• ILẸ̀ 49

  • IYE ÈÈYÀN 4,464,374,770

  • IYE AKÉDE 728,989

  • IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ 771,272

Látorí Ẹnì Kan Dórí Ẹni Púpọ̀

Lórílẹ̀-èdè Philippines, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jonathan ń dúró de dókítà tó sọ pé kó wá. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Laila, tó ń ṣiṣẹ́ ní yàrá ìgbàlejò tó wà níbẹ̀ rí Jonathan, ó rí bó ṣe múra dáadáa, tó sì wà létòletò, ó wá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá ilé iṣẹ́ abánigbófò ló ń bá ṣiṣẹ́. Jonathan ṣàlàyé fún un pé Ẹlẹ́rìí  Jèhófà lòun àti pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń gba ìtọ́jú níbẹ̀ lòun wá ràn lọ́wọ́. Inú Laila dùn gan-an, ó sọ fún Jonathan pé bàbá òun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kú máa ń ka Ilé Ìṣọ́ déédéé, kì í pa á jẹ. Jonathan wá ka Jòhánù 5:28, 29 fún un, ó sì fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú Ìrètí Wo Ló Wà Fáwọn Táa Fẹ́ràn Tí Wọ́n Ti Kú?

Philippines: Jonathan wàásù fún ẹni tó ń gbàlejò

Láwọn ìgbà tí Jonathan tún pa dà wá sí ilé ìwòsàn náà, ó mú àwọn ìwé míì wá fún Laila, ó sì fojú rẹ̀ mọ arábìnrin  kan, arábìnrin náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ Laila lẹ́kọ̀ọ́. Kò pẹ́ tí ọkọ Laila, àbúrò ẹ̀ obìnrin àti ìyá ẹ̀, tí gbogbo wọn ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀ fi dara pọ̀ mọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà.

Rose tó jẹ́ ará ilé Laila wá bá a, ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé kí ló dé tí ọ̀pọ̀ àlejò fi máa ń wà nílé ẹ̀. Laila ṣàlàyé pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Èyí mú kí Rose náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́, nígbà tó sì lọ kí àbúrò ẹ̀ níbi tó ń gbé, tayọ̀tayọ̀ ló fi sọ ohun tó ń kọ́ fún un. Abigail, àbúrò ẹ̀ fẹ́ mọ̀ sí i nípa ohun tó gbọ́, torí náà, ó ní kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá máa kọ́ òun náà lẹ́kọ̀ọ́. Ìyá Rose náà gbà láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Laila ṣèrìbọmi ní àpéjọ àgbègbè kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí. Ìyá ẹ̀ náà ti ṣèrìbọmi báyìí. Rose tó jẹ́ ará ilé ẹ̀ àti àbúrò Rose ṣèrìbọmi lọ́dún tó kọjá. Ìyá Rose náà kì í pa ìpàdé jẹ báyìí. Àwọn mọ̀lẹ́bí Laila kan sì ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ní pẹrẹu. Ẹnì kan péré tí wọ́n wàásù fún nílé ìwòsàn ló jẹ́ kí gbogbo èyí ṣẹlẹ̀!

Wọ́n Ń Lo Ìmọ̀ Ẹ̀rọ Láti Kàn sí Àwọn Adití

Ibi tí àwọn ará ti ń fi èdè adití wàásù ti pọ̀ sí i lórílẹ̀-èdè Siri Láńkà. Lọ́dún 2015, àwọn ará ti ní tó ọgọ́rin [80] àdírẹ́sì àwọn adití lọ́wọ́, wọ́n sì kọ wọ́n sínú ìwé pélébé-pélébé. Àtìgbà yẹn ni wọ́n ti dá ìjọ àkọ́kọ́ tó ń sọ èdè adití lọ́nà ti Siri Láńkà sílẹ̀, wọ́n sì ṣe ètò orí kọ̀ǹpútà kan tó gba orúkọ àwọn bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ogún [420] èèyàn àti àdírẹ́sì wọn pẹ̀lú máàpù téèyàn lè fi délé wọn. Àwọn ará ti kàn sí èyí tó pọ̀ jù nínú wọn lójúkojú, wọ́n fi fídíò orí íńtánẹ́ẹ̀tì pe àwọn kan, wọ́n sì fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sáwọn míì lórí fóònù. Tọkọtaya kan tó jẹ́ míṣọ́nnárì sọ pé: “Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn adití tí àwọn akéde wa tó jẹ́ adití mọ̀ nìkan ni wọ́n máa ń lọ sọ́dọ̀ wọn. Àmọ́ ní báyìí, a ti lè fún wọn ní ìpínlẹ̀ tí wọ́n á ti máa wàásù.”

 Òṣìṣẹ́ Ìjọba Kan Kọ̀wé Ọpẹ́

Àwọn ará ní Mòǹgólíà kì í fọ̀rọ̀ àkànṣe ìwàásù láwọn ibi tí èrò pọ̀ sí ṣeré, kódà nígbà tí òtútù bá mú gan-an. Òṣìṣẹ́ ìjọba kan mú àwọn ìwé kan níbi tí wọ́n pàtẹ ìwé sí, ó sì kọ̀wé ọpẹ́ ránṣẹ́. Ohun tó kọ sínú ìwé náà ni pé: “Ẹlẹ́sìn Búdà ni mí. Àmọ́ mo ti yẹ àwọn ẹ̀sìn míì wò, torí ìlànà ti mò ń tẹ̀ lé ni pé èèyàn ò gbọ́dọ̀ máa gba ọ̀nà kan ṣáá, ó yẹ kéèyàn yẹ àwọn ọ̀nà míì wò kó lè mọ bí wọ́n ṣe rí. Lẹ́yìn tí mo kà lára àwọn ìwé tẹ́ ẹ ṣe fáráyé, mo pinnu pé màá kọ lẹ́tà kan kí n lè sọ bó ṣe rí lára mi. Ó ṣe kedere sí mi pé ọ̀pọ̀ àkókò àti okun yín lẹ ti lò láti gbé àwọn ìsọfúnni tó gbéṣẹ́, tó sì ń ranni lọ́wọ́ jáde. Ohun kan tí mo kọ́ nínú àwọn ìwé yín ni pé ìwé tó yẹ kéèyàn máa kà ni Bíbélì. Òótọ́ ló wà nínú ìwé yìí. Bíbélì máa ń fúnni ní ìtọ́sọ́nà tó dáa nígbèésí ayé. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ takuntakun láti túmọ̀ àwọn ìwé yín sí èdè Mòǹgólíà. Mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn tó ń fún àwọn èèyàn níwèé láti ràn wọ́n lọ́wọ́, nígbà tóòrùn mú ganrín-ganrín àti nígbà tí òtútù mú gan-an.”

Mongolia: Wọ́n ń wàásù níbi tí èrò pọ̀ sí nígbà òtútù

Ọlọ́run Gbọ́ Àdúrà Rẹ̀

Lórílẹ̀-èdè Hong Kong, arákùnrin Brett tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lọ bá ọ̀dọ́kùnrin kan tó ti ń sún mọ́ ọgbọ̀n [30] ọdún, ó sì fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú Kí Ló Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀? Nígbà tí ọ̀dọ́kùnrin náà rí ìwé yìí, ṣe ló bú sẹ́kún. Ó sọ pé inú òtítọ́ ni wọ́n ti tọ́ òun dàgbà, àmọ́ nígbà tóun fi máa pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16], òun sá kúrò nílé. Ní ọdún márùn-ún tó tẹ̀ lé e, ọmọ ìta ló ń ṣe kiri, ó ń lo oògùn olóró, ó sì di bárakú fún un títí àjọ tó ń ran àwọn aláìní lọ́wọ́ fi rí i, tí wọ́n sì ràn án lọ́wọ́.

Ó ń bá ọ̀rọ̀ ẹ̀ lọ pé láàárọ̀ ọjọ́ tóun bá arákùnrin yìí pàdé, òun ti gbàdúrà sí Ọlọ́run pé, “Tó bá jẹ́ pé ìsìn àárọ̀  mi ni ìsìn tòótọ́, jọ̀ọ́ fi àmì kan hàn mí lónìí.” Ó gbà pé Ọlọ́run ti dáhùn àdúrà òun. Àwọn méjèèjì wá lọ sí ṣọ́ọ̀bù kọfí kan tó wà nítòsí, wọ́n sì jọ ka ohun tó wà nínú ìwé Jọ̀wọ́ Pa Dà Sọ́dọ̀ Jèhófà. Àmọ́ torí pé ọ̀dọ́kùnrin náà máa pa dà sórílẹ̀-èdè Faransé nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, àwọn méjèèjì gba àdírẹ́sì àti nọ́ńbà fóònù ara wọn. Nígbà tó yá, ọ̀dọ́kùnrin náà kọ̀wé ránṣẹ́ sí Brett pé: “Arákùnrin mi ọ̀wọ́n, Jèhófà ti dáhùn àdúrà mi. Màá lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó sún mọ́ mi lọ́jọ́ Sunday.” Ó kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Faransé, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ti ń lọ sípàdé.