• ILẸ̀ 58

  • IYE ÈÈYÀN 1,109,511,431

  • IYE AKÉDE 1,538,897

  • IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ 4,089,110

Ó Gbàdúrà Pé Kóun Rí Adití Bá Sọ̀rọ̀

Míṣọ́nnárì tó ń wàásù lédè adití lórílẹ̀-èdè Siria Lóònù ni Crystal. Lọ́jọ́ kan tó fẹ́ lọ sóde ìwàásù, ó gbàdúrà pé kí òun rí àwọn adití tóun máa wàásù fún. Láàárọ̀ ọjọ́ yẹn, níbi tó ti ń wá ẹnì kan tó fẹ́ pa dà lọ bẹ̀ wò, ó gba ọ̀nà ibì kan tí kì í gbà tẹ́lẹ̀. Ó bi àwọn aládùúgbò bóyá wọ́n mọ adití kankan ládùúgbò yẹn, wọ́n wá júwe ilé  kan fún un. Nígbà tó débẹ̀, ó rí ọ̀dọ́bìnrin kan tó fara balẹ̀ dáadáa, ara ẹ̀ yá mọ́ọ̀yàn, ó sì wù ú láti wá sípàdé tí wọ́n ń ṣe lédè adití. Àwọn ará àdúgbò wá bi Crystal bóyá ó máa fẹ́ rí adití míì. Bó tún ṣe rí ẹlòmíì tó nírẹ̀lẹ̀, tó sì fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nìyẹn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tí Crystal ti wàásù ládùúgbò yẹn, kò pàdé àwọn adití méjì tó rí láàárọ̀ ọjọ́ yẹn rí. Ó dá Crystal lójú pé tí kì í bá ṣe pé Jèhófà ran òun lọ́wọ́, òun ò lè rí àwọn tó lọ́kàn ìfẹ́ yẹn.

“Èmi Gan-An Ni Àsọyé Yẹn Ń Bá Wí!”

Lọ́jọ́ kan, Emmanuel, tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Làìbéríà ń wa mọ́tò lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, ó ń lọ sí ìpàdé òpin ọ̀sẹ̀. Bó ṣe ń lọ, ó rí ọ̀dọ́kùnrin kan tó dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ títì, ọ̀dọ́kùnrin náà múra dáadáa, àmọ́ inú ẹ̀ ò dùn rárá. Àánú ọ̀dọ́kùnrin yìí ṣe Emmanuel, ló bá páàkì mọ́tò rẹ̀ pé bóyá òun lè ràn án lọ́wọ́. Ọ̀dọ́kùnrin náà sọ pé Moses lorúkọ òun. Ó sọ pé ní alẹ́ tó ṣáájú ọjọ́ yẹn, wọ́n jí gbogbo owó òun, òun sì ti ń rò ó pé kóun lọ pa ara òun. Emmanuel fetí sí ohun tí Moses sọ, ó sì bá a sọ̀rọ̀ tàánú-tàánú, ó ní, “Jọ̀ọ́, jẹ́ ká jọ lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba.” Láwọn méjèèjì bá jọ lọ sípàdé. Ohun tí Moses gbọ́ níbẹ̀ wú u lórí débi pé ó bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. Lẹ́yìn tí àsọyé parí, Moses sọ pé: “Èmi gan-an ni àsọyé yẹn bá wí. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mà yàtọ̀ o!” Nígbà tí ìpàdé parí, Moses gbà láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ti ń wá sípàdé déédéé.

 “Mi Kì Í Ṣe Kèfèrí”

Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] ni Aminata, ọmọ iléèwé ni lórílẹ̀-èdè Gíní-Bìsaù. Nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá [13], olùkọ́ tó ń kọ́ wọn bí wọ́n ṣe ń yàwòrán sọ fún gbogbo wọn nínú kíláàsì pé kí wọ́n ya ohun táwọn èèyàn máa ń fi bojú tí wọ́n bá ń ṣayẹyẹ àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n máa ń lò nígbà ayẹyẹ. Àmọ́ ọ̀tọ̀ ni ohun tí Aminata yà. Àwòrán ibì kan táwọn ẹranko àtàwọn ewéko wà ló yà, ó wá kọ “Párádísè” sórí àwòrán náà. Nígbà tí olùkọ́ wọn gba ìwé tí wọ́n yàwòrán sí, ó sọ fún Aminata pé ohun tó yà ò bá ohun tí òun sọ pé kí wọ́n yà mu, ó sì fún un lódo. Nígbà tí kíláàsì parí, Aminata lọ rí olùkọ́ náà, ó sì bi í pé, “Àwọn wo ló ń ṣe ayẹyẹ tẹ́ ẹ sọ yìí?”

Olùkọ́ náà fèsì pé, “Àwọn kèfèrí ni.”

Gíní-Bìsaù: Aminata ya àwòrán “Párádísè”

Aminata wá sọ pé: “Mi kì í ṣe Kèfèrí, mi kì í ṣe irú àwọn ayẹyẹ yẹn. Ohun tí mo gbà gbọ́ ni pé Ọlọ́run máa tó sọ ayé di párádísè, ohun tí mo sì yàwòrán ẹ̀ nìyẹn.” Olùkọ́ náà wá sọ pé òun máa tún ìdánwò náà ṣe fún wọn, àmọ́ wọn ò ní yàwòrán lọ́tẹ̀ yìí. Kí wá lèsì ìdánwò yìí? Máàkì méjìdínlógún [18] ni Aminata gbà nínú ogún [20].

Ọ̀pọ̀ Èèyàn Ló Wá

Akéde méje ló wà nínú àwùjọ kan tó wà ládàádó ní abúlé kékeré kan lórílẹ̀-èdè Màláwì. Abẹ́ àtíbàbà kan tí wọ́n fi igi, ewé àti ẹní onígi kọ́ ni wọ́n ti ń ṣèpàdé. Nígbà tí alábòójútó àyíká wá bẹ̀ wọ́n wò, ó fún àwọn ará yẹn  níṣìírí, ìyẹn sì mú kí wọ́n fìtara pe àwọn èèyàn wá síbi Ìrántí Ikú Kristi. Lọ́jọ́ yẹn, àwọn àtùpà elépo tí wọ́n so mọ́ abẹ́ àtíbàbà náà ni alásọyé fi sọ àsọyé. Àmọ́ ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má lè yíra torí pé ọ̀pọ̀ àwọn ẹni tuntun tó wá sípàdé ló yí i ká. Ẹ wo bí inú àwọn akéde méje yẹn ṣe máa dùn tó nígbà tí wọ́n rí ọgọ́fà [120] èèyàn tó wá!

Màláwì: Ọgọ́fà [120] èèyàn ló wá

Ìwé Kan Yanjú Ìṣòro Àárín Òun àti Ọkọ Rẹ̀

Wíwàásù lọ́nà àkànṣe láwọn ibi térò pọ̀ sí sábà máa ń méso téèyàn lè má tètè rí jáde. Nílùú Lomé, tó jẹ́ olú ìlú Tógò, obìnrin kan lọ sídìí àtẹ táwọn Ẹlẹ́rìí kówèé sí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ará ń tì í, ó mú ìwé Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀ níbi àtẹ ìwé náà. Wọ́n wá bá a jíròrò ohun tó wà nínú ìwé Éfésù 5:3. Obìnrin náà àtàwọn Ẹlẹ́rìí yẹn gba nọ́ńbà fóònù ara wọn. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì, obìnrin náà pè, ó sì sọ pé: “Mi ò fi bẹ́ẹ̀ gba tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Síbẹ̀, mo ka ìwé yẹn, mo sì gbádùn ẹ̀ gan-an. Ó ti jẹ́ kí n lè yanjú àwọn ìṣòro kan láàárín èmi àti ọkọ mi, mo sì tún ti ran àwọn tọkọtaya méjì míì lọ́wọ́. Mo ti wá rí i pé èrò tí kò tọ́ ni mo ní sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ́lẹ̀. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Ní báyìí, wọ́n ti ń kọ́ obìnrin yìí àti ọ̀kan nínú àwọn tọkọtaya tó ràn lọ́wọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Ó Túmọ̀ Ìwé tí Wọ́n Fún Un sí Èdè Míì

Ankasie jẹ́ ìlú kékeré kan lórílẹ̀-èdè Gánà. Àwọn ọlọ́jà kan máa ń to ọjà wọn sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì máa ń pàtẹ ìwé wọn ní gbogbo ọjọ́ Monday, síbi térò máa ń gbà. Lọ́jọ́ kan, arákùnrin kan tó ń jẹ́ Samuel wàásù fún ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Enoch, ó sì gba ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run. Enoch wá bi Samuel bóyá ó ní ìwé kankan lédè Kusaal.

Gánà: Ó túmọ̀ ìwé tí wọ́n fún un sí èdè Kusaal

 Samuel fèsì pé: “Máà bínú, a ò ní. Àmọ́ a ní ìwé lédè Frafra,” ìyẹn èdè kan tó jọ èdè Kusaal. Kí Enoch tó pa dà síbi tó ti wá ní apá àríwá lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún, ó ní kí wọ́n fún òun níwèé sí i kóun lè pín in fún àwọn mọ̀lẹ́bí òun.

Nígbà tó pa dà wá sílùú Ankasie, ó fún Samuel níwèé kan. Àṣé Enoch ti túmọ̀ ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run sí èdè Kusaal! Ó ti ń lọ sípàdé dáadáa, ó sì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé.