Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORÍ KẸTÀLÁ

Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Ẹ̀mí Ni Kí Ìwọ Náà Máa Fi Wò Ó

Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Ẹ̀mí Ni Kí Ìwọ Náà Máa Fi Wò Ó
  • Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo ẹ̀mí?

  • Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo ìṣẹ́yún?

  • Báwo la ṣe lè fi hàn pé ẹ̀mí jọ wá lójú?

1. Ta ló dá gbogbo ohun alààyè?

WÒLÍÌ Jeremáyà sọ pé: “Ní òtítọ́, Jèhófà ni Ọlọ́run. Òun ni Ọlọ́run alààyè.” (Jeremáyà 10:10) Láfikún, Jèhófà Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá gbogbo ohun alààyè. Àwọn ẹ̀dá tó wà lọ́run sọ fún Jèhófà pé: “Ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.” (Ìṣípayá 4:11) Nínú orin ìyìn kan tí Ọba Dáfídì kọ sí Ọlọ́run, ó sọ pé: “Nítorí pé ọ̀dọ̀ rẹ ni orísun ìyè wà.” (Sáàmù 36:9) Nítorí náà, ẹ̀mí jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

2. Kí ni Ọlọ́run ṣe láti gbé ẹ̀mí wa ró?

2 Jèhófà tún ń gbé ẹ̀mí wa ró. (Ìṣe 17:28) Òun ló dá oúnjẹ tá à ń jẹ, omi tá à ń mu àti ilẹ̀ ayé tá à ń gbé. (Ka Ìṣe 14:15-17) Jèhófà ṣe gbogbo ìwọ̀nyí lọ́nà tí a ó fi lè gbádùn ìwàláàyè. Ṣùgbọ́n tá a bá fẹ́ gbádùn ìwàláàyè wa dáadáa, a gbọ́dọ̀ mọ àwọn òfin Ọlọ́run ká sì máa pa wọ́n mọ́.—Aísáyà 48:17, 18.

JẸ́ KÍ Ẹ̀MÍ OHUN ALÀÀYÈ JỌ Ọ́ LÓJÚ

3. Ojú wo ni Ọlọ́run fi wo pípa tí Kéènì pa Ébẹ́lì?

3 Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé kí ẹ̀mí jọ wá lójú, ì bá à jẹ́ ẹ̀mí àwa alára tàbí ẹ̀mí àwọn ẹlòmíràn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà ayé Ádámù àti Éfà, inú bẹ̀rẹ̀ sí bí Kéènì ọmọ wọn sí Ébẹ́lì àbúrò rẹ̀. Jèhófà kìlọ̀ fún un pé inú tó ń bí i yẹn lè mú kó  dẹ́ṣẹ̀ ńlá. Ṣùgbọ́n Kéènì kọ̀, kò gba ìkìlọ̀. Ẹ̀yìn-ọ̀-rẹyìn, ó “fipá kọlu Ébẹ́lì arákùnrin rẹ̀, ó sì pa á.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:3-8) Jèhófà ò jẹ́ kí Kéènì lọ láìjìyà nítorí pípa tó pa àbúrò rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 4:9-11.

4. Nínú Òfin Mósè, báwo ni Ọlọ́run ṣe tẹnu mọ́ ojú tó yẹ kéèyàn máa fi wo ẹ̀mí?

4 Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [2,400] ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láwọn òfin tí yóò jẹ́ kí wọ́n máa sìn ín lọ́nà tó fẹ́. Nígbà mìíràn, a máa ń pe àwọn òfin wọ̀nyí ní Òfin Mósè nítorí pé ipasẹ̀ wòlíì Mósè ni Ọlọ́run gbà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láwọn òfin náà. Ọ̀kan nínú àwọn òfin náà sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣìkà pànìyàn.” (Diutarónómì 5:17) Èyí jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ̀ pé ẹ̀mí èèyàn jọ Ọlọ́run lójú. Ó tún fi yé wọn pé ẹ̀mí àwọn ẹlòmíràn gbọ́dọ̀ jọni lójú.

5. Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo ìṣẹ́yún?

5 Ẹ̀mí ọmọ tí wọn ò tíì bí ńkọ́? Òfin Mósè sọ pé ó burú kéèyàn pa ọmọ tó ṣì wà nínú ìyá rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀mí ọmọ tí wọn ò tíì bí pàápàá ṣeyebíye lójú Jèhófà. (Ka Ẹ́kísódù 21:22, 23; Sáàmù 127:3) Èyí fi hàn pé kò tọ̀nà kéèyàn ṣẹ́yún.

6. Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ kórìíra èèyàn ẹlẹgbẹ́ wa?

6 Ọ̀nà mìíràn tá a lè gbà fi hàn pé ẹ̀mí jọ wá lójú ni pé ká má máa ní èrò búburú lọ́kàn sáwọn ẹlòmíràn. Bíbélì sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá kórìíra arákùnrin rẹ̀ jẹ́ apànìyàn, ẹ̀yin sì mọ̀ pé kò sí apànìyàn kankan tí ìyè àìnípẹ̀kun dúró nínú rẹ̀.” (1 Jòhánù 3:15) Tá a bá fẹ́ ní ìyè àìnípẹ̀kun, a ní láti fa gbogbo ìkórìíra tá a ní séèyàn ẹlẹgbẹ́ wa tu pátápátá kúrò lọ́kàn wa, nítorí pé ìkórìíra ló sábà máa ǹ fa ìwà ipá. (1 Jòhánù 3:11, 12) Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká nífẹ̀ẹ́ ẹnì kejì wa.

7. Irú àwọn ìwà wo lẹnì kan lè máa hù tí yóò fi hàn pé ẹ̀mí ò jọ ọ́ lójú?

7 Ẹ̀mí àwa fúnra wa ńkọ́, ṣé ó yẹ ká jẹ́ kó jọ wá lójú? Kò sẹ́ni tó fẹ́ kú, àmọ́, àwọn kan máa ń fi ẹ̀mí ara wọn  wewu nítorí fàájì. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ló ń mu tábà tàbí igbó, ọ̀pọ̀ ló sì ń fín aáṣáà tàbí tí wọ́n ń lo àwọn oògùn olóró mìíràn. Àwọn ohun wọ̀nyí máa ń ṣèpalára fún ara, wọ́n sì sábà máa ń gbẹ̀mí àwọn tó ń lò wọ́n. Ẹni tó bá ń lo àwọn nǹkan wọ̀nyí kò ka ẹ̀mí sí ohun ọ̀wọ̀. Lójú Ọlọ́run, ìwà àìmọ́ ni kéèyàn máa lo àwọn nǹkan wọ̀nyí. (Ka Róòmù 6:19; 12:1; 2 Kọ́ríńtì 7:1) Tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbá ìjọsìn wa, a gbọ́dọ̀ jáwọ́ nínú irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀. Ó lè má rọrùn láti jáwọ́, ṣùgbọ́n Jèhófà yóò ràn wá lọ́wọ́ ká lè jáwọ́. Tá a bá ń gbìyànjú láti fi hàn nínú ìṣe wa pé ẹ̀mí tí Jèhófà fún wa jọ wá lójú, Jèhófà yóò mọrírì rẹ̀.

8. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká fi ọ̀rọ̀ ààbò ṣeré?

8 Bí ẹ̀mí bá jọ wá lójú, a ò ní fi ọ̀rọ̀ ààbò ṣeré. A ò ní jẹ́ ẹni tí kò bìkítà, a ò sì ní máa fẹ̀mí ara wa wewu nítorí fàájì lásán-làsàn. A ò ní máa wakọ̀ níwàkuwà, a ò sì ní máa ṣe eré egéle tàbí eré oníwà ipá. (Sáàmù 11:5) Òfin tí Ọlọ́run fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láyé àtijọ́ sọ pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o kọ́ ilé tuntun [tó ní òrùlé pẹrẹsẹ], kí o ṣe ìgbátí [tàbí ògiri tí kò ga] sí òrùlé rẹ, kí ìwọ má bàa fi ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ sórí ilé rẹ nítorí pé ẹnì kan tí ń ṣubú lọ lè já bọ́ láti orí rẹ̀.” (Diutarónómì 22:8) Ìlànà tó wà nínú òfin náà fi hàn pé, tó o bá ní àtẹ̀gùn nínú ilé rẹ, kó o rí i pé o ṣe ibi ìfọwọ́mú sí i kéèyàn má bàa ṣubú tàbí kó ré lulẹ̀ lórí rẹ̀. Tó o bá ní ọkọ̀, rí i pé o ń tún un ṣe dáadáa kó má lọ di pàkúté ikú tó o bá ń wà á. Má ṣe jẹ́ kí ilé rẹ tàbí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ di ohun tó lè wuni léwu.

9. Tí ẹ̀mí bá jọ wá lójú, báwo ni a ó ṣe máa ṣe sáwọn ẹranko?

9 Ẹ̀mí ẹranko ńkọ́? Ẹlẹ́dàá ka ẹ̀mí ẹranko náà sí ohun ọ̀wọ̀. Ọlọ́run ò ní ká má pa ẹranko jẹ, ko sì ní ká má pa á láti rí nǹkan mìíràn tó wúlò lára rẹ̀, irú bí aṣọ. Tí ẹranko kan bá sì lè ṣeni léṣe, a lè pa á. (Jẹ́nẹ́sísì 3:21; 9:3; Ẹ́kísódù 21:28) Ṣùgbọ́n ó burú ká jẹ́ òǹrorò sí ẹranko tàbí ká kàn  máa pa wọ́n láti fi ṣe eré ìdárayá lásán. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ pé a ò ka ẹ̀mí sí ohun ọ̀wọ̀ rárá nìyẹn.—Òwe 12:10.

KA Ẹ̀JẸ̀ SÍ OHUN Ọ̀WỌ̀

10. Báwo ni Ọlọ́run ṣe fi hàn pé ẹ̀jẹ̀ àti ẹ̀mí bára wọn tan?

10 Lẹ́yìn tí Kéènì pa Ébẹ́lì àbúrò rẹ̀, Jèhófà sọ fún un pé: “Ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ ń ké jáde sí mi láti inú ilẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:10) Nígbà tí Ọlọ́run sọ pé, ẹ̀jẹ̀ Ébẹ́lì, ohun tó ní lọ́kàn ni ẹ̀mí Ébẹ́lì. Kéènì ò ní lọ láìjìyà nítorí pé ó gbẹ̀mí àbúrò rẹ̀. Àfi bíi pé ẹ̀jẹ̀ Ébẹ́lì, tàbí ẹ̀mí rẹ̀, ń ké pe Jèhófà pé kí Jèhófà gbẹ̀san. Lẹ́yìn Ìkún Omi ọjọ́ Nóà, Jèhófà tún fi hàn pé ẹ̀jẹ̀ àti ẹ̀mí bára tan. Ṣáájú Ìkún Omi, èso, ẹ̀fọ́, oúnjẹ oníhóró àtàwọn oríṣi oúnjẹ mìíràn làwọn èèyàn máa ń jẹ. Àmọ́ lẹ́yìn ìkún omi, Jèhófà sọ fún Nóà àtàwọn ọmọ rẹ̀ pé: “Gbogbo ẹran tí ń rìn, tí ó wà láàyè, lè jẹ́ oúnjẹ fún yín. Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ti ewéko tútù yọ̀yọ̀, mo fi gbogbo rẹ̀ fún yín ní ti gidi.” Àmọ́, Ọlọ́run kà á léèwọ̀ fún wọn pé: “Kìkì ẹran pẹ̀lú ọkàn rẹ̀ [tàbí ẹ̀mí]—ẹ̀jẹ̀ rẹ̀—ni ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:29; 9:3, 4) Nípa bẹ́ẹ̀, Jèhófà fi hàn pé ẹ̀jẹ̀ àti ẹ̀mí bára wọn tan pẹ́kípẹ́kí.

11. Látìgbà ayé Nóà, kí ni Ọlọ́run sọ pé a kò gbọ́dọ̀ fi ẹ̀jẹ̀ ṣe?

11 A lè fi hàn pé a ka ẹ̀jẹ̀ sí ohun ọ̀wọ̀ tí a kì í bá jẹ ẹ́. Nínú Òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó pàṣẹ pé: “Ní ti ọkùnrin èyíkéyìí . . . tí ó jẹ́ pé nígbà tí ó ń ṣọdẹ, ó mú ẹranko ìgbẹ́ tàbí ẹ̀dá abìyẹ́ tí a lè jẹ, bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ó da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ jáde, kí ó sì fi ekuru bò ó. . . . Mo wí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: ‘Ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ẹran ara èyíkéyìí.’” (Léfítíkù 17:13, 14) Ìyẹn fi hàn pé àṣẹ tí Ọlọ́run fún Nóà ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rin [800] ọdún ṣáájú kò tíì yí padà, ìyẹn àṣẹ tó sọ pé kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ẹran. Èrò Jèhófà lórí ọ̀ràn yìí ṣe kedere, pé: Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lè jẹ ẹran, ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀. Orí ilẹ̀ ni wọ́n gbọ́dọ̀ da ẹ̀jẹ̀ sí, nípa bẹ́ẹ̀ wọ́n á dá ẹ̀mí ẹranko náà padà fún Ọlọ́run.

12. Àṣẹ wo ni ẹ̀mí mímọ́ pa ní ọ̀rúndún kìíní tó ṣì wà dòní olónìí?

 12 Irú àṣẹ yìí wà fáwọn Kristẹni. Àwọn àpọ́sítélì àtàwọn ọkùnrin kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní ọ̀rúndún kìíní tí wọ́n ń mú ipò iwájú ṣèpàdé láti lè mọ àwọn àṣẹ tó yẹ kí gbogbo ìjọ Kristẹni máa pa mọ́. Ibi tí wọ́n fẹnu ọ̀rọ̀ jóná sí ni pé: “Ẹ̀mí mímọ́ àti àwa fúnra wa ti fara mọ́ ṣíṣàìtún fi ẹrù ìnira kankan kún un fún yín, àyàfi nǹkan pípọndandan wọ̀nyí, láti máa ta kété sí àwọn ohun tí a fi rúbọ sí òrìṣà àti sí ẹ̀jẹ̀ àti sí ohun tí a fún lọ́rùn pa [ìyẹn ẹran tí wọn kò ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dà nù] àti sí àgbèrè.” (Ìṣe 15:28, 29; 21:25) Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ máa ‘ta kété sí ẹ̀jẹ̀.’ Lójú Ọlọ́run, bí yíyẹra fún ìbọ̀rìṣà àti ìṣekúṣe ti ṣe pàtàkì, bẹ́ẹ̀ náà ni títa kété sí ẹ̀jẹ̀ ti ṣe pàtàkì.

Bí dókítà rẹ bá sọ fún ọ pé o kò gbọ́dọ̀ mú ọtí líle, ṣé wàá gbà kí ẹnì kan fà á sí ọ lára?

13. Ṣàpèjúwe bí àṣẹ tó sọ pé ká ta kété sí ẹ̀jẹ̀ ṣe kan ìfàjẹ̀sínilára.

13 Ṣe àṣẹ tó sọ pé kéèyàn ta kété sí ẹ̀jẹ̀ kan ìfàjẹ̀sínilára náà? Bẹ́ẹ̀ ni. Wo àpèjúwe yìí ná: Ká sọ pé oníṣègùn kan sọ fún ọ pé o kò gbọ́dọ̀ mú ọtí líle, ṣé wàá rò pé ohun tó ń sọ ni pé kó o sáà ti má gba ẹnu mu ún, pé o lè jẹ́ kí wọ́n fà á sí ọ lára? Ó dájú pé o kò ní rò bẹ́ẹ̀! Bákan náà, títakété sí ẹ̀jẹ̀ túmọ̀ sí pé èèyàn ò gbọ́dọ̀ gbà á sára lọ́nàkọnà. Nítorí náà, ohun tí àṣẹ tó sọ pé ká ta kété sí ẹ̀jẹ̀ ń sọ ni pé a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fa ẹ̀jẹ̀ sí wa lára.

14, 15. Bí oníṣègùn bá sọ pé ó di dandan kí Kristẹni kan gba ẹ̀jẹ̀ sára, kí lo rò pé ó máa ṣe, kí sì nìdí tó fi máa ṣe bẹ́ẹ̀?

14 Bí Kristẹni kan bá fara pa yánnayànna ńkọ́, tàbí tí wọ́n fẹ́ ṣiṣẹ́ abẹ tó le gan-an fún un? Ká sọ pé oníṣègùn sọ pé yóò kú tí kò bá gba ẹ̀jẹ̀ sára. Kí ló máa ṣe? Dájúdájú, Kristẹni náà ò ní fẹ́ kú. Nítorí pé kò ní fẹ́ pàdánù ẹ̀mí tó jẹ ẹ̀bùn iyebíye látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, yóò gbà kí wọ́n tọ́jú òun lọ́nà tí kò ní la ìfàjẹ̀sínilára lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, tí irú ìtọ́jú tí kò ní la ìfàjẹ̀sínilára lọ tá a sọ yìí bá wà, irú rẹ̀ lẹni náà máa wá. Ó sì tún lè wá oríṣi àwọn ìtọ́jú ìṣègùn mìíràn dípò gbígba ẹ̀jẹ̀ sára.

 15 Ǹjẹ́ o rò pé ó yẹ kí Kristẹni kan rú òfin Ọlọ́run nítorí kí ẹ̀mí rẹ̀ lè gùn díẹ̀ sí i nínú ayé yìí? Jésù sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ gba ọkàn [tàbí ẹ̀mí] rẹ̀ là yóò pàdánù rẹ̀; ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá pàdánù ọkàn rẹ̀ nítorí mi yóò rí i.” (Mátíù 16:25) Lóòótọ́, a ò fẹ́ kú. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé rírú òfin Ọlọ́run la fẹ́ fí dáàbò bo ẹ̀mí wa nísinsìnyí, a lè pàdánù ìyè àìnípẹ̀kun. Nítorí náà, ọlọgbọ́n ni wá tá a bá fọkàn tán òfin Ọlọ́run, tá a sì jẹ́ kó dá wa lójú pé bá a tiẹ̀ kú, Ẹni tó fún wa ní ẹ̀mí wa tó jẹ́ ẹ̀bùn iyebíye yóò rántí wa nígbà àjíǹde, yóò sì dá ẹ̀mí ọ̀hún padà fún wa.—Jòhánù 5:28, 29; Hébérù 11:6.

16. Kí ni ìpinnu àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lórí ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀?

16 Lónìí, ṣe ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ onígbọràn máa ń pinnu pé, ní tàwọn o, ohun tí Ọlọ́run sọ nípa ẹ̀jẹ̀ labẹ gé. Wọn ò ní jẹ ẹ̀jẹ̀ lọ́nàkọnà, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò ní gba á sára fún ìtọ́jú. * Wọ́n mọ̀ pé Ẹni tó dá ẹ̀jẹ̀ mọ ohun tó máa ṣe àwọn láǹfààní. Ǹjẹ́ ìwọ náà gbà pé Ẹlẹ́dàá mọ ohun tó máa ṣe wá láǹfààní?

Ọ̀NÀ KAN ṢOṢO TÓ TỌ́ LÁTI LO Ẹ̀JẸ̀

17. Lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ayé àtijọ́, ọ̀nà kan ṣoṣo wo ni Jèhófà Ọlọ́run fọwọ́ sí pé kí wọ́n máa gbà lo ẹ̀jẹ̀?

17 Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ ọ̀nà kan ṣoṣo  tó tọ́ láti lo ẹ̀jẹ̀. Jèhófà pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé àtijọ́ nípa ìjọsìn tó ní kí wọ́n máa ṣe, pé: “Ọkàn [tàbí ẹ̀mí] ara ń bẹ nínú ẹ̀jẹ̀, èmi tìkára mi sì ti fi sórí pẹpẹ fún yín láti ṣe ètùtù fún ọkàn yín, nítorí pé ẹ̀jẹ̀ ni ó ń ṣe ètùtù.” (Léfítíkù 17:11) Táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá dẹ́ṣẹ̀, kí Ọlọ́run lè dárí jì wọ́n, ńṣe ni wọ́n á pa ẹran, wọ́n á sì fi díẹ̀ lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sórí pẹpẹ tó wà nínú àgọ́ ìjọsìn. Nígbà tí wọ́n sì kọ́ tẹ́ńpìlì lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, orí pẹpẹ tó wà nínú tẹ́ńpìlì náà ni wọ́n máa ń fi ẹ̀jẹ̀ sí. Irú àwọn ìrúbọ bẹ́ẹ̀ nìkan ló tọ́ kí wọ́n lo ẹ̀jẹ̀ fún.

18. Ànfààní wo ni ẹ̀jẹ̀ Jésù ti wọ́n ta sílẹ̀ lè ṣe fún wa?

18 Àwọn Kristẹni kò sí lábẹ́ òfin Mósè o. Nítorí náà, wọn kì í fi ẹran rúbọ, wọn kì í sì í fi ẹ̀jẹ̀ ẹran sórí pẹpẹ. (Hébérù 10:1) Ṣùgbọn ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n máa ń fi sórí pẹpẹ lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ ṣàpẹẹrẹ ẹbọ iyebíye Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run. Bá a ṣe kẹ́kọ̀ọ́ ní Orí Karùn-ún ìwé yìí, Jésù fi  ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa nígbà tó jẹ́ kí wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ. Lẹ́yìn náà, ó padà sí ọ̀run ó sì fún Jèhófà ní ìtóye ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tí wọ́n ta sílẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. (Hébérù 9:11, 12) Ẹ̀jẹ̀ Jésù yẹn ló mú kí Ọlọ́run lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá ká sì ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun. (Mátíù 20:28; Jòhánù 3:16) O ò rí i pé ọ̀nà tó dára jù lọ láti lo ẹ̀jẹ̀ nìyí! (1 Pétérù 1:18, 19) Àfi téèyàn bá nígbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ Jésù nìkan ló fi lè rí ìgbàlà.

Báwo lo ṣe lè fi hàn pé ẹ̀mí jọ ọ́ lójú àti pé o ka ẹ̀jẹ̀ sí ohun ọ̀wọ̀?

19. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe kí “ọrùn [wa lè] mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn gbogbo”?

19 A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà fún àwọn ohun alààyè ní ẹ̀mí! Ǹjẹ́ kò yẹ kíyẹn mú ká lọ sọ fáwọn ẹlòmíràn pé àǹfààní ìyè àìnípẹ̀kun wà fáwọn tó bá nígbàgbọ́ nínú ẹbọ Jésù? Tó bá jẹ́ pé ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ẹ̀mí àwọn èèyàn làwa náà fi ń wò ó, ìtara àti ìháragàgà la ó fi lọ sọ fún wọn. (Ka Ìsíkíẹ́lì 3:17-21) Tá a bá fi gbogbo agbára wa ṣe ojúṣe wa yìí, a ó lè sọ bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé: “Ọrùn mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn gbogbo, nítorí pé èmi kò fà sẹ́yìn kúrò nínú sísọ gbogbo ìpinnu Ọlọ́run fún yín.” (Ìṣe 20:26, 27) Tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọrun àti ohun tó fẹ́ ṣe, ìyẹn á fi hàn pé ẹ̀mí jọ wá lójú, á sì tún fi hàn pé a ka ẹ̀jẹ̀ sí ohun ọ̀wọ̀.

^ ìpínrọ̀ 16 Kó o lè rí àlàyé nípa oríṣi ìtọ́jú mìíràn dípò gbígba ẹ̀jẹ̀ sára, wo ojú ìwé 13 sí 17 nínú ìwé pẹlẹbẹ náà, How Can Blood Save Your Life?, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe.