Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ohun Tó Wà Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

 ÌBÉÈRÈ 7

Kí Ni Bíbélì Sọ Tẹ́lẹ̀ Nípa Ọjọ́ Wa?

Kí Ni Bíbélì Sọ Tẹ́lẹ̀ Nípa Ọjọ́ Wa?

“Nítorí orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba . . . Gbogbo nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìroragógó wàhálà.”

Mátíù 24:7, 8

“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wòlíì èké yóò sì dìde, wọn yóò sì ṣi ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́nà; àti nítorí pípọ̀ sí i ìwà àìlófin, ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ yóò di tútù.”

Mátíù 24:11, 12

“Nígbà tí ẹ bá gbọ́ nípa àwọn ogun àti ìròyìn nípa àwọn ogun, ẹ má ṣe jáyà; nǹkan wọ̀nyí gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin kì í ṣe ìsinsìnyí.”

Máàkù 13:7

“Ìsẹ̀lẹ̀ ńláǹlà yóò sì wà, àti àwọn àjàkálẹ̀ àrùn àti àìtó oúnjẹ láti ibì kan dé ibòmíràn; àwọn ìran bíbanilẹ́rù yóò sì wà àti àwọn àmì ńláǹlà láti ọ̀run.”

Lúùkù 21:11

 “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run, àwọn tí wọ́n ní ìrísí fífọkànsin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀.”

2 Tímótì 3:1-5