Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?

 Apá 6

Jóòbù Pa Ìwà Títọ́ Rẹ̀ Mọ́

Jóòbù Pa Ìwà Títọ́ Rẹ̀ Mọ́

Sátánì ò gbà pé tọkàntọkàn ni Jóòbù fi ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run láìyẹsẹ̀, àmọ́ Jóòbù ń bá ìṣòtítọ́ rẹ̀ sí Jèhófà nìṣó

ǸJẸ́ a lè rí èèyàn èyíkéyìí tá máa bá a nìṣó láti jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run, tó bá dojú kọ àdánwò dé góńgó, tó sì dà bíi pé ṣíṣègbọràn ò mú àǹfààní tara kankan wá? Ìbéèrè yìí àti ìdáhùn rẹ̀ ò ṣẹ̀yìn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jóòbù.

Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣì wà ní Íjíbítì, Jóòbù, tó jẹ́ ìbátan Ábúráhámù, ń gbé níbi tá a mọ̀ sí Arébíà lónìí. Ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn áńgẹ́lì tó wà lọ́run pé jọ níwájú Ọlọ́run, Sátánì ọlọ̀tẹ̀ sì wà láàárín wọn. Jèhófà jẹ́ káwọn áńgẹ́lì náà mọ̀ pé òun fọkàn tán Jóòbù, ìránṣẹ́ òun olóòótọ́. Kódà, Jèhófà sọ pé kò sí ẹ̀dá èèyàn míì tó jẹ́ oníwà títọ́ bíi ti Jóòbù. Àmọ́, Sátánì wonkoko pé torí pé Ọlọ́run ń bù kún Jóòbù tó sì ń dáàbò bò ó ló mú kó máa sìn ín. Sátánì tẹnu mọ́ ọn pé bí Ọlọ́run bá gba gbogbo ohun tí Jóòbù ní kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, ó máa bú Ọlọ́run.

Ọlọ́run yọ̀ọ̀da fún Sátánì láti gbéjà ko Jóòbù, ó kọ́kọ́ pa ọrọ̀ rẹ̀ run, ó pa àwọn ọmọ rẹ̀, lẹ́yìn náà ló wá fi àìsàn kọ lù ú. Jóòbù ò mọ̀ pé Sátánì ló wà lẹ́yìn gbogbo àjálù yìí, torí náà ó ń ṣe kàyéfì nípa ohun tó fà á tí Ọlọ́run fi jẹ́ káwọn àdánwò yìí dé bá òun. Síbẹ̀, Jóòbù ò sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run.

Àwọn ọ̀rẹ́ àbòsí mẹ́ta wá sọ́dọ̀ Jóòbù. Nínú ọ̀rọ̀ jàn-ànràn jan-anran tí wọ́n sọ, èyí tó kúnnú ìwé Jóòbù, wọ́n fi àìmọ̀kan mọ̀kàn fẹ́ láti yí Jóòbù lérò pa dà kó lè gbà pé torí ẹ̀ṣẹ̀ ìkọ̀kọ̀ tóun dá ni Ọlọ́run ṣe ń han òun léèmọ̀. Wọ́n tiẹ̀ sọ pé inú Ọlọ́run kì í dùn sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, kì í sì í fọkàn tán wọn. Jóòbù ò fara mọ́ èrò òdì wọn. Pẹ̀lú ìdánilójú, Jóòbù polongo pé òun máa pa ìwà títọ́ òun mọ́ títí tóun fi máa kú!

Àmọ́, àṣìṣe tí Jóòbù ṣe ni pé ó dá ara ẹ̀ láre ju bó ṣe yẹ lọ. Ọkùnrin kan tó kéré lọ́jọ́ orí sí gbogbo wọn, ìyẹn Élíhù, tó ti tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ tí gbogbo wọ́n sọ látòkè délẹ̀, wá sọ tẹnu ẹ̀ wàyí. Élíhù bá Jóòbù wí torí pé kò fiyè sí i pé ìdáláre ipò Jèhófà Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ṣe pàtàkì ju ìdáláre ẹ̀dá èèyàn èyíkéyìí lọ fíìfíì. Élíhù tún bá àwọn ọ̀rẹ́ àbòsí wọ̀nyẹn wí gidigidi.

Lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà Ọlọ́run bá Jóòbù sọ̀rọ̀, ìyẹn sì mú kó yí èrò ẹ̀ pa dà. Jèhófà lo ọ̀pọ̀ ohun àgbàyanu tó wà nínú ìṣẹ̀dá láti mú kí Jóòbù rí i pé òun kéré sí Ọlọ́run, ẹni tí títóbi rẹ̀ ò láàlà. Jóòbù fìrẹ̀lẹ̀ gba ìbáwí tí Ọlọ́run fún un. Níwọ̀n bí Jèhófà sì ti jẹ́ “oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi nínú ìfẹ́ni” àti “aláàánú,” ó mú kí ara Jóòbù yá, ó dá ọrọ̀ rẹ̀ pa dà fún un ní ìlọ́po méjì, ó sì bí ọmọ mẹ́wàá mìíràn. (Jákọ́bù 5:11) Bí Jóòbù ṣe pa ìwà títọ́ rẹ̀ sí Jèhófà mọ́, nígbà tó wà lábẹ́ àdánwò líle koko, fi hàn pé irọ́ ni Sátánì pa pé kò sí ẹ̀dá èèyàn tá máa bá ìṣòtítọ́ rẹ̀ sí Ọlọ́run nìṣó bó bá dojú kọ àdánwò.

A gbé e ka ìwé Jóòbù.