Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?

 ORÍ KẸẸ̀Ẹ́DÓGÚN

Ìjọsìn Tó Ní Ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run

Ìjọsìn Tó Ní Ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run
  • Ǹjẹ́ gbogbo ìsìn ló wu Ọlọ́run?

  • Báwo la ṣe lè dá ìsìn tòótọ́ mọ̀?

  • Àwọn wo ni olùjọsìn tòótọ́ lónìí?

1. Báwo ni jíjọ́sìn Ọlọ́run ní ọ̀nà tó tọ́ yóò ṣe ṣe wá láǹfààní?

JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN bìkítà fún wa gán-an ni, ó sì fẹ́ ká jàǹfààní nínú ìtọ́sọ́nà tó fún wa tìfẹ́tìfẹ́. Tá a bá sìn ín lọ́nà tó tọ́, a óò láyọ̀ a ò sì ní kó sínú ọ̀pọ̀ ìṣòro tó wà láyé. Bákan náà, Jèhófà yóò bù kún wa, yóò sì ràn wá lọ́wọ́. (Aísáyà 48:17) Ṣùgbọ́n àìmọye ìsìn ló wà, gbogbo wọn ló sì ń sọ pé òtítọ́ lohun táwọn fi ń kọ́ni nípa Ọlọ́run. Síbẹ̀, ohun tí wọ́n fi ń kọ́ni nípa irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ àtohun tó fẹ́ ká ṣe kò dọ́gba.

2. Báwo la ṣe lè mọ ọ̀nà tó tọ́ láti jọ́sìn Jèhófà, àpèjúwe wo ló sì jẹ́ kí ìyẹn yé wa?

2 Báwo lo ṣe lè mọ ọ̀nà tó tọ́ láti jọ́sìn Jèhófà? Kò dìgbà tó o bá dán gbogbo ìsìn wò tó o sì fi ẹ̀kọ́ wọn wéra kó o tó lè mọ ọ̀nà tó tọ́ láti jọ́sìn Ọlọ́run. Kìkì ohun tó o ní láti ṣe ni pé kó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an nípa ìsìn tòótọ́. Wo àpèjúwe yìí ná: Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ni wọ́n ti máa ń ní ìṣòro ayédèrú owó. Ká sọ pé iṣẹ́ tìrẹ ni kó o máa yọ àwọn ayédèrú owó sọ́tọ̀, báwo ni wàá ṣe ṣe é? Ṣó o máa há gbogbo àmì téèyàn fi lè dá ayédèrú owó mọ̀ sórí ni? Rárá o. Ohun tí kò ní fàkókò rẹ ṣòfò ni pé kó o mọ àmì téèyàn fi ń dá owó gidi mọ̀. Tó o bá ti mọ bí owó gidi ṣe rí, kò ní ṣòro fún ọ láti dá èyí tó jẹ́ ayédèrú mọ̀. Bákan náà, tá a bá ti mọ bá a ṣe lè dá ìsìn tòótọ́ mọ̀, àtidá ìsìn èké mọ̀ kò ní ṣòro.

3. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Jésù sọ, kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà wa?

 3 Ó ṣe pàtàkì ká jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó fẹ́. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló rò pé gbogbo ìsìn ló wu Ọlọ́run, àmọ́, Bíbélì ò fi kọ́ni bẹ́ẹ̀ o. Kódà, kéèyàn wulẹ̀ sọ pé Kristẹni lòun gan-an kò tó. Jésù sọ pé: “Kì í ṣe olúkúlùkù ẹni tí ń wí fún mi pé, ‘Olúwa, Olúwa,’ ni yóò wọ ìjọba ọ̀run, bí kò ṣe ẹni tí ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run ni yóò wọ̀ ọ́.” Nítorí náà, kí Ọlọ́run tó lè tẹ́wọ́ gbà wá, a gbọ́dọ̀ mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe ká sì ṣe é. Jésù pe àwọn tí kò ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ní “oníṣẹ́ ìwà àìlófin.” (Mátíù 7:21-23) Bí ayédèrú owó ni ìsìn èké ṣe rí, kò wúlò fún nǹkan kan. Ohun tó tiẹ̀ wá burú jù níbẹ̀ ni pé, irú ìsìn bẹ́ẹ̀ lè ṣàkóbá fún èèyàn.

4. Kí ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nípa ọ̀nà méjì túmọ̀ sí, ibo sì ni ọ̀kọ̀ọ̀kan ọ̀nà méjèèjì náà yóò yọrí sí?

4 Gbogbo èèyàn tó wà láyé ni Ọlọ́run fún láǹfààní láti ní ìyè àìnípẹ̀kun. Ṣùgbọ́n, tá a bá fẹ́ ní ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè, a gbọ́dọ̀ jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́ ká sì gbé irú ìgbé ayé tó fẹ́. Ó ṣeni láàánú pé ọ̀pọ̀ ló fàáké kọ́rí pé àwọn ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ ní tàwọn. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ pé: “Ẹ gba ẹnubodè tóóró wọlé; nítorí fífẹ̀ àti aláyè gbígbòòrò ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn tí ń gbà á wọlé; nígbà tí ó jẹ́ pé, tóóró ni ẹnubodè náà, híhá sì ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn tí ń rí i.” (Mátíù 7:13, 14) Ìsìn tòótọ́ yóò yọrí si ìyè àìnípẹ̀kun. Àmọ́ ìparun ni ìsìn èké yóò yọrí sí. Jèhófà ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run, ìdí nìyẹn tó fi fún àwọn èèyàn níbi gbogbo láǹfààní pé kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nípa òun. (2 Pétérù 3:9) Nítorí náà, ọ̀nà tá a bá gbà jọ́sìn Ọlọ́run ló máa pinnu bóyá ìyè ni yóò jẹ tiwa tàbí ikú.

BÓ O ṢE LÈ DÁ ÌSÌN TÒÓTỌ́ MỌ̀

5. Báwo la ṣe lè dá àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ mọ̀?

5 Báwo lo ṣe lè rí “ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè”? Jésù sọ pé yóò  hàn lára àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ pé ìsìn tòótọ́ ni wọ́n ń ṣe. Ó sọ pé: “Nípa àwọn èso wọn ni ẹ ó fi dá wọn mọ̀. . . . Gbogbo igi rere a máa mú èso àtàtà jáde.” (Mátíù 7:16, 17) Lọ́rọ̀ mìíràn, ìwà àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ àtohun tí wọ́n gbà gbọ́ ni èèyàn máa fi dá wọn mọ̀ pé àwọn ni wọ́n ń ṣe ìsìn tòótọ́. Ní tòdodo, aláìpé làwọn tí ń ṣe ìsìn tòótọ́ wọ́n sì máa ń ṣàṣìṣe, ṣùgbọ́n ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ló máa ń jẹ gbogbo wọn lógún. Ní báyìí, jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ohun mẹ́fà téèyàn lè fi dá àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ mọ̀.

6, 7. Ojú wo làwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ fi ń wo Bíbélì, báwo sì ni Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ lórí ọ̀ràn yìí?

6 Bíbélì ni àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ máa ń gbé ẹ̀kọ́ wọn kà. Bíbélì fúnra rẹ̀ sọ pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo, kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.” (2 Tímótì 3:16, 17) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sì kọ̀wé sáwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ pé: “Nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí ẹ gbọ́ láti ọ̀dọ̀ wa, ẹ tẹ́wọ́ gbà á, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ lótìítọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (1 Tẹsalóníkà 2:13) Nítorí náà, ohun tí wọ́n ń ṣe nínú ìsìn tòótọ́ àti ohun tí wọ́n gbà gbọ́ kò dá lórí èrò èèyàn tàbí ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́, orí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí í ṣe Bíbélì ló dá lé.

7 Jésù Kristi fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ nípa jíjẹ́ kí àwọn ohun tó fi kọni dá lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nínú àdúrà tó gbà sí Bàbá rẹ̀ ọ̀run, ó sọ pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòhánù 17:17) Jésù gba Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́, gbogbo ohun tó sì fi kọ́ni ló bá Ìwé Mímọ́ mu. Jésù sábà máa ń sọ pé: “A kọ̀wé rẹ̀ pé.” (Mátíù 4:4, 7, 10) Lẹ́yìn náà, á fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan. Bíi ti Jésù, àwọn èèyàn Ọlọ́run lóde òní kì í fi èrò ara wọn kọ́ni. Wọ́n gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì, wọ́n sì máa ń jẹ́ kí ohun tí wọn fi ń kọ́ni dá lórí ohun tí Bíbélì sọ.

8. Kí ló jẹ́ ara ohun táwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà máa ń ṣe?

 8 Jèhófà nìkan làwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ ń jọ́sìn, wọ́n sì ń kéde orúkọ rẹ̀ fáwọn èèyàn. Jésù sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.” (Mátíù 4:10) Nítorí náà, àwọn èèyàn Ọlọ́run kì í jọ́sìn ẹlòmíràn lẹ́yìn Jèhófà. Jíjẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run tòótọ́ sì wà lára ohun tí wọ́n máa ń ṣe nínú ìjọsìn yìí. Sáàmù 83:18 sọ pé: “Ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, Ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” Jésù fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nípa bá a ṣe lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Ọlọ́run. A mọ̀ bẹ́ẹ̀ látinú àdúrà tó gbà pé: “Mo ti fi orúkọ rẹ hàn kedere fún àwọn ènìyàn tí ìwọ fi fún mi láti inú ayé.” (Jòhánù 17:6) Bákan náà lónìí, àwọn olùjọsìn tòótọ́ ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run, wọ́n ń jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe, àtàwọn ànímọ́ rẹ̀.

9, 10. Àwọn ọ̀nà wo làwọn Kristẹni tòótọ́ gbà ń fi ìfẹ́ hàn síra wọn?

9 Àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ máa ń fi ojúlówó ìfẹ́ hàn sí ara wọn. Jésù sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ wà láàárín àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀. Ìfẹ́ tí Ọlọ́run sọ pé ká ní yìí máa ń borí ẹ̀tanú tó máa ń wà láàárín ẹ̀yà tó yàtọ̀ síra àti orílẹ̀-èdè tó yàtọ̀ síra, ó sì máa ń so àwọn èèyàn pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ojúlówó ẹgbẹ́ ará tó wà níṣọ̀kan. (Ka Kólósè 3:14) Àwọn tó ń ṣe ìsìn èké kò ní irú ẹgbẹ́ ará tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn bẹ́ẹ̀. Kí ló jẹ́ ká mọ̀? Ohun tó jẹ́ ká mọ̀ ni pé wọ́n máa ń pa ara wọn nítorí pé ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti wá. Àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í gbé ohun ìjà láti pa àwọn Kristẹni ará wọn tàbí láti pa àwọn ẹlòmíràn. Bíbélì sọ pé: “Àwọn ọmọ Ọlọ́run àti àwọn ọmọ Èṣù hàn gbangba nípasẹ̀ òtítọ́ yìí: Olúkúlùkù ẹni tí kì í bá a lọ ní ṣíṣe òdodo kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀. . . . A ní láti ní ìfẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì; kì í ṣe bí Kéènì, ẹni  tí ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ẹni burúkú náà, tí ó sì fikú pa arákùnrin rẹ̀.”—1 Jòhánù 3:10-12; 4:20, 21.

10 Dájúdájú, fífi ojúlówó ìfẹ́ hàn kọjá pé àwọn èèyàn kì í para wọn. Àwọn Kristẹni tòótọ́ ń lo àkókò wọn, agbára wọn àti ohun ìní tara láti ran ara wọn lọ́wọ́ kí wọ́n sì fún ara wọn níṣìírí. (Hébérù 10:24, 25) Wọ́n máa ń ran ara wọn lọ́wọ́ lákòókò ìṣòro, inú kan ni wọ́n sì máa ń fi bá ara wọn lò. Ká sòótọ́, wọ́n ń fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé wọn, ìyẹn ìmọ̀ràn tó sọ pé: “Ẹ . . . máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn.”—Gálátíà 6:10.

11. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì ká gbà pé Jésù Kristi ni Ọlọ́run lò láti gbà wá là?

11 Àwọn Kristẹni tòótọ́ gbà pé Jésù Kristi ni Ọlọ́run lò láti gbà wá là. Bíbélì sọ pé: “Kò sí ìgbàlà kankan nínú ẹnikẹ́ni mìíràn, nítorí kò sí orúkọ mìíràn lábẹ́ ọ̀run tí a ti fi fúnni láàárín àwọn ènìyàn nípasẹ̀ èyí tí a ó fi gbà wá là.” (Ìṣe 4:12) Bá a ṣe rí i ní Orí Karùn-ún, Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ láti fi ṣe ìràpadà fún àwọn èèyàn tó bá ṣègbọràn. (Mátíù 20:28) Láfikún, Jésù ni Ọlọ́run yàn ṣe Ọba Ìjọba ọ̀run tí yóò ṣàkóso gbogbo ayé. Ọlọ́run sọ pé a ní láti ṣègbọràn sí Jésù ká sì fi ohun tó kọ́ wa sílò tá a bá fẹ́ ní ìyè àìnípẹ̀kun. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ ní ìyè àìnípẹ̀kun; ẹni tí ó bá ń ṣàìgbọràn sí Ọmọ kì yóò rí ìyè.”—Jòhánù 3:36.

12. Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn má ṣe jẹ́ apá kan ayé?

12 Àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ kì í ṣe apá kan ayé. Nígbà tí Jésù ń rojọ́ níwájú alákòóso kan tó jẹ́ ará Róòmù tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Pílátù, ó sọ pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.” (Jòhánù 18:36) Orílẹ̀-èdè tó wù káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tòótọ́ máa gbé, ọmọ abẹ́ Ìjọba rẹ̀ ọ̀run ni wọ́n jẹ́, ìdí sì nìyẹn tí wọn kì í fi í dá sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú ayé yìí. Wọn kì í dá sí àwọn awuyewuye tó máa ń ṣẹlẹ̀ lágbo àwọn olóṣèlú. Ṣùgbọ́n táwọn ẹlòmíràn bá fẹ́ dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú kan, tí wọ́n bá fẹ́ du ipò  kan, tàbí tí wọ́n bá fẹ́ dìbò, àwọn olùjọsìn Jèhófà kì í dí wọ́n lọ́wọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ kì í dá sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú, wọ́n máa ń pa òfin mọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n “wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga” ìjọba. (Róòmù 13:1) Ṣùgbọ́n, bí ètò ìṣèlú bá béèrè ohun tó jẹ́ ti Ọlọ́run, àwọn olùjọsìn tòótọ́ yóò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn àpọ́sítélì, tí wọ́n sọ pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:29; Máàkù 12:17.

13. Kí làwọn ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn Jésù ka Ìjọba Ọlọ́run sí, kí sì nìyẹn mú kí wọ́n máa ṣe?

 13 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tòótọ́ máa ń wàásù pé Ìjọba Ọlọ́run ni ìrètí kan ṣoṣo fún aráyé. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tòótọ́ kì í fi àwọn èèyàn lọ́kàn balẹ̀ pé àwọn alákòóso èèyàn ló máa yanjú ìṣòro wọn, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọn máa ń wàásù pé Ìjọba Ọlọ́run ni ìrètí kan ṣoṣo fún aráyé. (Sáàmù 146:3) Ìjọba pípé yẹn ni Jésù kọ́ wa pé ká máa gbàdúrà fún nígbà tó sọ pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:10) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé Ìjọba ọ̀run yìí “yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí [tí ń ṣàkóso báyìí] túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Dáníẹ́lì 2:44.

14. Ìsìn wo lo rò pé ó ń ṣe gbogbo ohun tí ìsìn tòótọ́ gbọ́dọ̀ máa ṣe?

14 Pẹ̀lú gbogbo ohun tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí, bi ara rẹ pé: ‘Ìsìn wo ni gbogbo ẹ̀kọ́ rẹ̀ dá lórí Bíbélì tó sì ń sọ orúkọ Jèhófà di mímọ̀ fáwọn èèyàn? Ìsìn wo ló ní ojúlówó ìfẹ́, tó ń lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù, tí kì í ṣe apá kan ayé, tó sì ń kéde pé Ìjọba Ọlọ́run ni ìrètí kan ṣoṣo tó dájú fún ọmọ aráyé? Nínú gbogbo ìsìn tó wà láyé, èwo ló ń ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí?’ Ó hàn gbangba pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni.—Ka Aísáyà 43:10-12.

KÍ NI WÀÁ ṢE?

15. Yàtọ̀ sí kéèyàn gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wà, kí ni Ọlọ́run tún fẹ́ kéèyàn ṣe?

15 Kéèyàn sáà ti gba Ọlọ́run gbọ́ kò tó láti wu Ọlọ́run o. Ó ṣe tán, Bíbélì sọ pé àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá gbà pé Ọlọ́run wà. (Jákọ́bù 2:19) Ó sì dájú pé àwọn ẹ̀mí èṣù wọ̀nyẹn kì í ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, nítorí náà, Ọlọ́run ò tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Tá a bá fẹ́ ní ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run, a ò kàn ní gbà gbọ́ pé Ọlọ́run  wà nìkan, a tún gbọ́dọ̀ ṣe ìfẹ́ rẹ̀. A tún gbọ́dọ̀ kúrò nínú ìsìn èké ká sì dara pọ̀ mọ́ ìsìn tòótọ́.

16. Ǹjẹ́ ó yẹ kéèyàn lọ́wọ́ sí ìsìn èké?

16 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn pé a ò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí ìsìn èké. Ó kọ̀wé pé: “‘Ẹ jáde kúrò láàárín wọn, kí ẹ sì ya ara yín sọ́tọ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘kí ẹ sì jáwọ́ nínú fífọwọ́kan ohun àìmọ́’; ‘dájúdájú, èmi yóò sì gbà yín wọlé.’” (2 Kọ́ríńtì 6:17; Aísáyà 52:11) Nítorí náà, àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í lọ́wọ́ sí ohunkóhun tó bá ti jẹ mọ́ ìsìn èké.

17, 18. Kí ni “Bábílónì Ńlá,” kí sì nìdí tó o fi gbọ́dọ̀ “jáde kúrò nínú rẹ̀” kíákíá?

17 Bíbélì fi hàn pé gbogbo ìsìn èké ló jẹ́ ara “Bábílónì Ńlá.” * (Ìṣípayá 17:5) Orúkọ yẹn mú wa rántí ìlú Bábílónì ayé ọjọ́un, ibi tí ìsìn èké ti bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn Ìkún Omi ọjọ́ Nóà. Bábílónì ni ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ tí ìsìn èké fi ń kọ́ni àtàwọn ohun tí wọ́n ń ṣe ti bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ará Bábílónì máa ń jọ́sìn àwọn ọlọ́run mẹ́ta nínú ẹyọ kan. Lóde òní, Mẹ́talọ́kan ni olórí ẹ̀kọ́ tí ọ̀pọ̀ ìsìn fi ń kọ́ni. Ṣùgbọ́n ohun tí Bíbélì fi kọ́ni ni pé Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà, ìyẹn Jèhófà, àti pé Ọmọ rẹ̀ ni Jésù Kristi. (Jòhánù 17:3) Àwọn ará Bábílónì tún gbà gbọ́ pé ẹ̀mí èèyàn kì í kú, pé ńṣe ló máa jáde kúrò nínú ara lẹ́yìn téèyàn bá kú. Wọ́n tún gbà pé ẹ̀mí yìí lè jìyà níbi ìdálóró. Lóde òní, ohun tí ọ̀pọ̀ ìsìn fi ń kọ́ni ni pé èèyàn ní ẹ̀mí tí kò lè kú tó sì lè joró ní ọ̀run àpáàdì.

18 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìjọsìn Bábílónì ayé ọjọ́un tàn dé gbogbo ayé, ó tọ́ tá a bá sọ pé Bábílónì Ńlá tòde òní ni ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé. Ọlọ́run sì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé òjijì ni ilẹ̀ ọba ìsìn èké yìí máa pa run. Ṣé o ti wá rí ìdí tí kò fi yẹ kó o lọ́wọ́ sí ohunkóhun tó bá ti jẹ mọ́ Bábílónì Ńlá? Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ kó o “jáde kúrò nínú rẹ̀” kíákíá kó tó pẹ́ jù.—Ka Ìṣípayá 18:48..

Tó o bá dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn Jèhófà láti sin Jèhófà, ìbùkún tí wàá rí á pọ̀ fíìfíì ju ohun tó ṣeé ṣe kó o pàdánù lọ

19. Ìbùkún wo ló máa jẹ́ tìẹ tó o bá sin Jèhófà?

 19 Àwọn kan lè sọ pé àwọn ò ní bá ọ kẹ́gbẹ́ mọ́ nítorí pé o pinnu pé o kò ní ṣe ìsìn èké mọ́. Ṣùgbọ́n tó o bá dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn Jèhófà láti sin Jèhófà, ìbùkún tí wàá rí á pọ̀ gan-an ju ohun tó ṣeé ṣe kó o pàdánù lọ. Bíi tàwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ tí wọ́n fi gbogbo ohun tí wọ́n ní sílẹ̀ kí wọ́n lè tẹ̀ lé Jésù, ìwọ náà yóò ní àìmọye àwọn arákùnrin àti arábìnrin nípa tẹ̀mí. Wàá di ara ẹgbẹ́ ará kan tó kárí ayé, àwọn tó máa fi ojúlówó ìfẹ́ hàn sí ọ. Ẹgbẹ́ ará yìí tóbi gan-an, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn Kristẹni tòótọ́ ló sì wà nínú rẹ̀. Wàá sì ní ìrètí àgbàyanu láti wà láàyè títí láé “nínú ètò àwọn nǹkan tí ń bọ̀.” (Ka Máàkù 10:28-30) Ta ló sì mọ̀, bóyá tó bá yá, àwọn tó pa ọ́ tì nítorí àwọn ohun tó o gbà gbọ́ yóò fẹ́ láti mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni kí wọ́n sì di olùjọsìn Jèhófà.

20. Kí ló ń dúró de àwọn tó bá ṣe ìsìn tòótọ́ ní ọjọ́ iwájú?

20 Bíbélì fi kọ́ni pé láìpẹ́, Ọlọ́run yóò fòpin sí ètò rúdurùdu Sátánì tó wà lórí ilẹ̀ ayé báyìí yóò sì fi ayé tuntun òdodo tí Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣàkóso lé lórí rọ́pò rẹ̀. (2 Pétérù 3:9, 13) Ayé yẹn á mà dùn o! Kó o sì wá wò ó, ìsìn kan ṣoṣo péré ni yóò wà nínú ayé tuntun òdodo yẹn, ìsìn tòótọ́ ni ìsìn kan ṣoṣo ọ̀hún yóò sì jẹ́. Nítorí náà, ǹjẹ́ kì í ṣe ìwà ọgbọ́n ni, pé kó o ṣe àwọn ohun tó pọn dandan kó o lè dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ ní báyìí?

^ ìpínrọ̀ 17 Kó o lè mọ̀ sí i nípa ìdí tí Bábílónì Ńlá fi dúró fún ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, wo Àfikún, “Bá A Ṣe Dá “Bábílónì Ńlá” Mọ̀.