Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORÍ KẸSÀN-ÁN

Ṣé “Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn” La Wà Yìí”?

Ṣé “Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn” La Wà Yìí”?
 • Kí làwọn ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò máa ṣẹlẹ̀ lákòókò tá a wà yìí?

 • Irú ìwà wo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé àwọn èèyàn yóò máa hù ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn”?

 • Àwọn ohun rere wo ni Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò máa ṣẹlẹ̀ ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn”?

1. Ibo la ti lè kọ́ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?

ǸJẸ́ o ti gbọ́ ìròyìn rí lórí rédíò tó o sì ṣe kàyéfì pé: ‘Ibo layé yìí tiẹ̀ ń lọ gan-an?’ Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ láabi ń ṣẹlẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀ tó fi jẹ́ pé kò sẹ́ni tó lè sọ ohun tí ilẹ̀ tó máa mọ́ lọ́la òde yìí máa bí. (Jákọ́bù 4:14) Ṣùgbọ́n Jèhófà mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. (Aísáyà 46:10) Tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn ni Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ohun búburú yóò máa ṣẹlẹ̀ lákòókò wa yìí. Ó tún sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ohun rere yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú tí kò jìnnà mọ́.

2, 3. Ìbéèrè wo làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bi í, báwo ló sì ṣe dá wọn lóhùn?

2 Jésù sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run, èyí tí yóò fòpin sí ìwà ibi tí yóò sì sọ ayé di Párádísè. (Lúùkù 4:43) Àwọn èèyàn sì máa ń fẹ́ láti mọ ìgbà tí Ìjọba náà yóò dé. Kódà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bi Jésù pe: “Kí ni yóò . . . jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?” (Mátíù 24:3) Jésù dá wọn lóhùn pé Jèhófà nìkan ló mọ ìgbà tí òpin ayé búburú yìí yóò dé. (Mátíù 24:36) Àmọ́ o, Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn nǹkan tí yóò máa ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé tó bá kù díẹ̀ kí Ìjọba Ọlọ́run mú àlàáfíà àti  ààbò wá fún aráyé. Àwọn ohun tó sì sọ tẹ́lẹ̀ ló ń ṣẹlẹ̀ báyìí!

3 Ká tó yẹ ẹ̀rí tó fi hàn pé “ìparí ètò àwọn nǹkan” la wà yìí wò, jẹ́ ká kọ́kọ́ jíròrò ní ṣókí nípa ogun kan tó jẹ́ pé kò sí ẹ̀dá èèyàn kankan tí ì bá mọ̀ pé ó jà nítorí pé ọ̀run ló ti wáyé, tí àbájáde rẹ̀ sì kàn wá.

OGUN KAN JÀ NÍ Ọ̀RUN

4, 5. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ ní ọ̀run ní kété lẹ́yìn tí Jésù di Ọba? (b) Bí Ìṣípayá 12:12 ti sọ, kí ni yóò jẹ́ àbájáde ogun tó jà ní ọ̀run?

4 Orí Kẹjọ ìwé yìí ṣàlàyé pé Jésù Kristi di Ọba ní ọ̀run lọ́dún 1914. (Ka Dáníẹ́lì 7:13, 14) Ní kété lẹ́yìn tí Jésù di Ọba, ó ṣe ohun kan. Bíbélì sọ pé: “Ogun sì bẹ́ sílẹ̀ ní ọ̀run: Máíkẹ́lì [orúkọ mìíràn tí Jésù ń jẹ́] àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ bá dírágónì náà [ìyẹn Sátánì Èṣù] jagun, dírágónì náà àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sì jagun.” * Sátánì àtàwọn áńgẹ́lì búburú rẹ̀, ìyẹn àwọn ẹ̀mí èṣù, fìdí rẹmi nínú ogun yẹn, wọ́n sì dẹni tí wọ́n lé kúrò lọ́run wá sórí ilẹ̀ ayé. Àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ yọ̀ pé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ti lọ. Ṣùgbọ́n ìgbẹ̀yìn ogun yìí kò máyọ̀ wá fọ́mọ aráyé o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Bíbélì sọ ni pé: “Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé . . . nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.”—Ìṣípayá 12:7, 9, 12.

