BÓ O ṢE LÈ WÁ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ RÍ

Àwọn ìwé kéékèèké mẹ́rìndínláàádọ́rin [66] ló para pọ̀ di Bíbélì. Apá méjì ló pín sí, ìyẹn Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti Árámáìkì tí wọ́n ń pè ní “Májẹ̀mú Láéláé” àti Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì tí wọ́n ń pè ní “Májẹ̀mú Tuntun.” Ìwé kọ̀ọ̀kan tó wà nínú Bíbélì ní àwọn orí àti ẹsẹ. Nígbà tá a bá tọ́ka sí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, nọ́ńbà tó tẹ̀ lé orúkọ ìwé yẹn dúró fún orí, nígbà tí nọ́ńbà tó tẹ̀ lé e dúró fún ẹsẹ. Bí àpẹẹrẹ,Jẹ́nẹ́sísì 1:1 túmọ̀ sí Jẹ́nẹ́sísì orí 1, ẹsẹ 1.