Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?

 ÀFIKÚN

Ṣé Oṣù December Ni Wọ́n Bí Jésù?

Ṣé Oṣù December Ni Wọ́n Bí Jésù?

BÍBÉLÌ ò sọ ìgbà tí wọ́n bí Jésù fún wa. Àmọ́, ó sọ àwọn ohun kan tó jẹ́ ká mọ̀ pé wọn ò bí Jésù ní oṣù December.

Ìwọ wo bí ojú ọjọ́ ṣe máa ń rí ní oṣù December ní ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí wọ́n bí Jésù sí. Nínú kàlẹ́ńdà àwọn Júù, oṣù Chislev (tó jẹ́ apá kan November àti apá kan December nínú kàlẹ́ńdà tiwa) jẹ́ oṣù tí òjò máa ń rọ̀ tí òtútù sì máa ń mú ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Oṣù tó máa ń tẹ̀ lé ìyẹn ni oṣù Tebeth (tó jẹ́ apá kan December àti apá kan January nínú kàlẹ́ńdà tiwa). Oṣù yìí ni òtútù ti máa ń mú jù nínú ọdún, kódà yìnyín máa ń já bọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láwọn ibi tó jẹ́ ilẹ̀ olókè. Jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ fún wa nípa bí ojú ọjọ́ àgbègbè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ṣe máa ń rí.

Ẹ́sírà tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì fi hàn pé òótọ́ ni òjò máa ń rọ̀ tí òtútù sì máa ń mú ní oṣù Chislev. Lẹ́yìn tí Ẹ́sírà sọ pé ọ̀pọ̀ èèyàn pé jọ ní Jerúsálẹ́mù “ní oṣù kẹsàn-án [ìyẹn oṣù Chislev] ní ogúnjọ́ oṣù náà,” ó wá ròyìn pé àwọn èèyàn náà “ń gbọ̀n nítorí . . . ọ̀wààrà òjò.” Kódà àwọn èèyàn tó pé jọ náà sọ nípa bí ojú ọjọ́ ṣe rí lákòókò yẹn, wọ́n ní: ‘Àsìkò ọ̀wààrà òjò ni, kò sì ṣeé  ṣe láti dúró lóde.’ (Ẹ́sírà 10:9, 13; Jeremáyà 36:22) Abájọ tó fi jẹ́ pé àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó wà lágbègbè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ò lè ṣe kí wọ́n máà kó àwọn àgùntàn wọn wọlé lálẹ́ ní oṣù December!

Àmọ́, Bíbélì sọ pé àwọn olùṣọ́ àgùntàn ń tọ́jú àwọn àgùntàn wọn ní ìta lálẹ́ ọjọ́ tí wọ́n bí Jésù. Kódà, Lúùkù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì fi hàn pé lákòókò náà, àwọn olùṣọ́ àgùntàn ‘ń gbé ní ìta, wọ́n sì ń ṣọ́ àwọn agbo ẹran wọn ní òru’ nítòsí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. (Lúùkù 2:8-12) Kíyè sí i pé ńṣe làwọn olùṣọ́ àgùntàn ń gbé ní ìta, kì í kàn án ṣe pé wọ́n ǹ rìn kiri níta lọ́sàn-án. Àwọn àgùntàn wọn wà lọ́dọ̀ wọn ní pápá ní òru. Tó bá jẹ́ pé oṣù December tí òtútù máa ń mú gan-an tí òjò sì máa ń rọ̀ ni, ǹjẹ́ àwọn olùṣọ́ àgùntàn á lè wà níta lóru? Rárá. Nítorí náà, bí ipò ojú ọjọ́ ṣe rí lákòókò tí wọ́n bí Jésù fi hàn pé kì í ṣe oṣù December ni wọ́n bí i. *

Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ìgbà tí Jésù kú gan-an fún wa, àmọ́ kò sọ ìgbà náà gan-an tí wọ́n bí i, ńṣe ló kàn sọ àwọn nǹkan tá a lè gùn lé láti mọ ìgbà tí wọ́n bí i. Èyí mú ká rántí ohun tí Ọba Sólómọ́nì sọ, pé: “Orúkọ sàn ju òróró dáradára, ọjọ́ ikú sì sàn ju ọjọ́ tí a bíni lọ.” (Oníwàásù 7:1) Nítorí náà, kò yà wá lẹ́nu pé Bíbélì sọ ọ̀pọ̀ nǹkan fún wa nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù àti ikú rẹ̀, nígbà tó sì jẹ́ pé nǹkan díẹ̀ ló sọ fún wa nípa ìgbà tí wọ́n bí i.

Nígbà tí wọ́n bí Jésù, àwọn olùṣọ́ àgùntàn àtàwọn àgùntàn wọn wà ní pápá ní òru

^ ìpínrọ̀ 1 Wo àfikún àlàyé nínú ìwé Reasoning From the Scriptures, ojú ìwé 176 sí 179. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé yìí.