Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?

 Apá 10

Sólómọ́nì Fọgbọ́n Ṣàkóso

Sólómọ́nì Fọgbọ́n Ṣàkóso

Jèhófà fún Sólómọ́nì Ọba ní ọkàn-àyà ọgbọ́n; nígbà ìṣàkóso Sólómọ́nì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbádùn àlàáfíà àti aásìkí rẹpẹtẹ

BÁWO layé ì bá ṣe rí ká ní odindi orílẹ̀-èdè kan àti alákòóso orílẹ̀-èdè náà ń ṣègbọràn sí Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé àwọn òfin Rẹ̀? A rí ohun tí ìdáhùn sí èyí jẹ́ nígbà tí Sólómọ́nì Ọba ṣàkóso fún ogójì [40] ọdún.

Kí Dáfídì tó kú, ó yan Sólómọ́nì, ọmọkùnrin rẹ̀, sípò gẹ́gẹ́ bí ọba tó máa jẹ lẹ́yìn òun. Nínú àlá, Ọlọ́run ní kí Sólómọ́nì béèrè ohun tó bá fẹ́. Sólómọ́nì béèrè fún ọgbọ́n àti ìmọ̀ tó máa fi ṣèdájọ́ àwọn èèyàn náà lọ́nà títọ́ àti lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu. Ohun tó béèrè dùn mọ́ Jèhófà nínú ó sì fún Sólómọ́nì ní ọgbọ́n àti òye. Jèhófà tún ṣèlérí fún un pé ó máa ní ọrọ̀, ògo àti ẹ̀mí gígùn, bó bá ń bá a nìṣó láti máa jẹ́ onígbọràn.

Gbogbo èèyàn ló mọ Sólómọ́nì mọ́ àwọn ìdájọ́ ọlọgbọ́n tó ṣe. Nígbà kan báyìí, àwọn obìnrin méjì kan jọ ń jà lé ọmọkùnrin jòjòló kan lórí, àwọn méjèèjì sì ń sọ pé ọmọ àwọn ni. Sólómọ́nì wá pàṣẹ pé kí wọ́n gé ọmọ náà sí méjì kí wọ́n sì pín in lé àwọn obìnrin náà lọ́wọ́. Obìnrin àkọ́kọ́ ní òun fara mọ́ ọn pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́ èyí tó jẹ́ ìyá ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀bẹ̀ pé kí wọ́n kúkú gbé ọmọ náà fún èkejì òun. Èyí mú kí Sólómọ́nì mọ̀ pé obìnrin tó fàánú hàn yẹn ló lọmọ, òun ló sì gbé ọmọ náà fún. Kò pẹ́ tí gbogbo Ísírẹ́lì fi gbọ́ nípa ẹjọ́ tí Sólómọ́nì dá yìí, gbogbo wọ́n sì rí i pé dájúdájú, ọgbọ́n Ọlọ́run wà nínú Sólómọ́nì.

Ọ̀kan tó ṣe pàtàkì jù lọ lára ohun tí Sólómọ́nì gbé ṣe ni tẹ́ńpìlì tó kọ́ fún Jèhófà. Tẹ́ńpìlì náà jẹ́ ilé rírẹwà kan tó kọ́ sí Jerúsálẹ́mù, èyí tó máa jẹ́ ojúkò ìjọsìn fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Nígbà ìyàsímímọ́ tẹ́ńpìlì náà, Sólómọ́nì gbàdúrà pé: “Wò ó! Àwọn ọ̀run, bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀run àwọn ọ̀run, kò lè gbà ọ́; nígbà náà, áńbọ̀sìbọ́sí ilé yìí tí mo kọ́!”—1 Àwọn Ọba 8:27.

Ìròyìn nípa Sólómọ́nì tàn dé àwọn ilẹ̀ míì, tó fi dé Ṣébà, nílùú Arébíà. Ayaba Ṣébà wá Sólómọ́nì wá kó bàa lè rí ògo àti ọrọ̀ rẹ̀, kó sì tún wádìí bí ọgbọ́n rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó. Ọgbọ́n Sólómọ́nì àti aásìkí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì wú ayaba náà lórí débi pé ó fìyìn fún Jèhófà pé ó gbé irú ọba tó jẹ́ ọlọgbọ́n bẹ́ẹ̀ gorí ìtẹ́. Kódà, Jèhófà bù kún ìṣàkóso Sólómọ́nì débi pé nínú gbogbo ìtàn Ísírẹ́lì ìgbàanì, kò sí àkóso tó láásìkí tí àlàáfíà sì jọba níbẹ̀ bíi tiẹ̀.

Ó ṣeni láàánú pé nígbà tó ṣe, Sólómọ́nì dẹ́kun àtimáa fọgbọ́n Jèhófà ṣèwà hù. Ó ṣàìgbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run, ó fẹ́ ọgọ́rọ̀ọ̀rún obìnrin, tó fi mọ́ àwọn tó ń sin àwọn ọlọ́run àjèjì. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn ìyàwó rẹ̀ darí ọkàn rẹ̀ kúrò nínú ìjọsìn Jèhófà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn òrìṣà. Jèhófà sọ fún Sólómọ́nì pé òun máa pín ìjọba ẹ̀ sí méjì, òun á sì gba apá kan kúrò lọ́wọ́ ẹ̀. Ọlọ́run sọ pé, apá kan ṣoṣo ló máa kù sílẹ̀ fún ìdílé ẹ̀, nítorí ti Dáfídì tó jẹ́ bàbá Sólómọ́nì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sólómọ́nì ṣàìgbọràn, Jèhófà ṣì ń bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́ sí májẹ̀mú Ìjọba tó bá Dáfídì dá.

A gbé e ka 1 Àwọn Ọba orí 1 sí 11; 2 Kíróníkà orí 1 sí 9; Diutarónómì 17:17.