Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ohun Tó Wà Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

 ÌBÉÈRÈ 14

Báwo Lo Ṣe Lè Fọgbọ́n Lo Ohun Ìní Rẹ?

Báwo Lo Ṣe Lè Fọgbọ́n Lo Ohun Ìní Rẹ?

“Ẹni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ àríyá yóò jẹ́ ẹnì kan tí ó wà nínú àìní; ẹni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ wáìnì àti òróró kì yóò jèrè ọrọ̀.”

Òwe 21:17

“Ayá-nǹkan sì ni ìránṣẹ́ awínni.”

Òwe 22:7

“Ta ni nínú yín tí ó fẹ́ kọ́ ilé gogoro kan tí kò ní kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbéṣirò lé ìnáwó náà, láti rí i bí òun bá ní tó láti parí rẹ̀? Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó lè fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó má lè parí rẹ̀, gbogbo òǹwòran sì lè bẹ̀rẹ̀ sí yọ ṣùtì sí i, pé, ‘Ọkùnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí kọ́lé ṣùgbọ́n kò lè parí rẹ̀.’”

Lúùkù 14:28-30

“Nígbà tí wọ́n yó tán, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: ‘Ẹ kó èébù tí ó ṣẹ́ kù jọpọ̀, kí ó má bàa sí ohun tí a fi ṣòfò.’”

Jòhánù 6:12