“Ìwé òfin yìí kò gbọ́dọ̀ kúrò ní ẹnu rẹ, kí o sì máa fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kà láti inú rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru, kí o lè kíyè sára láti máa ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí a kọ sínú rẹ̀; nítorí nígbà náà ni ìwọ yóò mú kí ọ̀nà rẹ yọrí sí rere, nígbà náà ni ìwọ yóò sì hùwà ọgbọ́n.”

Jóṣúà 1:8

“Wọ́n sì ń bá a lọ láti ka ìwé náà sókè, láti inú òfin Ọlọ́run tòótọ́, wọ́n ń làdí rẹ̀, wọ́n sì ń fi ìtumọ̀ sí i; wọ́n sì ń mú kí ìwé kíkà náà yéni.”

Nehemáyà 8:8

“Aláyọ̀ ni ènìyàn tí kò rìn nínú ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú . . . , ṣùgbọ́n inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà, ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin rẹ̀ tọ̀sán-tòru. . . . Gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.”

Sáàmù 1:1-3

“Fílípì sáré lọ sí ẹ̀gbẹ́, ó sì gbọ́ tí ó ń ka ìwé Aísáyà wòlíì sókè, ó sì wí pé: ‘Ní ti gidi, ìwọ ha mọ ohun tí o ń kà bí?’ Ó wí pé: “Ní ti tòótọ́, báwo ni mo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀, láìjẹ́ pé ẹnì kan fi mí mọ̀nà?’”

Ìṣe 8:30, 31

 “Nítorí àwọn ànímọ́ rẹ̀ tí a kò lè rí ni a rí ní kedere láti ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, nítorí a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ àwọn ohun tí ó dá, àní agbára ayérayé àti jíjẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní àwíjàre.”

Róòmù 1:20

“Máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá, kí ìlọsíwájú rẹ lè fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.”

1 Tímótì 4:15

“Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀.”

Hébérù 10:24, 25

“Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣaláìní ọgbọ́n, kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí òun a máa fi fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ìwà ọ̀làwọ́ àti láìsí gíganni; a ó sì fi í fún un.”

Jákọ́bù 1:5