Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2017

Fiji

 À Ń WÀÁSÙ A SÌ Ń KỌ́NI KÁRÍ AYÉ

Oceania

Oceania
  • ILẸ̀ 29

  • IYE ÈÈYÀN 41,051,379

  • IYE AKÉDE 98,574

  • IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ 67,609

Lẹ́yìn Ọdún Mẹ́sàn-án, Olùkọ́ Rẹ̀ Gbà

Nígbà tí Olivia tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà wà ní jẹ́lé-ó-sinmi, ó pe olùkọ́ rẹ̀ wá síbi Ìrántí Ikú Kristi. Ọdọọdún ni Olivia ń pe olùkọ́ rẹ̀ yìí wá síbi Ìrántí Ikú Kristi, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ fọ́dún mẹ́jọ tó tẹ̀ lé e. Nígbà tó yá, lọ́dún 2016, olùkọ́ rẹ̀ pè lórí fóònù pé òun máa wá. Ó ní inú òun dùn bí Olivia ṣe ka òun sí, tó ń pe òun  lọ́dọọdún wá síbi ìpàdé náà. Olùkọ́ náà àti ọkọ rẹ̀ wá síbi Ìrántí Ikú Kristi. Torí pé ọkọ rẹ̀ ti bá ìgbìmọ̀ tó ń ṣètò ìlú ṣiṣẹ́ rí, ó rántí ìgbà tí wọ́n ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà nílùú náà. Ó sọ fáwọn ará pé bí gbogbo nǹkan ṣe lọ létòlétò nígbà tí wọ́n ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba yẹn wú òun lórí gan-an. Olùkọ́ náà àti ọkọ rẹ̀ gbádùn àkókò tí wọ́n lò ní Gbọ̀ngàn Ìjọba lọ́jọ́ yẹn gan-an débi pé wọ́n wà lára àwọn tó kúrò níbẹ̀ gbẹ̀yìn.

Ọsirélíà: Lẹ́yìn ọdún mẹ́sàn-án tí Olivia ti ń gbìyànjú, ó ṣàṣeyọrí

Ó Ka Ìwé Náà Lẹ́ẹ̀mẹ́ta

Orílẹ̀-èdè Timor-Leste ni Jacintu àti ìyàwó rẹ̀ ń gbé. Ẹlẹ́sìn Kátólíìkì làwọn méjèèjì, wọn ò sì fọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ṣeré rárá. Nígbà tí ọmọ ẹ̀gbọ́n Jacintu di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí kò sì bá ìdílé náà jọ́sìn mọ́, ó ṣe wọ́n ní kàyéfì. Jacintu fẹ́ jẹ́ kí ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ mọ̀ pé ẹ̀sìn èké ló gbà, ló bá pinnu pé òun máa ka ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? kó lè wá ẹ̀kọ́ èké jáde níbẹ̀. Nígbà tó yá, ó sọ fún ìyàwó rẹ̀ pé: “Mo ti kàwé yẹn. Gbogbo ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ ló dáa.”

Ìyàwó ẹ̀ sọ pé, “O ò kà á dáadáa ni jàre. Tún un kà, àmọ́ fara balẹ̀ kà á lọ́tẹ̀ yìí.”

Jacintu ṣe bẹ́ẹ̀, ló bá tún sọ fún ìyàwó rẹ̀ pé: “Gbogbo ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ ló dáa.” Ó fi kún un pé: “Inú Bíbélì ni wọ́n ti mú gbogbo ọ̀rọ̀ inú ẹ̀. Kódà, inú Bíbélì ni wọ́n ti mú ohun tó sọ nípa jíjọ́sìn òkú.”

Ìyàwó ẹ̀ tún sọ pé: “Lọ kà á lẹ́ẹ̀kẹta, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, fàlà sí ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan, kó o fara balẹ̀ wò ó dáadáa. Irọ́ gbọ́dọ̀ wà níbẹ̀.”

 Jacintu fara balẹ̀ ka ìwé náà dáadáa, ó fàlà sí ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn tó fara balẹ̀ kà á lẹ́ẹ̀kẹta, ó ní: “Òótọ́ ni gbogbo ohun tó wà níbẹ̀! Òótọ́ lọmọ ẹ̀gbọ́n mi sọ.” Ní báyìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń kọ́ Jacintu lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Ọmọ Rẹ̀ Obìnrin Sọ̀rọ̀

Arábìnrin kan tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, tó ń gbé ní erékùṣù Guam, lọ sílé obìnrin kan tó wá láti erékùṣù Pohnpei, ó sì fi fídíò Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? hàn án. Arábìnrin náà sọ pé òun máa pa dà wá. Ó pa dà wá ní ẹ̀ẹ̀melòó kan, àmọ́ kò bá obìnrin náà nílé. Lọ́jọ́ tó bá ọmọ obìnrin náà nílé, arábìnrin náà fi fídíò kan lára àwọn fídíò Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà hàn án. Ọmọ náà gbádùn fídíò yẹn gan-an. Nígbà tí arábìnrin náà pa dà lọ, ìyá ọmọ náà ló bá nílé, ó sì tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ tó bá a sọ. Ó ní láti jẹ́ pé ọmọ náà ti sọ fún ìyá rẹ̀ pé káwọn lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì obìnrin tó fi fídíò han òun. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìyẹn ló mú kó wu ìyá rẹ̀ láti gbọ́rọ̀  wa. Arábìnrin náà jẹ́ kó rí bá a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ṣètò bí wọ́n á ṣe máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ.

Wọ́n Dà Bí “Àwọn Àgùntàn tí Kò Ní Olùṣọ́ Àgùntàn”

Terence, tó jẹ́ alábòójútó àyíká àti Stella ìyàwó ẹ̀ rìnrìn àjò lọ sílùú Inakor lórílẹ̀-èdè Papua New Guinea. Ìpínlẹ̀ tí a kò pín fúnni ni ibẹ̀. Terence sọ pé: “A ṣì ń sùn láàárọ̀ kùtù ọjọ́ kejì tá a débẹ̀, la bá gbọ́ tẹ́nì kan kan ilẹ̀kùn wa. Nígbà tá a ṣílẹ̀kùn, ọ̀pọ̀ èèyàn la bá níta tí wọ́n ń dúró dè wá, bá a ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù fún wọn nìyẹn, láti aago mẹ́fà àárọ̀ títí di ọ̀sán. Lẹ́yìn náà, a dáwọ́ dúró ká lè lọ wẹ̀, la bá tún rí i pé àwọn tó ń dúró dè wá ti pọ̀ sí i. Bá a ṣe tún bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù nìyẹn, láti aago méjì ọ̀sán títí di  ọ̀gànjọ́ òru.” Láàárọ̀ ọjọ́ kejì, àwọn tọkọtaya náà pinnu láti tètè jí kúrò níbi tí wọ́n dé sí kí wọ́n lè lọ wàásù ní àgbègbè míì. Ni ọ̀pọ̀ èèyàn bá tún wá wọn délé, àmọ́ wọn ò bá wọn. Terence sọ pé, “Nígbà tí wọ́n wá mọ ibi tá a lọ, wọ́n wá wa débẹ̀. Bá a tún ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù nìyẹn, títí di ọ̀sán. Nígbà tá a pa dà síbi tá a dé sí, àwọn míì tún ti ń dúró dè wá. Ohun tó sì máa ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́ nìyẹn. Àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ dà bí ‘àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.’ ”Mát. 9:36.

Papua New Guinea: Àwọn èèyàn ń dúró de Terence àti Stella tayọ̀tayọ̀

Ó Mú Ẹ̀bùn Wá fún Dókítà

Aṣáájú-ọ̀nà ni Agnès, orílẹ̀-èdè New Caledonia ló ń gbé. Apá ń dùn ún, ó sì di pé kó lọ rí dókítà tó ń to eegun. Nígbà tí dókítà náà ń tọ́jú Agnès lọ́wọ́, ó sọ fún Agnès pé àwọn tóun ti rí tí ìyà ń jẹ pọ̀ gan-an, ìyẹn sì ti mú kóun máa rò ó pé bóyá Ọlọ́run ò láàánú. Agnès dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà lọ́kàn rẹ̀ pé ó jẹ́ kóun rí àǹfààní láti gbèjà rẹ̀. Agnès wá fi ìwé àṣàrò kúkúrú tí àkòrí rẹ̀ sọ pé Ǹjẹ́ Ìyà Lè Dópin? han dókítà náà, ó sì ka Ìṣípayá 21:3, 4 fún un.

Dókítà náà sọ pé: “Mi ò rò pé ẹsẹ Bíbélì tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ kà yẹn wà nínú Bíbélì mi, torí ìwé Ìhìn Rere nìkan ló wà nínú Bíbélì tí mo ní.” Nígbà tó wá mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Agnès, ó sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí ti bá òun sọ̀rọ̀ rí ní orílẹ̀-èdè Chile tóun ti wá.

Agnès rántí pé òun ti wo fídíò orí Tẹlifíṣọ̀n JW kan rí, tó dá lórí ohun tí ẹ̀ka ọ́fíìsì Chile sọ̀ nípa ohun tó ń lọ lórílẹ̀-èdè náà. Torí náà, nígbà tó pa dà lọ sọ́dọ̀ dókítà náà, ó gbé tablet rẹ̀ dání, ó sì fi fídíò náà hàn án. Nígbà tí dókítà náà rí Bẹ́tẹ́lì àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó wà ní Chile,  orí ẹ̀ wú. Agnès wá sọ pé, “Bíbélì lódindi lohun kejì tí mo mú wá fún ẹ. Wàá lè ka Ìṣípayá 21:3, 4 níbẹ̀, ẹsẹ Bíbélì tí mo kà fún ẹ lọ́sẹ̀ tó kọjá!” Ni dókítà náà bá fò dìde lórí àga, ó sì dì mọ́ Agnès, ó ní, “O ṣé gan-an fún ẹ̀bùn àtàtà méjì tó o fún mi yìí!”

New Caledonia: Inú dókítà rẹ̀ dùn gan-an

Nígbà tí Agnès pa dà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó mú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? dání, ó sì túbọ̀ ṣàlàyé ohun tó fà á táwa èèyàn fi ń jìyà. Dókítà yẹn sọ pé òun máa tó lọ sí orílẹ̀-èdè Chile, ó ní òun fẹ́ gba ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́, àmọ́ òun máa mú ìwé náà dání kóun lè kà á látìbẹ̀rẹ̀ dópin.