Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?

 ÀFIKÚN

Kí Ni “Ọkàn” àti “Ẹ̀mí” Jẹ́ Gan-an?

Kí Ni “Ọkàn” àti “Ẹ̀mí” Jẹ́ Gan-an?

TÓ O bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, “ọkàn” àti “ẹ̀mí,” kí lo máa ń rò pé wọ́n túmọ̀ sí? Èrò àwọn kan ni pé “ọkàn” tàbí “ẹ̀mí” jẹ ohun tí kò lè kú tó wà nínú èèyàn. Wọ́n rò pé téèyàn bá kú, ohun tí kò ṣeé fojú rí tó wà nínú ara yìí yóò fi ara sílẹ̀ yóò sì máa wà láàyè lọ níbòmíràn. Nítorí pé ìgbàgbọ́ yìí wọ́pọ̀, ó máa ń ya àwọn kan lẹ́nu tí wọ́n bá gbọ́ pé kì í ṣe ohun tí Bíbélì fi kọ́ni rárá. Nígbà náà, kí ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ọkàn jẹ́, kí ló sì sọ pé ẹ̀mí jẹ́?

 BÍ BÍBÉLÌ ṢE LO Ọ̀RỌ̀ NÁÀ “ỌKÀN”

Kọ́kọ́ wo ọ̀rọ̀ náà, ọkàn. Ó ṣeé ṣe kó o rántí pé èdè Hébérù àti èdè Gíríìkì ni wọ́n fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ọ̀rọ̀ èdè Hébérù táwọn tó kọ Bíbélì lò fún ọkàn ni neʹphesh, ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì tí wọ́n sì lò fún un ni psy·kheʹ. Nínú Ìwé Mímọ́, ọ̀rọ̀ méjèèjì yìí fara hàn níye ìgbà tó ju ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ lọ, Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun sì túmọ̀ wọn sí “ọkàn” ní gbogbo ibi tí wọ́n ti fara hàn. Tó o bá ṣe àgbéyẹ̀wò bí Bíbélì ṣe lò “ọkàn,” wàá rí i pé ohun mẹ́ta pàtàkì tí ọ̀rọ̀ náà tọ́ka sí ni (1) èèyàn, (2) ẹranko, tàbí (3) ẹ̀mí tí èèyàn tàbí ẹranko ní. Jẹ́ ká wo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó fi ohun mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ọkàn túmọ̀ sí yìí hàn.

Èèyàn. “Ní àwọn ọjọ́ Nóà, . . . a gbé àwọn ènìyàn díẹ̀ la omi já láìséwu, èyíinì ni, ọkàn mẹ́jọ.” (1 Pétérù 3:20) Ó ṣe kedere pé àwọn èèyàn ni “ọkàn” tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí dúró fún, ìyẹn, Nóà, aya rẹ̀, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́ta àtàwọn aya wọn. Bákan náà, Ẹ́kísódù 16:16 sọ àwọn ìlànà tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa mánà kíkó. Ó sọ pé: “Ẹ kó lára rẹ̀ . . . ní iye ọkàn tí ọ̀kọ̀ọ̀kan yín ní nínú àgọ́ rẹ̀.” Ìyẹn ni pé iye èèyàn tó wá nínú ìdílé kọ̀ọ̀kan ló ń pinnu ìwọ̀n mánà tí wọ́n ń kó. Àpẹẹrẹ àwọn ibòmíràn tí Bíbélì ti lo “ọkàn” fún èèyàn ni Jẹ́nẹ́sísì 46:18; Jóṣúà 11:11; Ìṣe 27:37; àti Róòmù 13:1.

Ẹranko. Nínú àkọsílẹ̀ tó wà nínú Bíbélì nípa bí Ọlọ́run ṣe ṣẹ̀dá, a kà pé: “Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti wí pé: ‘Kí omi mú àwọn alààyè ọkàn agbáyìn-ìn máa gbá yìn-ìn, kí àwọn ẹ̀dá tí ń fò sì máa fò lókè ilẹ̀ ayé lójú òfuurufú ọ̀run.’ Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti wí pé: ‘Kí ilẹ̀ ayé mú alààyè ọkàn jáde ní irú tiwọn, ẹran agbéléjẹ̀ àti ẹran tí ń rìn ká àti ẹranko ìgbẹ́ ilẹ̀ ayé ní irú tirẹ̀.’ Ó sì wá rí bẹ́ẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:20, 24) Àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí pe ẹja, àwọn ẹran ilé àtàwọn ẹran ìgbẹ́ ní “ọkàn.” Bíbélì tún pe ẹyẹ àtàwọn ẹranko ní ọkàn nínú Jẹ́nẹ́sísì 9:10; Léfítíkù 11:46; àti Númérì 31:28.

Ẹ̀mí èèyàn. Nígbà mìíràn, “ọkàn” máa ń túmọ̀ sí ẹ̀mí èèyàn. Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Gbogbo ènìyàn tí ń dọdẹ ọkàn rẹ ti kú.” (Ẹ́kísódù 4:19) Kí làwọn ọ̀tá Mósè ń dọdẹ? Bí wọ́n ṣe máa gbẹ̀mí Mósè ni wọ́n ń wá. Ṣáájú àkókò náà, nígbà tí Rákélì ń rọbí Bẹ́ńjámínì, ‘ọkàn rẹ̀ jáde lọ (nítorí pé ó kú).’ (Jẹ́nẹ́sísì  35:16-19) Ní àkókò náà, Rákélì pàdánù ẹ̀mí rẹ̀. Tún gbé ohun tí Jésù sọ yẹ̀ wò. Ó sọ pé: “Èmi ni olùṣọ́ àgùntàn àtàtà; olùṣọ́ àgùntàn àtàtà fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn.” (Jòhánù 10:11) Jésù fi ọkàn rẹ̀, tàbí ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí aráyé. Nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyí, ẹ̀mí èèyàn ni “ọkàn” túmọ̀ sí. Wàá tún rí àpẹẹrẹ bí Bíbélì ṣe lo “ọkàn” fún ẹ̀mí èèyàn nínú 1 Àwọn Ọba 17:17-23; Mátíù 10:39; Jòhánù 15:13; àti Ìṣe 20:10.

Tó o bá túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wàá rí i pé kò síbì kankan nínú Bíbélì tó o ti lè rí i tí wọ́n lo àwọn ọ̀rọ̀ náà “àìleèkú” tàbí “ayérayé” fún “ọkàn.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Bíbélì sọ ni pé ọkàn ń kú. (Ìsíkíẹ́lì 18:4, 20) Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pe ẹni tó ti kú ní “òkú ọkàn.”—Léfítíkù 21:11.

A RÍ OHUN TÍ “Ẹ̀MÍ” TÚMỌ̀ SÍ

Ní báyìí, jẹ́ ká wo bí Bíbélì ṣe lo ọ̀rọ̀ náà, “ẹ̀mí.” Àwọn kan rò pé ńṣe ni “ẹ̀mí” wulẹ̀ jẹ́ ohun mìíràn tí wọ́n ń pe “ọkàn.” Àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀. Bíbélì fi hàn kedere pé ohun ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni “ẹ̀mí” àti “ọkàn” tọ́ka sí. Báwo ni wọ́n ṣe yàtọ̀?

Ọ̀rọ̀ èdè Hébérù tí àwọn tó kọ Bíbélì lò fún “ẹ̀mí” ni ruʹach, ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì tí wọ́n sì lò fún un ni pneuʹma. Ìwé Mímọ́ fúnra rẹ̀ fi ohun tí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí túmọ̀ sí hàn. Bí àpẹẹrẹ, Sáàmù 104:29 sọ pé: “Bí ìwọ [Jèhófà ] bá mú ẹ̀mí [ruʹach] wọn kúrò, wọn a gbẹ́mìí mì, wọn a sì padà lọ sínú ekuru wọn.” Bákan náà, Jákọ́bù 2:26 sọ pé ‘ara láìsí ẹ̀mí [pneuʹma] jẹ́ òkú.’ Nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyí, “ẹ̀mí” túmọ̀ sí ohun tó mú kí ara wà láàyè. Òkú ni ara láìsí ẹ̀mí. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì kò fi túmọ̀ ruʹach sí “ẹ̀mí” nìkan, àmọ́ tó tún túmọ̀ rẹ̀ sí “ipá,” tàbí ipá ìyè. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run sọ nípa Ìkún Omi ìgbà ayé Nóà pé: “Èmi yóò mú àkúnya omi wá sórí ilẹ̀ ayé láti run gbogbo ẹran ara tí ipá ìyè [ruʹach] ń ṣiṣẹ́ nínú wọn lábẹ́ ọ̀run.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:17; 7:15, 22) Nípa bẹ́ẹ̀, “ẹ̀mí” tọ́ka sí ipá kan tèèyàn ò lè rí tó mú kí ìwàláàyè ṣeé ṣe tàbí tó mú kí gbogbo ohun alààyè wà láàyè.

Ọkàn àti ẹ̀mí kì í ṣe nǹkan kan náà. Kí ara tó lè wà láàyè, ó nílò ẹ̀mí bí rédíò ṣe nílò bátìrì kó tó lè ṣiṣẹ́. Kó bàa lè yé ọ dáadáa, ìwọ ronú nípa rédíò kékeré kan ná. Tó o bá kó bátìrì sínú rédíò, agbára tó wà nínú bátìrì náà yóò mú kí rédíò náà ṣiṣẹ́.  Àmọ́, tó o bá kó bátìrì kúrò nínú rẹ̀, kò ní lè ṣiṣẹ́, ńṣe ló máa dà bí òkú rédíò. Bó ṣe rí pẹ̀lú oríṣiríṣi rédíò náà nìyẹn, tó o bá yọ okùn rẹ̀ kúrò lára iná mànàmáná, kò ní lè ṣiṣẹ́. Bí bátìrì àti iná mànàmáná ṣe ń mú kí rédíò ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé ẹ̀mí ló mú kí ara wà láàyè. Bí iná mànàmáná àti bátìrì kò ṣe lè mọ nǹkan kan tí kò sì lè ronú, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀mí kò ṣe lè mọ nǹkan kan tí kò sì lè ronú. Kò lè dá wà láìsí ara. Àmọ́ láìsí ẹ̀mí tàbí ipá ìyè yẹn, ara wa yóò ‘kú, yóò sì padà lọ sínú ekuru rẹ̀,’ gẹ́gẹ́ bí onísáàmù náà ti sọ. —Sáàmù 104:29.

Nígbà tí Oníwàásù 12:7 ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbà téèyàn bá kú, ó sọ pé: “Ekuru [ìyẹn ara èèyàn] yóò padà sí ilẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti wà tẹ́lẹ̀, àní ẹ̀mí yóò sì padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ tí ó fi í fúnni.” Tí ẹ̀mí tó jẹ́ agbára ìwàláàyè bá kúrò lára, ara á kú á sì padà sínú erùpẹ̀ ilẹ̀ tó ti wá. Ẹ̀mí pẹ̀lú á pada sọ́dọ̀ Ọlọ́run tó ti wá. (Jóòbù 34:14, 15; Sáàmù 36:9) Àmọ́, èyí kò túmọ̀ sí pé ẹ̀mí á rìnrin àjò lọ sí ọ̀run o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó túmọ̀ sí ni pé ìrètí onítọ̀hún láti ní ìyè lọ́jọ́ iwájú kù sọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run. Ká kúkú sọ pé ọwọ́ Ọlọ́run ni ẹ̀mí rẹ̀ wà. Agbára Ọlọ́run nìkan ló lè mú kó rí ẹ̀mí tàbí agbára ìwàláayè rẹ gbà padà, kó bàa lè tún wà láàyè.

Ìtùnú mà ló jẹ́ o, láti mọ̀ pé ohun tí Ọlọ́run máa ṣe fún gbogbo àwọn tó ń sinmi nínú “ibojì ìrántí” nìyẹn! (Jòhánù 5:28, 29) Nígbà àjíǹde, Jèhófà yóò dá ara tuntun fún àwọn tó ń sùn nínú oorun ikú, yóò sì sọ ara náà di alààyè nípa fífi ẹ̀mí, tàbí agbára ìwàláàyè, sínú rẹ̀. Inú èèyàn yóò mà dùn gidigidi lọ́jọ́ náà o!

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nipa bí Bíbélì ṣe lo àwọn ọ̀rọ̀ náà, “ọkàn” àti “ẹ̀mí,” wàá rí àlàyé tó wúlò nínú ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú? àti ìwé Reasoning From the Scriptures, ojú ìwé 375 sí 384. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé méjèèjì yìí.