Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ohun Tó Wà Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Ohun Tó Wà Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Wàá rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè ogún tó ṣe pàtàkì nínú Bíbélì.

ÌBÉÈRÈ 1

Ta Ni Ọlọ́run?

Ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn kọ́ni pé àdììtú ni Ọlọ́run tàbí pé Ọlọ́run kì í ṣe ẹni gidi, àmọ́ ohun tí Bíbélì sọ yàtọ̀ sí ohun tí àwọn ẹ̀sìn yìí sọ.

ÌBÉÈRÈ 2

Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Ọlọ́run?

Ṣé kíka Bíbélì nìkan tó láti mọ Ọlọ́run?

ÌBÉÈRÈ 3

Ta Ló Kọ Bíbélì?

Ṣé ìwé tí wọ́n fi ọgbọ́n orí èèyàn kọ ni Bíbélì àbí ọgbọ́n tó ju ti èèyàn lọ?

ÌBÉÈRÈ 4

Ṣé Bíbélì Máa Ń Tọ̀nà Tó Bá Sọ̀rọ̀ Nípa Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì?

Tó bá jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá, ó yẹ kí ohun tó bá sọ nípa sáyẹ́ǹsì tọ̀nà.

ÌBÉÈRÈ 5

Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?

Àwọn ẹsẹ Bíbélì mẹ́wàá kan jẹ́ ká mọ ẹsin ọ̀rọ̀ Bíbélì.

ÌBÉÈRÈ 6

Kí Ni Bíbélì Sọ Tẹ́lẹ̀ Nípa Mèsáyà?

Ọ̀pọ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù jẹ́ ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan.

ÌBÉÈRÈ 7

Kí Ni Bíbélì Sọ Tẹ́lẹ̀ Nípa Ọjọ́ Wa?

Kí ni ogun, ìyàn, ìwà àìlófin àti ìwà ìbàjẹ́ tó ń pọ̀ sí i jẹ́ ká mọ̀ nípa àkókò tá a wà yìí?

ÌBÉÈRÈ 8

Ṣé Ọlọ́run Ló Lẹ́bi Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé?

Ṣé Ọlọ́run ń fi ìyà dán wa wò ni?

ÌBÉÈRÈ 9

Kí Nìdí Táwọn Èèyàn Fi Ń Jìyà?

Tí kì í bá ṣe Ọlọ́run lo fa ìyà, ta ló wá ń fà á tàbí kí ló fà á?

ÌBÉÈRÈ 10

Kí Ni Bíbélì Ṣèlérí Nípa Ọjọ́ Ọ̀la?

Ìrètí àgbàyanu yìí máa yà ẹ́ lẹ́nu.

ÌBÉÈRÈ 11

Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Sẹ́ni Tó Bá Kú?

Ṣé ikú kàn jẹ́ ọ̀nà téèyàn ń gbà lọ sí ayé míì?

ÌBÉÈRÈ 12

Ìrètí Wo Ló Wà Fáwọn Tó Ti Kú?

Ṣé ikú lòpin ìgbé ayé ẹ̀dá?

ÌBÉÈRÈ 13

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Iṣẹ́?

Ọ̀pọ̀ máa ń wo iṣẹ́ bí ìṣòro ńlá, táá sì máa wù wọ́n pé kí iṣẹ́ ṣiṣe dópin lọ́jọ́ kan. Ṣé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ nìyẹn?

ÌBÉÈRÈ 14

Báwo Lo Ṣe Lè Fọgbọ́n Lo Ohun Ìní Rẹ?

Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ bí o ṣe lè máa lo àwọn ohun tó o ní, kí wọ́n má ṣe máa darí rẹ.

ÌBÉÈRÈ 15

Báwo Lo Ṣe Lè Rí Ayọ̀?

Ọ̀pọ̀ ọ̀nà tá a lè gbà rí ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn wà nínú Bíbélì.

ÌBÉÈRÈ 16

Tí Àníyàn Bá Ń Dà Ọ́ Láàmù Báwo Lo Ṣe Lè Fara Dà Á?

Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí àníyàn bá fẹ́ bò ẹ́ mọ́lẹ̀.

ÌBÉÈRÈ 17

Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Ran Ìdílé Rẹ Lọ́wọ́?

Wo bí ìdílé rẹ ṣe lè jẹ́ ibùgbé àlááfíà àti ayọ̀.

ÌBÉÈRÈ 18

Báwo Lo Ṣe Lè Sún Mọ́ Ọlọ́run?

Ó ṣeé ṣe kó o ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run.

ÌBÉÈRÈ 19

Kí Ló Wà Nínú Oríṣiríṣi Ìwé Tó Para Pọ̀ Di Bíbélì?

Wo àwọn ohun tó wà nínú Bíbélì.

ÌBÉÈRÈ 20

Báwo Lo Ṣe Lè Ka Bíbélì Kó sì Yé Ọ Dáadáa?

Láìka apá tó o bá ń kà nínú Bíbélì sí, wàá rí ẹ̀kọ́ tó pọ̀ kọ́ tó o bá ń wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè mẹ́rin kan.