Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?

 ORÍ KEJÌDÍNLÓGÚN

Ìrìbọmi Ló Máa Fìdí Àjọṣe Rẹ Pẹ̀lú Ọlọ́run Múlẹ̀

Ìrìbọmi Ló Máa Fìdí Àjọṣe Rẹ Pẹ̀lú Ọlọ́run Múlẹ̀
  • Báwo la ṣe ń ṣèrìbọmi fún Kristẹni?

  • Àwọn ohun wo lo gbọ́dọ̀ ṣe kó o tó lè kúnjú ìwọ̀n láti ṣèrìbọmi?

  • Báwo lẹnì kan ṣe lè ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run?

  • Kí nìdí pàtàkì tó fi yẹ kó o ṣèrìbọmi?

1. Kí nìdí tí ará Etiópíà tó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin fi sọ pé kí wọ́n ri òun bọmi?

“WÒ Ó! ìwọ́jọpọ̀ omi; kí ni ó dí mi lọ́wọ́ dídi ẹni tí a batisí?” Ará Etiópíà kan tó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin ló béèrè ìbéèrè yẹn ní ọ̀rúndún kìíní lẹ́yìn tí Kristẹni kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Fílípì fi yé e yékéyéké pé Jésù ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí. Nítorí  pé ohun tí ará Etiópíà náà kọ́ nínú Bíbélì wọ̀ ọ́ lọ́kàn gidigidi, ó ṣiṣẹ́ lé nǹkan tó kọ́. Ó ní kí wọ́n ri òun bọmi!—Ìṣe 8:26-36.

2. Kí nìdí tó fi yẹ kó o ronú gidigidi nípa ìrìbọmi?

2 Tó bá jẹ́ pé o ti fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ orí kìíní sí ìkẹtàdínlógún nínú ìwé yìí pẹ̀lú ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, o ṣeé ṣe kó o rí i pé o ti kúnjú ìwọ̀n láti béèrè pé: ‘Kí ló ń dí mi lọ́wọ́ dídi ẹni tí a batisí?’ Bá a ti ń sọ̀rọ̀ yìí, o ti mọ̀ pé Bíbélì ṣèlérí ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè. (Lúùkù 23:43; Ìṣípayá 21:3, 4) O tún ti mọ òtítọ́ ipò táwọn òkú wà àti ìrètí àjíǹde. (Oníwàásù 9:5; Jòhánù 5:28, 29) Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó o ti máa lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó o sì ti rí i bí wọ́n ṣe ń ṣe ìsìn tòótọ́. (Jòhánù 13:35) Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé, ó ṣeé ṣe kó o ti bẹ̀rẹ̀ sí bá Jèhófà Ọlọ́run dọ́rẹ̀ẹ́.

3. (a) Àṣẹ wo ni Jésù pa fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀? (b) Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe ìbatisí?

3 Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o fẹ́ sín Ọlọ́run? Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn.” (Mátíù 28:19) Jésù fúnra rẹ̀ fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nítorí pé òun náà ṣe ìbatisí. Kì í ṣe pé wọ́n wọ́n omi sí Jésù lára, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò kàn da omi sí i lórí. (Mátíù 3:16) Inú ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ sí “rì bọ̀” ni ọ̀rọ̀ náà, “batisí” ti wá. Nítorí náà, ṣíṣe ìbatisí fún Kristẹni túmọ̀ sí rírì í bọ inú omi pátápátá.

4. Kí ni ìrìbọmi tó o bá ṣe yóò fi hàn?

4 Gbogbo àwọn tó bá fẹ́ bá Jèhófà dọ́rẹ̀ẹ́ ni wọ́n gbọ́dọ̀ ṣèrìbọmi. Ìrìbọmi ní yóò fi han gbogbo èèyàn pé o fẹ́ láti sin Ọlọ́run. Yóò fi hàn pé ó wù ọ́ láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. (Sáàmù 40:7, 8) Ṣùgbọ́n àwọn ohun kan wà tó o gbọ́dọ̀ ṣe kó o tó lè kúnjú ìwọ̀n láti ṣèrìbọmi.

 O GBỌ́DỌ̀ NÍ ÌMỌ̀ ÀTI ÌGBÀGBỌ́

5. (a) Kí lohun àkọ́kọ́ tó o gbọ́dọ̀ ṣe kó o lè kúnjú ìwọ̀n láti ṣe ìrìbọmi? (b) Kí nìdí tí ìpàdé ìjọ fi ṣe pàtàkì?

5 Ohun àkọ́kọ́ tó o gbọ́dọ̀ ṣe ni pé kó o gba ìmọ̀ Jèhófà Ọlọ́run àti ti Jésù Kristi sínú nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. O sì ti ń ṣe bẹ́ẹ̀. (Ka Jòhánù 17:3) Àmọ́ ohun tó o ṣì ní láti kọ́ pọ̀ o. Àwọn Kristẹni máa ń fẹ́ “kún fún ìmọ̀ pípéye nípa ìfẹ́ [Ọlọ́run].” (Kólósè 1:9) Lílọ sí ìpàdé ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ gan-an láti ní ìmọ̀ pípéye yìí. Ó ṣe pàtàkì pé kó o máa lọ sípàdé. (Hébérù 10:24, 25) Tó o bá ń lọ sípàdé déédéé, ìmọ̀ Ọlọ́run tó o ní á pọ̀ sí i.

Kí ẹnì kan tó lè tóótun láti ṣe ìrìbọmi, ó ṣe pàtàkì pé kó ní ìmọ̀ pípéye nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

6. Báwo ni ìmọ̀ Bíbélì tó o ní ṣe gbọ́dọ̀ pọ tó kó o tó lè ṣèrìbọmi?

6 Ká sòótọ́, kò dìgbà tó o bá mọ gbogbo ohun tó wà nínú Bíbélì kó o tó lè kúnjú ìwọ̀n láti ṣèrìbọmi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ará Etiópíà tó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin ní ìmọ̀ díẹ̀ tẹ́lẹ̀, síbẹ̀ a rí i pé ẹnì kan ṣì ràn án lọ́wọ́ kó tó lè lóye àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan. (Ìṣe 8:30, 31) Bíi tọkùnrin yẹn, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ṣì kù tíwọ náà ní láti kọ́. Kódà, títí láé ni wàá máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. (Oníwàásù 3:11) Àmọ́ kó o tó lè ṣèrìbọmi, ó kéré tán, o gbọ́dọ̀ mọ àwọn àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì kó o sì gbà pé òótọ́ ni wọ́n. (Hébérù 5:12) Lára irú àwọn ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ ni, ipò táwọn òkú wà, pàtàkì orúkọ Ọlọ́run, àti Ìjọba Ọlọ́run.

7. Kí ló yẹ kí ẹ̀kọ́ tó ò ń kọ́ nínú Bíbélì mú kó o ṣe?

7 Ìmọ̀ nìkan kò tó, nítorí “láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wù [Ọlọ́run] dáadáa.” (Hébérù 11:6) Bíbélì sọ pé nígbà táwọn kan ní ìlú Kọ́ríńtì ayé ọjọ́un gbọ́ ìwàásù àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, wọ́n “bẹ̀rẹ̀ sí gbà gbọ́, a sì ń batisí wọn.” (Ìṣe 18:8) Bíi tiwọn, ó yẹ kí ẹ̀kọ́ tó ò ń kọ́ nínú Bíbélì mú kó o ní ìgbàgbọ́ pé, Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí Ọlọ́run mí sí. Ó yẹ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mú kó o gba àwọn ìlérí Ọlọ́run gbọ́. Ó sì yẹ kó mú kó o gbà gbọ́ pé ẹbọ Jésù lágbára láti gbà ọ́ là.—Jóṣúà 23:14; Ìṣe 4:12; 2 Tímótì 3:16, 17.

 SỌ ÒTÍTỌ́ TÓ O KỌ́ NÍNÚ BÍBÉLÌ FÁWỌN ẸLÒMÍRÀN

8. Kí ló máa mú kó o sọ ohun tó ò ń kọ́ fáwọn ẹlòmíràn?

8 Bí ìgbàgbọ́ tó o ní ṣe ń lágbára sí i, wàá rí i pé o kò ní lè pa ohun tó ò ń kọ́ mọ́ra láìsọ ọ́ fáwọn ẹlòmíràn. (Jeremáyà 20:9) Ìgbàgbọ́ yẹn yóò mú kó o fìtara sọ àwọn nǹkan tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fáwọn ẹlòmíràn.—Ka 2 Kọ́ríńtì 4:13.

Ìgbàgbọ́ tó o ní gbọ́dọ̀ mú kó o sọ ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíràn

9, 10. (a) Àwọn wo lo lè kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí máa bá sọ òtítọ́ tó ò ń kọ́ nínú Bíbélì? (b) Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá fẹ́ bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jáde lọ wàásù?

9 O lè bẹ̀rẹ̀ sí sọ òtítọ́ tó o kọ́ nínú Bíbélì fáwọn ẹlòmíràn nípa fífọgbọ́n wàásù fáwọn ìbátan rẹ, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ, àwọn aládùúgbò rẹ àtàwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ níbì kan náà. Bí àkókò ti ń lọ, wàá fẹ́ láti bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jáde ìwàásù. Bí ìfẹ́ yẹn bá ti wà lọ́kàn rẹ bẹ́ẹ̀, bá Ẹlẹ́rìí tó ń bá ọ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sọ ọ́. Tó bá hàn pé o ti tó ẹni tí ń jáde lọ wàásù, wọ́n á ṣètò pé kí ìwọ àtẹni tó ń bá ọ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ìpàdé pẹ̀lú alàgbà méjì.

10 Èyí á jẹ́ kó o mọ àwọn kan lára àwọn alàgbà tí wọ́n ń ṣolùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run. (Ìṣe 20:28; 1 Pétérù 5:2, 3) Báwọn alàgbà méjì náà bá rí i pé o ti mọ àwọn àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì tó o sì gba àwọn ẹ̀kọ́ náà gbọ́, tí wọ́n bá rí i pé ò ń gbé ìgbésí ayé rẹ níbàámu pẹ̀lú ìlànà Ọlọ́run, tí wọ́n sì rí i pé lóòótọ́ lo fẹ́ di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n á jẹ́ kó o mọ̀ pé o ti kúnjú ìwọ̀n láti máa báwọn ará lọ wàásù kó o sì di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi tó ń kéde ìhìn rere.

11. Àwọn àtúnṣe wo làwọn kan gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n tó lè kúnjú ìwọ̀n láti máa lọ sí òde ẹ̀rí?

11 Àmọ́ ó ṣeé ṣe káwọn àtúnṣe kan wà tó o ní láti ṣe nínú ìgbésí ayé rẹ àti nínú ìwà rẹ kó o tó lè kúnjú ìwọ̀n láti jáde òde ẹ̀rí. Èyí lè kan àwọn ìwà tí kò dára tó ṣeé ṣe kó o máa ha hù níkọ̀kọ̀. Nítorí náà, kó o tó sọ pé o fẹ́ di  akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, o gbọ́dọ̀ jáwọ́ nínú àwọn ìwà burúkú, irú bíi ṣíṣe ìṣekúṣe, mímutí lámupara àti lílo oògùn olóró.—Ka 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; Gálátíà 5:19-21.

RONÚ PÌWÀ DÀ KÓ O SÌ YÍ PADÀ

12. Kí nìdí tó fi pọn dandan kó o ronú pìwà dà?

12 Àwọn ohun mìíràn tún wà tó o ní láti ṣe kó o tó lè kúnjú ìwọ̀n láti ṣèrìbọmi. Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Ẹ ronú pìwà dà, kí ẹ sì yí padà, kí a lè pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́.” (Ìṣe 3:19) Kéèyàn ronú pìwà dà túmọ̀ sí pé kéèyàn kábàámọ̀ àwọn ohun tí kò dára tó ti ṣe tẹ́lẹ̀. Ẹni tó ń gbé ìgbé ayé oníwà àìmọ́ gbọ́dọ̀ ronú pìwà da. Ẹni tó ń gbé ìgbé ayé tó mọ́ díẹ̀ náà gbọ́dọ̀ ronú pìwà dà. Kí nìdí? Ìdí ni pé gbogbo èèyàn ni ẹlẹ́ṣẹ̀, tí wọ́n nílò ìdáríjì Ọlọ́run. (Róòmù 3:23; 5:12) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé kó o tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, o ò mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ṣé o lè sọ pé o ti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́? Rárá, o ò lè sọ bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, ó pọn dandan kó o ronú pìwà dà.

13. Kí ni ìyípadà?

13 Lẹ́yìn tó o bá ti ronú pìwà dà, o gbọ́dọ̀ yí padà. O ò kàn ní kábàámọ̀ àwọn ohun tó o ti ṣe nìkan. O gbọ́dọ̀ jáwọ́ nínú àwọn ohun tí kò dára tó ò ń ṣe tẹ́lẹ̀ kó o sì pinnu pé láti ìsinsìnyí lọ, ohun tó dára ni wàá máa ṣe. Kó o tó ṣèrìbọmi, o gbọ́dọ̀ ronú pìwà dà kó o sì yí padà.

YA ARA RẸ SÍ MÍMỌ́

14. Kí lohun pàtàkì tó o tún gbọ́dọ̀ ṣe kó o tó ṣèrìbọmi?

14 O tún ní láti ṣe ohun pàtàkì kan kó o tó ṣèrìbọmi. O gbọ́dọ̀ ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run.

Ǹjẹ́ o ti ya ara rẹ sí mímọ fún Ọlọ́run nípasẹ̀ àdúrà?

15, 16. Kí ló túmọ̀ sí pé kó o ya ara rẹ sí mímọ́ fún Ọlọ́run, kí ló sì máa ń mú èèyàn ṣe bẹ́ẹ̀?

15 Ohun tó túmọ̀ sí pé kó o ya ara rẹ sí mímọ́ ni pé, kó o gba àdúrà àtọkànwá sí Jèhófà Ọlọ́run kó o sì ṣèlérí fún un nínú àdúrà náà pé, òun nìkan lo fẹ́ máa sìn títí  láé. (Diutarónómì 6:15) Kí wá nìdí tó fi yẹ kó o fẹ́ láti sin Ọlọ́run títí láé? Tóò, jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí ná kó o bàa lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn. Ká sọ pé ọkùnrin kan ń fẹ́ obìnrin kan sọ́nà. Bó bá ṣe ń rí i pé obìnrin náà ní ìwà ọmọlúwàbí, bẹ́ẹ̀ ní yóò máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ sí i. Tó bá sì yá, yóò sọ pé káwọn ṣègbéyàwó. Ó mọ̀ pé bùkátà gidi lòun fẹ́ tọrùn bọ̀ o, síbẹ̀ yóò bá obìnrin yìí ṣègbéyàwó nítorí ìfẹ́ tó ní sí i.

16 Torí pé o mọ Jèhófà tó o sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ lo fi fẹ́ láti fi gbogbo agbára rẹ sìn ín láìka ohunkóhun tó lè ná ọ sí. Ẹnikẹ́ni tó bá sì fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi Ọmọ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ “sẹ́ níní ara rẹ̀.” (Máàkù 8:34) Bá a bá sẹ́ níní ara wa, ohun tó túmọ̀ sí ni pé a kò jẹ́ kí àwọn ohun tá a fẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ̀ àtàwọn ohun tá a nífẹ̀ẹ́ sí dí wa lọ́wọ́ tí a kò fi ní lè ṣègbọràn sí Ọlọ́run délẹ̀délẹ̀. Nítorí náà, kó o tó lè ṣèrìbọmi, ṣíṣe ohun tí Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ ló gbọ́dọ̀ ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé rẹ.—Ka 1 Pétérù 4:2.

MÁ BẸ̀RÙ ÌJÁKULẸ̀

17. Kí ló fà á táwọn kan fi ń fi yíya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run falẹ̀?

17 Àwọn kan ń fi yíya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà falẹ̀ nítorí pé àyà wọn ń já láti ṣe irú nǹkan pàtàkì bẹ́ẹ̀. Wọ́n ń bẹ̀rù pé táwọn bá ṣèyàsímímọ́ táwọn sì di Kristẹni, yóò di dandan káwọn jíhìn fún Ọlọ́run nípa gbogbo ohun táwọn bá ń ṣe. Nítorí ẹ̀rù tó ń bà wọ́n pé àwọn lè já Jèhófà kulẹ̀ táwọn bá ṣe ohun tí kò fẹ́, wọ́n rò pé ó kúkú sàn káwọn má ya ara àwọn sí mímọ́ fún Jèhófà rárá.

18. Kí ló lè mú kó wù ọ́ láti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà?

18 Ṣó o rí i, bó o bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe máa wù ọ́ láti ya ara rẹ sí mímọ́ fún un kó o sì ṣe gbogbo ohun tó bá wà ní agbára rẹ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Oníwàásù 5:4) Kò sí àní-àní pé lẹ́yìn tó o bá ṣèyàsímímọ́, wàá fẹ́ máa “rìn lọ́nà tí ó yẹ Jèhófà fún ète wíwù ú ní kíkún.”  (Kólósè 1:10) Nítorí ìfẹ́ tó o ní sí Ọlọ́run, kò ní ṣòro lójú rẹ láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Ó sì dájú pé wàá gbà pé òótọ́ lohun tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ, pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.”—1 Jòhánù 5:3.

19. Kí nìdí tí kò fi yẹ kó o máa bẹ̀rù àtiya ara rẹ sí mímọ́ fun Ọlọ́run?

19 Kò dìgbà tó o bá di ẹni pípé kó o tó lè ya ara rẹ sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Jèhófà mọ ibi tágbára rẹ mọ kò sì ní sọ pé kó o ṣe ju agbára rẹ lọ. (Sáàmù 103:14) Jèhófà yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ nítorí pé ó fẹ́ kó o yege. (Ka Aísáyà 41:10) Jẹ́ kó dá ọ lójú pé tó o bá fi gbogbo ọkàn rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ‘yóò mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.’—Òwe 3:5, 6.

 ṢÈRÌBỌMI LÁTI FI HÀN PÉ O TI YA ARA RẸ SÍ MÍMỌ́

20. Kí nìdí tó fi yẹ kí ẹnì kan tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fi hàn pé òun ti ṣe bẹ́ẹ̀?

20 Tó o bá ronú lórí gbogbo ohun tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí, o lè fẹ́ láti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà nípa gbígbàdúrà sí i. Gbogbo àwọn tó bá sì jẹ́ pé lóòótọ́ ni wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ni wọ́n gbọ́dọ̀ “ṣe ìpolongo ní gbangba fún ìgbàlà.” (Róòmù 10:10) Báwo ni wàá ṣe ṣe ìpolongo ní gbangba?

Tá a bá ṣèrìbọmi, ó túmọ̀ sí pé a ti dòkú sí irú ìgbé ayé tá à ń gbé tẹ́lẹ̀ a si ti di alààyè láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run

21, 22. Báwo lo ṣe lè ‘polongo’ ìgbàgbọ́ rẹ ní “gbangba”?

 21 Sọ fún alága àwọn alábòójútó ìjọ rẹ pé o fẹ́ ṣèrìbọmi. Yóò ṣọ̀nà báwọn alàgbà kan yóò ṣe bá ọ ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìbéèrè tó dá lórí àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Bíbélì. Táwọn alàgbà náà bá rí i pé o ti kúnjú ìwọ̀n, wọ́n á sọ fún ọ pé o lè ṣèrìbọmi nígbà ìrìbọmi tó kàn. * Ṣáájú ìrìbọmi, àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi máa ń kọ́kọ́ gbọ́ àsọyé kan tó ṣàlàyé ohun tí ìrìbọmi jẹ́. Lẹ́yìn náà ni olùbánisọ̀rọ̀ náà yóò ní kí gbogbo àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi dáhùn ìbéèrè méjì. Ìdáhùn náà jẹ́ ọ̀nà kan tí wọ́n máa ń gbà ‘polongo’ ìgbàgbọ́ wọn ní “gbangba.”

22 Ìrìbọmi ló máa fi han gbogbo èèyàn pé o ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Ọlọ́run o sì ti di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ńṣe la máa ń ri èèyàn bọmi pátápátá kí gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ lè rí i pé onítọ̀hún ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà.

OHUN TÍ ÌRÌBỌMI TÓ O ṢE TÚMỌ̀ SÍ

23. Kí ló túmọ̀ sí pé ká batisí ẹnì kan “ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́”?

23 Jésù sọ pé wọn yóò máa ri àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun bọmi “ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́.” (Mátíù 28:19) Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé ẹni tó fẹ́ ṣèrìbọmi náà mọ̀ pé agbára àti àṣẹ wà níkàáwọ́ Jèhófà àti Jésù Kristi. (Sáàmù 83:18; Mátíù 28:18) Bákan náà, ó mọ ipa tí ẹ̀mí mímọ́, tàbí ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run ń kó àtohun tó ń ṣe.—Gálátíà 5:22, 23; 2 Pétérù 1:21.

24, 25. (a) Kí ni ìrìbọmi túmọ̀ sí? (b) Ìbéèrè wo la gbọ́dọ̀ rí ìdáhùn sí?

24 Ṣùgbọ́n ìrìbọmi kì í ṣe ìwẹ̀ lásán o, àpẹẹrẹ ohun pàtàkì kan ló jẹ́. Ohun tí títẹ̀ tí wọ́n bá tẹ̀ ọ́ bọ inú omi  ṣàpẹẹrẹ ni pé, o ti dòkú sí irú ìgbé ayé tó ò ń gbé tẹ́lẹ̀. Gbígbé tí wọ́n bá gbé ọ sókè kúrò nínú omi túmọ̀ sí pé o ti di alààyè láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Kó o sì máa rántí pé Jèhófà Ọlọ́run lo ya ara rẹ sí mímọ́ fún, kì í ṣe fún iṣẹ́ kankan, kì í ṣe féèyàn kankan, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe fún ẹgbẹ́ kankan. Ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi tó o ṣe jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, ìyẹn àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀.—Sáàmù 25:14.

25 Ìrìbọmi kò túmọ̀ sí pé èèyàn ti rí ìgbàlà o. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì.” (Fílípì 2:12) Ìbẹ̀rẹ̀ lásán ni ìrìbọmi jẹ́, ìbẹ̀rẹ̀ kì í sì í ṣe oníṣẹ́. Nítorí náà, ìbéèrè tó yẹ ká rí ìdáhùn sí ni pé, Báwo lo ò ṣe ní kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run? Orí tó gbẹ̀yìn la ó ti rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí.

^ ìpínrọ̀ 21 Ìrìbọmi máa ń wáyé ní gbogbo àpéjọ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe lọ́dọọdún.