• Kí ló ń sọni di ọkọ rere?

  • Báwo lobìnrin ṣe lè ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyàwó ilé láṣeyọrí?

  • Kí ló ń sọni di òbí rere?

  • Ọ̀nà wo làwọn ọmọ lè gbà mú kí ìdílé jẹ́ aláyọ̀?

1. Kí ni yóò mú kí ìdílé jẹ́ aláyọ̀?

JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN fẹ́ kí ìdílé rẹ jẹ́ aláyọ̀. Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ojúṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé, èyí sì ni ìlànà tí Ọlọ́run fẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn máa tẹ̀ lé. Báwọn tó wà nínú ìdílé bá lè ṣe ojúṣe wọn bí ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run gbà wọ́n, ayọ̀ ni yóò tibẹ̀ jáde. Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!”—Lúùkù 11:28.

2. Kí ìdílé wa tó lè jẹ́ aláyọ̀, kí la gbọ́dọ̀ mọ̀?

2 Kí ìdílé wa tó lè jẹ́ aláyọ̀, a gbọ́dọ̀ mọ̀ pé Jèhófà ló dá ìdílé sílẹ̀. Jèhófà ni Jésù pè ní “Baba Wa.” (Mátíù 6:9) Ká ní Bàbá wa ọ̀run kò dá ìdílé sílẹ̀ ni, kì bá tí sí ìdílé kankan lórí ilẹ̀ ayé. Bàbá wa ọ̀run tó dá ìdílé sílẹ̀ sì mọ ohun tó lè mú kí ìdílé jẹ́ aláyọ̀. (Éfésù 3:14, 15) Nítorí náà, kí ni Bíbélì sọ pé ó jẹ́ ojúṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé?

ỌLỌ́RUN LÓ DÁ ÌDÍLÉ SÍLẸ̀

3. Kí ni Bíbélì sọ nípa bí ìdílé èèyàn ṣe bẹ̀rẹ̀, báwo la sì ṣe mọ̀ pé òótọ́ lohun tó sọ?

3 Jèhófà dá àwọn èèyàn àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, ó sì so  wọ́n pọ̀ bíi tọkọtaya. Ó fi wọ́n sínú ilé ẹlẹ́wà kan, ìyẹn ọgbà Édẹ́nì tó jẹ́ Párádísè lórí ilẹ̀ ayé, ó sì sọ fún wọn pé kí wọ́n máa bímọ. Jèhófà sọ pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:26-28; 2:18, 21-24) Èyí kì í ṣe ìtàn lásán o, nítorí pé Jésù fi hàn pé òótọ́ lohun tí ìwé Jẹ́nẹ́sísì sọ nípa bí ìdílé èèyàn ṣe bẹ̀rẹ̀. (Mátíù 19:4, 5) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìṣòro là ń ní nísinsìnyí tí ayé ò sì rí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí, jẹ́ ká wo ìdí tó fi ṣeé ṣe kí ayọ̀ wà nínú ìdílé.

4. (a) Báwo lẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé ṣe lè ṣe ipa tirẹ̀ láti jẹ kí ìdílé jẹ́ aláyọ̀? (b) Láti lè mú kí ìdílé jẹ́ aláyọ̀, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì kéèyàn kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìgbé ayé Jésù?

4 Ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé ló lè ṣe ipa tirẹ̀ kí ìdílé lè jẹ́ aláyọ̀. Bí wọ́n ṣe lè ṣe èyí ni pé kí wọ́n máa fìfẹ́ hàn bíi ti Ọlọ́run. (Éfésù 5:1, 2) Ṣùgbọ́n báwo la ṣe lè fara wé Ọlọ́run tá ò lè rí? Tóò, a lè mọ bí Jèhófà ṣe ń ṣe nǹkan nítorí pé ó rán àkọ́bí Ọmọ rẹ̀ wá sáyé látọ̀run. (Jòhánù 1:14, 18) Nígbà tí Ọmọ yìí, tí í ṣe Jésù Kristi, wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fara wé Bàbá rẹ̀ débi pé, téèyàn bá rí i tàbí tó gbọ́ ohun tó ń sọ, ńṣe ní á dà bí pé èèyàn wà lọ́dọ̀ Jèhófà téèyàn sì ń gbọ́ ohun tí Jèhófà ń sọ. (Jòhánù 14:9) Nítorí náà, tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìfẹ́ tí Jésù fi hàn tá a sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé yóò lè ṣe ipa tirẹ̀ láti jẹ́ kí ìdílé jẹ́ aláyọ̀.

ÀPẸẸRẸ TÓ YẸ KÍ ỌKỌ MÁA TẸ̀ LÉ

5, 6. (a) Báwo ni Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ tó yẹ káwọn ọkọ máa tẹ̀ lé lélẹ̀ nínú ọ̀nà tó gbà bá ìjọ lò? (b) Kí Ọlọ́run tó lè dárí ji ẹnì kan, kí lonítọ̀hún gbọ́dọ̀ máa ṣe?

5 Bíbélì sọ pé káwọn ọkọ máa bá àwọn aya wọn lò bí Jésù ṣe bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lò. Ronú lórí ohun tí Bíbélì sọ pé káwọn ọkọ máa ṣe yìí: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ, tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un . . . Lọ́nà yìí, ó yẹ kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn. Ẹni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀, nítorí pé kò sí ènìyàn kankan  tí ó jẹ́ kórìíra ara òun fúnra rẹ̀; ṣùgbọ́n a máa bọ́ ọ, a sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti ń ṣe sí ìjọ.”Éfésù 5:23, 25-29.

6 Ìfẹ́ tí Jésù ní sí ìjọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ rere tó yẹ káwọn ọkọ máa tẹ̀ lé. Jésù “nífẹ̀ẹ́ wọn dé òpin,” ó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ rúbọ fún wọn bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wọ́n. (Jòhánù 13:1; 15:13) Lọ́nà kan náà, Bíbélì rọ àwọn ọkọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, ẹ má sì bínú sí wọn lọ́nà kíkorò.” (Kólósè 3:19) Kí ni yóò ran ọkọ lọ́wọ́ kó lè fi ìmọ̀ràn yìí sílò, pàápàá lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tí aya rẹ̀ bá ṣe ohun tó kù díẹ̀ káàtó? Ohun tí yóò ràn án lọ́wọ́ ni pé kó máa rántí pé òun náà máa ń ṣàṣìṣe àti pé ohun kan wà tóun gbọ́dọ̀ ṣe láti rí ìdáríjì Ọlọ́run gbà. Kí lohun náà? Ohun náà ni pé ó gbọ́dọ̀ máa dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ ẹ́, aya rẹ̀ sì jẹ́ ọ̀kan lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Bákan náà sì ni aya gbọ́dọ̀ máa ṣe. (Ka Mátíù 6:12, 14, 15) Ṣé o ti wá rí ìdí táwọn kan fi sọ pé kí ìdílé tó lè ṣàṣeyọrí, tọkọtaya ní láti máa dárí ji ara wọn?

7. Kí ni Jésù máa ń gbà rò nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, àpẹẹrẹ wo ló sì tipa bẹ́ẹ̀ fi lélẹ̀ fáwọn ọkọ?

7 Ó tún yẹ káwọn ọkọ kíyè sí i pé gbogbo ìgbà ni Jésù máa ń gba tàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rò. Ó máa ń gba tiwọn rò nípa ibi tí agbára wọn mọ àtohun tí ara wọ́n nílò. Bí àpẹẹrẹ, nígbà kan tó rẹ̀ wọ́n, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bọ̀, ẹ̀yin fúnra yín, ní ẹ̀yin nìkan sí ibi tí ó dá, kí ẹ sì sinmi díẹ̀.” (Máàkù 6:30-32) Ó yẹ káwọn ọkọ náà máa gba tàwọn aya wọn rò. Bíbélì sọ pé wọ́n jẹ́ “ohun èlò tí ó túbọ̀ jẹ́ aláìlera,” ó sì pàṣẹ fáwọn ọkọ pé kí wọ́n fi “ọlá” fún wọn. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọkọ àti aya jọ ní “ojú rere ìyè tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí” ni. (1 Pétérù 3:7) Káwọn ọkọ máa rántí pé kì í ṣe kéèyàn jẹ́ ọkùnrin tàbí kó jẹ́ obìnrin ló máa ń mú kéèyàn ṣe pàtàkì lójú Ọlọ́run, bí kò ṣe kéèyàn jẹ́ olóòótọ́.—Sáàmù 101:6.

8. (a) Báwo ló ṣe jẹ́ pé ọkọ “tí ó bá nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara rẹ”? (b) Kí ni ọkọ àti aya ò gbọ́dọ̀ ṣe nítorí ‘jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ ara kan’?

8 Bíbélì sọ pé ọkọ “tí ó bá nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara rẹ.” Ìdí tó  fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé Jésù sọ pé ọkọ àti aya rẹ̀ “kì í ṣe méjì mọ́, bí kò ṣe ara kan.” (Mátíù 19:6) Nítorí náà, wọn ò gbọ́dọ̀ lójú mìíràn lóde, àárín ara wọn nìkan ni wọ́n gbọ́dọ̀ fi ìbálòpọ̀ mọ sí. (Òwe 5:15-21; Hébérù 13:4) Wọ́n á lè ṣe èyí tó bá jẹ́ pé ohun tó jẹ kálukú wọn lógún ni bó ṣe máa ṣe ohun tí ẹnì kejì rẹ̀ fẹ́. (1 Kọ́ríńtì 7:3-5) Ó yẹ kí ọkọ máa fi ọ̀rọ̀ pàtàkì tó wà nínú Bíbélì sọ́kàn, pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó jẹ́ kórìíra ara òun fúnra rẹ̀; ṣùgbọ́n a máa bọ́ ọ, a sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀.” Àwọn ọkọ ní láti máa nífẹ̀ẹ́ aya wọn bí wọ́n ṣe nífẹ̀ẹ́ ara wọn, kí wọ́n máa rántí pé àwọn yóò jábọ̀ fún Jésù Kristi tó jẹ́ orí tàwọn náà.—Éfésù 5:29; 1 Kọ́ríńtì 11:3.

9. Ànímọ́ wo ni Fílípì 1:8 sọ pé Jésù ní, kí sì nìdí tó fi yẹ káwọn ọkọ fi ànímọ́ yìí hàn sáwọn aya wọn?

9 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ‘Jésù ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́.’ (Fílípì 1:8) Jíjẹ́ tí Jésù jẹ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ mú kára máa tu àwọn èèyàn lọ́dọ̀ rẹ̀, èyí tó fa àwọn obìnrin tí wọ́n di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ́ra. (Jòhánù 20:1, 11-13, 16) Àwọn aya máa ń fẹ́ kí ọkọ wọn fi ìfẹ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn sí wọn.

ÀPẸẸRẸ TÓ YẸ KÍ ÀWỌN AYA MÁA TẸ̀ LÉ

10. Báwo ni Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fáwọn aya?

10 Ètò ni ìdílé. Nítorí náà, kí nǹkan tó lè máa lọ déédéé nínú ìdílé, olórí gbọ́dọ̀ wà. Kódà, Ẹnì kan wà tó jẹ́ Orí Jésù tí Jésù ń tẹrí ba fun. “Orí Kristi ni Ọlọ́run” gẹ́gẹ́ bó ti jẹ́ pé “orí obìnrin ni ọkùnrin.” (1 Kọ́ríńtì 11:3) Níwọ̀n bí àwa náà ti ní olórí tá a gbọ́dọ̀ fi ara wa sábẹ́ rẹ̀, àpẹẹrẹ àtàtà ni Jésù fi lélẹ̀ nítorí bó ṣe fi ara rẹ̀ sábẹ́ Ọlọ́run tí í ṣe orí rẹ̀.

