Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?

 Apá 5

Ọlọ́run Bù Kún Ábúráhámù àti Ìdílé Rẹ̀

Ọlọ́run Bù Kún Ábúráhámù àti Ìdílé Rẹ̀

Àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù láásìkí. Ọlọ́run dáàbò bo Jósẹ́fù ní Íjíbítì

JÈHÓFÀ mọ̀ pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tí Ẹni tóun kà sí ẹni ọ̀wọ́n jù lọ máa jìyà tó sì máa kú. Àkọsílẹ̀ tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15 mẹ́nu ba àsọtẹ́lẹ̀ tó jẹ mọ́ bí èyí ṣe máa wáyé. Ṣó máa ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti jẹ́ káráyé mọ ohun tí ikú náà máa ná òun? Àkàwé kan tó lè ràn wá lọ́wọ́ nípa èyí wà nínú Bíbélì. Ọlọ́run ní kí Ábúráhámù fi Ísákì, ọmọkùnrin rẹ̀ àyànfẹ́ rúbọ.

Ábúráhámù ní ìgbàgbọ́ gan-an nínú Ọlọ́run. Rántí pé, Ọlọ́run ti ṣèlérí fún un pé Olùdáǹdè, tàbí Irú-ọmọ náà máa tipasẹ̀ Ísákì wá. Níwọ̀n bó sì ti dá Ábúráhámù lójú pé Ọlọ́run lè jí Ísákì dìde bó bá pọn dandan pé kó ṣe bẹ́ẹ̀, ó ṣègbọràn sí Ọlọ́run ó sì ṣe tán láti fi ọmọ rẹ̀ rúbọ. Àmọ́, áńgẹ́lì kan ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ó sì dá a dúró kó tó dúńbú ọmọ náà. Ọlọ́run yin Ábúráhámù pé ó múra tán láti fi ohun tó ṣeyebíye sí i jù lọ rúbọ, ó sì rán an létí ìlérí tó ṣe fún un.

Nígbà tó ṣe, Ísákì bí ọmọkùnrin méjì, Ísọ̀ àti Jékọ́bù. Jékọ́bù yàtọ̀ sí Ísọ̀ torí pé ó mọyì àwọn nǹkan tẹ̀mí, Ọlọ́run sì san án lẹ́san. Ọlọ́run yí orúkọ Jékọ́bù pa dà sí Ísírẹ́lì, àwọn ọmọkùnrin méjìlá tí Ísírẹ́lì bí sì di olórí àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì. Àmọ́, báwo ni ìdílé yẹn ṣe di orílẹ̀-èdè ńlá?

Àwọn nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé nígbà tí èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù bẹ̀rẹ̀ sí í jowú Jósẹ́fù, àbúrò wọn. Wọ́n tà á lẹ́rú sí ilẹ̀ Íjíbítì. Àmọ́, Ọlọ́run bù kún ọ̀dọ́kùnrin olóòótọ́ àti onígboyà yẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jósẹ́fù fojú winá ọ̀pọ̀ ìṣòro, Fáráò olùṣàkóso ilẹ̀ Íjíbítì, yàn án láàyò ó sì gbé àṣẹ ńlá lé e lọ́wọ́. Èyí bọ́ sákòókò, ìdí sì ni pé nígbà tí ìyàn mú, Jékọ́bù rán lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ lọ sí Íjíbítì láti lọ ra oúnjẹ wá, ó sì wá já sí pé, Jósẹ́fù gan-an ni alábòójútó oúnjẹ! Lẹ́yìn tí Jósẹ́fù àtàwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀ tí wọ́n ti yíwà pa dà ṣàdédé fojú kanra, ó dárí jì wọ́n ó sì ṣètò pé kí gbogbo wọn, àtaya àtọmọ, kó wá sí ilẹ̀ Íjíbítì. Apá ibi tó dára gan-an ni Fáráò fi wọ́n sí ní ilẹ̀ náà, kí wọ́n lè máa gbilẹ̀ níbẹ̀, kí ohun ìní wọn sì máa pọ̀ sí i. Jósẹ́fù mọ̀ pé Ọlọ́run ló mú kí gbogbo èyí ṣeé ṣe kó bàa lè mú ìlérí Rẹ̀ ṣẹ.

Jékọ́bù arúgbó gbé èyí tó kù nínú ọjọ́ ayé rẹ̀ ní Íjíbítì, ìdílé ẹ̀ sì ń gbòòrò sí i níṣojú ẹ̀. Kó tó di pó kú, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Irú-ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí, tàbí Olùdáǹdè náà, máa jẹ́ Olùṣàkóso ńlá tó máa ti ìlà ìdílé ọmọkùnrin rẹ̀, Júdà wá. Kí Jósẹ́fù tó kú ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé lọ́jọ́ kan, Ọlọ́run máa kó ìdílé Jákọ́bù kúrò ní Íjíbítì.

—A gbé e ka Jẹ́nẹ́sísì orí 20 sí 50; Hébérù 11:17-22.