Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?

 Apá 16

Mèsáyà Dé

Mèsáyà Dé

Jèhófà fi hàn pé Jésù ti Násárétì ni Mèsáyà tóun ti ṣèlérí látìgbà pípẹ́

ṢÉ JÈHÓFÀ máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti dá Mèsáyà tó ṣèlérí mọ̀? Bẹ́ẹ̀ ni. Ìwọ wo ohun tí Ọlọ́run ṣe, ní nǹkan bí irínwó [400] ọdún lẹ́yìn tí wọ́n parí kíkọ àwọn Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù. Nínú ìlú kan tó ń jẹ́ Násárétì, ní àríwá ẹkùn ilẹ̀ Gálílì, ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ń jẹ́ Màríà gbàlejò kan tó ṣe é ní kàyéfì. Áńgẹ́lì kan tó ń jẹ́ Gébúrẹ́lì fara han wúńdíá yìí, ó sì sọ fún un pé Ọlọ́run máa lo ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀, ìyẹn ẹ̀mí mímọ́, láti mú kó bí ọmọkùnrin kan. Ọmọkùnrin yìí ló máa jẹ́ Ọba tí Ọlọ́run ti ṣèlérí látìgbà pípẹ́, òun ló sì máa ṣàkóso títí láé! Ọmọkùnrin Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni ọmọ yìí máa jẹ́, látọ̀run ni Ọlọ́run ti máa fi ìwàláàyè rẹ̀ sínú ikùn Màríà.

Màríà fìrẹ̀lẹ̀ tẹ́wọ́ gba ojúṣe àgbàyanu yẹn. Jósẹ́fù, gbẹ́nàgbẹ́nà tó ń fẹ́ ẹ sọ́nà, gbà láti fẹ́ ẹ sílé lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti rán áńgẹ́lì sí i kó bàa lè mọ ohun tó fà á tí Màríà fi lóyún. Àsọtẹ́lẹ̀ tó wá sọ pé ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni wọ́n máa bí Mèsáyà sí ńkọ́? (Míkà 5:2) Nǹkan bí ogóje [140] kìlómítà ni Jerúsálẹ́mù sí Násárétì!

Alákòóso ìlú Róòmù kan pàṣẹ pé kí wọ́n ka iye àwọn aráàlú. Àwọn èèyàn sì gbọ́dọ̀ lọ forúkọ sílẹ̀ ní ìlú tí wọ́n bí wọn sí. Ó jọ pé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù làwọn òbí Jósẹ́fù àti Màríà ti wá, torí náà, Jósẹ́fù mú ìyàwó ẹ̀ tó lóyún lọ síbẹ̀. (Lúùkù 2:3) Ibùso ẹran ni Màríà bí Jésù sí, ó sì tẹ́ ẹ síbi tí wọ́n ń kó oúnjẹ ẹran sí. Lẹ́yìn náà ni Ọlọ́run rán ògìdìgbó àwọn áńgẹ́lì láti sọ fún àwùjọ àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó wà lẹ́bàá òkè pé ọmọ tí Màríà ṣẹ̀ṣẹ̀ bí náà ni Mèsáyà, tàbí Kristi tóun ṣèlérí.

Àwọn míì náà máa tó jẹ́rìí sí i pé Jésù ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí. Wòlíì Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé ọkùnrin kan máa dìde, ó sì máa pa ọ̀nà mọ́ de iṣẹ́ pàtàkì tí Mèsáyà ń bọ̀ wá ṣe. (Aísáyà 40:3) Ẹni tá a rán ṣáájú yìí ni Jòhánù Oníbatisí. Nígbà tó rí Jésù, ó fìtara kígbe pé: “Wò ó, Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ!” Lójú ẹsẹ̀ ni díẹ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù bẹ̀rẹ̀ sí í tọ Jésù lẹ́yìn. Ọ̀kan lára wọn sọ pé: “Àwa ti rí Mèsáyà náà.”—Jòhánù 1:29, 36, 41.

Ẹ̀rí síwájú sí i tún wà pé Jésù ni Mèsáyà náà. Nígbà tí Jòhánù ri Jésù bọmi, Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ̀rọ̀ látọ̀run. Ó tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ yan Jésù gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà, ó sì sọ pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” (Mátíù 3:16, 17) Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí látìgbà pípẹ́ náà ti dé!

Nígbà wo ni dídé rẹ̀ bọ́ sí? Ọdún 29 Sànmánì Kristẹni ni, nígbà tí ọdún ọ̀rìnlénírínwó lé mẹ́ta [483] tí Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ náà parí. Dájúdájú, ìyẹn náà jẹ́ apá kan ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro tó ń fi hàn pé Jésù ni Mèsáyà, tàbí Kristi náà. Kí ni Jésù máa polongo rẹ̀ lákòókò tó fi máa gbé lórí ilẹ̀ ayé?

—A gbé e ka Mátíù orí 1 sí 3; Máàkù orí 1; Lúùkù orí 2; Jòhánù orí 1.