11. Báwo ló ṣe yẹ kí aya máa ṣe sí ọkọ rẹ̀, kí ló sì lè jẹ́ àbájáde ìwà rere rẹ̀?

11 Èèyàn aláìpé sábà máa ń ṣàṣìṣe, wọn ò sì lè ṣe olórí ìdílé láìkù síbì kan. Nítorí náà, kí ló yẹ kí aya ṣe? Kò gbọ́dọ̀ máa fojú kéré ohun tí ọkọ rẹ̀ ń ṣe nítorí àtigba ipò orí mọ́ ọn lọ́wọ́. Ó yẹ kí aya máa rántí pé Ọlọ́run mọyì kéèyàn máa ṣe jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kó sì ní ìwà tútù. (1 Pétérù 3:4) Tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, kò ní  ṣòro fún un láti máa tẹrí ba fún ọkọ rẹ̀, kódà nígbà tí nǹkan ò bá fi bẹ́ẹ̀ rọgbọ pàápàá. Láfikún, Bíbélì sọ pé: “Kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.” (Éfésù 5:33) Ṣùgbọ́n tí ọkọ kò bá gbà pé Kristi jẹ́ Orí òun ńkọ́, kí ni kí aya ṣe? Bíbélì rọ àwọn aya pé: “Ẹ wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ tiyín, kí ó lè jẹ́ pé, bí ẹnikẹ́ni kò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láìsọ ọ̀rọ̀ kan nípasẹ̀ ìwà àwọn aya wọn, nítorí fífi tí wọ́n fi ojú rí ìwà mímọ́ yín pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.”1 Pétérù 3:1, 2.

12. Kí nìdí tí kò fi burú kí aya sọ èrò rẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ lórí ohun tí wọ́n bá fẹ́ ṣe?

12 Yálà onígbàgbọ́ ni ọkọ tàbí aláìgbàgbọ́, tó bá jẹ́ pé ọgbọ́n ni aya fi ń sọ èrò tó yàtọ̀ sí ti ọkọ rẹ̀ nípa ohun tí wọ́n jọ ń gbèrò láti ṣe, kò ní jẹ́ ẹni tí kò bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀. Èrò rẹ̀ nípa ohun náà lè tọ̀nà, ó sì ṣeé ṣe kó ṣe gbogbo ará ilé láǹfààní tí ọkọ rẹ̀ bá gbọ́ tiẹ̀. Nígbà tí Sárà aya Ábúráhámù sọ àbá rẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe lè yanjú ìṣòro kan tí wọ́n ní nínú ìdílé wọn, Ábúráhámù kò gba àbá Sárà. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù pé: “Fetí sí ohùn rẹ̀.” (Ka Jẹ́nẹ́sísì 21:9-12) Tí ìpinnu tí ọkọ bá ṣe nípa ohun tí wọ́n ń gbèrò àtiṣe kò bá lòdì sí òfin Ọlọ́run, ó yẹ kí aya rẹ̀ bọ̀wọ̀ fún un nípa fífara mọ́ ìpinnu náà.—Ìṣe 5:29; Éfésù 5:24.

Àpẹẹrẹ rere wo ni Sárà fi lélẹ̀ fáwọn aya?

13. (a) Kí ni Títù 2:4, 5 rọ àwọn aya pé kí wọ́n ṣe? (b) Kí ni Bíbélì sọ nípa ìpínyà àti ìkọ̀sílẹ̀?

13 Bí aya ti ń ṣe ojúṣe rẹ̀, ọ̀pọ̀ ọ̀nà ló lè gbà tọ́jú ìdílé. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé káwọn aya ‘nífẹ̀ẹ́ àwọn ọkọ wọn, kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n jẹ́ ẹni tí ó yè kooro ní èrò inú, oníwà mímọ́, òṣìṣẹ́ ní ilé, ẹni rere, tí ń fi ara wọn sábẹ́ àwọn ọkọ tiwọn.’ (Títù 2:4, 5) Tóbìnrin kan bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ bó ṣe ń ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aya àti ìyá, ọkọ rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ yóò nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, wọn yóò sì bọ̀wọ̀ fún un. (Ka Òwe 31:10, 28) Ṣùgbọ́n níwọ̀n bó ti jẹ́ pé èèyàn aláìpé méjì ló jọ ṣègbéyàwó, àwọn ìṣòro kan tó le koko lè mú kí wọ́n pínyà tàbí kí wọ́n kọ ara wọn sílẹ̀. Bíbélì fàyè gbà kí wọ́n pínyà nítorí àwọn ipò kan. Àmọ́ ìpínyà kì í ṣe ohun ṣeréṣeré o, nítorí  ohun tí Bíbélì sọ ni pé: “kí aya má lọ kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ̀; . . . kí ọkọ má sì fi aya rẹ̀ sílẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 7:10, 11) Ohun kan ṣoṣo tí Ìwé Mímọ́ sì sọ tó lè mú kí wọ́n kọ ara wọn sílẹ̀ ni tí ẹnì kan nínú wọn bá ṣe àgbèrè.—Mátíù 19:9.

ÀPẸẸRẸ ÀTÀTÀ TÓ YẸ KÍ ÒBÍ MÁA TẸ̀ LÉ

14. Báwo ni Jésù ṣe ṣe sí àwọn ọmọdé, kí làwọn ọmọ sì ń fẹ́ látọ̀dọ̀ òbí wọn?

14 Jésù fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ fáwọn òbí nínú ọ̀nà tó gbà bá àwọn ọmọdé lò. Nígbà táwọn kan sọ pé kí àwọn ọmọdé má ṣe wá sọ́dọ̀ Jésù, Jésù sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi; ẹ má gbìyànjú láti dá wọn lẹ́kun.” Bíbélì sọ pé lẹ́yìn náà, ó “gbé àwọn ọmọ náà sí apá rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí súre fún wọn, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé wọn.” (Máàkù 10:13-16) Níwọ̀n bí Jésù ti wá àyè láti wà pẹ̀lú àwọn ọmọdé, ǹjẹ́ kò yẹ kí ìwọ náà máa wá àyè láti wà pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ? Ìwọ̀nba àkókò díẹ̀ kọ́ ló yẹ kó o máa fi wà pẹ̀lú wọn o, àkókò tó pọ̀ ni. O ní láti wá àyè láti kọ́ wọn, nítorí ohun tí Jèhófà sọ pé káwọn òbí ṣe nìyẹn.—Ka Diutarónómì 6:4-9.

15. Kí làwọn òbí lè ṣe láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn?

15 Bí ayé yìí ṣe ń burú sí i, ó yẹ káwọn òbí túbọ̀ máa dáàbò  bo àwọn ọmọ wọn nítorí àwọn tó fẹ́ ṣe wọ́n léṣe, ìyẹn àwọn tí wọ́n máa ń tan àwọn ọmọdé láti bá wọn ṣèṣekúṣe. Wo bí Jésù ṣe dáàbò bo àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó fi ìfẹ́ pè ní “Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké.” Nígbà táwọn èèyàn fàṣẹ ọba mú un, tí wọ́n sì ń múra àtipa á, ó wá ọ̀nà bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe sá lọ. (Jòhánù 13:33; 18:7-9) Gẹ́gẹ́ bí òbí, o ní láti wà lójúfò kó o lè mọ ìpalára tí Sátánì fẹ́ ṣe fáwọn ọmọ rẹ. O ní láti kìlọ̀ fún wọn ṣáájú. * (1 Pétérù 5:8) Látìgbà táláyé ti dáyé, àkókò wa yìí ni ewu tó ń wu àwọn ọmọdé nípa tara, nípa tẹ̀mí àti nípa ìwà híhù tíì pọ̀ jù.

Kí làwọn òbí lè rí kọ́ látinú bi Jésù ṣe bá àwọn ọmọdé lò?

16. Kí làwọn òbí lè rí kọ́ látinú ọ̀nà tí Jésù gbà bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wí nígbà tí wọ́n ṣe ohun tó kù díẹ̀ káàtó?

 16 Ní alẹ́ tí Jésù lò kẹ́yìn kí wọ́n tó pa á, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bá ara wọn jiyàn nípa ẹni to tóbi jù láàárín wọn. Kàkà kí Jésù bínú sí wọn, ńṣe ló fi pẹ̀lẹ́tù fi ọ̀rọ̀ ẹnu àti àpẹẹrẹ sọ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣe fún wọn. (Lúùkù 22:24-27; Jòhánù 13:3-8) Tó bá jẹ́ pé òbí ni ọ́, ǹjẹ́ o rí bó o ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nínú ọ̀nà tó ò ń gbà tọ́ àwọn ọmọ rẹ sọ́nà? Lóòótọ́, wọ́n nílò ìbáwí, ṣùgbọ́n kò yẹ kó o fìbínú bá wọn wí, ńṣe ló yẹ kó o bá wọn wí “dé ìwọ̀n tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” Ìwọ náà ò ní fẹ́ sọ̀rọ̀ láìronú “bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà.” (Jeremáyà 30:11; Òwe 12:18) Ó yẹ kó o bá ọmọ rẹ wí lọ́nà tóun fúnra rẹ̀ yóò fi mọ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé, ó dára bó o ṣe bá òun wí.—Éfésù 6:4; Hébérù 12:9-11.

ÀPẸẸRẸ TÓ YẸ KÁWỌN ỌMỌ MÁA TẸ̀ LÉ

17. Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ fáwọn ọmọdé?

17 Ǹjẹ́ àwọn ọmọ lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára Jésù? Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n lè rí ẹ̀kọ́ kọ́! Nípasẹ̀ àpẹẹrẹ òun fúnra rẹ, Jésù fi hàn pé ó yẹ káwọn ọmọ máa ṣègbọràn sáwọn òbí wọn. Ó sọ pé: ‘Ohun tí Baba kọ́ mi gan-an ni mò ń sọ.’ Ó tún sọ pé: “[Ìgbà] gbogbo ni mo ń ṣe ohun tí ó wù ú.” (Jòhánù 8:28, 29) Jésù ṣègbọràn sí Bàbá rẹ̀ ọ̀run, Bíbélì sì sọ pé káwọn ọmọ máa gbọ́ràn sáwọn òbí wọn lẹ́nu. (Ka Éfésù 6:1-3) Ẹni pípé ni Jésù, aláìpé sì làwọn òbí rẹ̀. Àmọ́ nígbà tó wà ní kékeré, ó ṣègbọràn sáwọn òbí rẹ̀, ìyẹn Jósẹ́fù àti Màríà. Kò sí àní-àní pé ìyẹn mú kí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó wà nínú ìdílé Jésù túbọ̀ láyọ̀!—Lúùkù 2:4, 5, 51, 52.

18. Kí nìdí tí Jésù fi máa ń ṣègbọràn sí Bàbá rẹ̀ ọ̀run ní gbogbo ìgbà, ta sì ni inú rẹ̀ máa dùn táwọn ọmọ bá ṣègbọràn sáwọn òbí wọn lónìí?

18 Ǹjẹ́ àwọn ọ̀nà mìíràn wà táwọn ọmọ lè gbà túbọ̀ ṣe bíi ti Jésù kí wọ́n si múnú àwọn òbí wọn dùn? Nígbà mìíràn, àwọn ọmọ lè rò pé kò rọrùn láti ṣègbọràn sáwọn òbí  àwọn, ṣùgbọ́n ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n ṣe nìyẹn. (Òwe 1:8; 6:20) Jésù máa ń ṣègbọràn sí Bàbá rẹ̀ ọ̀run, kódà nígbà tí kò bá rọrùn rárá. Nígbà kan tí Ọlọ́run fẹ́ kí Jésù ṣe ohun kan tó le gan-an, Jésù sọ pé: “Mú ife yìí [ìyẹn ohun kan tí Ọlọ́run ní kó ṣe] kúrò lórí mi.” Ṣùgbọ́n Jésù ṣe ohun tí Ọlọ́run ní kó ṣe, nítorí ó mọ̀ pé Bàbá rẹ̀ mọ ohun tó dára jù lọ. (Lúùkù 22:42) Táwọn ọmọ bá jẹ́ onígbọràn, wọn yóò múnú àwọn òbí wọn àti inú Bàbá wọn ọ̀run dùn. *Òwe 23:22-25.

Kí ló yẹ káwọn ọ̀dọ́ ronú nípa rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá rí àdánwò?

19. (a) Báwo ni Sátánì ṣe ń dán àwọn ọmọdé wò? (b) Báwo ló ṣe máa rí lára àwọn òbí tí ọmọ wọn bá ṣèṣekúṣe?

19 Èṣù dán Jésù wò, ó sì dá wa lójú pé yóò dán àwọn ọmọdé náà wò pé kí wọ́n ṣe ohun tí kò dára. (Mátíù 4:1-10) Ohun tí Sátánì Èṣù máa ń lò ni ẹ̀mí ṣe-ohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe, ẹ̀mí tó jẹ́ pé ó lè má rọrùn láti yàgò fún. O ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé káwọn ọmọ má ṣe bá àwọn ọmọ oníwàkiwà kẹ́gbẹ́! (1 Kọ́ríńtì 15:33) Dínà ọmọbìnrin Jékọ́bù lọ bá àwọn tí kì í jọ́sìn Jèhófà ṣọ̀rẹ́, ìyẹn sì kó o sí yọ́ọ́yọ́ọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 34:1, 2) Wo bó ṣe máa dun gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé kan tó bí ẹnì kan nínú ìdílé yẹn bá lọ ṣèṣekúṣe!—Òwe 17:21, 25.

 OHUN TÓ LÈ MÚ KÍ ÌDÍLÉ JẸ́ ALÁYỌ̀

20. Kí ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó wà nínú ìdílé gbọ́dọ̀ ṣe kí ìdílé wọn bàa lè jẹ́ aláyọ̀?

20 Bí àwọn tó wà nínú ìdílé bá fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò, kò ní ṣòro fún wọn láti yanjú ìṣòro ìdílé. Táwọn tó wà nínú ìdílé bá sì fi àwọn ìmọ̀ràn yẹn sílò, ìdílé á jẹ́ aláyọ̀. Nítorí náà, ìwọ ọkọ, nífẹ̀ẹ́ aya rẹ kó o sì bá a lò lọ́nà tí Jésù gbà ń bá ìjọ rẹ̀ lò. Ìwọ aya, tẹrí ba fún ọkọ rẹ tó jẹ́ orí rẹ kó o sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ aya tó dáńgájíá tí Òwe 31:10-31 ṣàpèjúwe. Ẹ̀yin òbí, ẹ tọ́ àwọn ọmọ yín. (Òwe 22:6) Ẹ̀yin bàbá, ‘ẹ máa mójú tó agbo ilé yín lọ́nà tó dára.’ (1 Tímótì 3:4, 5; 5: 8) Kí ẹ̀yin ọmọ sì máa gbọ́ràn sáwọn òbí yín lẹ́nu. (Kólósè 3:20) Kò sẹ́ni tí kì í ṣàṣìṣe nínú ìdílé nítorí gbogbo yín ni aláìpé. Nítorí náà, ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, kẹ́ ẹ máa tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ara yín.

21. Kí ló ṣì ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú, báwo la sì ṣe lè ní ìdílé aláyọ̀ nísinsìnyí?

21 Dájúdájú, ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn tó dára àti ìlànà ló wà nínú Bíbélì nípa bí ìdílé ṣe lè jẹ́ aláyọ̀. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Bíbélì tún kọ́ wa nípa ayé tuntun Ọlọ́run àti Párádísè ilẹ̀ ayé tó máa kún fún àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ aláyọ̀ tí wọ́n sì ń sin Jèhófà. (Ìṣípayá 21:3, 4) O ò rí i pé àgbàyanu ayọ̀ ló ṣì ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú! Kódà ní báyìí, a lè ní ìdílé aláyọ̀ tá a bá fi àwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò.

^ ìpínrọ̀ 15 Ohun tó lè ranni lọ́wọ́ láti lè dáàbò bo àwọn ọmọ wà ní ojú ìwé 32 nínú ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe.

^ ìpínrọ̀ 18 Ìgbà tí òbí bá ní kí ọmọ ṣe ohun tó lòdì sí òfin Ọlọ́run nìkan ni kò yẹ kí ọmọ gbọ́ràn sí i lẹ́nu.—Ìṣe 5:29.