Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?

 Apá 22

Àwọn Àpọ́sítélì Wàásù Láìbẹ̀rù

Àwọn Àpọ́sítélì Wàásù Láìbẹ̀rù

Ìjọ Kristẹni ń yára gbèrú láìka inúnibíni sí

NÍ ỌJỌ́ kẹwàá lẹ́yìn tí Jésù ti gòkè re ọ̀run, nǹkan bí ọgọ́fà [120] lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kóra jọ sínú ilé kan ní Jerúsálẹ́mù, nígbà Ayẹyẹ Àwọn Júù ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Lójijì, ariwo bíi ti ẹ̀fúùfù tí ń rọ́ yìí kún inú ilé náà. Lọ́nà ìyanu, àwọn ọmọ ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí í fi èdè tí wọn ò mọ̀ tẹ́lẹ̀ sọ̀rọ̀. Kí ló fà á tí ìṣẹ̀lẹ̀ àrà ọ̀tọ̀ yìí fi wáyé? Ohun tó fà á ni pé Ọlọ́run tú ẹ̀mí mímọ́ dà sórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn.

Ogunlọ́gọ̀ èèyàn wà lóde ibi táwọn ọmọ ẹ̀yìn kóra jọ sí, torí pé ọ̀pọ̀ àlejò ló tàwọn ìlú míì wá síbi ayẹyẹ náà. Ó yà wọ́n lẹ́nu báwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe ń sọ èdè wọn lọ́nà tó yọ̀ mọ́ wọn lẹ́nu tó bẹ́ẹ̀. Nígbà tí Pétérù ń ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀, ó mẹ́nu kan àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Jóẹ́lì pé Ọlọ́run máa “tú” ẹ̀mí rẹ̀ “jáde,” èyí tó máa fún àwọn tó bá bà lé ní ẹ̀bùn lọ́nà ìyanu. (Jóẹ́lì 2:28, 29) Ẹ̀mí mímọ́ tí Ọlọ́run tú jáde yìí mú kó ṣe kedere pé ìyípadà pàtàkì kan ti ṣẹlẹ̀, ìyẹn ni pé Ọlọ́run ti sún ojú rere rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó ti fi fún ìjọ Kristẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fìdí múlẹ̀. Ní báyìí, àwọn tó fẹ́ láti sin Ọlọ́run lọ́nà tó ṣètẹ́wọ́gbà gbọ́dọ̀ di ọmọlẹ́yìn Kristi.

Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, àtakò túbọ̀ ń pọ̀ sí i, àwọn ọ̀tá sì ń gbé àwọn ọmọ ẹ̀yìn jù sẹ́wọ̀n. Àmọ́ lóru, áńgẹ́lì Jèhófà ṣí àwọn ilẹ̀kùn ọgbà ẹ̀wọ̀n ó sì sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn pé kí wọ́n máa wàásù nìṣó. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, wọ́n ń bá ìwàásù wọn nìṣó. Wọ́n wọnú tẹ́ńpìlì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ìhìn rere nípa Jésù. Inú bí àwọn ẹlẹ́sìn tó ń ṣàtakò sí wọn, wọ́n sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe wàásù mọ́. Àwọn àpọ́sítélì fìgboyà dá wọn lóhùn pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:28, 29.

Inúnibíni tún pọ̀ sí i. Àwọn Júù kan tiẹ̀ fẹ̀sùn kan Sítéfánù pó sọ̀rọ̀ òdì, wọ́n sì sọ ọ́ lókùúta pa. Ọ̀dọ́mọkùnrin kan, ìyẹn Sọ́ọ̀lù ará Tásù, wà níbẹ̀, òun náà sì fọwọ́ sí ikú rẹ̀. Lẹ́yìn náà ló lọ sí Damásíkù láti lọ mú ẹnikẹ́ni tó bá ń tọ Kristi lẹ́yìn. Bí Sọ́ọ̀lù ti ń lọ lójú ọ̀nà, ìmọ́lẹ̀ kan láti ọ̀run wá tàn yí i ká, ohùn kan sì ké sí i pé: “Sọ́ọ̀lù, Sọ́ọ̀lù, èé ṣe tí ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi?” Lẹ́yìn tí ìmọ́lẹ̀ náà ti fọ́ Sọ́ọ̀lù lójú, ó béèrè pé: “Ta ni ọ́?” Ohùn náà dá a lóhùn pé: “Èmi ni Jésù.”—Ìṣe 9:3-5.

Ní ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà, Jésù rán ọmọ ẹ̀yìn kan tó ń jẹ́ Ananíà láti la ojú rẹ̀. Sọ́ọ̀lù ṣèrìbọmi ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fìgboyà wàásù nípa Jésù. Sọ́ọ̀lù yìí la wá mọ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó di ara ìjọ Kristẹni, ó sì jẹ́ onítara.

Àwọn Júù àtàwọn ará Samáríà nìkan làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún. Ní báyìí, áńgẹ́lì kan fara han Kọ̀nílíù, olùbẹ̀rù Ọlọ́run, tó jẹ́ ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù, ó sì sọ fún un pé kó ránṣẹ́ pe àpọ́sítélì Pétérù. Pétérù àtàwọn míì lọ láti jẹ́ ìpè Kọ̀nílíù, ó sì wàásù fún òun àti agboolé rẹ̀. Bí Pétérù ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ẹ̀mí mímọ́ bà lé àwọn Kèfèrí onígbàgbọ́ yẹn, àpọ́sítélì náà sì pàṣẹ pé kí wọ́n batisí wọn lórúkọ Jésù. Bó ṣe di pé ọ̀nà ṣí sílẹ̀ fáwọn Kèfèrí láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun nìyẹn o. Ní báyìí, ìjọ Kristẹni ti wà ní sẹpẹ́ láti wàásù ìhìn rere jákèjádò.

—A gbé e ka Ìṣe 1:1–11:21.