Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ohun Tó Wà Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

 ÌBÉÈRÈ 15

Báwo Lo Ṣe Lè Rí Ayọ̀?

Báwo Lo Ṣe Lè Rí Ayọ̀?

“Oúnjẹ tí a fi ọ̀gbìn oko sè, níbi tí ìfẹ́ wà, sàn ju akọ màlúù tí a bọ́ yó ní ibùjẹ ẹran tòun ti ìkórìíra.”

Òwe 15:17

“Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.”

Aísáyà 48:17

“Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn, níwọ̀n bí ìjọba ọ̀run ti jẹ́ tiwọn.”

Mátíù 5:3

“Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.”

Mátíù 22:39

“Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, ẹ máa ṣe bákan náà sí wọn.”

Lúùkù 6:31

“Aláyọ̀ ni àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!”

Lúùkù 11:28

 “Nígbà tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.”

Lúùkù 12:15

“Bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.”

1 Tímótì 6:8

“Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”

Ìṣe 20:35