Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORÍ KỌKÀNDÍNLÓGÚN

Má Ṣe Kúrò Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run

Má Ṣe Kúrò Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run
  • Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?

  • Báwo la ò ṣe ní kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run?

  • Báwo ni Jèhófà yóò ṣe san èrè fáwọn tí kò kúrò nínú ìfẹ́ rẹ̀?

Ǹjẹ́ wàá fi Jèhófà ṣe ibi ààbò rẹ láwọn àkókò oníwàhálà tá à wà yìí?

1, 2. Ibo la ti lè rí ibi ààbò lónìí?

FOJÚ inú wò ó pé bó o ṣe ń rìn lọ lójú ọ̀nà lọ́jọ́ kan ni àgbáàràgbá ìjì bá bẹ̀rẹ̀ sí í jà. Òkùnkùn ṣú bolẹ̀. Nígbà tó ṣe, ààrá bẹ̀rẹ̀ sí í sán, ìmọ́lẹ̀ ń bù yẹ̀rì, àrágbáyamúyamù òjò sì fọba lé e. Bẹ́ẹ̀ lò ń sáré, tó ò ń wá ibi tó o máa forí pa mọ́ sí. Lo bá tajú kán rí ilé kékeré kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà. Ilé ọ̀hún dúró sán-ún, àfẹ́sí òjò kò sì wọnú rẹ̀. Wàá mà mọyì ibi tó ṣeé forí pa mọ́ sí tó o rí yẹn o!

2 Àkókò oníjì la wà yìí. Wàhálà ń pọ̀ sí i ni láyé. Ṣùgbọ́n ibi tá a lè forí pa mọ́ sí wà, tó jẹ́ ibi ààbò tá a lè sá sí tí ewu ayérayé ò ti lè wu wá. Ibo ni ibi ààbò ọ̀hún? Ìwọ wo ohun tí Bíbélì fi kọ́ni, ó ní: “Ṣe ni èmi yóò wí fún Jèhófà pé: ‘Ìwọ ni ibi ìsádi mi àti ibi odi agbára mi, Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi yóò gbẹ́kẹ̀ lé dájúdájú.’”—Sáàmù 91:2.

3. Báwo la ṣe fi Jèhófà ṣe ibi ààbò wa?

3 Tiẹ̀ rò ó wò ná! Jèhófà, tí í ṣe òyígíyigì Ẹlẹ́dàá àti Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run, lè jẹ́ ibi ààbò wa. Ó lè dáàbò bò wá nítorí pé ó lágbára  fíìfíì ju ohunkóhun tó lè fẹ́ wu wá léwu lọ. Kódà, tí nǹkan kan bá tiẹ̀ pa wá lára, Jèhófà lè mú gbogbo aburú tí ohun náà bá fà kúrò. Báwo la ṣe lè fi Jèhófà ṣe ibi ìsádi tàbí ibi ààbò wa? A lè ṣe èyí nípa gbígbẹ́kẹ̀lé e. Láfikún, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá pé: “Ẹ pa ara yín mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.” (Júúdà 21) Bẹ́ẹ̀ ni, a ò gbọ́dọ̀ kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, ńṣe ló yẹ ká ní àjọṣe onífẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Bàbá wa ọ̀run, ká má sì jẹ́ kí àjọṣe náà bà jẹ́. Ìgbà náà ni yóò lè dá wa lójú pé, òun ni ibi ààbò wa. Àmọ́, báwo la ṣe lè ní irú àjọṣe bẹ́ẹ̀?

MỌ BÍ ỌLỌ́RUN ṢE NÍFẸ̀Ẹ́ RẸ KÍ ÌWỌ NÁÀ SÌ NÍFẸ̀Ẹ́ RẸ̀ PADÀ

4, 5. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà fìfẹ́ hàn sí wa?

4 Ká má bàa kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, a ní láti mọ àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà fìfẹ́ hàn sí wa. Ronú nípa díẹ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó o ti kọ́ nínú ìwé yìí. O ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà, Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá ló fún wa ní ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ilé wa ká lè máa gbádùn rẹ̀. Ó dá oúnjẹ rẹpẹtẹ sórí ilẹ̀ ayé, ó dá omi, ó dá àwọn ohun àmúṣọrọ̀ tó wà nínú ilẹ̀, irú bíi góòlù, ó dá oríṣiríṣi ẹranko, ó sì ṣe ojú ilẹ̀ ayé lẹ́wà. Ọlọ́run tó jẹ́ òǹṣèwé Bíbélì sọ orúkọ ara rẹ̀ àtàwọn ànímọ́ rẹ̀ fún wa nínú Bíbélì. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi yé wa pé ó rán Jésù Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n wá sáyé kó lè jìyà kó sì kú fún wa. (Jòhánù 3:16) Àǹfààní wo sì ni ìyẹn ṣe fún wa? Ó jẹ́ ká ní ìrètí ọjọ́ ọ̀la tó dára rèǹtè-rente.

5 Ohun mìíràn kan tí Ọlọ́run ṣe ló jẹ́ ká ní ìrètí tá a ní nípa ọjọ́ ọ̀la. Ohun náà ni Ìjọba Mèsáyà tí Jèhófà ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀. Ìjọba yẹn máa tó fòpin sí gbogbo ojú tó ń pọ́n aráyé yóò sì sọ ilẹ̀ ayé di Párádísè. Ro ìyẹn wò ná! A lè wà láàyè títí láé nínú Párádísè tí àlàáfíà ti jọba tí ayọ̀ sì gbilẹ̀. (Sáàmù 37:29) Kódà, Ọlọ́run fún wa ní ìtọ́sọ́nà nípa bá a ṣe lè gbádùn ìwàláàyè nísinsìnyí. Ó tún fún wa ní ẹ̀bùn àdúrà, pé ká máa bá òun sọ̀rọ̀ ní fàlàlà. Ìwọ̀nyí jẹ́ díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí gbogbo aráyé lápapọ̀ àti sí ẹnì kọ̀ọ̀kan, títí kan ìwọ náà.

6. Kí lo máa ṣe látàrí bí Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ yìí?

 6 Ó wá yẹ kó o ronú lórí ìbéèrè pàtàkì kan. Ìbéèrè ọ̀hún ni pé: Kí ni màá ṣe látàrí bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ mi yìí? Ọ̀pọ̀ ló máa dáhùn pé: “Ńṣe ló yẹ kí èmi náà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.” Ṣé ìdáhùn tìẹ náà nìyẹn? Tóò, àṣẹ tí Jésù sọ pé ó ju gbogbo àṣẹ lọ ni pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.” (Mátíù 22:37) Ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tó fi yẹ kó o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n ìbéèrè kan rèé o: Ṣé tó o bá sáà ti mọ̀ lọ́kàn ara rẹ pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, o ti fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo èrò inú rẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ nìyẹn?

7. Ǹjẹ́ ohun kan tún wà téèyàn gbọ́dọ̀ ṣe yàtọ̀ sí kó kàn mọ̀ lọ́kàn ara rẹ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run? Ṣàlàyé.

7 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé nínífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run kì í wulẹ̀ ṣe ohun téèyàn kàn ń mọ̀ lọ́kàn ara rẹ̀ lásán. Lóòótọ́, ó ṣe pàtàkì kéèyàn mọ̀ lọ́kàn ara rẹ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àmọ́ ìbẹ̀rẹ̀ níní ìfẹ́ gidi sí Ọlọ́run ló wulẹ̀ jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá fẹ́ ní igi eléso kan tí yóò máa so èso fún ọ jẹ, kóró èso náà gbọ́dọ̀ tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́. Tẹ́nì kan bá sì wá fún ọ ní kóró èso ọ̀hún, ṣé o ti ní igi eléso náà nìyẹn? Rárá o! Ìbẹ̀rẹ̀ lásán ni rírí tó o rí kóró èso náà jẹ́; o gbọ́dọ̀ gbìn ín kó o tó lè ní igi eléso. Bẹ́ẹ̀ náà ni kéèyàn kàn mọ̀ lọ́kàn ara rẹ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ṣe jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ lásán. Bíbélì fi kọ́ni pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.” (1 Jòhánù 5:3) Kí ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run tó lè jẹ́ ojúlówó, ó gbọ́dọ̀ so èso rere. A gbọ́dọ̀ fi hàn nínú ìwà wa pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.​—Ka Mátíù 7:16-20.

8, 9. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti pé a mọrírì ohun tó ṣe fún wa?

8 Tá a bá ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́ tá a sì ń fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò, à ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ nìyẹn. Àwọn àṣẹ Ọlọ́run ò sì  ṣòroó pa mọ́. Àwọn òfin Jèhófà kì í kó èèyàn sí ìnira, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Jèhófà fún wa láwọn òfin náà ká lè gbé ìgbé ayé rere, tó máa fún wa ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn. (Aísáyà 48:17, 18) Tá a bá ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà Bàbá wa ọ̀run, ohun tá à ń sọ fún un ni pé a mọrírì gbogbo ohun tó ṣe fún wa. Ṣùgbọ́n ó dunni pé láyé tá a wà yìí, àwọn tó ń fi hàn pé àwọn mọrírì ohun tí Ọlọ́run ṣe kò tó nǹkan. A ò ní fẹ́ jẹ́ aláìmoore bíi tàwọn èèyàn kan nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé. Odindi adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá ni Jésù wò sàn, ẹnì kan ṣoṣo péré lára wọn ló padà wá dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. (Lúùkù 17:12-17) Kò sí àní-àní pé ẹni tó moore yìí la fẹ́ fìwà jọ, a ò fẹ́ jọ àwọn mẹ́sàn-án tí wọ́n ya abaraámóorejẹ!

9 Kí wá ni àwọn àṣẹ Jèhófà tá a gbọ́dọ̀ pa mọ́? Àwọn àṣẹ rẹ̀ tá a ti kẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé yìí pọ̀ díẹ̀, àmọ́ jẹ́ ká ṣàtúnyẹ̀wò díẹ̀ lára wọn. Tá a bá ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, à ò ní kúrò nínú ìfẹ́ rẹ̀.

SÚN MỌ́ JÈHÓFÀ PẸ́KÍPẸ́KÍ

10. Ṣàlàyé ìdí tó fi ṣe pàtàkì kó o máa bá a lọ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ kó o lè ní ìmọ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run.

10 Ọ̀nà kan pàtàkì tó o fi lè sún mọ́ Jèhófà  ni pé kó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀. Ẹ̀kọ́ yìí ò sì lópin, nítorí pé ẹ̀kọ́ téèyàn ń kọ́ títí láé ni. Ká sọ pé ò ń yáná lóru ọjọ́ kan tí òtútù ń mú gan-an. Ká sọ pé òtútù yẹn pọ̀ débi pé tí iná tí ò ń yá náà bá ku, ẹ̀mí rẹ wà nínú ewu! Ṣé wàá wá lajú sílẹ̀ kí iná náà máa jo lọ sílẹ̀ díẹ̀ díẹ̀ títí tó fi máa kú? O ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Ńṣe ni wàá máa fi igi tàbí kẹrosíìnì sí i kó lè máa jó lala kó lè máa mú ooru jáde. Bí igi tàbí kẹrosíìnì ṣe ń jẹ́ kí iná máa jó lala, bẹ́ẹ̀ ni “ìmọ̀ Ọlọ́run” yóò ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ tó o ní sí Jèhófà máa lágbára.—Òwe 2:1-5.

Bí iná ṣe nílò igi tàbí kẹrosíìnì kó má bàa kú, bẹ́ẹ̀ ni iná ìfẹ́ tó o ní sí Jèhófà ṣe nílò àwọn ohun tí kò ní jẹ́ kó kú

11. Báwo ni àlàyé tí Jésù ṣe fún méjì lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe rí lára wọn?

11 Jésù fẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa bá a lọ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì, kí iná ìfẹ́ náà sì máa jó lala. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó ṣàlàyé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tó ṣẹ sí i lára fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ méjì kan. Báwo ló ṣe rí lára wọn? Àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjì náà fẹnu ara wọn sọ lẹ́yìn náà pé: “Ọkàn-àyà wa kò ha ń jó fòfò bí ó ti ń bá wa sọ̀rọ̀ ní ojú ọ̀nà, bí ó ti ń ṣí Ìwé Mímọ́ payá fún wa lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́?”—Lúùkù 24:32.

12, 13. (a) Lóde òní, kí lo ń ṣẹlẹ̀ sí ìfẹ́ tí ọ̀pọ̀ jù lọ ọmọ aráyé ní sí Ọlọ́run àti ìfẹ́ tí wọ́n ní sí òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì? (b) Kí la lè ṣe tí ìfẹ́ wa kò fi ní tutù?

12 Nígbà tó o kọ́kọ́ mọ àwọn ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an, ǹjẹ́ o kíyè sí i pé ayọ̀ àti ìtara bẹ̀rẹ̀ sí í jó bí iná lọ́kàn rẹ tí ìfẹ́ tó o ní sí Ọlọ́run sì lágbára? Ó dájú pé o kíyè sí i. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì ti ṣẹlẹ̀ sí bẹ́ẹ̀. Ohun tó wá ṣòro níbẹ̀ ni bí wàá ṣe jẹ́ kí iná ìfẹ́ tó lágbára náà máa jó nìṣó kó sì máa pọ̀ sí i. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ yóò di tútù.” (Mátíù 24:12) A ò sì ní fẹ́ kí ìfẹ́ tiwa di tútù. Kí wá lo lè ṣe tí ìfẹ́ tó o ní sí Jèhófà àti ìfẹ́ tó o ní sí òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì kò fi ní tutù?

13 Ńṣe lo ò ní dáwọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ dúró kó o lè ní ìmọ̀ Jèhófà àti ti Jésù Kristi. (Jòhánù 17:3) Máa ṣàṣàrò tàbí kó o ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ohun tó o bá kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. O lè máa ṣàṣàrò lórí àwọn ohun tó o bá kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa bíbí ara rẹ pé:  ‘Kí ni èyí ń kọ́ mi nípa Jèhófà Ọlọ́run? Kí tún ni ìdí mìíràn tí mo rí nínú ẹ̀kọ́ yìí tó fi yẹ kí n máa fi gbogbo ọkàn mi àti gbogbo èrò inú mi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?’ (Ka 1 Tímótì 4:15) Irú àṣàrò bẹ́ẹ̀ yóò mú kí iná ìfẹ́ tó o ní sí Jèhófà máa jó lala.

14. Báwo ni àdúrà ṣe lè jẹ́ ká máa bá a lọ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?

14 Ọ̀nà mìíràn tó o tún lè gbà máa jẹ́ kí iná ìfẹ́ tó o ní sí Jèhófà máa jó lala ni pé kó o máa gbàdúrà déédéé. (1 Tẹsalóníkà 5:17) Ní Orí Kẹtàdínlógún ìwé yìí, a kẹ́kọ̀ọ́ pé àdúrà jẹ́ ẹ̀bùn iyebíye tí Ọlọ́run fún wa. Bí àjọṣe tó wà láàárín àwọn èèyàn ṣe máa ń lágbára tí wọ́n bá ń bára wọn sọ̀rọ̀ fàlàlà nígbà gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni àjọṣe tó wà láàárín àwa àti Jèhófà yóò ṣe lágbára tá a bá ń gbàdúrà sí i déédéé. Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká má ṣe jẹ́ kí àdúrà wa di èyí tí kò wá látinú ọkàn, tó jẹ́ pé nǹkan kan náà la kàn ń sọ lásọtúnsọ ní gbogbo ìgbà, tí kò sì nítumọ̀ tàbí tí ọkàn wa kò sí níbẹ̀. Bí ọmọ ṣe máa ń bá baba rẹ̀ ọ̀wọ́n sọ̀rọ̀ ló ṣe yẹ ká máa bá Jèhófà sọ̀rọ̀. Lóòótọ́, a ní láti bá a sọ̀rọ̀ tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀, àmọ́ a ò gbọ́dọ̀ fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, ohun tó wà lọ́kàn wa gan-an la gbọ́dọ̀ sọ. (Sáàmù 62:8) Bẹ́ẹ̀ ni o, dídákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti gbígbàdúrà látọkànwá jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn wa, wọ́n sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.

JẸ́ KÍ ÌJỌSÌN TÓ Ò Ń ṢE FÚN Ọ LÁYỌ̀

15, 16. Kí nìdí tá a fi lè ka iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tá à ń ṣe sí àǹfààní àti ìṣúra?

15 Ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àdúrà jẹ́ ara ọ̀nà tá à ń gbà jọ́sìn téèyàn lè dá ṣe lóun nìkan. Ṣùgbọ́n ní báyìí, jẹ́ ká wo wíwàásù fún àwọn ẹlòmíràn nípa ohun tá a gbà gbọ́, tó jẹ́ ìjọsìn tá a máa ń ṣe ní gbangba. Ṣé o ti sọ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì fáwọn kan rí? Tó o bá ti ṣe bẹ́ẹ̀, àǹfààní ńlá nìyẹn. (Lúùkù 1:74) Tá a bá ń sọ òtítọ́ tá a kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run fáwọn ẹlòmíràn, iṣẹ́ pàtàkì tí Jésù gbé lé gbogbo Kristẹni tòótọ́ lọ́wọ́ là ń ṣe yẹn, ìyẹn iṣẹ́ wíwàásù Ìjọba Ọlọ́run.—Ka Mátíù 24:14; 28:19, 20.

16 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ka iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ sí ohun tó ṣeyebíye, ó pè é ní ìṣúra. (2 Kọ́ríńtì 4:7) Kò síṣẹ́ tó dára tó kó o máa sọ ohun  tí Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ ṣe fáwọn èèyàn. Tó o bá ń ṣe é, Ọ̀gá tó ju gbogbo ọ̀gá lọ lò ń sìn, àǹfààní tó sì ju gbogbo àǹfààní lọ ni wàá rí nínú rẹ̀. Tó o bá ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí, wàá ran àwọn olóòótọ́ èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè sún mọ́ Bàbá wa ọ̀run kí wọ́n sì rìn lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun! Ǹjẹ́ iṣẹ́ mìíràn wà tó lè  fún èèyàn láyọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Ko mọ síbẹ̀ o, jíjẹ́rìí tó o bá ń jẹ́rìí nípa Jèhófà àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ máa pọ̀ sí i, yóò sì jẹ́ kí ìfẹ́ tó o ní sí Jèhófà máa lágbára sí i. Gbogbo ìyànjú tó ò ń gbà sì ni Jèhófà mọrírì. (Hébérù 6:10) Tó o bá ń fi ìtara ṣe iṣẹ́ yìí ní gbogbo ìgbà, o ò ní kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.—Ka 1 Kọ́ríńtì 15:58.

17. Kí nìdí tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni fi di kánjúkánjú lónìí?

17 Ó ṣe pàtàkì ká máa rántí pé iṣẹ́ tá a ní láti ṣe kíákíá ni iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé: “Wàásù ọ̀rọ̀ náà, wà lẹ́nu rẹ̀ ní kánjúkánjú.” (2 Tímótì 4:2) Kí wá nìdí tó fi di kánjúkánjú tó bẹ́ẹ̀? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún wa pé: “Ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé. Ó sún mọ́lé, ìyára kánkán rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.” (Sefanáyà 1:14) Ńṣe ni àkókò tí Jèhófà yóò fòpin sí gbogbo ètò àwọn nǹkan búburú ń yára sún mọ́lé. A gbọ́dọ̀ kìlọ̀ fáwọn èèyàn! Wọ́n gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ìsinsìnyí ni wọ́n gbọ́dọ̀ gba Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ wọn. Òpin ‘ò ní pẹ́ dé.’—Hábákúkù 2:3.

18. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa pé jọ pẹ̀lú àwọn Kristẹni tòótọ́ láti jọ́sìn Jèhófà?

18 Jèhófà fẹ́ ká máa kóra jọ pẹ̀lú àwọn Kristẹni tòótọ́ láti máa jọ́sìn òun. Ìdí nìyẹn tí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi sọ pé: “Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àwọn kan ti ní àṣà náà, ṣùgbọ́n kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì, pàápàá jù lọ bí ẹ ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.” (Hébérù 10:24, 25) Pípéjọ pẹ̀lú àwọn Kristẹni bíi tiwa nípàdé máa ń jẹ́ ká ní àǹfààní iyebíye láti máa yin Ọlọ́run wa ọ̀wọ́n ká sì máa sìn ín. Ó tún ń jẹ́ ká lè máa gbé ara wa ró ká sì máa fún ara wa níṣìírí.

19. Kí la lè ṣe kí okùn ìfẹ́ tó wà láàárín àwa àtàwọn ará nínú ìjọ lè máa lágbára sí i?

19 Bá a ṣe ń bá àwọn tó ń sin Jèhófà kẹ́gbẹ́, okùn ìfẹ́ tó wà láàárín àwa àtàwọn ará nínú ìjọ yóò máa lágbára sí i, àjọṣe wa yóò sì máa túbọ̀ dán mọ́rán. Ó ṣe pàtàkì pé ka máa wo ibi táwọn ẹlòmíràn dára sí, bó ṣe jẹ́ pé ibi táwa náà dára sí ni Jèhófà ń wò. Má ṣe retí pé àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ á máa  hùwà bí ẹni pípé o. Máa rántí pé ibì kan náà kọ́ ni gbogbo wa dàgbà dé nípa tẹ̀mí, gbogbo wa la sì ń ṣàṣìṣe. (Ka Kólósè 3:13) Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gidigidi ni kó o máa wá láti yàn lọ́rẹ̀ẹ́ kòríkòsùn, kó o bàa lè máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Dájúdájú, tó o bá ń jọ́sìn Jèhófà láwùjọ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin rẹ nípa tẹ̀mí, èyí á ràn ọ́ lọ́wọ́ láti má ṣe kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run. Báwo ni Jèhófà ṣe máa san èrè fáwọn tó bá sìn ín tọkàntọkàn tí wọn kò sì tipa bẹ́ẹ̀ kúrò nínú ìfẹ́ rẹ̀?

MÁA WÁ “ÌYÈ TÒÓTỌ́”

20, 21. Kí ni “ìyè tòótọ́,” kí sì nìdí tó fi jẹ́ ìrètí àgbàyanu?

20 Ìyè ni èrè tí Jèhófà yóò san fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́. Àmọ́, irú ìyè wo nìyẹn? Ó dára, ṣé ìyè gidi lèyí tó o ní nísinsìnyí? Ọ̀pọ̀ jù lọ wa ló máa dáhùn pé, bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣe tán, à ń mí, à ń jẹun, a sì ń mumi. Òótọ́ ni, tá ò bá wà láàyè, a ò lè máa ṣe nǹkan wọ̀nyí. Kódà nígbà mìíràn tí fàájì bá ń ṣàn èèyàn lè sọ pé: “Ìgbádùn gidi rèé!” Àmọ́ tá a bá ní ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, Bíbélì fi hàn pé kò sẹ́ni tó ń gbádùn ní ti gidi nísinsìnyí.

Jèhófà fẹ́ kó o ní “ìyè tòótọ́.” Ṣé wàá fẹ́ láti ní in?

21 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá pé ká “di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.” (1 Tímótì 6:19) Ìyẹn fi hàn pé ọjọ́ iwájú la máa tó ní “ìyè tòótọ́,” ìyẹn ìyè gidi. Bó ṣe rí nìyẹn o, ó dìgbà tá a bá dẹni pípé ká tó lè ní ìyè gidi, nítorí pé irú ìgbésí ayé tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbé nígbà tó kọ́kọ́ dá èèyàn la óò máa gbé nígbà yẹn. Ìgbà tá a bá ń gbé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé, tá a ní ìlera pípé, tá a ní àlàáfíà àti ayọ̀ la óò tó ní “ìyè tòótọ́,” tí í ṣe ìyè àìnípẹ̀kun. (1 Tímótì 6:12) Ǹjẹ́ ìrètí àgbàyanu kọ́ nìyẹn?

22. Báwo lo ṣe lè “di ìyè tòótọ́ mú gírígírí”?

22 Báwo la ṣe lè “di ìyè tòótọ́ mú gírígírí”? Nínú ẹsẹ tó ṣáájú ẹsẹ tí Pọ́ọ̀lù ti sọ̀rọ̀ yìí, Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n “máa ṣe rere” kí wọ́n sì “jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà.” (1 Tímótì 6:18) Nítorí náà, láti lè di ìyè tòótọ́ mú gírígírí, a ní láti máa fi òtítọ́ tá a ti kẹ́kọ̀ọ́ nínú Bíbélì sílò dáadáa. Ṣé ohun tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn ni pé ìyè àìnípẹ̀kun jẹ́ ẹ̀tọ́ tí Ọlọ́run máa fún  wa nítorí iṣẹ́ rere tá a bá ṣe? Rárá o, nítorí pé “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí” tí Ọlọ́run fi hàn sí wa ló mú ká ní irú ìrètí àgbàyanu bẹ́ẹ̀. (Róòmù 5:15) Ṣùgbọ́n àwọn tó bá sin Jèhófà tọkàntọkàn ni Jèhófà fẹ́ fún lérè yìí. Jèhófà fẹ́ kó o ní “ìyè tòótọ́.” Àwọn tí wọ́n ò bá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run nìkan ni yóò ní ìyè àìnípẹ̀kun, níbi tí ayọ̀ àti àlàáfíà yóò ti gbilẹ̀.

23. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká má ṣe kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run?

23 Ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bi ara rẹ̀ pé, ‘Ǹjẹ́ mò ń sin Ọlọ́run ní ọ̀nà tó là sílẹ̀ nínú Bíbélì?’ Tó bá jẹ́ pé, bẹ́ẹ̀ ni, ni ìdáhùn wa sí ìbéèrè yìí nígbà gbogbo, a jẹ́ pé a wà lójú ọ̀nà tó tọ́ nìyẹn. Ìyẹn á jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà ni ibi ààbò wa. Yóò fààbò rẹ̀ bo àwọn olùjọsìn rẹ̀ olóòótọ́ kí wọ́n lè la àwọn ọjọ́ ìkẹyìn oníhílàhílo yìí já. Bákan náà, Jèhófà yóò mú wa wọnú ètò tuntun ológo tó ti sún mọ́lé báyìí. Inú wa yóò mà dùn gan-an o tákòókò yẹn bá ṣojú wa! A óò sì láyọ̀ pé a ṣe ìpinnu tó tọ́ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tá a wà yìí! Tó o bá ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀ nísinsìnyí, wàá ní “ìyè tòótọ́,” ìyẹn irú ìyè tí Jèhófà fẹ́ ká ní, títí láé!