn tí àkọ́bí ọmọkùnrin Fáráò ti kú, Fáráò pàṣẹ pé kí Mósè àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò nílẹ̀ Íjíbítì. Kò sì pẹ́ táwọn ogunlọ́gọ̀ náà fi kóra jọ, tí wọ́n sì jáde kúrò ní Íjíbítì. Àmọ́, Fáráò yí ọkàn rẹ̀ pa dà. Ó fi ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ogun àti kẹ̀kẹ́ ogun lé wọn. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì dé bèbè Òkun Pupa, ó dà bíi pé kò sọ́nà àbáyọ fún wọn mọ́. Jèhófà pín Òkun Pupa sí méjì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì rìn kọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ, láàárín omi òkun tó pínyà náà! Nígbà táwọn ará Íjíbítì rọ́ tẹ̀ lé wọn, Ọlọ́run jẹ́ kí omi náà ya bò wọ́n mọ́lẹ̀, Fáráò àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì rì sínú òkun.

Nígbà tó yá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pàgọ́ sórí Òkè Sínáì, Jèhófà sì bá wọn dá májẹ̀mú. Ọlọ́run lo Mósè gẹ́gẹ́ bí alárinà, ó sì fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láwọn òfin táá máa tọ́ wọn sọ́nà táá sì máa dáàbò bò wọ́n nínú gbogbo nǹkan tí wọ́n bá ń ṣe. Níwọ̀n ìgbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ń fòótọ́ ọkàn tẹ́wọ́ gba ìṣàkóso Ọlọ́run, Jèhófà á máa wà pẹ̀lú wọn á sì mú kí orílẹ̀-èdè náà máa kóre ran àwọn orílẹ̀-èdè míì.

Pẹ̀lú gbogbo èyí, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò múnú Ọlọ́run dùn torí àìnígbàgbọ́ wọn. Torí náà, Jèhófà mú kí ìran àwọn tí kò nígbàgbọ́ náà rìn káàkiri nínú aginjù fún ogójì [40] ọdún. Lẹ́yìn náà, Mósè pàṣẹ fún Jóṣúà tó jẹ́ adúróṣinṣin pé kó gbapò òun. Níkẹyìn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì múra tán láti wọ ilẹ̀ tí Ọlọ́run ti ṣèlérí fún Ábúráhámù.

—A gbé e ka Ẹ́kísódù; Léfítíkù; Númérì; Diutarónómì; Sáàmù 136:10-15; Ìṣe 7:17-36.