Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?

 Apá 18

Jésù Ṣe Iṣẹ́ Ìyanu

Jésù Ṣe Iṣẹ́ Ìyanu

Àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe jẹ́ ká mọ ọ̀nà tó máa gbà lo agbára rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba

ỌLỌ́RUN fún Jésù lágbára láti ṣe àwọn nǹkan tí ẹ̀dá èèyàn mìíràn ò lè ṣe. Jésù ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu ńlàǹlà, èyí sì sábà máa ń jẹ́ níbi tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti lè fojú ara wọn rí i. Àwọn iṣẹ́ ìyanu yẹn fi hàn pé Jésù lágbára lórí àwọn ọ̀tá àtàwọn ohun ìdènà táwa ẹ̀dá èèyàn aláìpé ò lágbára láti mú kúrò. Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

Ebi. Iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́ tí Jésù ṣe ni pé ó sọ omi di ọtí wáìnì. Nígbà méjì míì, ó fi ìṣù àkàrà díẹ̀ àti ẹja wẹ́wẹ́ bọ́ ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tí ebi ń pa. Nígbà méjèèjì yìí, olúkúlùkù jẹ àjẹyó àti àjẹṣẹ́kù.

Àìsàn. Jésù wo àwọn èèyàn tí wọ́n ní “gbogbo onírúurú òkùnrùn àti gbogbo onírúurú àìlera” sàn. (Mátíù 4:23) Jésù la ojú àwọn afọ́jú, ó mú káwọn adití gbọ́ràn, ó wo àrùn ẹ̀tẹ̀ àti wárápá sàn. Ó wo àwọn amúkùn-ún àti arọ sàn, ó sì tún mú àwọn abirùn lára dá. Kò sí àìsàn tó pọ̀ jù fún Jésù láti wò sàn.

Ojú ọjọ́ tí kò dára. Nígbà tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ń wọkọ̀ ojú omi ré kọjá Òkun Gálílì, ìjì ẹlẹ́fùúùfù ṣàdédé bẹ̀rẹ̀. Jìnnìjìnnì bo àwọn ọmọ ẹ̀yìn. Ńṣe ni Jésù wulẹ̀ bojú wo ìjì náà, tó sì sọ pé: “Ṣe wọ̀ọ̀! Dákẹ́!” Bó ṣe sọ bẹ́ẹ̀ tán ni ẹ̀fúùfù náà rọlẹ̀ wọ̀ọ̀. (Máàkù 4:37-39) Nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀, ó rìn lórí omi nígbà tí ìjì kan tó bani lẹ́rù ń jà.—Mátíù 14:24-33.

Àwọn ẹ̀mí búburú. Àwọn ẹ̀mí èṣù lágbára ju àwọn ẹ̀dá èèyàn lọ fíìfíì. Ọ̀pọ̀ èèyàn tó sì ti kó sí akóló àwọn òǹrorò ọ̀tá Ọlọ́run wọ̀nyí ni ò ṣeé ṣe fún láti jàjàbọ́. Síbẹ̀, ní gbogbo ìgbà tí Jésù bá pàṣẹ pé kí wọ́n jáde kúrò lára àwọn èèyàn, ńṣe ló ń tú irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sílẹ̀ kúrò nínú páńpẹ́ wọn. Kò bẹ̀rù àwọn ẹ̀mí èṣù. Àwọn gan-an mọ̀ pé ó lágbára, wọ́n sì máa ń bẹ̀rù rẹ̀.

Ikú. Bíbélì tọ̀nà nígbà tó pe ikú ní “ọ̀tá ìkẹyìn,” torí pé ọ̀tá táráyé ò lè rí gbé ṣe ni. (1 Kọ́ríńtì 15:26) Síbẹ̀, Jésù jí òkú dìde, lára wọn ni ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí ìyá rẹ̀ jẹ́ opó àti ọ̀dọ́mọbìnrin kan táwọn òbí rẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀. Ọ̀kan tó tiẹ̀ wá pabanbarì ni ti Lásárù, ọ̀rẹ́ Jésù, tí Jésù jí dìde níwájú ọ̀pọ̀ èrò tó ń ṣọ̀fọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti tó ọjọ́ mẹ́rin tí ọkùnrin náà ti kú! Àwọn tó jẹ́ ọ̀tá paraku fún Jésù pàápàá gbà pé ó ṣiṣẹ́ ìyanu yìí.—Jòhánù 11:38-48; 12:9-11.

Kí nìdí tí Jésù fi ṣe gbogbo iṣẹ́ ìyanu yẹn? Ó ṣe tán, gbogbo àwọn tó jí dìde ló pa dà kú. Òótọ́ ni, àmọ́ a ṣì ń jàǹfààní ohun tí Jésù ṣe yẹn títí di báyìí. Wọ́n jẹ́rìí sí i pé gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ tí ń múni lọ́kàn yọ̀ nípa àkóso Mèsáyà Ọba máa nímùúṣẹ. Kò sídìí tá a fi gbọ́dọ̀ máa ṣiyè méjì bóyá Ọba tí Ọlọ́run yàn sípò á lè mú ebi, àìsàn, ojú ọjọ́ tí kò dára, àwọn ẹ̀mí èṣù, tàbí ikú pàápàá kúrò. Ó ti fẹ̀rí hàn pé Ọlọ́run ti fún òun lágbára láti ṣe gbogbo ìyẹn.

A gbé e ka ìwé Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù.