Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?

 ORÍ KEJÌ

Bíbélì—Ìwé Kan Tó Wá Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run

Bíbélì—Ìwé Kan Tó Wá Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run
  • Àwọn ọ̀nà wo ni Bíbélì fi yàtọ̀ sáwọn ìwé mìíràn?

  • Báwo ni Bíbélì ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè kojú àwọn ìṣòro rẹ?

  • Kí nìdí tó o fi lè gbẹ́kẹ̀ lé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì?

1, 2. Àwọn ọ̀nà wo ni Bíbélì gbà jẹ́ ẹ̀bùn tí ń múnú ẹni dùn, tó sì ń mára ẹni yá gágá, tí Ọlọ́run fún wa?

ǸJẸ́ o lè rántí ìgbà kan tí ọ̀rẹ́ rẹ kan fún ọ lẹ́bùn pàtàkì kan? Ó dájú pé inú rẹ dùn, ọkàn rẹ sì yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ nígbà tó fún ọ lẹ́bùn náà. Ó ṣe tán, tẹ́nì kan bá fúnni lẹ́bùn, ó máa ń múnú ẹni dùn ó sì máa ń jẹ́ kéèyàn mọ̀ pé ẹni tó fúnni lẹ́bùn náà nífẹ̀ẹ́ ẹni dénúdénú. Ó sì dájú pé wàá dúpẹ́ lọ́wọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí.

2 Bíbélì jẹ́ ẹ̀bùn kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ó sì yẹ ká dúpẹ́ gidigidi nítorí rẹ̀. Ọba ìwé yìí sọ àwọn ohun kan fún wa tá ò lè rí nínú ìwé mìíràn. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ fún wa nípa bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ilẹ̀ ayé, ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́. Àwọn ìlànà wà nínú Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè kojú àwọn ìṣòro àti àníyàn ìgbésí ayé. Bíbélì ṣàlàyé bí Ọlọ́run ṣe máa ṣe àwọn ohun tó ní lọ́kàn ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti bó ṣe máa tún ilẹ̀ ayé ṣe. Ìwé tí ń múnú ẹni dùn, tó sì ń mára ẹni yá gágá mà ni Bíbélì o!

3. Kí nìdí tí Bíbélì fi jẹ́ ẹ̀bùn kan tó ń mọ́kàn ẹni yọ̀, kí ni èyí sì fi hàn nípa Jèhófà, Ẹni tó fún wa lẹ́bùn náà?

3 Bíbélì tún jẹ́ ẹ̀bùn tí ń mọ́kàn ẹni yọ̀ torí pé ó fi ohun kan hàn nípa Jèhófà Ọlọ́run, Ẹni tó fún wa lẹ́bùn náà.  Ohun tó fi hàn náà ni pé Jèhófà fẹ́ ká mọ òun dáadáa. Ká sòótọ́, Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jèhófà.

4. Kí ló mú kí ìpínkiri Bíbélì jọ ọ́ lójú?

4 Àwọn tó ní Bíbélì pọ̀, ó sì ṣeé ṣe kí ìwọ náà ní ọ̀kan. Wọ́n ti tẹ odindi Bíbélì tàbí apá kan rẹ̀ jáde ní èdè tó ju ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta lọ. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé nínú èèyàn mẹ́wàá, à óò rí ẹni mẹ́sàn-án tó ní Bíbélì lọ́wọ́. Tá a bá wo iye Bíbélì tí wọ́n ń pín kiri, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ ju mílíọ̀nù kan lọ tó ń dọ́wọ́ àwọn èèyàn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀! Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún odindi Bíbélì tàbí apá kan rẹ̀ ni wọ́n ti tẹ̀. Dájúdájú, kò sí ìwé mìíràn tó dà bí Bíbélì.

Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun” wà ní ọ̀pọ̀ èdè

5. Ọ̀nà wo ni Bíbélì gbà jẹ́ ìwé tí “Ọlọ́run mí sí”?

5 Síwájú sí i, “Ọlọ́run [ló] mí sí” Bíbélì. (Ka 2 Tímótì 3:16) Lọ́nà wo? Bíbélì fúnra rẹ̀ dáhùn pé: ‘Àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ti darí wọn.’ (2 Pétérù 1:21) Jẹ́ ká ṣàpẹẹrẹ rẹ̀ lọ́nà yìí: Ọkùnrin oníṣòwò kan lè ní kí akọ̀wé òun ba òun kọ lẹ́tà kan. Ohun tí ọkùnrin oníṣòwò náà bá sọ ló máa wà nínú lẹ́tà náà. Nítorí náà, lẹ́tà ọkùnrin oníṣòwò náà ni, kì í ṣe tí akọ̀wé rẹ̀. Lọ́nà kan náà, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló wà nínú  Bíbélì, kì í ṣe ọ̀rọ̀ àwọn tó kọ ọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, òótọ́ pọ́nńbélé ni pé gbogbo Bíbélì látòkèdélẹ̀ jẹ́ “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”—1 Tẹsalóníkà 2:13.

ÀWỌN ÀKỌSÍLẸ̀ INÚ RẸ̀ BÁRA MU, Ó SÌ JÓÒÓTỌ́

6, 7. Kí nìdí tó fi jọni lójú pé Bíbélì bára mu látòkèdélẹ̀?

6 Ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [1,600] ọdún ni wọ́n fi kọ Bíbélì. Àkókò kan náà kọ́ làwọn tó kọ ọ́ gbé ayé, wọ́n kàwé jura wọn lọ, iṣẹ́ kan náà kọ́ ni wọ́n sì ń ṣe. Àwọn kan nínú wọn jẹ́ àgbẹ̀, apẹja, tàbí olùṣọ́ àgùntàn. Àwọn mìíràn jẹ́ wòlíì, onídàájọ́ tàbí ọba. Oníṣègùn ni Lúùkù tó kọ ọ̀kan lára àwọn ìwé ìhìn rere. Bí àwọn tó kọ Bíbélì sì ṣe yàtọ̀ síra lóríṣiríṣi ọ̀nà tó yẹn, Bíbélì bára mu látìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí. *

7 Ìwé àkọ́kọ́ nínú Bíbélì sọ bí ìṣòro aráyé ṣe bẹ̀rẹ̀ fún wa. Ìwé tó kẹ́yìn fi hàn pé gbogbo ayé yóò di Párádísè, tàbí ọgbà ẹlẹ́wà kan. Àkọsílẹ̀ ìtàn tó gba ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ló wà nínú àwọn ìwé tó wà nínú Bíbélì, ó sì jẹ́ ká lóye ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe àti bó ṣe máa ṣe é. Bí Bíbélì ṣe bára mu jọni lójú, bó sì ṣe yẹ ká retí pé kí ìwé tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ṣe rí náà nìyẹn.

8. Sọ àwọn àpẹẹrẹ tó fi hàn pé àkọsílẹ̀ Bíbélì bá ohun tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ mu.

8 Àkọsílẹ̀ Bíbélì bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu. Kódà ó pẹ́ tó ti kọ́ni láwọn ohun pàtàkì kan káwọn èèyàn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá mọ̀ nípa rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwé Léfítíkù, Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ ní òfin pé kí àwọn tí wọ́n ní àrùn máa gbé lọ́tọ̀ kí àrùn má bàa ran àwọn ẹlòmíràn, ó tún fún wọn lófin ìmọ́tótó, bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká ò mọ nǹkan kan nípa irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ lákòókò yẹn. Lákòókò tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní èrò tí kò tọ̀nà nípa bí ayé ṣe rí, Bíbélì sọ pé ayé rí rogodo, tàbí pé ó jẹ́ òbíríkítí. (Aísáyà 40:22) Bíbélì tún sọ gẹ́lẹ́ bó ṣe rí pé,  ayé “rọ̀ sórí òfo.” (Jóòbù 26:7) Lóòótọ́, Bíbélì kì í ṣe ìwé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, àmọ́ tó bá mẹ́nu kan àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì báyìí, ohun tó bá sọ máa ń jóòótọ́. Ǹjẹ́ kì í ṣe bó ṣe yẹ kí ìwé tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá máa sòótọ́ nìyẹn?

9. (a) Tó bá kan ti ọ̀rọ̀ ìtàn, báwo ló ṣe hàn pé òtítọ́ ni ohun tí Bíbélì máa ń sọ àti pé ó ṣeé gbára lé? (b) Kí ni bí àwọn tó kọ Bíbélì kì í ṣeé fi òtítọ́ pa mọ́ jẹ́ kó o mọ̀ nípa Bíbélì?

9 Bákan náà, tó bá kan ti ọ̀rọ̀ ìtàn, òótọ́ ni ohun tó máa ń wà nínú àkọsílẹ̀ Bíbélì, ó sì ṣeé gbára lé gan-an. Àkọsílẹ̀ ìtàn inú Bíbélì máa ń ṣe pàtó. Ìdí ni pé ó máa ń sọ orúkọ àwọn èèyàn àti orúkọ àwọn baba ńlá wọn. * Àwọn òpìtàn ayé ọjọ́un kì í sábà ṣàkọsílẹ̀ báwọn ọ̀tá ṣe ṣẹ́gun orílẹ̀-èdè wọn, ṣùgbọ́n àwọn tó kọ Bíbélì ṣe irú àkọsílẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní tiwọn nítorí pé wọn kì í fi òtítọ́ pa mọ́, kódà wọ́n ṣàkọsílẹ̀ àṣìṣe tiwọn fúnra wọn àti ti orílẹ̀-èdè wọn. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwé Bíbélì tá a mọ̀ sí Númérì, Mósè tó jẹ́ òǹkọ̀wé Bíbélì fọwọ́ ara rẹ̀ kọ àṣìṣe tó burú jáì tó ṣe tí Ọlọ́run fi bá a wí. (Númérì 20:2-12) Irú òótọ́ bẹ́ẹ̀ ṣọ̀wọ́n nínú àwọn ìwé ìtàn ayé, àmọ́ wọ́n wà nínú Bíbélì nítorí pé ìwé tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni.

ÌWÉ ỌGBỌ́N

10. Kí nìdí tí kò fi yà wá lẹ́nu pé Bíbélì jẹ́ ìwé ọgbọ́n?

10 Nítorí pé Ọlọ́run ló mí sí Bíbélì, ó “ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́.” (2 Tímótì 3:16) Ó dájú hán-únhán-ún pé ìwé tó ń kọ́ni lọ́gbọ́n ni Bíbélì. Ó ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa irú ẹ̀dá téèyàn jẹ́. Kò sì yà wá lẹ́nu pé Bíbélì ṣe irú àlàyé bẹ́ẹ̀, ó ṣe tán, Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ òǹṣèwé Bíbélì ló dá wa! Ó mọ ìrònú wa àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa ju bí àwa fúnra wa ṣe mọ̀ lọ. Kò mọ síbẹ̀ o, Jèhófà tún mọ ohun tó lè mú ká jẹ́ aláyọ̀. Ó tún mọ àwọn ìwà tí kò yẹ ká máa hù.

11, 12. (a) Àwọn àkòrí ọ̀rọ̀ wo ni Jésù sọ̀rọ̀ lé lórí nínú Ìwàásù orí Òkè? (b) Àwọn ìlànà pàtàkì mìíràn wo ni Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, kí sì nìdí tí ìwúlò ìmọ̀ràn Bíbélì kò fi mọ sígbà kan?

 11 Ṣàgbéyẹ̀wò àsọyé Jésù tá à ń pè ní Ìwàásù orí Òkè, tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ wà ní Mátíù orí 5 si 7. Nínú ìwàásù tó fakíki yìí, Jésù sọ̀rọ̀ lórí àwọn àkòrí ọ̀rọ̀ tó pọ̀ díẹ̀, irú bíi, bá a ṣe lè rí ojúlówó ayọ̀, bá a ṣe lè yanjú aáwọ̀, bó ṣe yẹ ká máa gbàdúrà àti bá a ṣe lè ní èrò tó tọ́ nípa níní àwọn ohun ìní tara.  Báwọn ọ̀rọ̀ Jésù ṣe lágbára tí wọ́n sì wúlò nígbà yẹn náà ni wọ́n ṣe lágbára tí wọ́n sì wúlò lónìí.

12 Àwọn ìlànà Bíbélì kan dá lórí ìgbésí ayé ìdílé, irú ọwọ́ tó yẹ kéèyàn máa fi mú iṣẹ́, àti àjọṣe èèyàn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Àwọn ìlànà inú Bíbélì kan gbogbo èèyàn, kò sì sígbà kan tí ìmọ̀ràn rẹ̀ kì í ṣeni láǹfààní. Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run gbẹnu wòlíì Aísáyà sọ ló ṣe àkópọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì, ó sọ pé: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní.”—Aísáyà 48:17.

ÌWÉ ÀSỌTẸ́LẸ̀

Aísáyà tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìṣubú Bábílónì

13. Kúlẹ̀kúlẹ̀ wo ni Jèhófà mí sí wòlíì Aísáyà pé kó ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nípa Bábílónì?

13 Àìmọye àsọtẹ́lẹ̀ ló wà nínú Bíbélì, ọ̀pọ̀ wọn ló sì tí nímùúṣẹ. Gbé àpẹẹrẹ kan lára wọn yẹ̀ wò. Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ wòlíì Aísáyà, ẹni tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni, pé ìlú Bábílónì yóò pa run. (Aísáyà 13:19; 14:22, 23) Ó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìyẹn ṣe máa ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́. Àwọn ọmọ ogun tó gbógun wá yóò mú kí odò Bábílónì gbẹ wọn yóò sì fẹsẹ̀ rìn wọnú ìlú náà wọ́ọ́rọ́wọ́. Kò mọ síbẹ̀ o. Kódà àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà dárúkọ ọba tó máa ṣẹ́gun Bábílónì, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Kírúsì.—Ka Aísáyà 44:27–45:2.

14, 15. Báwo làwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan nínú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà nípa Bábílónì ṣe nímùúṣẹ?

14 Ní nǹkan bí igba [200] ọdún lẹ́yìn náà, ìyẹn ní òru October 5 mọ́jú October 6 ní ọdún 539 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ogun kan pabùdó sítòsí Bábílónì. Ta ni ọ̀gá ẹ̀gbẹ́ ológun náà? Ọba Páṣíà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kírúsì ni. Ọ̀nà tí àsọtẹ́lẹ̀ àgbàyanu yìí máa gbà nímùúṣẹ ló tipa báyìí ṣí sílẹ̀ yìí. Àmọ́, ṣé wọ́ọ́rọ́wọ́ ni ẹgbẹ́ ọmọ ogun Kírúsì máa rìn wọnú ìlú Bábílónì láìbá wọn jà, gẹ́gẹ́ bí Aísáyà ti sọ tẹ́lẹ̀?

15 Ayẹyẹ kan làwọn ará Bábílónì ń ṣe ní òru ọjọ́ náà, ọkàn wọn sì balẹ̀ pé kò séwu kankan nítorí odi gìrìwò tó yí ìlú wọn po. Ṣùgbọ́n bí wọ́n ṣe ń ṣayẹyẹ, bẹ́ẹ̀ ni Kírúsì ń fọgbọ́n darí  omi odò tó ṣàn kọjá ìlú náà gba ibòmíràn lọ. Èyí tá à ń wí yìí pẹ́, odò ọ̀hún ti fà; làwọn ọmọ ogun rẹ̀ bá wọ́dò kọjá lọ sí ìdí odi ìlú. Àmọ́ báwo làwọn ọmọ ogun Kírúsì yóò ṣe wọnú ìlú pẹ̀lú odi gìrìwò tó wà níwájú wọn yìí? Kàyéfì ńlá ló jẹ́ pé, lálẹ́ ọjọ́ náà, gbayawu ni wọ́n ṣí ilẹ̀kùn ẹnu ibodè ìlú náà sílẹ̀!

16. (a) Kí ni Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò jẹ́ ìgbẹ̀yìn Bábílónì? (b) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà pé Bábílónì yóò dahoro ṣe nímùúṣẹ?

16 Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa Bábílónì pé: “A kì yóò gbé inú rẹ̀ mọ́ láé, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí mọ́ láti ìran dé ìran. Àwọn ará Arébíà kì yóò sì pàgọ́ sí ibẹ̀, àwọn olùṣọ́ àgùntàn kì yóò sì jẹ́ kí agbo ẹran wọn dùbúlẹ̀ sí ibẹ̀.” (Aísáyà 13:20) Kì í ṣe pé àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sọ pé Bábílónì á ṣubú nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún fi hàn pé yóò dahoro títí láé. Ẹ̀rí wà pé lóòótọ́ ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí nímùúṣẹ. Bábílónì àtijọ́ wà ní nǹkan bí àádọ́ta ibùsọ̀ sí gúúsù ìlú Baghdad, ní orílẹ̀-èdè Ìráàkì. Kò sẹ́nì kankan tó ń gbé ibẹ̀ mọ́, èyí sì jẹ́ ẹ̀rí pé ohun tí Jèhófà gbẹnu Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nímùúṣẹ, ìyẹn ni pé: “Èmi yóò . . . fi ìgbálẹ̀ ìparẹ́ráúráú gbá a.”—Aísáyà 14:22, 23. *

Àwókù ìlú Bábílónì

17. Báwo ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó nímùúṣẹ ṣe ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹni lágbára?

