Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ọ̀pọ̀ nǹkan, síbẹ̀ ẹṣin ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo ni ìwàásù rẹ̀ dá lé lórí, ìyẹn ni Ìjọba Ọlọ́run

KÍ NI Jésù wá ṣe lórí ilẹ̀ ayé? Òun fúnra rẹ̀ sọ pé: “Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run . . . nítorí pé tìtorí èyí ni a ṣe rán mi jáde.” (Lúùkù 4:43) Ṣàgbéyẹ̀wò ohun mẹ́rin tí Jésù fi kọ́ni nípa ohun tí ìwàásù rẹ̀ dá lé, ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run.

1. Ọlọ́run ti yan Jésù láti jẹ́ Ọba Ìjọba náà. Jésù sọ ní tààràtà pé òun ni Mèsáyà tá a sọ tẹ́lẹ̀. (Jòhánù 4:25, 26) Ó tún fi hàn pé òun ni Ọba tí wòlíì Dáníẹ́lì rí nínú ìran. Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tóun máa jókòó sórí “ìtẹ́ ògo,” àwọn náà sì máa jókòó sórí àwọn ìtẹ́. (Mátíù 19:28) Ó pe àwùjọ àwọn olùṣàkóso yìí ní “agbo kékeré” òun, ó sì tún sọ pé òun ní “àwọn àgùntàn mìíràn,” tí kì í ṣe ti agbo yẹn.—Lúùkù 12:32; Jòhánù 10:16.

2. Ìwà ìrẹ́jẹ ò ní sí nínú Ìjọba Ọlọ́run. Jésù fi hàn pé Ìjọba yẹn máa mú gbogbo onírúurú ìwà ìrẹ́nijẹ kúrò nípa yíya orúkọ Jèhófà Ọlọ́run sí mímọ́ àti fífọ̀ ọ́ mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gàn tí Sátánì ti kó bá a látìgbà ìṣọ̀tẹ̀ tó wáyé nínú ọgbà Édẹ́nì. (Mátíù 6:9, 10) Jésù ò ṣe ojúsàájú, ó kọ́ àwọn èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ọlọ́rọ̀ àti òtòṣì, lẹ́kọ̀ọ́ láì dá ẹnikẹ́ni sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ńṣe ni Ọlọ́run rán an láti wá kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́kọ̀ọ́, ó sapá láti ran àwọn ará Samáríà àtàwọn Kèfèrí, tàbí àwọn tí kì í ṣe Júù lọ́wọ́. Kò ṣe bíi tàwọn aṣáájú ẹ̀sìn tó wà láyé nígbà náà, kò ṣe ojúsàájú sí ẹnikẹ́ni.

3. Ìjọba Ọlọ́run ò ní jẹ́ apá kan ayé yìí. Nígbà tí Jésù ń gbé lórí ilẹ̀ ayé, nǹkan ò fara rọ lágbo òṣèlú. Látòkèèrè làwọn aláṣẹ míì ti ń ṣàkóso ilẹ̀ ìbílẹ̀ rẹ̀. Síbẹ̀, nígbà táwọn èèyàn gbìyànjú láti mú kó bá wọn lọ́wọ́ sí ètò òṣèlú, ó yẹra fún wọn. (Jòhánù 6:14, 15) Ó sọ fún olóṣèlú kan pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.” (Jòhánù 18:36) Ó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ kì í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 15:19) Kò gbà kí wọ́n lo àwọn ohun èlò ogun, kò tiẹ̀ jẹ́ kí wọ́n fi gbèjà òun.—Mátíù 26:51, 52.

“Ó . . . lọ láti . . . abúlé dé abúlé, ó ń wàásù, ó sì ń polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run.” —Lúùkù 8:1

4. Kristi máa fìfẹ́ ṣàkóso. Jésù ṣèlérí pé òun máa fáwọn èèyàn ní ìtura, òun á sì mú kí ẹrù wọ́n fúyẹ́. (Mátíù 11:28-30) Ohun tó sì ṣe gan-an nìyẹn. Ó fún wọn ní ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tó ṣeé fi sílò nípa bí wọ́n ṣe lè kojú àníyàn, bí wọ́n ṣe lè mú kí àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn míì sunwọ̀n sí i, bí wọ́n ṣe lè kojú ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì àti bí wọ́n ṣe lè máa láyọ̀. (Mátíù, orí 5 sí 7) Torí pé Jésù máa ń fi ìfẹ́ hàn sáwọn ẹlòmíì, onírúurú èèyàn lara máa ń tù láti tọ̀ ọ́ lọ. Kódà, àwọn táwọn èèyàn ń pọ́n lójú máa ń tọ̀ ọ́ lọ, torí wọ́n mọ̀ pé ó máa fi inú rere báwọn lò, ó sì máa buyì kún àwọn. Olùṣàkóso tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni Jésù máa jẹ́!

Ọ̀nà pàtàkì míì tún wà tí Jésù gbà kọ́ni nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ó ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu. Kí nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká wò ó ná.

A gbé e ka ìwé Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù.