Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2017

Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Ẹ̀yin Ará Wa Ọ̀wọ́n:

Ọlọ́run fi ìran àgbàyanu kan han wòlíì Ìsíkíẹ́lì ní ọgọ́rùn-ún ọdún keje Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ó rí kẹ̀kẹ́ gìrìwò kan, ìyẹn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run, Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run ló sì ń darí rẹ̀. Ohun tó jọni lójú jù lọ nípa kẹ̀kẹ́ náà ni bó ṣe ń rìn. Ó ń sáré lọ bí ìgbà tí mànàmáná bá kọ, ó sì lè yí bìrí bó ṣe ń lọ láìtiẹ̀ dẹwọ́ eré tàbí kó yíjú sẹ́gbẹ̀ẹ́!Ìsík. 1:4, 9, 12, 14, 16-27.

Ìran yẹn rán wa létí pé apá ti ọ̀run lára ètò Jèhófà kò fìgbà kan dáwọ́ eré dúró. Apá ti ilẹ̀ ayé náà ò dáwọ́ eré dúró, lọ́nà wo? Ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá ti jẹ́ kó ṣe kedere pé Jèhófà ń darí àwọn èèyàn rẹ̀ tó wà létòlétò lórí ilẹ̀ ayé lọ́nà tó wúni lórí.

Apá ti ọ̀run lára ètò Jèhófà kò fìgbà kan dáwọ́ eré dúró

Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà níbí, ọwọ́ ìdílé Bẹ́tẹ́lì dí bí wọ́n ṣe ń kó kúrò ní Brooklyn lọ sí oríléeṣẹ́ wa tuntun nílùú Warwick, ní New York, àwọn kan ń lọ sí àwọn ọ́fíìsì wa míì, àwọn míì sì ń lọ sí pápá. Láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì míì kárí ayé, ọwọ́ àwọn ìdílé Bẹ́tẹ́lì dí bí àwọn kan nínú wọn ṣe ń kọ́lé, táwọn kan ń ṣe àtúntò, tí wọ́n ń pa àwọn ọ́fíìsì kan pọ̀, táwọn míì sì ń kó lọ sáwọn ọ́fíìsì tuntun. Ìwọ náà ńkọ́? Ká tiẹ̀ ló ò kó lọ ibì kankan, ó dájú pé ọwọ́ tiẹ̀ náà dí láwọn ọ̀nà míì.

 Inú àwa Ìgbìmọ̀ Olùdarí dùn gan-an, ó sì wú wa lórí pé ọwọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run kárí ayé ti dí ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, bí wọ́n ṣe ń bá ètò Ọlọ́run rìn. Ọ̀pọ̀ ló ti lọ sìn níbi tá a ti nílò oníwàásù púpọ̀ sí i. Àwọn míì sì ti kọ́ èdè tuntun kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Àwọn kan ti gbìyànjú ọ̀nà tuntun láti wàásù. Ọ̀pọ̀ ló sì ti fi kún ohun tí wọ́n ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run láwọn ọ̀nà míì. Gbogbo àwọn Kristẹni olóòótọ́, títí kan àwọn àgbàlagbà àtàwọn tí ara wọn ò le, ló ń sá eré ìje ìyè náà láìdẹwọ́, ọwọ́ wọn dí lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà, ìyẹn sì ń jẹ́ kí wọ́n lè tú Sátánì fó pé òpùrọ́ ni!1 Kọ́r. 9:24.

Ẹ jẹ́ kó dá yín lójú pé Jèhófà mọyì ẹ̀mí tí ẹ̀ ń fi hàn. (Héb. 6:10) Bí ẹ ṣe ń yọ̀ǹda ara yín tinútinú mú wa rántí Ábúráhámù àti Sárà. Ábúráhámù ti lé ní  àádọ́rin [70] ọdún nígbà tó kó kúrò nílùú Úrì nílẹ̀ Kálídíà tòun ti ìdílé rẹ̀ lọ sí ìyànníyàn ilẹ̀ Kénáánì, níbi tó ti ń gbé inú àgọ́, ibẹ̀ ló sì ti lo ọgọ́rùn-ún [100] ọdún tó lò kẹ́yìn láyé. Àbẹ́ ò rí ẹ̀mí tó dáa tí òun àti ìyàwó rẹ̀ ọ̀wọ́n fi hàn!Jẹ́n. 11:31; Ìṣe 7:2, 3.

Ṣé irú ẹ̀mí yẹn náà lo ní? Gbogbo ẹ̀yin tẹ́ ẹ jẹ́ olóòótọ́ bẹ́ ẹ ṣe ń fara da ìṣòro lákòókò tí nǹkan le yìí lẹ̀ ń ṣe ohun tí Jésù ní ká ṣe. Ó sọ pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́.”Mát. 28:19.

Bí Jésù ṣe lo ọ̀rọ̀ náà, “ẹ lọ” fi hàn pé ó yẹ kí ọwọ́ wa dí. Ẹ wo bó ṣe wúni lórí tó láti rí ohun táwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tí wọ́n nítara gbé ṣe lọ́dún tó kọjá! Ó ṣe kedere pé Jèhófà ń rọ̀jò ìbùkún rẹ̀ sórí iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tó ń lọ ní gbogbo orílẹ̀-èdè.Máàkù 13:10.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń gba òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Lọ́dún tó kọjá, iye akéde jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́jọ, ọ̀kẹ́ mẹ́tàdínlógún àti ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé mẹ́tàdínláàádọ́ta [8,340,847], iye yìí ló sì ròkè jù. Àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lóṣooṣù jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́wàá, ẹgbẹ̀rún lọ́nà márùndínlọ́gọ́fà àti igba ó lé mẹ́rìnlélọ́gọ́ta [10,115,264]. Ó ṣe kedere pé kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run ò dáwọ́ eré dúró, ẹ̀yin náà ò sì kẹ̀rẹ̀! Ẹ máa bá iṣẹ́ rere yín lọ ní àkókò díẹ̀ tó kù yìí kí Jèhófà ti ilẹ̀kùn ìgbàlà pa.

Ẹ ò rí i pé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2017 bá a mu wẹ́kú, ó sọ pé: “Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí o sì máa ṣe rere”! (Sm. 37:3) Tẹ́ ẹ bá ń ṣe ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ, tí ẹ̀ ń ṣe rere, ìyẹn tí ẹ̀ ń fún Jèhófà ní ìjọsìn mímọ́, ṣe lẹ̀ ń fi  hàn pé ẹ gbẹ́kẹ̀ lé e. A fẹ́ kó máa wà lọ́kàn yín pé ẹ ò dá wà. Jésù ò ní ṣàìmú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ, ó ní: “Wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.”Mát. 28:20.

Ẹ jẹ́ kó dá yín lójú pé Jèhófà ò ní dáwọ́ ìbùkún rẹ̀ dúró lórí iṣẹ́ ìsìn tí ẹ̀ ń fi òótọ́ inú ṣe. Bóyá ohun tí ẹ̀ ń ṣe kéré àbí ó pọ̀, ohun tó ṣe pàtàkì sí Jèhófà ni pé kó jẹ́ gbogbo ohun tí ẹ lè ṣe lẹ̀ ń ṣe, kó sì jẹ́ ọkàn tó dáa lẹ fi ń ṣe é. Irú àwọn ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀ máa ń mú ọkàn rẹ̀ yọ̀, tayọ̀tayọ̀ ló sì máa ń tẹ́wọ́ gbà á. (2 Kọ́r. 9:6, 7) Torí náà, ẹ máa gbàdúrà déédéé, ẹ máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ẹ máa lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni, ẹ sì máa lọ sóde ìwàásù déédéé. Tí ẹ bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, ẹ̀ẹ́ máa sún mọ́ Bàbá yín onífẹ̀ẹ́.

Títí “àkókò kúkúrú” tó kù fún Èṣù, ọlọ̀tẹ̀ burúkú yẹn, máa fi dópin, ó ti pinnu láti lo gbogbo ohun tó wà níkàáwọ́ rẹ̀ kó lè mú ká kúrò lójú ọ̀nà ìwà títọ́ wa sí Jèhófà. (Ìṣí. 12:12) Ẹ má fi Jèhófà sílẹ̀ o! Tí ẹ ò bá fi í sílẹ̀, gbogbo ọgbọ́n tó wù kí Èṣù dà, ó dájú pé ó máa pòfo. (Sm. 16:8) A fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ yín gan-an, a sì mọyì ìrànlọ́wọ́ yín bẹ́ ẹ ṣe ń kọ́wọ́ ti ire Ìjọba Ọlọ́run láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí.

Àwa arákùnrin yín,

Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́ ỌDÚN 2017:

“Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí o sì máa ṣe rere”