1. Jèhófà dá Ádámù àti Éfà ó sì fẹ́ kí wọ́n máa gbé títí láé nínú Párádísè. Sátánì parọ́ mọ́ Ọlọ́run ó sì pe ẹ̀tọ́ rẹ̀ láti ṣàkóso níjà. Ádámù àti Éfà dara pọ̀ mọ́ Sátánì nínú ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú ikú wá sórí ara wọn àtàwọn ọmọ wọn

  2. Jèhófà dájọ́ ikú fáwọn ọlọ̀tẹ̀ náà, ó sì ṣèlérí pé Olùdáǹdè kan, tàbí Irú-ọmọ máa wá, á pa Sátánì run, á sì tipa bẹ́ẹ̀ mú àbájáde búburú ìṣọ̀tẹ̀ Sátánì àti ẹ̀ṣẹ̀ kúrò

  3. Jèhófà ṣèlérí fún Ábúráhámù àti Dáfídì pé wọ́n máa jẹ́ baba-ńlá Irú-ọmọ, tàbí Mèsáyà náà, ẹni tó máa ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba títí láé

  4. Jèhófà mí sí àwọn wòlíì láti sàsọtẹ́lẹ̀ pé Mèsáyà máa wá ojútùú sí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Òun àtàwọn tó máa ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ máa ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run, èyí tó máa fòpin sí gbogbo ogun, àìsàn àti ikú pàápàá

  5. Jèhófà rán Ọmọ rẹ̀ wá sáyé, ó sì fi hàn pé Jésù ni Mèsáyà náà. Jésù wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run ó sì fẹ̀mí ara rẹ̀ rúbọ. Lẹ́yìn náà ni Jèhófà wá jí i dìde gẹ́gẹ́ bí ẹni ẹ̀mí

  6. Jèhófà gbé Ọmọ rẹ̀ gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba lókè ọ̀run, èyí tó sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Jésù ń ṣamọ̀nà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé bí wọ́n ti ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run jákèjádò ayé

  7. Jèhófà fún Ọmọ rẹ̀ láṣẹ láti nasẹ̀ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run dórí ilẹ̀ ayé. Ìjọba náà máa pa gbogbo ìjọba búburú run, ó máa mú Párádísè wá, ó sì máa sọ àwọn olóòótọ́ èèyàn di pípé. Èyí máa dá ẹ̀tọ́ Jèhófà láti ṣàkóso láre, orúkọ rẹ̀ yóò sì di èyí tá a yà sí mímọ́ títí láé