Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ohun Tó Wà Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

 ÌBÉÈRÈ 11

Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Sẹ́ni Tó Bá Kú?

Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Sẹ́ni Tó Bá Kú?

“Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó padà sínú ilẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé.”

Sáàmù 146:4

“Nítorí àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá . . . Gbogbo ohun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi agbára rẹ ṣe é, nítorí pé kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù, ibi tí ìwọ ń lọ.”

Oníwàásù 9:5, 10

[Jésù] fi kún un pé: ‘Lásárù ọ̀rẹ́ wa ti lọ sinmi, ṣùgbọ́n mo ń rìnrìn àjò lọ sí ibẹ̀ láti jí i kúrò lójú oorun.’ Bí ó ti wù kí ó rí, Jésù sọ̀rọ̀ nípa ikú rẹ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n lérò pé ó ń sọ̀rọ̀ nípa sísinmi nínú oorun. Nítorí náà, ní àkókò yẹn, Jésù wí fún wọn láìfọ̀rọ̀-bọpo-bọyọ̀ pé: ‘Lásárù ti kú.’”

Jòhánù 11:11, 13, 14