Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ÌBÉÈRE 16

Tí Àníyàn Bá Ń Dà Ọ́ Láàmù Báwo Lo Ṣe Lè Fara Dà Á?

Tí Àníyàn Bá Ń Dà Ọ́ Láàmù Báwo Lo Ṣe Lè Fara Dà Á?

“Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró. Kì yóò jẹ́ kí olódodo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.”

Sáàmù 55:22

“Dájúdájú, àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní, ṣùgbọ́n ó dájú pé àìní ni olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń kánjú forí lé.”

Òwe 21:5

“Má fòyà, nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ. Má wò yí ká, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Dájúdájú, èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́. Èmi yóò fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin ní ti tòótọ́.”

Aísáyà 41:10

“Ta ni nínú yín, nípa ṣíṣàníyàn, tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ìwọ̀n gígùn ìwàláàyè rẹ̀?”

Mátíù 6:27

“Nítorí náà, ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, nítorí ọ̀la yóò ní àwọn àníyàn tirẹ̀. Búburú ti ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tó fún un.”

Mátíù 6:34

 “Máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.”

Fílípì 1:10

“Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.”

Fílípì 4:6, 7