Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Mẹ́síkò: Wọ́n jọ ń kọ́ béèyàn ṣe ń ka ìwé àwọn afọ́jú

 À Ń WÀÁSÙ A SÌ Ń KỌ́NI KÁRÍ AYÉ

Àwọn Ilẹ̀ Amẹ́ríkà

Àwọn Ilẹ̀ Amẹ́ríkà
  • ILẸ̀ 57

  • IYE ÈÈYÀN 998,254,087

  • IYE AKÉDE 4,154,608

  • IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ 4,353,152

“Èmi Àtìẹ Á Jọ Kọ́ Ọ”

Ismael, tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, pinnu pé òun máa ka Bíbélì láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. Láàárín ọdún kan, ó ti kà á lẹ́ẹ̀mejì, àmọ́ nígbà tó yá, kò ríran mọ́. Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń jẹ́ Ángel pàdé Ismael, ó sì sọ àwọn ìlérí Ọlọ́run fún un. Ó yá Ismael lára láti mọ̀ sí i, àmọ́ ó sọ pé, “Mi ò ríran, ìyẹn ò ní jẹ́ kí n lè ka Bíbélì.”

 Ángel fi dá a lójú pé òun máa kọ́ ọ bí wọ́n ṣe ń ka ìwé àwọn afọ́jú, pé kó fọkàn balẹ̀.

Ismael bi í pé, “Ṣé o mọ̀ ọ́n kà ni?”

Ángel fèsì pé, “Rárá, àmọ́ èmi àtìẹ á jọ kọ́ ọ.” Ó ya Ismael lẹ́nu pé Ángel máa tìtorí òun ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tí Ángel délé, ó ṣèwádìí nípa bí wọ́n ṣe ń ka ìwé àwọn afọ́jú, ó wá kọ ọ̀rọ̀ sára páálí kan bí wọ́n ṣe máa ń ṣe ìwé àwọn afọ́jú. Ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ Ismael bí wọ́n ṣe ń ka ìwé àwọn afọ́jú. Kò pẹ́ tí Ismael fi mọ àwọn álífábẹ́ẹ̀tì orí ìwé, kò sì pẹ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé, tó sì ń ka àwọn ìwé wa tá a ṣe fáwọn afọ́jú. Ángel ti ń kọ́ àwọn mẹ́rin tó jẹ́ afọ́jú lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí. Ó máa ń wù wọ́n gan-an kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ nípa ìgbà tí ayé máa di Párádísè lọ́jọ́ iwájú, táwọn náà á tún lè ríran.

Kò Dá A Mọ̀

Viannei, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá [14] tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kọ̀wé pé: “Lọ́jọ́ kan, olùkọ́ kan wá kọ́ wa nípa ìwà àti ìṣe ẹ̀dá láwùjọ, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn. Ó ní ká dárúkọ àwọn ẹ̀sìn tó wà, mo wá dárúkọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn ọmọ kíláàsì mi bú sẹ́rìn-ín, wọ́n ní ṣe la máa ń fàkókò àwọn èèyàn ṣòfò, pé a ò ní nǹkan gidi tá a fẹ́ ṣe. Wọ́n tún ní ṣe làwọn máa ń sọ ìwé wa dà nù. Olùkọ́ wa náà sọ̀rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láìdáa.

“Mo wá gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún mi nígboyà kí n lè wàásù. Mo sọ fún wọn pé kì í ṣe torí àtifi àkókò wọn ṣòfò la ṣe máa ń wá sí ilé wọn, àmọ́ torí pé Jèhófà rán wa sí  wọn la ṣe ń wá sọ́dọ̀ wọn ká lè fi Bíbélì gbà wọ́n nímọ̀ràn tó wúlò. Mo ní kí wọ́n má ju ìwé wa nù mọ́, pé ó lè tún ìgbésí ayé wọn ṣe, kó sì gbà wọ́n là. Olùkọ́ mi ní kí n máà bínú, ó ṣèlérí pé nígbà míì tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá wá sílé òun, òun máa ṣílẹ̀kùn fún wọn, òun á gbọ́rọ̀ wọn, òun á sì ka ìwé wa. Eré ni mo pè é.

“Oṣù mẹ́rin lẹ́yìn náà tí mo pa dà rí i, ó yà mí lẹ́nu pé ó ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Oṣù mẹ́fà lẹ́yìn ìgbà yẹn, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá  mi kiri níléèwé kó lè dúpẹ́ lọ́wọ́ mi pé mo wàásù fún òun. Mi ò tiẹ̀ dá a mọ̀ torí ó ti gẹ irun ẹ̀, ó sì ti fá irùngbọ̀n ẹ̀. Ó ti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi.”

Wọ́n Ń Wàásù Níbi Odò Amazon

Lọ́dún tó kọjá, àgbègbè odò Amazon làwọn èèyàn Jèhófà lórílẹ̀-èdè Brazil fún láfiyèsí, ibẹ̀ sì tóbi gan-an. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn tó ń gbébẹ̀ ni ò tíì gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run rí. Ìdí nìyẹn tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí fi fọwọ́ sí i pé kí àwọn ará  lọ fi odindi ọdún kan wàásù níbẹ̀, kí wọ́n lè wàásù fún ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé láwọn ibi tó wọnú jù lágbègbè odò Amazon.

Brazil: Wọ́n ń wàásù níbi odò Amazon

Nígbà yẹn, ẹ̀ka ọ́fíìsì yan ìlú mẹ́tàléláàádọ́ta [53] tó wà káàkiri àwọn ibi tí odò Amazon ṣàn dé pé kí àwọn ará lọ wàásù níbẹ̀. Láàárín oṣù mẹ́rin péré, àwọn akéde tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún [6,500] ló sọ pé àwọn máa lọ.

Àdádó ni ìlú Anamã wà, kò sí akéde Ìjọba Ọlọ́run kankan níbẹ̀. Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin mẹ́wàá lo ọjọ́ mọ́kànlá [11] níbẹ̀, ìwé tí wọ́n fi síta lé ní ẹgbẹ̀rún méjìlá ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún [12,500], wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ nǹkan bí igba [200] èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Orí fóònù ni wọ́n ti ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà báyìí. Àwọn ará yìí tún máa ń ṣèpàdé nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀. Ní ìpàdé tí wọ́n ṣe gbẹ̀yìn kí wọ́n tó kúrò, inú wọn dùn gan-an nígbà tí wọ́n rí àádọ́rùn-ún [90] èèyàn tó wá. A ò tíì mọ gbogbo ohun tí àkànṣe ìwàásù táwọn ará ṣe yìí máa mú jáde.

Ó Ní Kó Lọ Wo Ìkànnì jw.org

Látọdún mẹ́fà sẹ́yìn, kíláàsì kan náà ni Jehizel àti Mariana wà níléèwé lórílẹ̀-èdè Fẹnẹsúélà. Mariana sábà máa ń fi Jehizel ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Mariana gbà pé Jehizel ò mayé jẹ. Lọ́jọ́ kan tí Mariana tún sọ̀rọ̀ tí kò dáa sí arábìnrin wa yìí, ohun kan sọ sí i lọ́kàn, ló bá sọ pé: “Mariana, lọ wo ìkànnì wa, jw.org. Lọ sí ‘Àwọn Fídíò Tó Dá Lórí Bíbélì,’ kó o wá tẹ ‘Àwọn Ọ̀dọ́.’”

Lọ́sàn-án ọjọ́ yẹn, Mariana pe Jehizel, ó sì sọ fún un pé, “Mo ti wá mọ ìdí tó o fi ń ṣe bó o ṣe ń ṣe.”

 Àmọ́ ohun tó sọ kò yé Jehizel dáadáa, ó wá bi í pé, “O tún ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́, àbí?”

Mariana fèsì pé, “Rárá o, mi ò tún fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ mọ́. Ọpẹ́lọpẹ́ rẹ, mo ti wá mọ̀ pé àwọn ohun tí mò ń ṣe, tí mo sọ pé ‘mò ń jayé’, ló ń fa ọ̀pọ̀ ìṣòro tí mo ní.” Wọ́n ṣètò bí Mariana á ṣe máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, ó sì ti ń lọ sí gbogbo ìpàdé báyìí.

Ó Bi Pásítọ̀ Ní Ìbéèrè

Gérole ni akọ̀wé ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Haiti. Ó wú u lórí nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi Bíbélì dáhùn gbogbo ìbéèrè tó bi wọ́n. Òun àti ọmọ rẹ̀ obìnrin sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́  Bíbélì. Ohun tí wọ́n ń kọ́ wọ̀ wọ́n lọ́kàn gan-an débi pé wọ́n ní ẹ̀ẹ̀mejì lọ́sẹ̀ làwọn fẹ́ máa kẹ́kọ̀ọ́.

Lẹ́yìn oṣù mẹ́ta tí wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́, Gérole lọ bá pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀, ó sì bi í níbèérè mẹ́rin. Ó bi í pé: “Ọdún wo ni Jésù di ọba? Ibo làwọn ẹni rere ń lọ tí wọ́n bá kú? Ibo làwọn ẹni burúkú ń lọ tí wọ́n bá kú? Ṣé orí àgbélébùú ni Jésù kú sí àbí orí òpó?” Pásítọ̀ náà sọ pé ìbéèrè kejì àti ìkẹta nìkan lòun lè dáhùn. Ó ní, “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] làwọn tó ń lọ sọ́run. Àmọ́ ohun témi máa sọ ni pé gbogbo àwọn tó ń ṣèfẹ́ Ọlọ́run ló máa lọ sọ́run. Ní tàwọn ẹni burúkú, wọ́n á máa jó nínú iná ọ̀run àpáàdì títí láé.” Gérole ní kó fi han òun nínú Bíbélì, àmọ́ pásítọ̀ náà ò rí nǹkan kan sọ. Ọ̀rọ̀ yìí ya Gérole lẹ́nu gan-an, àmọ́ àtìgbà yẹn ló ti pinnu pé òun ò ní dá ìkẹ́kọ̀ọ́ òun nínú Bíbélì dúró láé. Ó kúrò ní ṣọ́ọ̀ṣì tó ń lọ, lẹ́yìn náà, ó sọ pé láàárín oṣù mẹ́ta táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ohun tóun ti mọ̀ pọ̀ ju nǹkan tí òun mọ̀ láti ohun tó lé ní ọgbọ̀n [30] ọdún tóun ti ń lọ ṣọ́ọ̀ṣì. Àìpẹ́ yìí ni Gérole àti ọmọ rẹ̀ ṣèrìbọmi, àwọn mẹ́tàlélógún [23] ni wọ́n sì ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní abúlé wọn.

Haiti: Gérole àti ọmọ rẹ̀ obìnrin ní ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì