“Mósè ṣe àkọsílẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà.”

Ẹ́kísódù 24:4

“Dáníẹ́lì fúnra rẹ̀ lá àlá, ó sì rí àwọn ìran orí rẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀. Ní àkókò yẹn, ó kọ àlá náà sílẹ̀. Ó sì sọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn nípa ọ̀ràn náà.”

Dáníẹ́lì 7:1

“Nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí ẹ gbọ́ láti ọ̀dọ̀ wa, ẹ tẹ́wọ́ gbà á, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ lótìítọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”

1 Tẹsalóníkà 2:13

“Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni.”

2 Tímótì 3:16

“A kò fi ìgbà kankan rí mú àsọtẹ́lẹ̀ wá nípa ìfẹ́ ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí wọn.”

2 Peter 1:21