JÈHÓFÀ ràn wá lọ́wọ́ ká lè dá Mèsáyà tó ṣèlérí pé yóò jẹ́ Olùdáǹdè mọ̀. Bó ṣe ràn wá lọ́wọ́ ní pé ó mí sí àwọn wòlíì rẹ̀ pé kí wọ́n sọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìbí Mèsáyà, iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, àti ikú rẹ̀. Gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ tí wọ́n sọ tá a rí nínú Bíbélì ló ṣẹ sára Jésù  Kristi, kò já létí; bí wọ́n sì ṣe sọ pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà yóò ṣe ṣẹ ni wọ́n ṣe ṣẹ. Kó o lè mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, jẹ́ ká wo àsọtẹ́lẹ̀ mélòó kan tó sọ nípa ìbí Jésù àti nípa ìgbà tó wà ní kékeré.

Wòlíì Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé Mèsáyà yóò jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ọba Dáfídì. (Aísáyà 9:7) Inú ìran ìdílé Dáfídì ni wọ́n sì bí Jésù sí lóòótọ́.—Mátíù 1:1, 6-17.

 Wólìí Ọlọ́run mìíràn tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Míkà sọ tẹ́lẹ̀ pé “Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Éfúrátà” ni wọn yóò bí ọmọ yìí sí ó sì tún sọ pé yóò di olùṣàkóso lásẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀. (Míkà 5:2) Lákòókò tí wọ́n bí Jésù, ìlú méjì ni wọ́n ń pè ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Ọ̀kan wà nítòsí ìlú Násárétì tó wà ní àríwá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, èkejì sì wà nítòsí Jerúsálẹ́mù ní Júdà. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, Éfúrátà ni wọ́n ń pe Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tó wà nítòsí Jerúsálẹ́mù. Bí àsọtẹ́lẹ̀ Míkà sì ṣe sọ, Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tó wà nítòsí Jerúsálẹ́mù yìí ni wọ́n bí Jésù sí!—Mátíù 2:1.

Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì mìíràn sọ pé Ọlọ́run yóò pe Ọmọ rẹ̀ “láti Íjíbítì.” Nígbà tí Jésù wà ní kékeré, wọ́n gbé e lọ́ sí Íjíbítì. Àmọ́ lẹ́yìn tí ọba Hẹ́rọ́dù kú, wọ́n gbé Jésù padà láti Íjíbítì. Bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ṣẹ nìyẹn.—Hóséà 11:1; Mátíù 2:15.

Nínú àtẹ ìsọfúnnni tá a pe àkọ́lé rẹ̀ ní “ Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Mèsáyà,” a to àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Mèsáyà sábẹ́ àkòrí tá a pè ní “Àsọtẹ́lẹ̀.” Jọ̀wọ́ fi àwọn ẹsẹ Bíbélì náà wé àwọn èyí tá a tò sábẹ́ àkòrí tá a pè ní “Ìmúṣẹ.” Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ tó o ní, pé òótọ́ ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, yóò lágbára sí i.

Bó o ṣe ń gbé àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyí yẹ̀ wò, fi sọ́kàn pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú kí wọ́n tó bí Jésù ni wọ́n ti kọ àwọn tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyẹn. Jésù sọ pé: “Gbogbo ohun tí a kọ̀wé rẹ̀ nípa mi nínú òfin Mósè àti nínú àwọn Wòlíì àti àwọn Sáàmù ni a gbọ́dọ̀ mú ṣẹ.” (Lúùkù 24:44) Bí ìwọ náà ṣe rí i kà nínú Bíbélì, gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run sọ nípa Mèsáyà ló nímùúṣẹ, kò já létí!