5 Jọ̀wọ́ ṣàkíyèsí àbájáde ogun tó jà ní ọ̀run. Èṣù yóò mú wàhálà tàbí ègbé bá ayé nítorí inú tó ń bí i. O máa tó rí i pé àkókò wàhálà yẹn gan-an la wà yìí. Ṣùgbọ́n kò ní pẹ́ o, “sáà àkókò kúkúrú” ni. Kódà, Sátánì mọ̀ pé àkókò kúkúrú lòun yóò fi fa wàhálà. Bíbélì pe sáà àkókò yìí ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (2 Tímótì 3:1) A mà dúpẹ́ o, pé Ọlọ́run yóò ká Èṣù lọ́wọ́ kò láìpẹ́ kó má bàa lè ṣe nǹkan kan fún ayé mọ́! Wá jẹ́ ká wo àwọn ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ tó  ti ń ṣẹlẹ̀ báyìí. Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yẹn á fi hàn pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí, á sì fi hàn pé láìpẹ́, Ìjọba Ọlọ́run yóò mú ìbùkún tí ò lópin wá bá àwọn tó fẹ́ràn Jèhófà. Ní báyìí, jẹ́ ká kọ́kọ́ wo mẹ́rin lára àwọn àmì tí Jésù sọ pé yóò jẹ́ àmì àkókò tá a wà.

ÀWỌN OHUN BÚBURÚ TÍ YÓÒ MÁA ṢẸLẸ̀ LÁWỌN ỌJỌ́ ÌKẸYÌN

6, 7. Báwo lohun tí Jésù sọ nípa ogun àti àìtó oúnjẹ ṣe ń nímùúṣẹ lónìí?

6 “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba.” (Mátíù 24:7) Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ni ogun pa ní ọgọ́rùn-ún ọdún tó kọjá. Òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan kọ̀wé pé: “Látìgbà táláyé ti dáyé, ọ̀rúndún ogún ni wọ́n ti pààyàn jù. . . . Òun ni ọ̀rúndún tó jẹ́ pé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ìgbà kan tógun ò jà, nítorí pé láwọn orílẹ̀-èdè kan, gbogbo ìgbà ni wọ́n ń dìídì dá ogun sílẹ̀; ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan logun kì í jà.” Ìròyìn kan látọ̀dọ̀ Àjọ Tó Ń Rí sí Àwọn Ohun Tó Ń Lọ Lágbàáyé sọ pé: “Ìlọ́po mẹ́ta iye àwọn tí ogun pa láti ọ̀rúndún kìíní Ọdún Olúwa Wa títí di ọdún 1899 ni ogun pa ní ọ̀rúndún ogún nìkan.” Láti ọdún 1914, ó ju ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù èèyàn lọ tó kú látàrí ogun. Tó bá jẹ́ pé àwọn èèyàn tiwa náà ti bógun lọ rí, ó ṣeé ṣe ká ti rí ìbànújẹ́ tó máa ń bá àwọn  téèyàn wọn bógun lọ. Àmọ́, ṣé a lè mọ àpapọ̀ ìbànújẹ́ tó bá ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn jákèjádò ayé tógun ti pa àwọn èèyàn wọn? Rárá, a ò lè mọ̀ ọ́n.

7 “Àìtó oúnjẹ . . . yóò wà.” (Mátíù 24:7) Àwọn olùṣèwádìí sọ pé oúnjẹ tá à ń pèsè ti pọ̀ sí i lọ́nà tó yamùrá láti ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn títí di àkókò yìí. Síbẹ̀síbẹ̀, àìtó oúnjẹ ṣì wà nítorí pé àwọn èèyàn ò lówó tó tó láti fi ra oúnjẹ, àwọn kan ò sì nílẹ̀ tí wọ́n lè gbin nǹkan sí. Láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló jẹ́ pé ìwọ̀nba owó táṣẹ́rẹ́ ni wọ́n ń rí lójúmọ́, ebi àpafẹ́ẹ̀ẹ́kú ló sì ń pa ọ̀pọ̀ jù lọ wọn. Àjọ Ìlera Àgbáyé díwọ̀n rẹ̀ pé àìrí oúnjẹ aṣaralóore jẹ ló ń ṣokùnfà ikú tó ń pa àwọn ọmọdé tí iye wọn ju mílíọ̀nù márùn-ún lọ lọ́dọọdún.

8, 9. Kí ló fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù sọ nípa ìmìtìtì ilẹ̀ àti àjàkálẹ̀ àrùn ń nímùúṣẹ?

8 “Ìsẹ̀lẹ̀ ńláǹlà yóò sì wà.” (Lúùkù 21:11) Àjọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà Tí Ń Ṣèwádìí Nípa Ilẹ̀ Ayé Àtàwọn Ohun Tó Wà Nínú Rẹ̀ sọ pé láti ọdún 1990, mẹ́tàdínlógún lára àwọn ìmìtìtì ilẹ̀ tó ń wáyé lọ́dọọdún ló lágbára débi tí wọ́n fi ń ba ọ̀pọ̀ ilé jẹ́ tí wọ́n sì ń fa ilẹ̀ ya. Bákan náà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ lè jẹ́ pé ọdọọdún làwọn ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára tó láti wó ilé ń ṣẹlẹ̀. Ìwé mìíràn tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ  pé: “Ọgọ́rọ̀ọ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ni ìmìtìtì ilẹ̀ pa ní ọgọ́rùn-ún ọdún tó kọjá, díẹ̀ sì ni ìtẹ̀síwájú nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ń ṣe láti gba ẹ̀mí àwọn èèyàn là.”

9 ‘Àwọn àjàkálẹ̀ àrùn yóò wà.’ (Lúùkù 21:11) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtẹ̀síwájú ń ṣẹlẹ̀ lágbo ìmọ̀ ìṣègùn, àwọn àìsàn tó ti wà tipẹ́tipẹ́ àtàwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọjú ṣì ń pọ́n ọmọ aráyé lójú. Ìròyìn kan sọ pé ogún àrùn táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa ti wá wọ́pọ̀ gan-an láti ẹ̀wádún díẹ̀ sẹ́yìn títí di àsìkò yìí. Lára irú àwọn àrùn bẹ́ẹ̀ ni ikọ́ ẹ̀gbẹ, ibà àti àrùn onígbá méjì. Oríṣi àwọn àrùn kan ò sì fẹ́ gbóògùn mọ́. Ó kéré tán, ọgbọ̀n àrùn ló tún ṣẹ̀ṣẹ̀ yọjú. Àwọn kan lára wọn ò gbóògùn, gbẹ̀mígbẹ̀mí sì ni wọ́n.

IRÚ ÌWÀ TÁWỌN ÈÈYÀN YÓÒ MÁA HÙ LÁWỌN ỌJỌ́ ÌKẸYÌN

10. Nínú àwọn ohun tí 2 Tímótì 3:1-5 sọ tẹ́lẹ̀, èwo lo fúnra rẹ rí táwọn èèyàn ń hù níwà lónìí?

10 Yàtọ̀ sáwọn ohun burúkú tí yóò máa ṣẹlẹ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn, Bíbélì tún sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn nǹkan ò ní rí bó ṣe máa ń rí mọ́ láwùjọ ẹ̀dá. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ irú èèyàn tí ọ̀pọ̀ jù lọ yóò yà. Ó sọ pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà  níhìn-ín.” (Ka 2 Tímótì 3:1-5) Ara ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn èèyàn yóò yà ni

 • olùfẹ́ ara wọn

 • olùfẹ́ owó

 • aṣàìgbọràn sí òbí

 • aláìdúróṣinṣin

 • aláìní ìfẹ́ni àdánidá

 • aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu

 • òǹrorò

 • olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run

 • àwọn tí wọ́n ní ìrísí fífọkànsin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀

11. Báwo ni Sáàmù 92:7 ṣe ṣàpèjúwe ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sáwọn ẹni ibi?

11 Ṣé irú èèyàn táwọn tó wà ládùúgbò rẹ yà nìyẹn? Ó dájú pé bẹ́ẹ̀ ni. Kò síbi táwọn èèyàn tí ìwàkiwà kún ọwọ́ wọn ò sí. Ohun tí ìyẹn sì fi hàn ni pé Ọlọ́run ò ní pẹ́ wá nǹkan ṣe sí i, nítorí Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí àwọn ẹni burúkú bá rú jáde bí ewéko, tí gbogbo àwọn aṣenilọ́ṣẹ́ bá sì yọ ìtànná, kí a lè pa wọ́n rẹ́ ráúráú títí láé ni.”—Sáàmù 92:7.

ÀWỌN ÌṢẸ̀LẸ̀ RERE!

12, 13. Báwo ni “ìmọ̀ tòótọ́” ṣe di púpọ̀ yanturu ní “àkókò òpin” yìí?

12 Kò sí àní-àní pé, bí Bíbélì ti  sọ tẹ́lẹ̀, wàhálà ló kúnnú ayé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Ṣùgbọ́n nínú ayé oníwàhálà yìí, àwọn ohun rere ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn tó ń sin Jèhófà.

13 Ìwé Bíbélì tá à ń pè ní Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé, “ìmọ̀ tòótọ́ yóò . . . di púpọ̀ yanturu.” Ìgbà wo nìyẹn máa wáyé? “Àkókò òpin” ni. (Dáníẹ́lì 12:4) Ní pàtàkì láti ọdún 1914 ni Jèhófà ti ń jẹ́ kí àwọn tó fẹ́ sìn ín tọkàntọkàn máa túbọ̀ lóye àwọn ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Wọ́n ti túbọ̀ mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa orúkọ Ọlọ́run àtohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn tó fi dá ilẹ̀ ayé, wọ́n ti mọ òtítọ́ nípa ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi, ipò táwọn òkú wà, àti àjíǹde. Kò mọ síbẹ̀ o, àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà ti mọ bí wọ́n á ṣe máa gbé ìgbé ayé wọn lọ́nà tí yóò ṣe wọ́n láǹfààní tí yóò sì mú ìyìn bá Ọlọ́run. Wọ́n tún ti túbọ̀ mọ ipa tí Ìjọba Ọlọ́run fẹ́ kó àti bí yóò ṣe mú àwọn ìṣòro tó wà lórí ilẹ̀ ayé kúrò. Kí wá ni wọ́n ń fi ìmọ̀ tí wọ́n ní yìí ṣe? Ìbéèrè yẹn tún mú wa lọ sórí àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn tó ń nímùúṣẹ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí.

“A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.”​—Mátíù 24:14

14. Ibo ni ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ti gbòòrò dé lónìí, àwọn wo ló sì ń wàásù rẹ̀?

14 Nígbà tí Jésù ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa “ìparí ètò àwọn nǹkan,” ó ní: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” (Ka Mátíù 24:3, 14) Jákèjádò ayé, ó ju igba ó lé ọgbọ̀n ilẹ̀ [230] lọ tá a ti ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn, ohun tí Ìjọba náà jẹ́, ohun tí yóò gbé ṣe, àti bá a ṣe lè rí àwọn ìbùkún tí yóò mú wá gbà. Ó sì ju irínwó [400] èdè lọ tá a fi ń wàásù náà. Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń fi ìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Wọ́n wá látinú “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n.” (Ìṣípayá 7:9) Ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù àwọn èèyàn tí wọ́n fẹ́ mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ nínú ilé wọn. Ìjọlójú gbáà ló jẹ́, pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí lè máa nímùúṣẹ báyìí pàápàá lójú  ohun tí Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn Kristẹni tòótọ́ yóò jẹ́ “ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn”!—Lúùkù 21:17.

KÍ NI WÀÁ ṢE?

15. (a) Ǹjẹ́ o gbà pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí, kí sì nìdí tó o fi dáhùn bó o ṣe dáhùn? (b) Kí ni “òpin” yóò mú bá àwọn tó ń ta ko Jèhófà, kí sì ni yóò mú bá àwọn tó fi ara wọn sábẹ́ àkóso Ìjọba Ọlọ́run?

15 Pẹ̀lú bí ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe ń nímùúṣẹ lákòókò yìí, ǹjẹ́ o ò gbà pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí? Ó dá jú pé “òpin” yóò dé tá a bá ti wàásù débi tó tẹ́ Jèhófà lọ́rùn pé ká wàásù dé. (Mátíù 24:14) “Òpin” ni ìgbà tí Ọlọ́run yóò mú ìwà búburú kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn tó ń mọ̀ọ́mọ̀ ta kò Jèhófà ni Jèhófà yóò lo Jésù àtàwọn áńgẹ́lì Rẹ̀ alágbára láti pa run. (2 Tẹsalóníkà 1:6-9) Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kò tún ní máa ṣi àwọn orílẹ̀-èdè lọ́nà mọ́. Lẹ́yìn náà, Ìjọba Ọlọ́run yóò mú ìbùkún rẹpẹtẹ bá àwọn tó bá fi ara wọn sábẹ́ àkóso òdodo rẹ̀.—Ìṣípayá 20:1-3; 21:3-5.

16. Kí lohun tó máa dára pé ká ṣe?

16 Níwọ̀n bí òpin ètò Sátánì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé, ohun tó yẹ ká bi ara wa ni pé: ‘Kí ló yẹ kí ń máa ṣe báyìí?’ Ohun tó máa dára pé ká ṣe ni pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà àtàwọn ohun tó ń béèrè lọ́wọ́ wa. (Jòhánù 17:3) Máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójú méjèèjì. Jẹ́ kó di àṣà rẹ láti máa bá àwọn tó jẹ́ pé ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ló jẹ wọ́n lógún kẹ́gbẹ́. (Ka Hébérù 10:24, 25) Máa gba ìmọ̀ tí Jèhófà ń fún àwọn èèyàn jákèjádò ayé sínú, kó o sì ṣe àwọn ìyípadà tó pọn dandan nínú ìgbésí ayé rẹ kó o bàa lè rí ojú rere Ọlọ́run.—Jákọ́bù 4:8.

17. Kí nìdí tí ìparun àwọn ẹni ibi yóò fi dé bá ọ̀pọ̀ èèyàn lójijì?

17 Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé ọ̀pọ̀ jù lọ ló máa rí ẹ̀rí tó fi hàn pé ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí, àmọ́ wọn kò ní kà á sí. Ńṣe ni ìparun àwọn ẹni ibi yóò dé lójijì. Yóò bá ọ̀pọ̀ èèyàn láìròtẹ́lẹ̀ bí ìgbà tí olè bá dé lójijì. (Ka 1 Tẹsalóníkà 5:2) Jésù kìlọ̀ pé: “Bí àwọn ọjọ́ Nóà ti rí, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí. Nítorí bí wọ́n ti wà ní ọjọ́ wọnnì ṣáájú ìkún  omi, wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, a sì ń fi àwọn obìnrin fúnni nínú ìgbéyàwó, títí di ọjọ́ tí Nóà wọ ọkọ̀ áàkì; wọn kò sì fiyè sí i títí ìkún omi fi dé, tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí.”—Mátíù 24:37-39.

18. Kí ni ìkìlọ̀ Jésù tá a gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn?

18 Ìyẹn ló mú kí Jésù sọ fáwọn olùgbọ́ rẹ̀ pé: “Ẹ kíyè sí ara yín, kí ọkàn-àyà yín má bàa di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri àti àwọn àníyàn ìgbésí ayé, lójijì tí ọjọ́ yẹn yóò sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn. Nítorí yóò dé bá gbogbo àwọn tí ń gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé. Ẹ máa wà lójúfò, nígbà náà, ní rírawọ́ ẹ̀bẹ̀ ní gbogbo ìgbà, kí ẹ lè kẹ́sẹ járí ní yíyèbọ́ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti ṣẹlẹ̀, àti ní dídúró [ìyẹn ni, láti wà ní ipò ẹni tá a ṣojú rere sí] níwájú Ọmọ ènìyàn.” (Lúùkù 21:34-36) Ọlọgbọ́n lẹni tó bá fi ọ̀rọ̀ Jésù yìí sọ́kàn o. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn tó bá rí ojú rere Jèhófà Ọlọ́run àti ti “Ọmọ ènìyàn,” ìyẹn Jésù Kristi, yóò nírètí láti la òpin ètò Sátánì já wọn yóò sì nírètí láti gbé nínú ayé tuntun àgbàyanu tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé báyìí!—Jòhánù 3:16; 2 Pétérù 3:13.

^ ìpínrọ̀ 4 Tó o bá fẹ́ rí àlàyé síwájú sí i tó fi hàn pé Máíkẹ́lì jẹ́ orúkọ mìíràn tí Jésù ń jẹ́, wo Àfikún, “Ta Ni Máíkẹ́lì Olú-Áńgẹ́lì?”.