Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ÌBÉÈRÈ 5

Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?

Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?

“Èmi yóò sì fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀. Òun yóò pa ọ́ ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀.”

Jẹ́nẹ́sísì 3:15

“Nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ sì ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn nítorí òtítọ́ náà pé ìwọ ti fetí sí ohùn mi.”

Jẹ́nẹ́sísì 22:18

“Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”

Mátíù 6:10

“Ní tirẹ̀, Ọlọ́run tí ń fúnni ní àlàáfíà yóò tẹ Sátánì rẹ́ lábẹ́ ẹsẹ̀ yín láìpẹ́.”

Róòmù 16:20

“Nígbà tí a bá ti fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀ tán, nígbà náà ni Ọmọ fúnra rẹ̀ pẹ̀lú yóò fi ara rẹ̀ sábẹ́ Ẹni tí ó fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀, kí Ọlọ́run lè jẹ́ ohun gbogbo fún olúkúlùkù.”

1 Kọ́ríńtì 15:28

 “Wàyí o, àwọn ìlérí náà ni a sọ fún Ábúráhámù àti fún irú-ọmọ rẹ̀ . . . , tí í ṣe Kristi. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí ẹ bá jẹ́ ti Kristi, ẹ̀yin jẹ́ irú-ọmọ Ábúráhámù ní ti tòótọ́.”

Gálátíì 3:16, 29

“Ìjọba ayé di ìjọba Olúwa wa àti ti Kristi rẹ̀, yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba títí láé àti láéláé.”

Ìṣípayá 11:15

“Bẹ́ẹ̀ ni a fi dírágónì ńlá náà sọ̀kò sísàlẹ̀, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà; a fi í sọ̀kò sísàlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé, a sì fi àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ sọ̀kò sísàlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀.”

Ìṣípayá 12:9

“Ó sì gbá dírágónì náà mú, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí í ṣe Èṣù àti Sátánì, ó sì dè é fún ẹgbẹ̀rún ọdún.”

Ìṣípayá 20:2