Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ÌBÉÈRÈ 6

Kí Ni Bíbélì Sọ Tẹ́lẹ̀ Nípa Mèsáyà?

Kí Ni Bíbélì Sọ Tẹ́lẹ̀ Nípa Mèsáyà?

ÀSỌTẸ́LẸ̀

“Ìwọ, Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Éfúrátà, . . . inú rẹ ni ẹni tí yóò di olùṣàkóso Ísírẹ́lì yóò ti jáde tọ̀ mí wá.”

Míkà 5:2

ÌMÚṢẸ

“Lẹ́yìn tí a bí Jésù ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Jùdíà ní àwọn ọjọ́ Hẹ́rọ́dù Ọba, wò ó! àwọn awòràwọ̀ láti àwọn apá ìlà-oòrùn wá sí Jerúsálẹ́mù.”

Mátíù 2:1

ÀSỌTẸ́LẸ̀

“Wọ́n pín ẹ̀wù mi láàárín ara wọn, wọ́n sì ṣẹ́ kèké lé aṣọ mi.”

Sáàmù 22:18

ÌMÚṢẸ

“Wàyí o, nígbà tí àwọn ọmọ ogun ti kan Jésù mọ́gi tán, wọ́n mú ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀, wọ́n sì pín in sí apá mẹ́rin . . . Ṣùgbọ́n ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ náà kò ní ojú rírán, ó jẹ́ híhun láti òkè jálẹ̀jálẹ̀ gígùn rẹ̀. Nítorí náà, wọ́n sọ fún ara wọn pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ya á, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a pinnu nípa ṣíṣẹ́ kèké lé e, ti ta ni yóò jẹ́.’”

Jòhánù 19:23, 24

 ÀSỌTẸ́LẸ̀

“Ó ń ṣọ́ gbogbo egungun ẹni yẹn; a ò ṣẹ́ ìkankan nínú wọn.”

Sáàmù 34:20

ÌMÚṢẸ

“Ní dídé ọ̀dọ̀ Jésù, bí wọ́n ti rí i pé ó ti kú nísinsìnyí, wọn kò ṣẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.”

Jòhánù 19:33

ÀSỌTẸ́LẸ̀

“A gún un nítorí ìrélànàkọjá wa.”

Aísáyà 53:5

ÌMÚṢẸ

“Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ogun náà fi ọ̀kọ̀ gún ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹ̀jẹ̀ àti omi sì tú jáde.”

Jòhánù 19:34

ÀSỌTẸ́LẸ̀

“Wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti san owó ọ̀yà mi, ọgbọ̀n ẹyọ fàdákà.”

Sekaráyà 11:12, 13

ÌMÚṢẸ

“Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn méjìlá náà, ẹni tí a ń pè ní Júdásì Ísíkáríótù, lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà, ó sì wí pé: “Kí ni ẹ óò fún mi láti fi í lé yín lọ́wọ́?” Wọ́n ṣe àdéhùn pàtó láti fún un ní ọgbọ̀n ẹyọ fàdákà.”

Mátíù 26:14, 15; 27:5