Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Azerbaijan

 À Ń WÀÁSÙ A SÌ Ń KỌ́NI KÁRÍ AYÉ

Yúróòpù

Yúróòpù
  • ILẸ̀ 47

  • IYE ÈÈYÀN 744,482,011

  • IYE AKÉDE 1,611,290

  • IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ 834,121

Ìdáhùn Pẹ̀lẹ́

Lórílẹ̀-èdè Jọ́jíà, ọkùnrin kan wá síbi tí àwọn ará pàtẹ ìwé sí, ó ń pariwo pé: “Mi ò ní jẹ́ kẹ́ ẹ wàásù níbí! Kristẹni ẹlẹ́sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ni wá lórílẹ̀-èdè Jọ́jíà.” Arákùnrin tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àtẹ ìwé náà fohùn tútù béèrè lọ́wọ́ ọkùnrin náà bóyá ó ti ka ìkankan nínú àwọn ìwé wa rí. Ọkùnrin náà dáhùn pé, “Rárá, mi ò kà á rí.” Ni arákùnrin náà bá fọgbọ́n  sọ fún un pé kó gbìyànjú láti kà á. Bí wọ́n ṣe bá ọkùnrin náà sọ̀rọ̀ mú kára ẹ̀ wálẹ̀, ó sì mú àwọn ìwé díẹ̀. Ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, ọkùnrin náà pa dà wá, ó sì tọrọ àforíjì nítorí ìwà tó hù sí wọn lọ́jọ́sí. Ó ní òun ti ka ìwé ìròyìn wa fún ìyá òun tó jẹ́ afọ́jú. Àwọn méjèèjì gbádùn ìwé náà gan-an, wọ́n sì ń wá tuntun míì tí wọ́n máa kà. Ní báyìí, àtìgbàdégbà ló máa ń wá síbi tí à ń pàtẹ ìwé sí láti gba ìwé ìròyìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde.

Ọ̀nà Tó Dáa Jù Láti Yanjú Aáwọ̀

Nígbà tí àwọn ará méjì ń wàásù lórílẹ̀-èdè Azerbaijan, wọ́n lọ sọ́dọ̀ ọ̀dọ́kùnrin kan tó dúró níwájú ilé, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù fún un. Ọkùnrin náà sọ pé, “Mi ò lè gbọ́ gbogbo nǹkan tí ẹ̀ ń sọ yìí; ẹ̀ṣẹ̀ ló máa jẹ́ fún mi.” Ló bá fa ọ̀bẹ kan yọ nínú àpò ẹ̀yìn ṣòkòtò ẹ̀, ó sì sọ pé, “Ẹnì kan rẹ́ mi jẹ, ọ̀bẹ yìí ni mo sì fẹ́ lọ fi yanjú ẹ̀.”

Ẹnú ya àwọn arákùnrin náà, àmọ́ wọ́n sọ pé, “Ẹ̀ṣẹ̀ ni kéèyàn pààyàn.”

Ọkùnrin náà sọ pé, “Kí wá ni kí n ṣe?” Wọ́n ka Róòmù 12:17-21 fún un, wọ́n sì ṣàlàyé pé Ọlọ́run ló ni ẹ̀san àti pé a ò gbọ́dọ̀ ‘jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun wa, ṣùgbọ́n [ká] máa fi ire ṣẹ́gun ibi.’ Wọ́n sọ agbára tí ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ ní fún un, wọ́n sì jẹ́ kó yé e pé tó bá ṣe èèyàn léṣe tàbí tó pààyàn, ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ á máa dà á láàmù. Ohun tí ọkùnrin náà gbọ́ múnú ẹ̀ dùn, ó sì kúrò lọ́dọ̀ wọn.

Lẹ́yìn nǹkan bíi wákàtí kan, ọkùnrin yìí rí àwọn arákùnrin náà, ó sì sọ pé: “Ọ̀dọ̀ ẹni tí mo fẹ́ lọ pa tẹ́lẹ̀ ni mo ti ń bọ̀ yìí. Mi ò ṣe nǹkan kan fún un, ńṣe ni mo kàn yanjú ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ẹ̀. Ẹ ṣeun tẹ́ ẹ kó mi yọ, tẹ́ ò jẹ́  kí n dá wàhálà sílẹ̀.” Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà ṣàlàyé fún un pé Jèhófà gan-an ló kó o yọ.

Àtẹ Ìwé Ran Arábìnrin Kan Tó Ti Di Aláìṣiṣẹ́mọ́ Lọ́wọ́

Láwọn ọdún kan sẹ́yìn, arábìnrin kan lórílẹ̀-èdè Nọ́wè fi òtítọ́ sílẹ̀. Lẹ́yìn tá a wá bẹ̀rẹ̀ sí í pàtẹ ìwé láwọn ibi térò pọ̀ sí, ó máa ń gba ibẹ̀ kọjá tó bá fẹ́ lọ ra nǹkan.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í yà sọ́dọ̀ àwọn ará tó wà nídìí àtẹ ìwé náà, ó máa ń kíyè sí àwọn àwòrán gàdàgbà tó fani mọ́ra tí wọ́n gbé síbẹ̀ àti bí wọ́n ṣe to ìwé sórí àtẹ náà lọ́nà tó wuni lórí. Ohun tó rí yìí, títí kan bí ara àwọn tó wà níbẹ̀ ṣe máa ń yá mọ́ọ̀yàn, tí wọ́n sì máa ń múra dáadáa mú kó wù ú láti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.

Ó tún kíyè sí àwòrán ìkànnì wa, ìyẹn jw.org, torí náà ó pinnu láti lọ sórí ìkànnì náà. Inú ẹ̀ dùn nígbà tó rí bó ṣe rọrùn tó láti wá àdírẹ́sì Gbọ̀ngàn Ìjọba tó sún mọ́ni àti àkókò tí wọ́n ń ṣèpàdé níbẹ̀. Ó wa àwọn ìwé díẹ̀ jáde, ó sì lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba bó tiẹ̀ jẹ́ pé ara ń tì í. Wọ́n gbà á tọwọ́tẹsẹ̀, àwọn alàgbà sì ṣètò arábìnrin kan táá máa kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kò pẹ́ tó fi ní àwọn ọ̀rẹ́ gidi nínú ìjọ, ó sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe dáadáa nípa tẹ̀mí. Ní báyìí, ó ti ń wá sípàdé déédéé, ó sì ń lọ sóde ẹ̀rí, inú ẹ̀ dùn pé òun ti tún ń gbádùn àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà.

Ó Wàásù fún Àwọn Ọmọ Kíláàsì Ẹ̀ Nínú Bọ́ọ̀sì Ilé-ìwé

Lọ́jọ́ kan tí Ronja tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] lórílẹ̀-èdè Nọ́wè wà nínú bọ́ọ̀sì ilé-ìwé wọn, ó bá àwọn ọmọkùnrin mẹ́ta tí wọ́n wà ní kíláàsì ẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ẹfolúṣọ̀n. Ohun tó gbà gbọ́ ò nítumọ̀ létí àwọn ọmọ náà rárá, èyí ò sì múnú arábìnrin wa kékeré yìí dùn. Àmọ́  torí pé kò fi bẹ́ẹ̀ mọ ohun tó lè sọ lórí ọ̀rọ̀ náà, ó sọ fún mọ́mì ẹ̀ nígbà tó délé pé kó ran òun lọ́wọ́ kí òun lè rí àwọn kókó pàtàkì tí òun lè fi jẹ́ kí àwọn ọmọ náà mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá wà.

Nọ́wè: Ronja gbèjà ìgbàgbọ́ ẹ̀

Nínú bọ́ọ̀sì náà lọ́jọ́ kejì, Ronja lo àwọn kókó tó ti múra sílẹ̀. Àmọ́ ńṣe làwọn ọmọ náà yẹ̀yẹ́ ìgbàgbọ́ tó ní nínú Jèhófà. Ọ̀kan nínú wọn pariwo pé: “Kò sẹ́ni tó gba Jèhófà gbọ́ nínú bọ́ọ̀sì yìí! Kí ẹni tó bá gba ẹfolúṣọ̀n gbọ́ nawọ́, kí ẹni tó bá sì gba Jèhófà gbọ́ náà nawọ́.” Ó ya Ronja lẹ́nu nígbà tí ọmọkùnrin kan tó jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ nawọ́ sókè tó sì sọ pé, “Mo gba Jèhófà gbọ́!” Àwọn ọmọ méjì míì sọ pé àwọn náà gba Jèhófà gbọ́! Àwọn ọmọ míì ti gbọ́ ohun tí Ronja ń bá àwọn ọmọ kíláàsì ẹ̀ sọ, wọ́n sì gbà pé òótọ́ ni àwọn ohun tí Ronja sọ!

 Ọkùnrin Kan tí Kò Mọ̀wé Kà Rí Ìwé Kan

Lọ́sàn-án ọjọ́ kan, àwọn ọkùnrin méjì láti Síríà tí wọ́n ń sọ èdè Lárúbáwá wá sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè Denmark. Wọ́n sọ fún arábìnrin tó wà ní yàrá ìgbàlejò pé àwọn fẹ́ rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tí arábìnrin náà jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ibi tó yẹ kí wọ́n wá ni wọ́n wá, inú àwọn ọkùnrin náà dùn gan-an. Àmọ́ ibo ni wọ́n ti rí àdírẹ́sì? Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé, wọ́n fi fọ́tò tí wọ́n fi fóònù wọn yà han àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìkówèésí tó wà fún àwọn aráàlú. Fọ́tò ìsọfúnni tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? ni. Ìyẹn ló wá jẹ́ kí àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìkówèésí náà lè rí àdírẹ́sì ẹ̀ka ọ́fíìsì wa fún wọn.

Àwọn ọkùnrin méjèèjì ò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ èdè Danish. Torí náà, wọ́n pe arákùnrin kan tó ń sọ èdè Lárúbáwá wá sí yàrá ìgbàlejò. Ó wá ṣe kedere pé ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin náà ti ń wá bó ṣe máa túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Arákùnrin náà gba nọ́ńbà fóònù àti àdírẹ́sì ẹ̀, ó sì ṣèlérí fún un pé òun máa kàn sí i láìpẹ́ àti pé òun á mú arákùnrin míì tó ń sọ èdè Lárúbáwá dání.

Nígbà tí àwọn arákùnrin náà lọ sílé ọkùnrin yìí, wọ́n rí i pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan ò wá sọ́dọ̀ ẹ̀ rí. Ó sọ fún wọn pé òun rí ìwé kan tí wọ́n fi èdè Lárúbáwá kọ nínú àpótí lẹ́tà òun, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sórúkọ lára àpótí náà tó fi hàn pé ẹni tó ń sọ èdè Lárúbáwá ló ni ín. Àmọ́ torí pé kò mọ̀wé ka, ó ní kí ọ̀rẹ́ òun bá òun ka ìwé náà, wọ́n sì fi ọjọ́ mẹ́ta parí ẹ̀. Ohun tó gbọ́ yìí ti tó fún un láti gbà pé ó ti rí òtítọ́.

Torí pé àgọ́ àwọn tí ogun lé kúrò lórílẹ̀-èdè wọn ló wà, tó sì jìnnà sí ìdílé ẹ̀, inú ẹ̀ kì í dùn rárá, àmọ́ ọ̀rọ̀ Bíbélì  ló fi ń tu ara ẹ̀ nínú. Ọjọ́ àkọ́kọ́ tí àwọn arákùnrin náà wá sọ́dọ̀ ẹ̀, ó bi wọ́n pé: “Kí ló dé tẹ́ ò wá sọ́dọ̀ mi rí? Ohun tí mo nílò gan-an nìyí.” Ó ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ lọ pẹ̀lú àwọn arákùnrin náà, ó sì fara sí ohun tó ń kọ́.

Ìbànújẹ́ Di Ayọ̀

Ọ̀gá ni Dmitry ní iléeṣẹ́ tí wọ́n ti ń ṣe sìgá lórílẹ̀-èdè Ukraine, àmọ́ nígbà tó túbọ̀ rí ìpalára ńlá tí sìgá ń ṣe fún ìlera èèyàn, ó fi iṣẹ́ tó ń mówó gọbọi wọlé yìí sílẹ̀. Kò pẹ́ sígbà yẹn, tí ìyá ẹ̀ àti ìyá ìyàwó ẹ̀ fi kú láàárín oṣù mẹ́ta péré. Àgbákò ńlá ni ikú àwọn méjèèjì jẹ́ fún un. Ó rò pé àwọn ará ṣọ́ọ̀ṣì òun máa tu òun nínú, tí òun á sì mọ ohun tó fà á táwọn nǹkan yìí fi ṣẹlẹ̀, àmọ́ kò sóhun tó jọ bẹ́ẹ̀. Ọ̀rẹ́ ẹ̀ kan sọ fún un pé ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ Kristẹni onísìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ni pé “kéèyàn ṣáà ti máa gbé àgbélébùú kọ́rùn, bí ò tiẹ̀ mọ nǹkan kan nípa Ọlọ́run.” Bó sì ṣe rí lára Dmitry gẹ́lẹ́ nìyẹn. Ó rí i pé òun ò mọ nǹkan kan nípa Ọlọ́run àti Bíbélì. Ìdààmú bá a, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ran òun lọ́wọ́. Ó rántí ohun tó gbọ́ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó rí ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, inú ẹ̀ sì dùn gan-an láti rí ọ̀pọ̀ ìsọfúnni nípa Bíbélì lórí ìkànnì náà. Lẹ́yìn náà, ó wá ibi tí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó sún mọ́ ọn jù wà, ó sì lọ síbẹ̀. Nígbà tó dé ibi tí wọ́n ń gbọ́kọ̀ sí, ẹni tó ń bójú tó èrò béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ bóyá nǹkan kan wà tí òun lè ṣe fún un. Dmitry sọ pé, “Mo fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Ó ti tó oṣù mẹ́fà báyìí tó ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó ń wá sípàdé déédéé, ó sì ń kópa níbẹ̀.

Wọ́n Kọ̀wé Sílẹ̀ Kí Iná Ìfẹ́ Àwọn tí Wọ́n Rí Má Bàa Kú

Paul àti Faith tí wọ́n ń gbé ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì gbádùn ọ̀rọ̀ tí àwọn àti obìnrin kan tó ń jẹ́ Susan sọ, wọ́n sì ṣètò láti  pa dà lọ. Nígbà tí wọ́n pa dà lọ, Susan ò sí nílé. Paul àti Faith wá tẹ̀ lé àbá tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù November 2014 pé a lè kọ̀wé sílẹ̀, wọ́n bá kọ̀wé sílẹ̀ fún Susan pé àwọn máa pa dà wá lọ́jọ́ kejì. Nígbà tí wọ́n pa dà lọ, wọ́n rí ìwé tí Susan kọ dè wọ́n lẹ́nu ilẹ̀kùn, èyí sì yà wọ́n lẹ́nu gan-an. Ó ṣàlàyé pé òun lọ ra àwọn nǹkan táwọn máa lò nígbà ìgbéyàwó ọmọ òun obìnrin. Paul àti Faith kọ ìwé míì sílẹ̀ dè é, wọ́n ní àwọn máa pa dà wá lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e. Lọ́tẹ̀ yìí, Susan ti ń dúró dè wọ́n, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni ṣèkẹ́kọ̀ọ́.

Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì: Paul àti Faith ń kọ̀wé sílẹ̀

Torí pé ọmọ Susan ò ní pẹ́ ṣègbéyàwó, ó ní kí wọ́n bá òun sún ìgbà tí wọ́n máa pa dà wá síwájú. Nígbà tí Paul àti Faith tún pa dà lọ, wọn ò rẹ́nì kankan, ni wọ́n bá kọ̀wé sílẹ̀, wọ́n sì fi nọ́ńbà fóònù wọn sí i. Inú wọn dùn nígbà tí wọ́n rí ọ̀rọ̀ tí Susan fi ránṣẹ́ sí wọn lórí fóònù, ó ní kí wọ́n máà bínú pé àwọn ò ríra; aládùúgbò  ẹ̀ kan ló ń bá sọ̀rọ̀ lẹ́yìnkùlé. Látìgbà yẹn, wọ́n ń kọ́ Susan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, ó ń gbádùn ẹ̀, ó sì wá sípàdé nígbà àkọ́kọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí.

Ó máa ń yá Paul àti Faith lára láti kọ̀wé sílẹ̀ de eni tí wọn ò bá bá nílé. Wọ́n ní, “Ọ̀pọ̀ lára àwọn míì tá ò bá ló ti ka ìwé tá a kọ sílẹ̀ dè wọ́n. Ọ̀nà yìí dáa gan-an!”

Ìgbàgbọ́ Tó Ní Ran Nọ́ọ̀sì Rẹ̀ Lọ́wọ́

Lóṣù August, ọdún 2014, wọ́n gbé arákùnrin kan lọ sílé ìwòsàn lórílẹ̀-èdè Hungary, àìsàn tí kì í jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ wọnú ẹ̀dọ̀fóró ló ń ṣe é. Ó bani nínú jẹ́ pé kò pẹ́ tó fi kú. Ìyàwó arákùnrin náà kọ̀wé nípa nọ́ọ̀sì tó ń jẹ́ Tünde, tó dìídì ran ọkọ ẹ̀ lọ́wọ́, ó ní:

“Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 2015, èmi àti ọmọ mi ọkùnrin lọ sí àpéjọ àgbègbè ‘Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù!’ Ibi tí wọ́n ń gbé ọkọ̀ sí la wà lẹ́yìn tí ìpàdé ọjọ́ kẹta parí, a ti fẹ́ máa pa dà sílé, ni obìnrin kan bá wá bá mi, ó gbé báàgì ẹ̀ sílẹ̀, ó dì mọ́ mi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. Òun ni nọ́ọ̀sì tó tọ́jú ọkọ mi nílé ìwòsàn ní nǹkan bí ọdún kan sẹ́yìn. Ó ṣàlàyé bí iṣẹ́ wọn ṣe rí, ó ní wọ́n máa ń yan aláìsàn tí nọ́ọ̀sì kọ̀ọ̀kan máa tọ́jú tó bá ti fẹ́ gbaṣẹ́ lọ́jọ́ kan. Gbogbo ìgbà ló máa ń gbàdúrà pé kó jẹ́ ọ̀dọ̀ ọkọ mi ni wọ́n máa yan òun sí. Ohun tó sì ń ṣẹlẹ̀ látìgbàdégbà nìyẹn!

“Ohun tí Tünde sọ fi hàn pé ìwà dáadáa ọkọ mi àti ìgbàgbọ́ ẹ̀ pẹ̀lú bó ṣe máa ń sọ nípa ìrètí tó ní lohun tó kọ́kọ́ sún òun láti rí i pé ó yẹ kóun bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójú méjèèjì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

“Tünde ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí, ó sì ń retí ìgbà tó máa kí ọkọ mi káàbọ̀ nígbà àjíǹde. Ó fẹ́ jẹ́ kó mọ̀ pé ìwà ẹ̀  àti ìgbàgbọ́ ẹ̀ tó lágbára ló ran òun lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà àti àwọn ìlérí àgbàyanu rẹ̀.”

Wọ́n Ń Wàásù Láti Inú Ọkọ̀ Kan Dé Òmíràn

Bọ̀géríà: Wọ́n ń wàásù fún àwọn tó ń wa ọkọ̀ akẹ́rù ní ibodè

Àwọn ìgbà kan wà tí wọ́n máa ń ti àwọn ibodè tí wọ́n ti ń yẹni wò láàárín orílẹ̀-èdè Gíríìsì àti Bọ̀géríà torí pé àwọn kan ń wọ́de, wọ́n sì ń dí ọ̀nà. Èyí máa ń mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀ tò lọ rẹrẹ. Ìjọ kan tó wà nítòsí ibẹ̀ lórílẹ̀-èdè Bọ̀géríà lo àǹfààní ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí láti máa pín ìwé tó dá lórí Bíbélì fún àwọn tó wà níbẹ̀. Àwọn ará gbéra lọ sí ibodè orílẹ̀-èdè náà, wọ́n kó àwọn ìwé dání ní èdè méjìlá [12] ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ó ti rẹ ọ̀pọ̀ nínú àwọn tó ń wa ọkọ̀ akẹ́rù, nǹkan sì ti tojú sú wọn, àmọ́ wọ́n ṣì fẹ́ bá àwọn ará sọ̀rọ̀. Àwọn ará náà fetí sí wọn tìfẹ́tìfẹ́, wọ́n fún wọn níṣìírí, wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n nírètí. Awakọ̀ kan bi wọ́n pé, “Ṣé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni yín?” Lẹ́yìn tí wọ́n dá a lóhùn pé bẹ́ẹ̀ ni, ó sọ pé, “Mo ti mọ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ló máa ń wàásù bíi tiyín yìí.” Inú awakọ̀ míì tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Austria dùn, ló bá fi àwàdà sọ pé: “Kódà níbi tá a wà yìí, a ò tún bọ́ lọ́wọ́ yín! Mo bá yín yọ̀! Ẹ jọ̀ọ́, ẹ máa tu àwọn èèyàn nínú, kẹ́ ẹ sì máa jẹ́ kí wọ́n nírètí.” Ẹlòmíì sọ pé: “Ìwé yín ò wù mí kà rí. Àmọ́ ní báyìí, tìdùnnú-tìdùnnú ni màá fi kà á.” Omi bẹ̀rẹ̀ sí í bọ́ lójú awakọ̀ kan nígbà tí arákùnrin kan wàásù fún un. Ó ní Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Àwọn arákùnrin náà gbà á níyànjú pé kó ka ìwé tí wọ́n fún un, kó sì wá ìjọ kan máa lọ.