Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?

A ṣe ìwé tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ Bíbélì yìí kí o lè mọ onírúurú ẹ̀kọ́ Bíbélì, bí ìdí tí a fi ń jìyà, ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ téèyàn bá kú, bí ìdílé wa ṣe lè jẹ́ aláyọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ṣé Ohun Tí Ọlọ́run Fẹ́ Kó Máa Ṣẹlẹ̀ Nìyí?

O lè máa wò ó pé kí ni ìdí tí ìṣòro fi pọ̀ tó báyìí ní òde òní. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Bíbélì sọ pé àwọn ohun rere máa tó ṣẹlẹ̀ àti pé ìwọ náà lè jàǹfààní láti inú rẹ̀?

ORÍ 1

Kí Ni Òtítọ́ Nípa Irú Ẹni Tí Ọlọ́run Jẹ́?

Ǹjẹ́ o rò pé Ọlọ́run bìkítà nípa rẹ? Kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ànímọ́ rẹ̀ àti bí o ṣe lè sún mọ́ ọn.

ORÍ 2

Bíbélì—Ìwé Kan Tó Wá Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run

Báwo ni Bíbélì ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè kojú àwọn ìṣòro rẹ? Kí nìdí tó o fi lè gbẹ́kẹ̀ lé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú rẹ̀?

ORÍ 3

Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn Tó Fi Dá Ilẹ̀ Ayé?

Ṣé ayé yìí ṣì máa di Párádísè bí Ọlọ́run ṣe sọ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìgbà wo?

ORÍ 4

Ta Ni Jésù Kristi?

Kọ́ nípa ìdí tó fi jẹ́ pé Jésù ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí, ibi tó ti wá àti ìdí tó fi jẹ́ pé òun ni Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Jèhófà.

ORÍ 5

Ìràpadà—Ẹ̀bùn Tó Ṣeyebíye Jù Lọ Tí Ọlọ́run Fúnni

Kí ni ìràpadà? Àǹfààní wo ló lè ṣe fún ọ́?

ORÍ 6

Ibo Làwọn Òkú Wà?

Kọ́ nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa ibi tí àwọn òkú wà àti ìdí tá a fi ń kú.

ORÍ 7

Ojúlówó Ìrètí Fáwọn Èèyàn Rẹ Tó Ti Kú

Ǹjẹ́ o ní èèyàn kan tó ti kú rí? Ǹjẹ́ o rò pé o ṣì lè rí ẹni náà pa dà? Kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Bíbélì kọ́ni nípa àjíǹde.

ORÍ 8

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ Àdúrà Olúwa. Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà: “Kí ìjọba rẹ dé”?

ORÍ 9

Ṣé “Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn” La Wà Yìí”?

Wo bí ìwà àti ìṣe àwọn èèyàn tó wà láyìíká wa ṣe fi hàn pé a ti wà ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀.

ORÍ 10

Àwọn Ẹ̀dá Ẹ̀mí—Ohun Tí Wọ́n Ń Ṣe fún Wa

Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn áńgẹ́lì àti àwọn ẹ̀mí èṣù. Ṣé lóòótọ́ ni wọ́n wà? Ṣé wọ́n lè ràn ọ́ lọ́wọ́ tàbí kí wọ́n pa ọ́ lára?

ORÍ 11

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló rò pé Ọlọ́run ló fa ìyà tó ń jẹ́ àwa èèyàn. Kí lèrò rẹ? Kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Ọlọ́run sọ pé ó fa ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn.

ORÍ 12

Gbé Ìgbé Ayé Tó Múnú Ọlọ́run Dùn

O lè gbé ìgbé ayé tó múnú Jèhófà dùn. Kódà, o lè di ọ̀rẹ́ rẹ̀.

ORÍ 13

Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Ẹ̀mí Ni Kí Ìwọ Náà Máa Fi Wò Ó

Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo ìṣẹ́yún, gbígba ẹ̀jẹ̀ sára àti ẹ̀mí ẹranko?

ORÍ 14

Ohun Tó O Lè Ṣe Kí Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀

Àwọn ọkọ, àwọn aya, àwọn òbí àti àwọn ọmọ lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ bí Jésù ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Ẹ̀kọ́ wo ni àpẹẹrẹ Jésù kọ́ wa?

ORÍ 15

Ìjọsìn Tó Ní Ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run

Wo ohun mẹ́fà téèyàn lè fi dá àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ mọ̀.

ORÍ 16

Fi Hàn Pé Ìsìn Tòótọ́ Lo Fẹ́ Ṣe

Àwọn ìṣòro wo lo lè ní tí o bá ń sọ àwọn ohun tó o gbà gbọ́ fún àwọn èèyàn? Báwo lo ṣe lè ṣe é láì múnú bí wọn?

ORÍ 17

Sún Mọ́ Ọlọ́run Nípasẹ̀ Àdúrà

Ṣé Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà rẹ? Kó o lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, ó yẹ kó o mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa àdúrà.

ORÍ 18

Ìrìbọmi Ló Máa Fìdí Àjọṣe Rẹ Pẹ̀lú Ọlọ́run Múlẹ̀

Àwọn ohun wo lo gbọ́dọ̀ ṣe kó o tó lè kúnjú ìwọ̀n láti ṣèrìbọmi? Kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí ìrìbọmi túmọ̀ sí àti bó ṣe yẹ ká ṣe é.

ORÍ 19

Má Ṣe Kúrò Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run

Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti pé a mọrírì ohun tó ṣe fún wa?

ÀFIKÚN

Ìtumọ̀ Orúkọ Ọlọ́run àti Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Lò Ó

Wọ́n ti yọ orúkọ Ọlọ́run kúrò nínú ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì. Kí nìdí? Ǹjẹ́ ó ṣe pàtàkì pé ká máa lo orúkọ Ọlọ́run?

ÀFIKÚN

Bí Dáníẹ́lì Ṣe Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Ìgbà Tí Mèsáyà Yóò Dé

Ní ohun tó ju ọgọ́rùn-ún márùn-ún ọdún ṣáájú, Ọlọ́run fi ìgbà tí Mèsáyà máa dé gẹ́lẹ́ hàn. Kẹ́kọ̀ọ́ nípa àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì yìí!

ÀFIKÚN

Jésù Kristi Ni Mèsáyà Tí Ọlọ́run Ṣèlérí

Gbogbo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa Mèsáyà pátá ló ṣẹ sí Jésù lára. Ka àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí nínú Bíbélì rẹ kí o lè rí i pé gbogbo ohun tí Bíbélì sọ pátá ló ṣẹ.

ÀFIKÚN

Òtítọ́ Nípa Baba, Ọmọ, àti Ẹ̀mí Mímọ́

Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ẹ̀kọ́ Métalọ́kan wà nínú Bíbélì. Ṣé òótọ́ ni?

ÀFIKÚN

Ìdí Táwọn Kristẹni Tòótọ́ Kì Í Fi Í Lo Àgbélébùú Nínú Ìjọsìn

Ṣé orí àgbélébùú ni Jésù Kristi kú sí lóòótọ́? Ka ohun tí Bíbélì sọ.

ÀFIKÚN

Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa—Ìrántí Ikú Kristi Tá A Ń Ṣe Láti Bọlá fún Ọlọ́run

Jésù pàsẹ fún àwọn Kristẹni pé kí wọ́n máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Ìgbà wo ló yẹ ká máa ṣe é, báwo ló sì ṣe yẹ ká máa ṣe é?

ÀFIKÚN

Kí Ni “Ọkàn” àti “Ẹ̀mí” Jẹ́ Gan-an?

Ọ̀pọ̀ rò pé téèyàn bá kú, ohun tí kò ṣeé fojú rí tó wà nínú ara máa fi ara sílẹ̀, á sì máa wà láàyè lọ níbòmíràn. Kí ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún wa?

ÀFIKÚN

Kí Ni Ṣìọ́ọ̀lù àti Hédíìsì?

Àwọn olùtumọ̀ Bíbélì kan fi “sàréè” tàbí “ọ̀run àpáàdì” rọ́pò Ṣìọ́ọ̀lù àti Hédíìsì. Kí ni àwọn ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí?

ÀFIKÚN

Kí Ni Ọjọ́ Ìdájọ́?

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Ọjọ́ Ìdájọ́ á ṣe jẹ́ ìbùkún fún àwọn olóòótọ́ èèyàn.

ÀFIKÚN

Ọdún 1914—Ọdún Pàtàkì Nínú Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì

Ẹ̀rí wo ló wà nínú Bíbélì tó fi hàn pé ọdún pàtàkì ni ọdún 1914?

ÀFIKÚN

Ta Ni Máíkẹ́lì Olú-Áńgẹ́lì?

Bíbélì sọ ẹni tí áńgẹ́lì alágbára yìí jẹ́. Kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹni tó jẹ́ àti ohun tó ń ṣe báyìí.

ÀFIKÚN

Bá A Ṣe Dá “Bábílónì Ńlá” Mọ̀

Ìwé ìṣípayá tàbí Ìfihàn sọ̀rọ̀ nípa obìnrin kan tá a pè ní “Bábílónì Ńlá.” Ṣé obìnrin gidi kan ni? Kí ni Bíbélì sọ nípa rẹ̀?

ÀFIKÚN

Ṣé Oṣù December Ni Wọ́n Bí Jésù?

Wo bí ojú ọjọ́ ṣe máa ń rí ní oṣù December ní ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí wọ́n bí Jésù sí. Kí ni ìyẹn kọ́ wa nípa ìgbà tí wọ́n bí Jésù?

ÀFIKÚN

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Máa Ṣe Ọdún àti Àwọn Ayẹyẹ Kan?

Ibo ni èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ọdún àti àwọn ayẹyẹ tí àwọn èèyàn ń ṣe ní àdúgbò rẹ ti wá? Wà á rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí.