Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 Apá 24

Pọ́ọ̀lù Kọ Lẹ́tà Sáwọn Ìjọ

Pọ́ọ̀lù Kọ Lẹ́tà Sáwọn Ìjọ

Àwọn lẹ́tà Pọ́ọ̀lù gbé àwọn ìjọ Kristẹni ró

IṢẸ́ ńlá ni ìjọ Kristẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ máa ṣe kó bàa lè mú ète Jèhófà ṣẹ. Àmọ́, kò pẹ́ táwọn ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní yìí fi bẹ̀rẹ̀ sí í fojú winá àtakò. Ṣé wọ́n máa pa ìwà títọ́ wọn sí Ọlọ́run mọ́ bí wọ́n ṣe ń dojú kọ inúnibíni láti ìta, táwọn ewu míì sì rọra ń fínná mọ́ wọn láàárín ìjọ? Lẹ́tà mọ́kànlélógún [21] tó wà nínú àwọn Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, fún wa ní ọ̀rọ̀ ìyànjú àti ọ̀rọ̀ ìṣírí tá a nílò.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ló kọ mẹ́rìnlá [14] lára àwọn lẹ́tà náà, bẹ̀rẹ̀ látorí ìwé Róòmù títí dé ìwé Hébérù. Orúkọ àwọn tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà wọ̀nyí sí ló fi pe ìwé tó kọ sí wọn, yálà ẹnì kan tàbí àwọn ará tó wà nínú ìjọ pàtó kan. Díẹ̀ rèé lára àwọn kókó táwọn lẹ́tà Pọ́ọ̀lù dá lé lórí.

Ìṣílétí lórí ohun tó tọ́ ká máa ṣe àti ohun tí kò yẹ ká máa hù níwà. Àwọn tó bá ń ṣe àgbèrè, panṣágà, tí wọ́n sì tún ń hu àwọn ìwà bíburú jáì míì “kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.” (Gálátíà 5:19-21; 1 Kọ́ríńtì 6:9-11) Àwọn tó ń sin Ọlọ́run gbọ́dọ̀ máa wà níṣọ̀kan láìka orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti wá sí. (Róòmù 2:11; Éfésù 4:1-6) Wọ́n gbọ́dọ̀ máa fi tinútinú múra tán láti ran àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tó bá ṣaláìní lọ́wọ́. (2 Kọ́ríńtì 9:7) Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ máa gbàdúrà láìdabọ̀.” Kódà, ó gba àwọn olùjọsìn Ọlọ́run níyànjú láti máa ṣí ohun tó bá wà lọ́kàn wọn payá fún Jèhófà. (1 Tẹsalóníkà 5:17; 2 Tẹsalóníkà 3:1; Fílípì 4:6, 7) Ẹni tó ń gbàdúrà gbọ́dọ̀ lo ìgbàgbọ́ kí Ọlọ́run tó lè gbọ́ àdúrà rẹ̀.—Hébérù 11:6.

Kí ló máa ran àwọn ìdílé lọ́wọ́ láti kẹ́sẹ járí? Àwọn ọkọ gbọ́dọ̀ fẹ́ràn àwọn aya wọn bí ara wọn. Àwọn aya gbọ́dọ̀ máa ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fáwọn ọkọ wọn. Àwọn ọmọ gbọ́dọ̀ máa gbọ́ràn sáwọn òbí wọn lẹ́nu, torí èyí máa ń múnú Ọlọ́run dùn. Ó pọn dandan káwọn òbí máa fi ìlànà Ọlọ́run ṣamọ̀nà àwọn ọmọ wọn tìfẹ́tìfẹ́.—Éfésù 5:22–6:4; Kólósè 3:18-21.

Ó tànmọ́lẹ̀ sórí ète Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ lára àwọn nǹkan tí Òfin Mósè pa láṣẹ ló pa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ́ títí dìgbà tí Kristi dé. (Gálátíà 3:24) Àmọ́, kò pọn dandan káwa Kristẹni pa Òfin yẹn mọ́ ká tó lè sin Ọlọ́run. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sáwọn Hébérù, ìyẹn àwọn tó jẹ́ pé Júù ni wọ́n kí wọ́n tó di Kristẹni, ó tànmọ́lẹ̀ sórí ohun tí Òfin túmọ̀ sí àti bí Kristi ṣe mú ète Ọlọ́run ṣẹ. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé apá púpọ̀  nínú Òfin náà wúlò fún mímú ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ. Bí àpẹẹrẹ, fífi àwọn ẹran rúbọ̀ ṣàpẹẹrẹ ikú ìrúbọ tí Jésù kú, èyí tó máa mú ká rí ojúlówó ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. (Hébérù 10:1-4) Nípasẹ̀ ikú Jésù, Ọlọ́run mú májẹ̀mú Òfin kúrò, torí pé a kò nílò rẹ̀ mọ́.—Kólósè 2:13-17; Hébérù 8:13.

Ìtọ́ni lórí ìṣètò ìjọ. Àwọn ọkùnrin tó ń fẹ́ láti máa bójú tó àwọn ojúṣe kan nínú ìjọ gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run tí kò fàyè gbàgbàkugbà kí wọ́n sì kúnjú ìwọ̀n àwọn ohun tí Ìwé Mímọ́ béèrè fún. (1 Tímótì 3:1-10, 12, 13; Títù 1:5-9) Àwọn olùjọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run gbọ́dọ̀ máa pé jọ déédéé pẹ̀lú àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ kí wọ́n bàa lè máa gba ara wọn níyànjú. (Hébérù 10:24, 25) Àwọn ìpàdé fún ìjọsìn gbọ́dọ̀ máa gbéni ró kí wọ́n sì kún fún ẹ̀kọ́.—1 Kọ́ríńtì 14:26, 31.

Pọ́ọ̀lù ti wà ní Róòmù nígbà tó kọ lẹ́tà kejì sí Tímótì; wọ́n ti jù ú sẹ́wọ̀n, ó sì ń dúró de ìgbẹ́jọ́. Àwọn díẹ̀ tí wọ́n nígboyà ni wọ́n forí wewu àtilọ máa bẹ̀ ẹ́ wò. Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé àkókò díẹ̀ ló kù fóun. Torí náà, ó kọ̀wé pé: “Mo ti ja ìjà àtàtà náà, mo ti sáré ní ipa ọ̀nà eré ìje náà dé ìparí, mo ti pa ìgbàgbọ́ mọ́.” (2 Tímótì 4:7) Ó jọ pé kò pẹ́ sígbà yẹn ni wọ́n pa Pọ́ọ̀lù nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀. Àmọ́, àwọn lẹ́tà tó kọ ń ṣamọ̀nà àwọn tó ń fòótọ́ sin Ọlọ́run títí di báyìí.

—A gbé e ka Róòmù; 1 Kọ́ríńtì; 2 Kọ́ríńtì; Gálátíà; Éfésù; Fílípì; Kólósè; 1 Tẹsalóníkà; 2 Tẹsalóníkà; 1 Tímótì; 2 Tímótì; Títù; Fílémónì; Hébérù.