Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ohun Tó Wà Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

 ÌBÉÈRÈ 1

Ta Ni Ọlọ́run?

Ta Ni Ọlọ́run?

“Kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, Ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”

Sáàmù 83:18

“Kí ẹ mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run. Òun ni ó ṣẹ̀dá wa, kì í sì í ṣe àwa fúnra wa.”

Sáàmù 100:3

“Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi; èmi kì yóò sì fi ògo mi fún ẹlòmíràn, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi ìyìn mi fún àwọn ère fífín.”

Aísáyà 42:8

“Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là.”

Róòmù 10:13

“Dájúdájú, olúkúlùkù ilé ni a kọ́ láti ọwọ́ ẹnì kan, ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run.”

Hébérù 3:4

 “Ẹ gbé ojú yín sókè réré, kí ẹ sì wò. Ta ni ó dá nǹkan wọ̀nyí? Ẹni tí ń mú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn jáde wá ni, àní ní iye-iye, àwọn tí ó jẹ́ pé àní orúkọ ni ó fi ń pe gbogbo wọn. Nítorí ọ̀pọ̀ yanturu okun rẹ̀ alágbára gíga, àti ní ti pé òun ní okun inú nínú agbára, kò sí ìkankan nínú wọn tí ó dàwáàrí.”

Aísáyà 40:26