“Kí ẹnu má yà yín sí èyí, nítorí pé wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yóò sì jáde wá.”

Jòhánù 5:28, 29

“Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.”

Ìṣe 24:15

“Mo sì rí àwọn òkú, ẹni ńlá àti ẹni kékeré, tí wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ náà, a sì ṣí àwọn àkájọ ìwé sílẹ̀. Ṣùgbọ́n a ṣí àkájọ ìwé mìíràn sílẹ̀; àkájọ ìwé ìyè ni. A sì ṣèdájọ́ àwọn òkú láti inú nǹkan tí a kọ sínú àwọn àkájọ ìwé náà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ wọn. Òkun sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú rẹ̀ lọ́wọ́, ikú àti Hédíìsì sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú wọn lọ́wọ́, a sì ṣèdájọ́ wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ní ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ wọn.”

Ìṣípayá 20:12, 13