Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ṣé Ohun Tí Ọlọ́run Fẹ́ Kó Máa Ṣẹlẹ̀ Nìyí?

Ṣé Ohun Tí Ọlọ́run Fẹ́ Kó Máa Ṣẹlẹ̀ Nìyí?

KA ÌWÉ ìròyìn èyíkéyìí tó o bá rí. Wo tẹlifíṣọ̀n, tàbí kó o gbọ́ rédíò, wàá rí i pé ìròyìn nípa ìwà ọ̀daràn, ogun àti ìpániláyà ló gbayé kan. Ronú nípa ìdààmú ọkàn tíwọ fúnra rẹ náà ní. Bóyá àìlera tàbí ikú ẹnì kan tó o fẹ́ràn ló tiẹ̀ ń kó ìdààmú ọkàn bá ọ. Ó lè máa ṣe ọ́ bíi ti Jóòbù tó sọ pé, “ìdààmú bo [òun] mọ́lẹ̀.”—Jóòbù 10:15, Ìtumọ̀ Bíbélì The Holy Bible in the Language of Today.

Wá bí ara rẹ pé:

  • Ṣé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kó máa ṣẹlẹ̀ sí mi àti sáwọn èèyàn yòókù láyé rèé?

  • Ibo ni màá ti rí ìrànlọ́wọ́ tí màá fi lè kojú àwọn ìṣòro mi?

  • Ǹjẹ́ ìrètí kankan tiẹ̀ wà pé àlàáfíà ṣì ń bọ̀ wá jọba lórí ilẹ̀ ayé yìí?

Inú Bíbélì la ti lè rí ìdáhùn tí ń tẹni lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.

 BÍBÉLÌ FI KỌ́NI PÉ ỌLỌ́RUN YÓÒ MÚ KÍ ÀWỌN OHUN RERE WỌ̀NYÍ ṢẸLẸ̀ LÓRÍ ILẸ̀ AYÉ.

“Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.”Ìṣípayá 21:4

“Ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe.”Aísáyà 35:6

“Ojú àwọn afọ́jú yóò là.” Aísáyà 35:5

 “Gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò . . . jáde wá.”Jòhánù 5:28, 29

“Kò sì sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”Aísáyà 33:24

“Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀.”Sáàmù 72:16

 JÀǸFÀÀNÍ NÍNÚ OHUN TÍ BÍBÉLÌ FI KỌ́NI

Má ṣe yára rò pé àlá tí ò lè ṣẹ làwọn ohun tó o rí ní àwọn ojú ìwé tó ṣáájú. Ọlọ́run ti ṣèlérí pé òun á ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyẹn fún wa, Bíbélì sì sọ bó ṣe máa ṣe é.

Àmọ́ kì í ṣe bí Ọlọ́run ṣe máa ṣe àwọn ohun tó ṣèlérí nìkan ni Bíbélì sọ o. Ó tún sọ bó o ṣe lè máa gbé ìgbé ayé aláyọ̀, kódà, lákòókò tá a wà yìí pàápàá. Ronú fúngbà díẹ̀ ná nípa ìdààmú ọkàn àti ìṣòro tó o máa ń ní. Ó lè jẹ́ ìṣòro àìlówó lọ́wọ́, ìṣòro ìdílé, ìṣòro àìlera tàbí ikú èèyàn rẹ kan. Bíbélì lè ràn ọ́ lọ́wọ́ ko o lè fara da àwọn ìṣòro wọ̀nyẹn nísinsìnyí, ó sì lè mára tù ọ́ nípa dídáhùn àwọn ìbéèrè bíi:

  • Kí nìdí tá a fi ń jìyà?

  • Báwo la ṣe lè borí àníyàn ìgbésí ayé?

  • Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ìdílé wa túbọ̀ láyọ̀?

  • Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà tá a bá kú?

  • Ǹjẹ́ a óò tún padà rí àwọn èèyàn wa tó ti kú?

  • Báwo ló ṣe lè dá wa lójú pé Ọlọ́run yóò mú àwọn ohun tó ṣèlérí pé òun yóò ṣe ní ọjọ́ ọ̀la ṣẹ?

 Kíkà tó ò ń ka ìwé yìí fi hàn pé wàá fẹ́ láti mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an. Ìwé yìí á sì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ̀ ọ́n. Kíyè sí i pé ìbéèrè ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan wà ní ìsàlẹ̀ ojú ìwé tí ìpínrọ̀ náà wà. Ọ̀pọ̀ ló ń gbádùn ìlànà lílo ìbéèrè àti ìdáhùn nígbà tí wọ́n bá ń bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fọ̀rọ̀ wérọ̀ nínú Bíbélì. A nírètí pé ìwọ náà yóò gbádùn rẹ̀. Kí Ọlọ́run bù kún ọ bó o ti ń gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ alárinrin nípa àwọn ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an!