 17 Bá a ṣe ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀nà tí Bíbélì gbà jẹ́ ìwé àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣeé gbára lé yìí mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ó ṣe tán, níwọ̀n bí Jèhófà Ọlọ́run ti mú àwọn ìlérí tó ṣe láyé ọjọ́un ṣẹ, ó yẹ kó dá wa lójú hán-únhán-ún pé yóò mú ìlérí tó ṣe nípa bó ṣe máa sọ ilẹ̀ ayé di Párádísè ṣẹ. (Ka Númérì 23:19) Dájúdájú, a ní “ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun, èyí tí Ọlọ́run, ẹni tí kò lè purọ́, ti ṣèlérí tipẹ́tipẹ́.”—Títù 1:2. *

“Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN YÈ”

18. Ọ̀rọ̀ tó lágbára wo ni Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run”?

18 Látinú àwọn kókó tá a ti gbé yẹ̀ wò nínú orí yìí, a rí i kedere pé, lóòótọ́, ìwé tí ò lẹ́gbẹ́ ni Bíbélì. Àmọ́, ìwúlò Bíbélì ò mọ sórí pé ó bára mu, kò mọ sórí pé àkọsílẹ̀ inú rẹ̀ bá  ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì mu, kò sì mọ sórí pé ó jóòótọ́ tó bá kan ti ọ̀rọ̀ ìtàn, bẹ́ẹ̀ ni kò tún mọ sórí pé ọgbọ́n inú rẹ̀ wúlò púpọ̀, kò sì mọ sórí pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú rẹ̀ ṣeé gbára lé. Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára, ó mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ, ó sì ń gúnni àní títí dé pípín ọkàn àti ẹ̀mí níyà, àti àwọn oríkèé àti mùdùnmúdùn wọn, ó sì lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.”—Hébérù 4:12.

19, 20. (a) Báwo ni Bíbélì ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yẹ ara rẹ̀ wò? (b) Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o mọrírì ẹ̀bùn tí ò láfiwé tí Ọlọ́run fún wa, ìyẹn Bíbélì?

19 Tá a bá ń ka “ọ̀rọ̀” Ọlọ́run nínú Bíbélì, ó lè yí ìgbésí ayé wa padà. Ó lè jẹ́ ká túbọ̀ mọ irú ẹni tá a jẹ́. A lè sọ pé a fẹ́ràn Ọlọ́run o, àmọ́ ohun tó máa fi ohun tó wà lọ́kàn wa gan-an hàn, bóyá lóòótọ́ la fẹ́ràn rẹ̀, ni ìṣarasíhùwà wa sí ohun tí Bíbélì, tó jẹ́ Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ tó mí sí, fi kọ́ni.

20 Lóòótọ́, ìwé tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì. Ìwé tó yẹ kéèyàn kà, tó yẹ kéèyàn kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ dáadáa, kéèyàn sì tún mọyì rẹ̀ ni Bíbélì. Máa ṣàyẹ̀wò ohun tó wà nínú ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wa yìí nígbà gbogbo láti fi hàn pé o mọrírì rẹ̀. Bó o ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá máa túbọ̀ lóye ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe fún aráyé. Ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe yìí gan-an àti bó ṣe máa ṣe é la óò kẹ́kọ̀ọ́ nínú orí tó kàn.

^ ìpínrọ̀ 6 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan sọ pé àwọn ẹsẹ Bíbélì kan ta ko ara wọn, ọ̀rọ̀ tí wọn sọ yìí ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. Wo ojú ìwé 14 sí 17 nínú ìwé pẹlẹbẹ náà, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe.

^ ìpínrọ̀ 9 Bí àpẹẹrẹ, wo bí Bíbélì ṣe to àwọn baba ńlá Jésù lẹ́sẹẹsẹ nínú Lúùkù 3:23-38.

^ ìpínrọ̀ 16 Fún àlàyé síwájú sí i nípa àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, wo ojú ìwé 27 sí 29 nínú ìwé pẹlẹbẹ náà, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe.

^ ìpínrọ̀ 17 Ńṣe ni ìparun Bábílónì wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ti nímùúṣẹ. Lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn tó ti nímùúṣẹ ni ìparun ìlú Tírè àti Nínéfè. (Ìsíkíẹ́lì 26:1-5; Sefanáyà 2:13-15) Wòlíì Dáníẹ́lì náà sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn agbára ayé tó máa ṣàkóso tẹ̀ lé Bábílónì. Lára àwọn agbára ayé náà ni Páṣíà àti Gíríìsì. (Dáníẹ́lì 8:5-7, 20-22) Fún àlàyé lórí ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà tó ṣẹ sára Jésù Kristi, wo Àfikún, ojú ìwé 199 sí 201.