• Ǹjẹ́ àwọn áńgẹ́lì máa ń ran èèyàn lọ́wọ́?

  • Báwo làwọn ẹ̀dá ẹ̀mí búburú ṣe ń mú káwọn èèyàn máa ṣe ohun tí kò dára?

  • Ǹjẹ́ ó yẹ ká máa bẹ̀rù àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí búburú?

1. Kí nìdí tó fi yẹ ká fẹ́ láti mọ̀ nípa àwọn áńgẹ́lì?

TÁ A bá fẹ́ dojúlùmọ̀ ẹnì kan dáadáa, ara ohun tá a máa ṣe ni pé ká mọ̀ nípa ìdílé rẹ̀. Bákan náà, tá a bá fẹ́ mọ Jèhófà Ọlọ́run dáadáa, a ní láti mọ̀ nípa àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ ara ìdílé Jèhófà tó wà lókè ọ̀run. Bíbélì pe àwọn áńgélì ní “àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Jóòbù 38:7) Nítorí náà, ipò wo ni wọ́n dì mú nínú ètò Ọlọ́run? Ǹjẹ́ wọ́n ti ṣe nǹkan kan rí tó kan aráyé? Ǹjẹ́ ohun táwọn áńgẹ́lì ń ṣe kàn ọ́? Tó bá kàn ọ́, ọ̀nà wo ló gbà kàn ọ́?

2. Ibo làwọn áńgẹ́lì ti wá, mélòó sì ni wọ́n?

2 Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìgbà ni Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn áńgẹ́lì. Jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ibi tí Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn áńgẹ́lì ká lè mọ̀ sí i nípa wọn. Ibo làwọn áńgẹ́lì ti wá? Kólósè 1:16 sọ pé: “Nípasẹ̀ rẹ̀ [ìyẹn Jésù Kristi] ni a dá gbogbo ohun mìíràn ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.” Nípa bẹ́ẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run ló tipasẹ̀ àkọ́bí Ọmọ rẹ̀ dá ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tá à ń pè ní áńgẹ́lì. Àwọn áńgẹ́lì mélòó ló wà? Bíbélì fi hàn pé ọ̀kẹ́ àìmọye áńgẹ́lì ni Ọlọ́run dá, gbogbo wọn ló sì lágbára.—Sáàmù 103:20. *

3. Kí ni Jóòbù 38:4-7 sọ fún wa nípa àwọn áńgẹ́lì?

 3 Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún wa pé nígbà tí Ọlọ́run fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀, “gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí hó yèè nínú ìyìn.” (Jóòbù 38:4-7) Ìyẹn fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì ti wà tipẹ́tipẹ́ kí Ọlọ́run tó dá èèyàn, kódà wọ́n ti wà kí Ọlọ́run tó dá ilẹ̀ ayé. Ẹsẹ Bíbélì yẹn tún fi hàn pé ohun tó bá ṣẹlẹ̀ máa ń kan àwọn áńgẹ́lì, nítorí ó sọ pé “wọ́n jùmọ̀ ń fi ìdùnnú ké jáde.” Kíyè sí i pé nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, ńṣe ni “gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run” jùmọ̀ yọ̀. Nígbà yẹn, gbogbo àwọn áńgẹ́lì ló jẹ́ ara ìdílé Ọlọrun tó wà níṣọ̀kan tó sì ń sin Ọlọ́run.

ÀWỌN ÁŃGẸ́LÌ Ń RANNI LỌ́WỌ́ WỌ́N SÌ Ń DÁÀBÒ BONI

4. Báwo ni Bíbélì ṣe fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ ọmọ aráyé?

4 Látìgbà táwọn ẹ̀dá ẹ̀mí rere ti rí tí Ọlọ́run dá èèyàn ni wọ́n ti nífẹ̀ẹ́ pé kọ́mọ aráyé pọ̀ sí i kí ètò tí Ọlọ́run ṣe sì yọrí sí ibi tí Ọlọ́run fẹ́ kó yọrí sí. (Òwe 8:30, 31; 1 Pétérù 1:11, 12) Àmọ́, bọ́dún ṣe ń gorí ọdún làwọn áńgẹ́lì ń rí i pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn ni kì í sin Ẹlẹ́dàá wọn mọ́. Kò sí àní-àní pé èyí á máa ba àwọn áńgẹ́lì rere nínú jẹ́. Ṣùgbọ́n nígbàkigbà táwọn èèyàn bá padà sọ́dọ̀ Jèhófà, kódà bó ṣe ẹnì kan péré, ńṣe ni “ìdùnnú máa ń sọ láàárín àwọn áńgẹ́lì.” (Lúùkù 15:10) Níwọ̀n bí ire àwọn tó ń sin Ọlọ́run ti jẹ àwọn áńgẹ́lì lógún tó báyìí, a mọ̀ pé Jèhófà á ti lo àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láìmọye ìgbà láti fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lágbára, ìyẹn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé tó ń ṣègbọràn sí i. (Ka Hébérù 1:7, 14) Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

“Ọlọ́run mi rán áńgẹ́lì rẹ̀, ó sì dí ẹnu àwọn kìnnìún náà.”​—Dáníẹ́lì 6:22

5. Àwọn àpẹẹrẹ wo ló wà nínú Bíbélì nípa báwọn áńgẹ́lì ṣe ń ran èèyàn lọ́wọ́?

5 Nígbà tí ìlú Sódómù àti Gòmórà pa run nítorí ìwà búburú tí wọ́n ń hù níbẹ̀, áńgẹ́lì méjì ló ran Lọ́ọ̀tì, tí í ṣe olódodo, àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ lọ́wọ́, tí wọ́n fi lè la ìparun náà já. Ńṣe làwọn áńgẹ́lì náà fà wọ́n lọ́wọ́ tí wọ́n sì mú wọn kúrò nínú ìlú yẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 19:15, 16) Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà,  àwọn olubi ju wòlíì Dáníẹ́lì sínú ihò kìnnìún, ṣùgbọ́n àwọn kìnnìún ò ṣe é ní nǹkan kan. Dáníẹ́lì sọ pé: “Ọlọ́run mi rán áńgẹ́lì rẹ̀, ó sì dí ẹnu àwọn kìnnìún náà.” (Dáníẹ́lì 6:22) Ní ọ̀rúndún kìíní, áńgẹ́lì kan dá àpọ́sítélì Pétérù sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. (Ìṣe 12:6-11) Kò mọ síbẹ̀ o, àwọn áńgẹ́lì ran Jésù lọ́wọ́ nígbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. (Máàkù 1:13) Lẹ́yìn náà, nígbà tó kù díẹ̀ tí wọ́n máa pa Jésù, áńgẹ́lì kan lọ bá a “ó sì fún un lókun.” (Lúùkù 22:43) Ó dájú pé ìrànlọ́wọ́ táwọn áńgẹ́lì ṣe fún Jésù yìí fún un lágbára gan-an láwọn àkókò tó ṣe pàtàkì yẹn nínu ìgbésí ayé rẹ̀!

6. (a) Báwo làwọn ańgẹ́lì ṣe ń dáàbò bo àwọn èèyàn Ọlọ́run lónìí? (b) Àwọn ìbéèrè wo la fẹ́ gbé yẹ̀ wò báyìí?

6 Lóde òní, àwọn áńgẹ́lì kì í wá sórí ilẹ̀ ayé láwọ̀ èèyàn mọ́ láti fara han àwọn èèyàn Ọlọ́run. Alágbára ni àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè rí wọn, wọ́n ṣì máa ń dáàbo bo àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ní pàtàkì, wọ́n máa ń dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ ohunkóhun tó lè wu wọ́n léwu nípa tẹ̀mí. Bíbélì sọ pé: “Áńgẹ́lì Jèhófà dó yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká, ó sì ń gbà wọ́n sílẹ̀.” (Sáàmù 34:7) Kí nìdí tó fi yẹ kí ọ̀rọ̀ yẹn fi wá lọ́kàn balẹ̀ gan-an? Ìdí ni pé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí búburú wà tí wọ́n fẹ́ ba tiwa jẹ́! Ta ni wọ́n? Ibò ni wọ́n ti wá? Báwo sì ni wọ́n ṣe ń gbìyànjú láti ṣe wá níbi? Ká lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí, jẹ́ ká gbé ohun kan tó ṣẹlẹ̀ nígbà ìwáṣẹ̀ ẹ̀dá èèyàn yẹ̀ wò.

ÀWỌN Ẹ̀DÁ Ẹ̀MÍ TÓ JẸ́ Ọ̀TÁ WA

7. Báwo ni Sátánì ṣe ṣàṣeyọrí tó nínú bo ṣe gbìyànjú láti mú káwọn èèyàn kẹ̀yìn sí Ọlọ́run?

7 A kẹ́kọ̀ọ́ ní Orí Kẹta ìwé yìí pé, ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì fẹ́ láti jọba lórí àwọn ẹlòmíràn. Díẹ̀ díẹ̀, ìfẹ́ yẹn jọba lọ́kàn rẹ̀, ìyẹn sì mú kó kẹ̀yìn sí Ọlọ́run. Nígbà tó yá, a wá mọ áńgẹ́lì yìí sí Sátánì Èṣù. (Ìṣípayá 12:9) Látìgbà tí Sátánì ti tan Éfà jẹ títí di nǹkan bí ọ̀rúndún mẹ́rìndínlógún lẹ́yìn náà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ lè jẹ́ pé gbogbo ẹ̀dá èèyàn ni Sátánì mú kó kẹ̀yìn sí Ọlọ́run, àyàfi àwọn díẹ̀ bí Ébẹ́lì, Énọ́kù, àti Nóà.—Hébérù 11:4, 5, 7.

8. (a) Báwo làwọn áńgẹ́lì kan ṣe di ẹ̀mí èṣù? (b) Kí ló di dandan káwọn ẹ̀mí èṣù ṣe kí wọ́n tó lè la Ìkún Omi ọjọ́ Nóà já?

8 Nígbà ayé Nóà, àwọn áńgẹ́lì mìíràn ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. Wọ́n fi ibi tí Ọlọ́run fi wọ́n sí nínú ìdílé rẹ̀ tó wà lọ́run sílẹ̀, wọ́n wá sórí ilẹ̀ ayé wọ́n sì para dà di èèyàn. Nítorí kí ni? A kà ní Jẹ́nẹ́sísì 6:2 pé: “Àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́ bẹ̀rẹ̀ sí kíyè sí àwọn ọmọbìnrin ènìyàn, pé wọ́n dára ní ìrísí; wọ́n sì ń mú aya fún ara wọn, èyíinì ni, gbogbo ẹni tí wọ́n bá yàn.” Ṣùgbọ́n Jèhófà ò jẹ́ kí ìwàkiwà àwọn áńgẹ́lì náà àti ìwà ìbàjẹ́ tíyẹn mú káwọn èèyàn máa hù máa bá a lọ bẹ́ẹ̀. Ó fi ìkún omi tó kárí ayé pa gbogbo èèyàn búburú ìgbà yẹn  run, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ṣègbọràn sí i nìkan ló dá sí. (Jẹ́nẹ́sísì 7:17, 23) Ló bá di dandan káwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ tí wọ́n di ẹ̀mí ẹ̀sù yìí bọ́ ara èèyàn sílẹ̀, kí wọ́n sì padà sí ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí. Wọ́n sọ ara wọn di ọmọlẹ́yìn Èṣù. Èṣù sì tipa bẹ́ẹ̀ di “olùṣàkóso àwọn ẹ̀mí èṣù.”—Mátíù 9:34.

9. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn ẹ̀mí èṣù nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀run? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nípa àwọn ẹ̀mí èṣù?

9 Nígbà táwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ yìí padà dé ọ̀run, ṣe ni Ọlọ́run kọ̀ wọ́n lọ́mọ bíi ti Sátánì tó jẹ́ olórí wọn. (2 Pétérù 2:4) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò lè para dà di èèyàn mọ́, wọ́n ṣì ń mú káwọn èèyàn máa ṣe ohun tí kò dára. Kódà, àwọn ẹ̀mí èṣù wọ̀nyí ni Sátánì ń lò láti fi “ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (Ìṣípayá 12:9; 1 Jòhánù 5:19) Báwo làwọn ẹ̀mí èṣù ṣe ń ṣini lọ́nà? Àwọn ohun kan ni wọ́n ń lò láti fi ṣini lọ́nà. (Ka 2 Kọ́ríńtì 2:11) Jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ohun tí wọ́n ń lò náà.

BÁWỌN Ẹ̀MÍ ÈṢÙ ṢE MÁA Ń ṢINI LỌ́NÀ

10. Kí ni ìbẹ́mìílò?

10 Àwọn ẹ̀mí èṣù máa ń lo ìbẹ́mìílò láti fi ṣi àwọn èèyàn lọ́nà. Ìbẹ́mìílò ni kéèyàn máa ní àjọṣe pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí èṣù fúnra èèyàn tàbí nípasẹ̀ ẹni tó ń bẹ́mìílò. Bíbélì sọ pé ìbẹ́mìílò kò dára ó sì kìlọ̀ pé ká yàgò fún gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìbẹ́mìílò. (Gálátíà 5:19-21) Ńṣe làwọn ẹ̀mí èṣù ń lo ìbẹ́mìílò bí ìdẹ táwọn tó ń pẹja máa ń lò. Apẹja máa ń lo oríṣiríṣi ìdẹ fún oríṣiríṣi ẹja. Bẹ́ẹ̀ náà làwọn ẹ̀dá ẹ̀mí búburú ṣe máa ń lo onírúurú ìbẹ́mìílò láti fi mú káwọn èèyàn kó sọ́wọ́ wọn.

11. Kí ni iṣẹ́ wíwò, kí sì nìdí tí kò fi yẹ ká lọ́wọ́ nínú rẹ̀?

11 Ìdẹ kan táwọn ẹ̀mí èṣù máa ń lò ni iṣẹ́ wíwò. Kí ni iṣẹ́ wíwò? Iṣẹ́ wíwò ni kéèyàn máa wádìí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la tàbí ohun kan tẹ́dàá ò mọ̀. Díẹ̀ lára oríṣiríṣi iṣẹ́ wíwò tó wà ni wíwo ìràwọ̀, lílo káàdì tí wọ́n fi ń sọ àsọtẹ́lẹ̀, wíwo dígí sọ tẹ́lẹ̀, wíwo àtẹ́lẹwọ́ sọ tẹ́lẹ̀, àti wíwá ìtumọ̀ àlá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí kò léwu ni ọ̀pọ̀ èèyàn ka iṣẹ́ wíwò sí, Bíbélì fi  hàn pé àwọn woṣẹ́woṣẹ́ ń bá àwọn ẹ̀mí èṣù lò. Bí àpẹẹrẹ, Ìṣe 16:16-18 sọ nípa “ẹ̀mí èṣù ìwoṣẹ́” kan tó ń fún ọmọbìnrin kan lágbára kó lè ‘máa sọ àsọtẹ́lẹ̀.’ Àmọ́ kò lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ mọ́ nígbà tí wọ́n lé ẹ̀mí èṣù náà jáde kúrò lára rẹ̀.

Oríṣiríṣi ọ̀nà làwọn ẹ̀mí èṣù ń gbà tan àwọn èèyàn jẹ

12. Kí nìdí tó fi léwu téèyàn bá ń gbígbìyànjú láti bá òkú sọ̀rọ̀?

12 Ọ̀nà mìíràn táwọn ẹ̀mí èṣù gbà ń ṣi awọn èèyàn lọ́nà ni nípa jíjẹ́ káwọn èèyàn ní ìgbàgbọ́ pé wọ́n lè bá òkú sọ̀rọ̀. Ìgbàgbọ́ èké nípa àwọn tó ti kú ni wọ́n máa ń fi tan àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ jẹ. Abẹ́mìílò kan lè sọ ohun àṣírí kan nípa ẹni tó kú náà fún àwọn èèyàn, ó sì lè ṣe ohùn rẹ̀ bí ẹni pé ẹni tó kú yẹn gan-an ló ń sọ̀rọ̀. Èyí ló ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa rò pé àwọn tó kú ṣì wà láàyè àti pé àwọn lè rí ìrànlọ́wọ́ àti ìtùnú gbà táwọn bá bá wọn sọ̀rọ̀. Àmọ́ ìtùnú èké ni irú “ìtùnú” bẹ́ẹ̀, ó sì léwu. Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn ẹ̀mí ẹ̀sù lè ṣe ohùn bíi ti ẹni tó ti kú, wọ́n sì lè jẹ́ kí abẹ́mìílò mọ àṣírí kan nípa ẹni tó kú náà. (1 Sámúẹ́lì 28:3-19) Tún rántí pé a kẹ́kọ̀ọ́ ní Orí Kẹfà pé àwọn tó ti kú ti daláìsí, pé wọn ò sí níbì kankan mọ́. (Sáàmù 115:17) Nítorí náà, bí “ẹnikẹ́ni [bá] ń ṣèwádìí  lọ́dọ̀ òkú,” àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí búburú ti ṣi onítọ̀hún lọ́nà nìyẹn o, ohun tí Ọlọ́run kórìíra lonítọ̀hún sì ń ṣe. (Ka Diutarónómì 18:10, 11; Aísáyà 8:19) Nítorí náà, ṣọ́ ara rẹ kí àwọn ẹ̀mí èṣù má bàa fi ìdẹ búburú yìí fà ọ́ mọ́ra.

13. Kí ni àìmọye àwọn tó máa ń bẹ̀rù àwọn ẹ̀mí èṣù tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ ti ṣe?

13 Yàtọ̀ sí pé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí búburú máa ń ṣini lọ́nà, wọ́n tún máa ń dẹ́rù bani. Lónìí, Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ gboró ju ti tẹ́lẹ̀ lọ nítorí wọ́n mọ̀ pé ‘àkókò kúkúrú’ ló kù tí Ọlọ́run yóò ká àwọn lọ́wọ́ kò tí àwọn ò fi ní lè ṣe nǹkan kan mọ́. (Ìṣípayá 12:12, 17) Bí wọ́n sì ṣe gboró tó yẹn náà, àìmọye àwọn tó jẹ́ pé ojoojúmọ́ ni wọ́n ń bẹ̀rù wọn nígbà kan, ni wọn ò bẹ̀rù wọn mọ́ nísinsìnyí. Báwo ni wọ́n ṣe ṣe é tí wọn ò fi bẹ̀rù wọn mọ́? Kí sì lẹnì kan tó ti ń bẹ́mìí lò lè ṣe?

BÓ O ṢE LÈ GBÉJÀ KO ÀWỌN Ẹ̀DÁ Ẹ̀MÍ BÚBURÚ

14. Bíi tàwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù ní ọ̀rúndún kìíní, báwo la ṣe lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí búburú?

14 Bíbélì sọ bá a ṣe lè gbéjà ko àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí búburú àti bá a ṣe lè bọ́ lọ́wọ́ wọn. Gbé àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ní ìlú Éfésù yẹ̀ wò. Àwọn kan lára wọn lọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò kí wọ́n tó di Kristẹni. Nígbà tí wọ́n sì wá pinnu pé àwọn fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ìbẹ́mìílò, kí ni wọ́n ṣe? Bíbélì sọ pé: “Ọ̀pọ̀ lára àwọn tí wọ́n fi idán pípa ṣiṣẹ́ ṣe, kó àwọn ìwé wọn pa pọ̀, wọ́n sì dáná sun wọ́n níwájú gbogbo ènìyàn.” (Ìṣe 19:19) Bí àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni yẹn ṣe sun àwọn ìwé tí wọ́n fi ń pidán, ńṣe ni wọ́n fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fáwọn tó bá fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí búburú lónìí. Àwọn tó bá fẹ́ sin Jèhófà gbọ́dọ̀ kó gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìbémìílò dà nù, ì báà jẹ́ ìwé, fídíò, àwòrán ara ògiri tàbí orin tó bá ń fún àwọn èèyàn níṣìírí pé kí wọ́n lọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò tó sì ń mú kí ìbẹ́mìílò dà bí ohun tó ń gbádùn mọ́ni. Àwọn ohun mìíràn táwọn tó bá fẹ́ sin Jèhófà gbọ́dọ̀ kó dà nù ni ìfúnpá, ońdè, òòka ẹ̀rẹ, owó ẹyọ, tírà tàbí àwọn ohun mìíràn tí wọ́n ń wọ̀ sára láti fi dáàbò bo ara wọn.—1 Kọ́ríńtì 10:21.

15. Láti lè gbógun ti àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí búburú, kí la ní láti ṣe?

 15 Lẹ́yìn ọdún mélòó kan táwọn Kristẹni ní Éfésù ti dáná sun àwọn ìwé oògùn wọn, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí wọ́n pé: “Àwa ní gídígbò kan . . . lòdì sí àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú.” (Éfésù 6:12) Àwọn ẹ̀mí èṣù ò tíì dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn ará Éfésù. Wọ́n ṣì ń wá ọ̀nà tí wọ́n á fi máa jọ̀gá lé wọn lórí padà. Nítorí náà, kí ló tún kù táwọn Kristẹni wọ̀nyẹn ní láti ṣe? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Lékè ohun gbogbo, ẹ gbé apata ńlá ti ìgbàgbọ́, èyí tí ẹ ó lè fi paná gbogbo ohun ọṣẹ́ oníná ti ẹni burúkú náà [ìyẹn Sátánì].” (Éfésù 6:16) Bí apata ìgbàgbọ́ wa bá ṣe lágbára tó, bẹ́ẹ̀ la ó ṣe ní agbára tó láti gbógun ti agbo ọmọ ogun ẹ̀mí búburú.—Mátíù 17:20.

16. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára?

16 Báwo la wá ṣe lè jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára? A lè jẹ́ kó lágbára nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí ògiri kan bá máa dúró dáadáa, ìpìlẹ̀ rẹ̀ gbọ́dọ̀ lágbára. Bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbàgbọ́ wa ṣe rí. Kí ìgbàgbọ́ wa tó lè lágbára, ìpìlẹ̀ rẹ̀, tí í ṣe ìmọ̀ pípéye Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, gbọ́dọ̀ lágbára. Nítorí náà, tá a bá ń ka Bíbélì lójoojúmọ́ tá a sì ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, ìgbàgbọ́ wa yóò lágbára. Ìgbàgbọ́ tó lágbára bí ògiri tó dúró sán-ún kò ní jẹ́ káwọn ẹ̀dá ẹ̀mí búburú lè sún wa ṣe ohun tí kò dára.—1 Jòhánù 5:5.

17. Ká tó lè gbéjà ko àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí búburú, kí ló pọn dandan pé ká ṣe?

17 Kí tún lohun mìíràn táwọn Kristẹni ará Éfésù ní láti ṣe? Wọ́n túbọ̀ nílò ààbò nítorí pé ìbẹ́mìílò ti pọ̀ jù nínú ìlú tí wọ́n ń gbé. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi sọ fún wọn pé: “Pẹ̀lú gbogbo oríṣi àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀, kí ẹ máa bá a lọ ní gbígbàdúrà ní gbogbo ìgbà nínú ẹ̀mí.” (Éfésù 6:18) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé inú ayé tó kún fún ìbẹ́mìílò làwa náà ń gbé, ó pọn dandan ká máa gbàdúrà tọkàntọkàn sí Jèhófà pé kó dáàbò bò wá bá a ti ń gbéjà ko àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí búburú. A tún ní láti máa dárúkọ Jèhófà nínú àdúrà wa. (Ka Òwe 18:10) Nítorí náà, kò yẹ ká dáwọ́ àdúrà tá à ń gbà sí Ọlọ́run dúró pé kó “dá wa  nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà,” ìyẹn Sátánì Èṣù. (Mátíù 6:13) Jèhófà ò sì ní ṣàìdáhùn irú àdúrà tá a bá gbà tọkàntọkàn bẹ́ẹ̀.—Sáàmù 145:19.

18, 19. (a) Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé a lè borí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí búburú? (b) Ìbéèrè wo lá óò dáhùn nínú orí tó kàn?

18 Lóòótọ́ o, ìkà làwọn ẹ̀dá ẹ̀mí búburú, ṣùgbọ́n tá a bá kọjúùjà sí Èṣù tá a sì sún mọ́ Ọlọ́run nítorí pé à ń ṣe ohun tó fẹ́, a ò ní máa bẹ̀rù wọn. (Ka Jákọ́bù 4:7, 8) Ó níbi tágbára àwọn ẹ̀mí èṣù mọ. Ọlọ́run fìyà jẹ wọ́n nígbà ayé Nóà, Ọlọ́run yóò sì tún fìyà tó máa kẹ́yìn jẹ wọ́n lọ́jọ́ iwájú. (Júúdà 6) Tún rántí o, pé àwọn áńgẹ́lì Jèhófà alágbára náà ń dáàbò bò wá. (2 Àwọn Ọba 6:15-17) Ohun táwọn áńgẹ́lì olódodo yẹn ń fẹ́ gan-an ni pé ká borí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí búburú, wọ́n sì ń fún wa níṣìírí bá a ti ń sapá láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká sún mọ́ Jèhófà àtàwọn ẹ̀dá ẹ̀mí olóòótọ́ tí wọ́n jẹ́ ara ìdílé rẹ̀. Ká tún máa yàgò fún onírúurú ìbẹ́mìílò ká sì fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò. (1 Pétérù 5:6, 7; 2 Pétérù 2:9) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé a óò borí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí búburú.

19 Àmọ́, kí ló dé tí Ọlọ́run fi fàyè gba àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí búburú àti ìwà ibi tó ti fa ìjìyà tó pọ̀ gan-an fáwọn èèyàn? A óò dáhùn ìbéèrè yìí nínú orí tó kàn.

^ ìpínrọ̀ 2 Ìṣípayá 5:11 sọ nípa àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ olóòótọ́ pé: “Iye wọn sì jẹ́ ẹgbẹẹgbàárùn-ún lọ́nà ẹgbẹẹgbàárùn-ún.” Nípa bẹ́ẹ̀, Bíbélì fi hàn pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún mílíọ̀nù áńgẹ́lì ni Ọlọ́run dá.