Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORÍ KẸTA

Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn Tó Fi Dá Ilẹ̀ Ayé?

Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn Tó Fi Dá Ilẹ̀ Ayé?
  • Kí ni Ọlọ́run ní lọ́kàn fún aráyé?

  • Báwo lẹnì kan ṣe ta ko Ọlọ́run?

  • Báwo nìgbésí ayé ṣe máa rí lórí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ iwájú?

1. Kí ni Ọlọ́run ní lọ́kàn tó fi dá ilẹ̀ ayé?

KÒ SÍ àní-àní pé ohun àgbàyanu ni Ọlọ́run ní lọ́kàn tó fi dá ilẹ̀ ayé. Jèhófà fẹ́ káwọn èèyàn kún ilẹ̀ ayé, kí wọ́n máa láyọ̀ kí wọ́n sì ní ìlera pípé. Bíbélì sọ pé “Ọlọ́run gbin ọgbà kan ní Édẹ́nì” ó sì “mú kí olúkúlùkù igi tí ó fani mọ́ra ní wíwò, tí ó sì dára fún oúnjẹ hù.” Lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá ọkùnrin àtobìnrin àkọ́kọ, Ó fi wọ́n sínú ilé tó dára rèǹtè-rente yẹn ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:8, 9, 15) Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fáwọn èèyàn ni pé kí wọ́n bímọ, kí wọn mú kí Párádísè yẹn tàn ká gbogbo ilẹ̀ ayé kí wọ́n sì máa bójú tó àwọn ẹranko.

2. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run yóò mú ohun tó ní lọ́kàn tó fi dá ilẹ̀ ayé ṣẹ? (b) Irú àwọn èèyàn wo ni Bíbélì sọ pé yóò wà láàyè títí láé?

2 Ǹjẹ́ o rò pé ohun tí Jèhófà Ọlọ́run ní lọ́kàn fún àwọn èèyàn pé kí wọ́n máa gbé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé yóò nímùúṣẹ? Ọlọ́run polongo pé: “Àní mo ti sọ ọ́, . . . èmi yóò ṣe é pẹ̀lú.” (Aísáyà 46:9-11; 55:11) Kò sí àní-àní, Ọlọ́run á ṣe ohun tó pinnu láti ṣe fún ilẹ̀ ayé dájúdájú! Ó sọ pé oun “kò wulẹ̀ dá [ilẹ̀ ayé] lásán,” ṣùgbọ́n òun “ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀.” (Aísáyà  45:18) Irú àwọn èèyàn wo ni Ọlọ́run fẹ́ kó máa gbé lórí ilẹ̀ ayé? Ọdún mélòó ló sì fẹ́ kí wọ́n fi máa gbé níbẹ̀? Bíbélì dáhùn pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”Sáàmù 37:29; Ìṣípayá 21:3, 4.

3. Àwọn ohun tí ń bani nínú jẹ́ wo ló ń ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé báyìí, àwọn ìbéèrè wo lèyí sì mú ká béèrè?

3 Ó ṣe kedere sí gbogbo wa pé ìyẹn ò tíì ṣẹlẹ̀. Ní báyìí, àwọn èèyàn ń ṣàìsàn wọ́n sì ń kú; wọ́n tiẹ̀ tún ń bára wọn jà wọ́n sì ń para wọn. Nǹkan kan ló fà á. Ṣùgbọ́n ó dájú pé bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ pé kí ilẹ̀ ayé rí kọ́ ló rí lónìí! Kí ló fà á? Kí nìdí tí ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ò fi tíì nímùúṣẹ? Kò sí ìwé ìtàn kan téèyàn kọ tó lè sọ ìdí rẹ̀ fún wa o, nítorí pé ọ̀run ni wàhálà náà ti bẹ̀rẹ̀.

BÍ ẸNÌ KAN ṢE DI Ọ̀TÁ

4, 5. (a) Ta lẹni náà gan-an tó lo ejò láti fi bá Éfà sọ̀rọ̀? (b) Báwo ni èèyàn dáadáa tó jẹ́ olóòótọ́ ṣe lè yí padà di olè?

4 Ìwé àkọ́kọ́ nínú Bíbélì sọ nípa ẹnì kan tó di alátakò Ọlọ́run nínú ọgbà Édẹ́nì. Bíbélì pè é ní “ejò,” àmọ́ alátakò yìí kì í wulẹ̀ ṣe ejò gidi kan tó ń fàyà fà. Ìwé tó kẹ́yìn Bíbélì sọ pé òun ni “ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” Ó tún pè é ní “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:1; Ìṣípayá 12:9) Áńgẹ́lì tàbí ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára téèyàn ò lè rí yìí lo ejò kan láti fi bá Éfà sọ̀rọ̀. Ó ṣe èyí lọ́nà tí ẹnì kan tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí lè gbà máa sọ̀rọ̀ kí ó sì dà bí ẹni pé ẹranko kan tàbí ọmọlangidi kan ló ń sọ̀rọ̀. Ìṣojú ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára yìí kúkú ni Ọlọ́run ṣe dá ilẹ̀ ayé fún èèyàn.—Jóòbù 38:4, 7.

5 A lè wá béèrè pé nígbà tó jẹ́ pé gbogbo ohun tí Jèhófà dá ló dára láìkù síbì kan, ta ló dá “Èṣù” tàbí “Sátánì” yìí? Ká má fọ̀pá pọ̀ọ̀lọ̀-pọọlọ pejò, ìdáhùn ìbéèrè yìí ni  ọ̀kan lára àwọn ọmọ Ọlọ́run tó jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí ló sọ ara rẹ̀ di Èṣù. Báwo nìyẹn ṣe lè ṣeé ṣe? Tóò, a mọ̀ pé èèyàn dáadáa kan tó jẹ́ olóòótọ́ lè yí padà di olè. Báwo ló ṣe lè ṣẹlẹ̀? Ẹnì náà lè jẹ́ kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ jọba lọ́kàn òun. Tí kò bá sì yéé rónú nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ náà, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yìí lè lágbára lọ́kàn rẹ̀. Tó bá wá rí àǹfààní kan pẹ́nrẹ́n, ó lè ṣe ohun búburú tó ń rò lọ́kàn.—Ka Jákọ́bù 1:13-15.

6. Báwo ni ọmọ Ọlọ́run kan tó jẹ ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára ṣe di Sátánì Èṣù?

6 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Sátánì Èṣù gan-an nìyẹn. Ketekete ló ń gbọ́ nígbà tí Ọlọ́run ń sọ fún Ádámù àti Éfà pé kí wọ́n bímọ kí irú ọmọ wọn sì kún ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28) Ó dájú pé ohun tí Sátánì rò lọ́kàn ara rẹ̀ ni pé, ‘Tiẹ̀ gbọ́ ná, gbogbo àwọn èèyàn wọ̀nyí mà lè máa sìn mí dípò Ọlọ́run!’ Bí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ṣe bẹ̀rẹ̀ lọ́kàn rẹ̀ nìyẹn o. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó ṣe ohun tó ń rò lọ́kàn, ló bá tan Éfà jẹ nípa píparọ́ mọ́ Ọlọ́run lọ́dọ̀ Éfà. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Bó ṣe di “Èṣù,” tó túmọ̀ sí “Afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́” nìyẹn o. Ó tún di “Sátánì,” tó túmọ̀ sí “Alátakò.”

7. (a) Kí nìdí tí Ádámù àti Éfà fi kú? (b) Kí nìdí tí gbogbo ọmọ Ádámù fi ń darúgbó tí wọ́n sì ń kú?

7 Sátánì lo irọ́ àti ẹ̀tàn láti fi mú kí Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17; 3:6) Ìyẹn ló fà á tí wọ́n fi kú lásẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ nítorí Ọlọ́run ti sọ pé wọ́n á kú tí wọ́n bá ṣàìgbọràn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:17-19) Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé Ádámù di aláìpé nígbà tó dẹ́ṣẹ̀, gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ jogún ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ rẹ̀. (Ka Róòmù 5:12) A lè fi ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn wé agolo tí wọ́n fi ń ṣe búrẹ́dì. Bí agolo yẹn bá ní àmì kan lára, báwo ni ara gbogbo búrẹ́dì tí wọ́n fi agolo yẹn ṣe á ṣe rí? Gbogbo búrẹ́dì tí wọ́n bá fi ṣe ló máa ní àmì, tàbí àléébù yẹn lára. Lọ́nà kan náà, gbogbo èèyàn ló ti jogún àmì àìpé látọ̀dọ̀ Ádámù. Ìdí nìyẹn tí gbogbo èèyàn fi ń darúgbó tí wọ́n sì ń kú.—Róòmù 3:23.

8, 9. (a) Ẹ̀sùn wo ló hàn gbangba pé Sátánì fi kan Ọlọ́run? (b) Kí nìdí tí Ọlọ́run kò fi pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà run lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀?

8 Nígbà tí Sátánì ti Ádámù àti Éfà dẹ́ṣẹ̀, ó tipa bẹ́ẹ̀ sọ ara rẹ̀ di olórí ọlọ̀tẹ̀. Ó sọ pé bí Ọlọ́run ṣe ń ṣàkóso kò dára. Ohun tí Sátánì ń dọ́gbọ́n sọ ni pé, Ọlọ́run kì í ṣe alákòóso rere. Ó sọ pé irọ́ ni Ọlọ́run ń pa àti pé Ọlọ́run ń fi ohun rere du àwọn èèyàn tó ń ṣàkóso lé lórí ni. Ó  ní kò pọn dandan káwọn èèyàn jẹ́ kí Ọlọ́run máa ṣàkóso àwọn. Ó tún sọ pé àwọn èèyàn lè pinnu ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́ fúnra wọn. Paríparí rẹ̀, ó sọ pé nǹkan á ṣẹnuure fáwọn èèyàn tóun bá ń ṣàkóso wọn. Kí ni kí Ọlọ́run ṣe sí ẹ̀sùn tí Sátánì fi kàn án yìí? Àwọn kan lè rò pé ṣe ló yẹ kí Ọlọ́run pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Àmọ́, ṣe ìyẹn ì bá fi hàn pé irọ́ ni ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan Ọlọ́run? Ṣé ì bá fi hàn pé ọ̀nà tó tọ́ ni Ọlọrun ń gbà ṣàkóso?

9 Nítorí tí Jèhófà jẹ́ onídàájọ́ òdodo, kò pa àwọn ọlọ̀tẹ̀ mẹ́ta yẹn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ó mọ̀ pé ó máa gba àkókò láti fi hàn tẹ́rùntẹ́rùn pé irọ́ ni ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan òun àti láti fi hàn pé òpùrọ́ ni Èṣù. Ni Ọlọ́run bá pinnu pé òun á fàyè gba àwọn èèyàn kí wọ́n ṣàkóso ara wọn lábẹ́ Sátánì fún àkókò tó gùn díẹ̀. Ní Orí Kọkànlá ìwé yìí, a óò rí ìdí ti Ọlọ́run fi yọ̀ọ̀da àkókò tó gùn tó bẹ́ẹ̀ kó tó yanjú ọ̀ràn náà. Àmọ, jẹ́ ká ronú nípa èyí ná: Ǹjẹ́ ó tọ́ kí Ádámù àti Éfà gba Sátánì tí kò ṣe ohun rere kankan fún wọn rí gbọ́? Ṣé ó tọ́ kí wọn gbà gbọ́ pé òǹrorò àti òpùrọ́ ni Jèhófà tó fún wọn ní gbogbo ohun tí wọ́n ní? Ká ní ìwọ ni, kí lò bá ṣe?

10. Báwo lo ṣe lè wà ní ìhà ọ̀dọ̀ Jèhófà bí Jèhófà ṣe ń fi hàn pé irọ́ ni ẹ̀sùn Sátánì?

10 Ó yẹ ká ronú nípa àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nítorí pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló ń dojú kọ àwọn ọ̀ràn tó fara jọ ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn lónìí. O láǹfààní láti wà níhà ọ̀dọ̀ Jèhófà bí Jèhófà ṣe ń fi hàn pé irọ́ ni ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan òun. O lè gba Jèhófà gẹ́gẹ́ bí alákòóso rẹ kó o sì fi hàn pé òpùrọ ni Sátánì. (Sáàmù 73:28; Ka Òwe 27:11) Ó bani nínú jẹ́ pé lára ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn tó wà láyé, àwọn díẹ̀ ló máa ń pinnu pé àwọn á ṣe bẹ́ẹ̀. Ìyẹn ló mú kí ìbéèrè pàtàkì kan jẹ yọ pé, Ṣé lóòótọ́ ni Bíbélì fi kọ́ni pé Sátánì ló ń ṣàkóso ayé?

 TA LÓ Ń ṢÀKÓSO AYÉ YÌÍ?

Ǹjẹ́ Sátánì á fi gbogbo ìjọba ayé lọ Jésù tó bá jẹ́ pé wọn kì í ṣe tirẹ̀?

11, 12. (a) Báwo ni ìdẹwò tí Sátánì gbé ko Jésù lójú ṣe fi hàn pé Sátánì ni alákòóso ayé yìí? (b) Kí ló tun fi hàn pé Sátánì ni alákòóso ayé yìí?

11 Jésù ò jiyàn rẹ̀ rí pé Sátánì ni alákòóso ayé yìí. Nígbà kan, Sátánì fi “gbogbo ìjọba ayé àti ògo wọn hàn” Jésù lọ́nà iṣẹ́ ìyanu. Ó wá ṣèlérí fún Jésù pé: “Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi yóò fi fún ọ dájúdájú bí ìwọ bá wólẹ̀, tí o sì jọ́sìn mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.” (Mátíù. 4:8, 9; Lúùkù 4:5, 6) Ronú nípa rẹ̀ ná. Ǹjẹ́ ohun tí Sátánì fi lọ Jésù yẹn ì bá jẹ́ ìdẹwò ká ní kì í ṣe Sátánì ló ń ṣàkóso lórí àwọn ìjọba ayé yìí? Jésù kò jiyàn pé ti Sátánì ni gbogbo ìjọba ayé yìí. Ká ní kì í ṣe Sátánì ni agbára tó wà lẹ́yìn àwọn ìjọba wọ̀nyẹn ni, ó dájú pé Jésù ì bá ti jẹ́ kó yé e pé wọn kì í ṣe tirẹ̀.

12 Dájúdájú, Jèhófà ni Ọlọ́run Olódùmarè, Ẹlẹ́dàá gbogbo àgbáyé tó lọ salalu. (Ìṣípayá 4:11) Ṣùgbọ́n kò sí ibi tí Bíbélì ti sọ pé Ọlọ́run tàbí Jésù Kristi ni alákòóso ayé yìí. Kódà, Jésù pe Sátánì ní “olùṣàkóso ayé yìí.” (Jòhánù 12:31; 14:30; 16:11) Bíbélì tún pe Sátánì Èṣù ní “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí.” (2 Kọ́ríǹtì 4:3, 4) Ohun tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ nípa alátakò yìí, tàbí Sátánì, ni pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.”—1 Jòhánù 5:19.

BÍ AYÉ SÁTÁNÌ YÓÒ ṢE DÀWÁTÌ

13. Kí nìdí tá a fi nílò ayé tuntun?

13 Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, bẹ́ẹ̀ layé ń di ibi eléwu sí i. Àwọn tí wọ́n ń jagun, àwọn olóṣèlú jẹgúdújẹrá, àwọn alágàbàgebè aṣáájú ẹ̀sìn àtàwọn ọ̀daràn tí wọ́n jẹ́ ọ̀dájú ló kún inú ayé. Wọ́n ti ba gbogbo nǹkan jẹ́. Bíbélì fi hàn pé àkókò ń bọ̀ tí Ọlọ́run á mú ayé búburú yìí kúrò; èyí á wáyé nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì. Ayé tuntun òdodo á sì rọ́pò rẹ̀.—Ìṣípayá 16:14-16.

14. Ta ni Ọlọ́run yàn ṣe Ọba Ìjọba Rẹ̀, báwo sì ni Bíbélì ṣe sọ èyí tẹ́lẹ̀?

 14 Jésu Kristi ni Jèhófà Ọlọ́run yàn ṣe Ọba Ìjọba Rẹ̀ ọ̀run. Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Nitori a bi ọmọ kan fun wa, a fi ọmọkọnrin kan fun wa: ijọba yio si wà li ejika rẹ̀: a o si ma pe orukọ rẹ̀ ni . . . Ọmọ-Alade Alafia. Ijọba yio bi si i, alafia ki yio ni ipẹkun.” (Aísáyà 9:6, 7, Bibeli Mimọ) Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà nípa ìjọba yìí pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:10) Bá a ṣe máa rí i nínú ìwé yìí tó bá yá, Ìjọba Ọlọ́run yóò pa gbogbo ìjọba ayé yìí rún láìpẹ́, Ìjọba tirẹ̀ yóò wá rọ́pò gbogbo wọn. (Ka Dáníẹ́lì 2:44) Lẹ́yìn náà, Ìjọba Ọlọ́run yóò mú Párádísè wá sórí ilẹ̀ ayé.

AYÉ TUNTUN Ò NÍ PẸ́ DÉ MỌ́!

15. Kí ni “ayé tuntun”?

15 Bíbélì fi dá wa lójú pe: “Ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí [Ọlọ́run], nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” (2 Pétérù 3:13; Aísáyà 65:17) Nígbà mìíràn, tí Bíbélì bá sọ̀rọ̀ nípa “ilẹ̀ ayé,” àwọn èèyàn inú rẹ̀ ló túmọ̀ sí. (Jẹ́nẹ́sísì 11:1) Nítorí náà, àwùjọ àwọn èèyàn tó rí ojú rere Ọlọ́run ni “ayé tuntun.”

16. Ẹ̀bùn tó ṣeyebíye wo ni Ọlọ́run máa fún àwọn tó bá ṣojú rere sí, kí sì la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ rí ẹ̀bùn náà gbà?

16 Jésù ṣèlérí pé nínú ayé tuntun tó ń bọ̀, awọn tó bá rí ojú rere Ọlórun yóò rí ẹ̀bùn “ìyè àìnípẹ̀kun” gbà. (Máàkù 10:30) Jọ̀wọ́, ṣí Bíbélì rẹ sí Jòhánù 3:16 àti Jòhánù 17:3, kó o sì ka ohun tí Jésù sọ pé a gbọ́dọ̀ ṣe ká tó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. Àwọn tó bá kúnjú ìwọ̀n láti gba ẹ̀bùn tó ṣeyebíye tí Ọlọ́run máa fúnni yìí yóò gbádùn ọ̀pọ̀ ìbùkún nínú Párádísè tó ń bọ̀. Ní báyìí, jẹ́ ká gbé àwọn ìbùkún náà yẹ̀ wò nínú Bíbélì.

17, 18. Báwo ló ṣe lè dá wa lójú pé àlàáfíà àti ààbò á wà níbi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé?

 17 Ìwà ibi, ogun jíjà, ìwà ọ̀daràn àti ìwà ipá kò ní sí mọ́. “Ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́ . . . Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 37:10, 11) Àlàáfíà yóò wà nítorí pé ‘Ọlọ́run yóò mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ ayé.’ (Sáàmù 46:9; Aísáyà 2:4) Nígbà náà ni “olódodo yóò rú jáde, àti ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà títí òṣùpá kì yóò fi sí mọ́,” ìyẹn ni pé, àlàáfíà yóò wà títí láé!—Sáamù 72:7.

18 Inú ààbò làwọn olùjọsìn Jèhófà yóò máa gbé. Gbogbo ìgbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé àtijọ́ bá gbọ́ràn sí Ọlọ́run lẹ́nu ní wọ́n máa ń gbé nínú ààbò. (Léfítíkù 25:18, 19) Ohun alárinrin ní yóò mà jẹ́ o, láti máa gbé nínú irú ààbò bẹ́ẹ̀ nínú Párádísè!—Ka Aísáyà 32:18; Míkà 4:4.

19. Báwo la ṣe mọ̀ pé oúnjẹ á pọ̀ rẹpẹtẹ nínú ayé tuntun Olọ́run?

19 Kò ní sí àìtó oúnjẹ. Onísáàmù kọ ọ́ lórin pé: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.” (Sáàmù 72:16) Jèhófà yóò bù kún àwọn olódodo, “ilẹ̀ ayé yóò [sì] máa mú èso rẹ̀ wá.”—Sáàmù 67:6.

20. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé gbogbo ilẹ̀ ayé yóò di Párádísè?

20 Gbogbo ilẹ̀ ayé yóò di Párádísè. Àwọn ilé tuntun tó jojú ní gbèsè àti ọgbà ẹlẹ́wà ni yóò wà lórí ilẹ̀ táwọn kọ̀lọ̀rọ̀sí ẹ̀dá ti bà jẹ́ yìí. (Ka Aísáyà 65:21-24; Ìṣípayá 11:18) Bọ́dún ti ń gorí ọdún, àwọn ibi táwọn èèyàn ń gbé á máa gbòòrò sí i títí tí gbogbo ilẹ̀ ayé yóò fi di ẹlẹ́wà tí yóò sì lọ́ràá bí ọgbà Édẹ́nì. Ọlọ́run ò ní ṣaláì ‘ṣí ọwọ́ rẹ̀ kí ó sì tẹ́ ìfẹ́ ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.’—Sáàmù 145:16.

21. Kí ló fi hàn pé àlàáfíà yóò wà láàárín èèyàn àtẹranko?

21 Àlàáfíà yóò wà láàárín èèyàn àti ẹranko. Ńṣe làwọn ẹranko ẹhànnà àtàwọn ẹran ilé yóò jọ máa jẹun. Kódà  nígbà yẹn, àwọn ọmọdé ò ní máa bẹ̀rù àwọn ẹranko tó ń ṣèèyàn léṣe nísinsìnyí mọ́.—Ka Aísáyà 11:6-9; 65:25.

22. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àìsàn?

22 Àìsàn yóò pòórá. Níwọ̀n bó ti jẹ pé Jésù Kristi ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, yóò ṣe ìwòsán tó pọ̀ gan-an ju èyí tó ṣe nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. (Mátíù 9:35; Máàkù 1:40-42; Jòhánù 5:5-9) Nígbà yẹn, “Kò [ní] sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”—Aísáyà 33:24; 35:5, 6.

23. Kí nìdí tí àjíǹde yóò fi mú wa lọ́kàn yọ̀?

23 Àwọn èèyàn wa tó ti kú yóò jí dìde wọn yóò sì nírètí pé àwọn ò ní kú mọ́. Gbogbo àwọn tí ń sùn nínú oorun ikú, tí wọ́n sì wà nínú ìrántí Ọlọrun, yóò jí dìde. Ní tòdodo, “àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.”—Ìṣe 24:15; Ka Jòhánù 5:28, 29.

24. Báwo ni èrò gbígbé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé ṣe rí lára rẹ?

24 Ọjọ́ ọ̀la tó dára rèǹtè-rente mà ló ń dúró de àwọn tó bá pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá o, tí wọ́n sì pinnu láti sìn ín! Párádísè orí ilẹ̀ ayé tó ń bọ̀ yẹn ni Jésù tọ́ka sí nígbà tó ṣèlérí fún ẹni ibi tó kú lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ pé: “Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.” (Lúùkù 23:43) Ó ṣe pàtàkì pé ká kẹ́kọ̀ọ́ ohun púpọ̀ sí i nípa Jésù, ipasẹ̀ ẹni tí gbogbo ìbùkún yìí yóò fi ṣeé ṣe.