Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?

 ÀFIKÚN

Kí Ni Ṣìọ́ọ̀lù àti Hédíìsì?

Kí Ni Ṣìọ́ọ̀lù àti Hédíìsì?

Ó JU àádọ́rin ìgbà lọ tí ọ̀rọ̀ èdè Hébérù náà, sheʼohlʹ àti ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì náà, haiʹdes fara hàn nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ọ̀rọ̀ méjèèjì ló sì jẹ mọ́ ikú. Àwọn olùtumọ̀ Bíbélì kan túmọ̀ wọn sí “sàréè,” “ọ̀run àpáàdì,” tàbí “ihò.” Àmọ́, ní ọ̀pọ̀ èdè, kò sí àwọn ọ̀rọ̀ tó lè gbé ìtumọ̀ tó wà nínú ọ̀rọ̀ Hébérù àti Gíríìkì náà yọ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé “Ṣìọ́ọ̀lù” àti “Hédíìsì” ni Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lò. Kí làwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí túmọ̀ sí gan-an? Jẹ́ ká wo bí wọ́n ṣe lò wọ́n nínú onírúurú ẹsẹ Bíbélì.

Oníwàásù 9:10 sọ pé: “Kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù, ibi tí ìwọ ń lọ.” Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé Ṣìọ́ọ̀lù jẹ́ ibì kan pàtó, tàbí sàréè tí wọ́n sin ẹnì kan sí? Rárá o. Ṣó o rí i, láwọn ibi tí Bíbélì bá ti tọ́ka sí sàréè tàbí ibi ìsìnkú kan pàtó, kì í lo sheʼohlʹ àti haiʹdes, àwọn ọ̀rọ̀ èdè Hébérù àti ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì mìíràn ló máa ń lò. (Jẹ́nẹ́sísì 23:7-9; Mátíù 28:1) Bákan náà, Bíbélì kò lo “Ṣìọ́ọ̀lù” fún ibi ìsìnkú tí wọ́n sin ọ̀pọ̀ èèyàn sí, irú bí ibojì ìdílé tàbí kòtò gìrìwò tí wọ́n sin ọ̀pọ̀ èèyàn pa pọ̀ sí.—Jẹ́nẹ́sísì 49:30, 31.

Kí wá ni “Ṣìọ́ọ̀lù” ń tọ́ka sí gan-an? Bíbélì fi hàn pé ohun tí “Ṣìọ́ọ̀lù” àti “Hédíìsì” ń tọ́ka sí tilẹ̀ ju kòtò gìrìwò tí wọ́n sin ọ̀pọ̀ èèyàn pa pọ̀ sí lọ. Bí àpẹẹrẹ, Aísáyà 5:14 sọ pé Ṣìọ́ọ̀lù jẹ́ “aláyè gbígbòòrò, ó sì ti ṣí ẹnu rẹ̀ sílẹ̀ gbayawu ré kọjá ààlà.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ni Ṣìọ́ọ̀lù ti gbé mì, ó dà bíi pé kì í kún, bíi kó sáà máa rí ọ̀pọ̀ èèyàn mì sí i ló ń rí nígbà gbogbo. (Òwe 30:15, 16) Ṣìọ́ọ̀lù kò dà bí ibi ìsìnkú gidi tó jẹ́ pé èèyàn kan tàbí èèyàn díẹ̀ ni wọ́n lè sin síbẹ̀ nítorí pé, ‘Ṣìọ́ọ̀lù kì í ní ìtẹ́lọ́rùn.’ (Òwe 27:20) Ìyẹn ni pé, Ṣìọ́ọ̀lù kì í kún. Nítorí náà, Ṣìọ́ọ̀lù tàbí Hédíìsì kì í ṣe ibi gidi kan téèyàn lè rí níbì kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ipò òkú ni, ìyẹn ibi ìṣàpẹẹrẹ tí ọ̀pọ̀ jù lọ aráyé tí ń sùn nínú oorun ikú wà.

Ẹ̀kọ́ tí Bíbélì fi kọ́ni nípa àjíǹde tún jẹ́ ká túbọ̀ mọ ìtumọ̀ “Ṣìọ́ọ̀lù” àti “Hédíìsì.” Nígbà tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bá ń sọ̀rọ̀ nípa Ṣìọ́ọ̀lù àti Hédíìsì, ó máa ń fi hàn pé àwọn tó bá lọ  síbẹ̀ yóò jíǹde. * (Jóòbù 14:13; Ìṣe 2:31; Ìṣípayá 20:13) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún fi hàn pé kì í ṣe àwọn tó sin Jèhófà nìkan ló wà ní Ṣìọ́ọ̀lù tàbí Hédíìsì, àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn tí kò sìn ín náà wà níbẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 37:35; Sáàmù 55:15) Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé “àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.”—Ìṣe 24:15.

^ ìpínrọ̀ 4 Àmọ́, Bíbélì fi hàn pé àwọn òkú tó ‘wà ní Gẹ̀hẹ́nà’ ni kò ní jí dìde, kì í ṣe àwọn òkú tó wà ní Ṣìọ́ọ̀lù tàbí Hédíìsì. (Mátíù 5:30; 10:28; 23:33) Bíi ti Ṣìọ́ọ̀lù àti Hédíìsì, Gẹ̀hẹ́nà náà kì í ṣe ibì kan pàtó, ibi ìṣàpẹẹrẹ ló jẹ́.